Ẹ̀rọ Ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS (Fídíò)

Kíni àwọn ìgbìrò ohun tí a fẹ́ láti wo àwọn ohun tó wà nínú fídíò pẹ̀lú Ẹ̀rọ Ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS?

O gbọ́dọ̀ ní ọ̀kan lára àwọn bráósà ayélujára àti àwọn ẹdàya Flash tí a gbé sórí ẹ̀rọ kọ̀mpútà rẹ.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́: Tí flásh rẹ bá ńjá ṣá, jọ̀wọ́ sọ ohun èlò to nmú flash tètè nṣiṣẹ́ di aláìlágbara. Èyí gbọ́dọ̀ dá jíjá náà dúró kí ó sì fáyègba àtúnwò fídíò náà láti tẹ̀síwájú. Jọ̀wọ́ wo àwọn àṣẹ náà lórí bí o ó ṣe ṣe èyí.

PC Fèrèsé

Mac

Bráósà

  • ààbò irin
  • Firefox 3.0.1 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ
  • Ìwákiri 6 SP1 Ẹ̀rọ Ayélujára
  • Ìwákiri 7 Ẹ̀rọ Ayélujára
  • Ìwákiri 8 Ẹ̀rọ Ayélujára
  • Sàfárì 3.2.2 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ
  • Sàfárì 4 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ
  • ààbò irin
  • Firefox 3.0.1 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ
  • Sàfárì 3.2.2 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ
  • Sàfárì 4 tàbí gígajùbẹ́ẹ̀ lọ

Flash

  • Ẹ̀rọ Ìgbàlódé kẹ́wá ti Flash
  • Ẹ̀rọ Ìgbàlódé kẹ́wá ti Flash

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́: Àwọn wàhálà wà tí a mọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dàya Flash 10.1.85.3. Jọ̀wọ́ gbé ipò rẹ̀ sókè sí ẹ̀dàya Flash ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde tí o bá ní ìrírí àwọn wàhálà láti wo àwọn ohun tó wà nínú fídíò pẹ̀lú Ẹ̀rọ Ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS.

Bákanáà a ti kíyèsí ọ̀ràn kan pẹ̀lú iOS 4.3x Lẹ́hìnnáa títẹ bọ́tìnì ìṣiṣẹ́, jọ̀wọ́ dúró fún ìṣẹ́jú akàn díẹ̀ nígbàtí ó ńkórajọ àti pé nígbànáà ó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́. Nígbàtí ó bá ńkórajọ, jọ̀wọ́ máṣe tẹ̀ bọ́tìnì ìṣiṣẹ́ tàárín lẹ́ẹ̀kansi tàbí ọ̀kan tí yíò fara hàn ní igun náà. Èyí kàn má a nṣẹlẹ̀ ni 4.3x


Kínìdí tí fídíò fi máa ńfìgbàmíràn kálòlò tàbí dúró ní àkókò íṣiṣẹ́ padà sẹ́hìn?

Fídíò lè kálòlò tàbí dúró ní àkókò íṣiṣẹ́ padà sẹ́hìn tí sísopọ̀ Ayélujára rẹ kò bá yára tó tàbí tí ẹ̀rọ ayárabíàṣá rẹ bá ní àìfi ìgbàkúgbà lọ́ra ní ṣíṣe tàbí RAM kékeré (ìrántí). Àní lórí àwọn ísopọ̀ èdìdígbòòrò, ìkúndétí Ẹ̀rọ̀ Ayélujára tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe lè jásí ìgéwẹ́wẹ́ íṣiṣẹ́ padà sẹ́hìn tàbí títún ààbò lórí ìṣòro ṣe.

Báwo ni mo ṣe lè ṣàbápín ìsopọ̀ kan sí fídíò pàtàkì kan lọ́tọ̀?

Lo Fídíò Pípín tàbí Gba Ìsopọ̀ àwọn ìyàn látinú ìyíkálórí ìdárúkọ àwọn bọ́tìnì lórí ẹ̀rọ ìgbàlodé náà. O lè ṣe ẹ̀dà ìsopọ̀ kí o sì lẹ̀ẹ́ mọ́ ọ̀rọ̀ ayélujára kan tàbí ojú ewé wẹ́ẹ̀bù.

Kíni “Gba ẹ̀là” ńṣe?

Ìyàn Gbígba ẹ̀là náà ńfàyè gbà ọ láti ṣe ẹ̀dà ẹ̀là wíwàninú ti HTML fún ẹ̀rọ ìgbàlódé kan kí o sì lẹ̀ẹ́ mọ́ ojú ewé wẹ́ẹ̀bù rẹ. O lè lo ìyàn yí láti mú Ẹ̀rọ Ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS jẹ́ apákan ti ojú ewé wẹ́ẹ̀bù rẹ.

Ẹ̀rọ Ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS ńfi ìkìlọ̀ kan hàn tí ó ńsọ pé mo nílò láti mú Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Flash dára si. Báwo ni mo ṣe lè mu dára si?

Ẹ̀rọ ìgbàlódé ti Ohun èlò náà yíò gbé ọ̀rọ̀ kan síta tí ó rí bíi èyí:

O lè tẹ orí ọ̀rọ̀ náà láti gba ẹ̀dà Ẹ̀rọ ìgbàlódé Flash tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, láti ọ̀dọ̀ Adobe.

Ẹ̀rọ ìgbàlódé ti Ohun èlò LDS kò gbé nkan síta pérépéré tàbí ó ńgbé fídíò tí a kò fẹ́ síta. Báwo ni mo ṣe lè tún èyí ṣe?

Bráósà wẹ́ẹ̀bù rẹ lè máa gbé ìwífúnni tí ó wà ní ìpamọ́ (tàbí tí o ti pẹ́) síta. Láti yọ àwọn nkan tó wà ní ìpamọ nínú bráósà rẹ kúrò kí o sì rí ẹ̀dàyà ojú ewé tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé èyítí o wà lórí rẹ̀, tẹ CTRL + F5 fún àwọn Fèrèsé tàbíCOMMAND + SHIFT + R fún Mac.

Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Ohun Èlò Àwọn Fèrèsé (Fídíò tàbí Gbígbọ́ Nìkan)

ChurchofJesusChrist.org ńlo Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Ohun Èlò Àwọn Fèrèsé láti ọ̀dọ̀ Mícrosoft láti pèsè fídíò àti àwọn ohun gbígbọ́. Láti wòó tàbí fetísí fídíò tàbí ohun gbígbọ́ náà, ìwọ yíò níláti fi Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Ohun Èlò Àwọn Fèrèsé sórí kọ̀mpútà rẹ tí o kò bá tíì ni tẹ́lẹ̀.

Láti lè mọ̀ bóyá o ní tàbí o kò ní Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Ohun Èlò Àwọn Fèrèsé lórí kọ̀mpútà rẹ, tẹ ìdánwò Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Ohun Èlò Àwọn Fèrèsé Tí fèrèsé kékeré kan bá jáde wá tí o sì ńgbọ́ ohùn, o ti ní ẹ̀rọ Ẹ̀rọ Ìgbàlódé náà. Tí bráósà rẹ bá fihàn pé o kò ní ìtẹ̀-sínú tàbí olùrànlọ́wọ́ ìfisí tí a kò lè ṣe aláìní, nígbànáà o lè mú Ẹrọ Ìgbàlódé Ohun Èlò àwọn fèrèsé kalẹ̀ ní ọ̀fẹ́