2018
Bí A Ṣe Nlọ Síwájú Papọ̀
April 2018


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹrin 2018

Bí A Ṣe Nlọ Síwájú Papọ̀

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, mo ní ìrẹ̀lẹ̀ láti wà pẹ̀lú yín ní àárọ̀ yí. Ọjọ́ mẹ́rin sẹ́hìn a tẹ́ akínkanjú ọkùnrin nlá kan sí ibi ìsinmi, wòlíì Ọlọ́run kan—Ààrẹ̀ Thomas S. Monson. Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè ṣe ìdáláre tó sí ohun nlá àti ọlọ́lá ti ìgbe ayé rẹ̀ jẹ́. Èmi ó máa ṣe ìkẹ́ ìbáṣọ̀rẹ́ wa títíláé pẹ̀lú ìmoore fún ohun tí ó kọ́ mi. Nísisìyí a gbọ́dọ̀ wo iwájú sí ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù Krístì, ẹnití Ìjọ yí i ṣe tirẹ̀.

Ọjọ́ méjì sẹ́hìn gbogbo àwọn Àpọ́stélì alààyè pàdé nínú yàrà òkè ti Tẹ́mpìlì Salt Lake. Níbẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìpinnu ìfohùnṣọkan, àkọ́kọ́, láti tún Àjọ Ààrẹ Ìkínní tò nísisìnyí àti, ìkejì, pé kí èmi sìn bí Ààrẹ Ìjọ. Àwọn ọ̀rọ̀ kò kún ojú òsùnwọ̀n tó láti sọ fún yín bí ìmọ̀lára náà ti rí láti ní kí àwọn arákùnrin mi—àwọn Arákùnrin tí wọ́n di gbogbo kọ́kọ́rọ́ oye-àlùfáà mú tí a mú padàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith ní àkókò yí—gbé ọwọ́ wọn lé mi lórí láti yàmí sí mímọ́ àti láti yàmí sọ́tọ̀ bíi Ààrẹ Ìjọ. Ó jẹ́ ìrírí mímọ́ àti rírẹnisílẹ̀ kan.

Ó di ojúṣe mi nígbànáà láti ṣe ìdámọ̀ ẹnití Olúwa ti pèsè sílẹ̀ láti jẹ́ àwọn olùdámọ̀ràn mi. Báwo ni mo ṣe lè yan méjì péré lára àwọn Àpọ́stélì méjìlá míràn, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹnití mo nífẹ̀ẹ́ dáradára? Mo ní ìmoore tó jinlẹ̀ sí Olúwa fún dídáhùn àdúrà kárakára mi. Mo dúpẹ́ gidigidi pé Ààrẹ Dallin Harris Oaks àti Ààrẹ Henry Bennion Eyringṣetán láti sìn pẹ̀lú mi bí Olùdámọ̀ràn kínní àti ìkejì, bí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn. Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf ti gba ipò rẹ̀ padà nínú Iyejú àwọn Àpọ́stélì méjìlá. Ó ti gba àwọn ìfiṣẹ́lenilọ́wọ́ pàtàkì àwọn èyí tí ó yege fún ní àrà ọ̀tọ̀.

Mo kan sárá sí òun àti sí Ààrẹ Eyring fún iṣẹ́ ìsìn ọlánlá bí àwọn Olùdámọ̀ràn sí Ààrẹ Monson. Wọ́n ti jẹ́ ẹnití ókún ojú ìwọ̀n, olùfọkànsìn, àti ẹni ìmísí pátápátá. A fi ìmoore hàn gidigidi fún wọn. Olukúlùkù ṣetán láti sìn nísisìnyí ní ibi tí a ti nílò wọn jùlọ.

Bí Àpọ́stélì tí ó jẹ́ ẹnìkejì ní ipò àgbà, Ààrẹ Oaks bákannáà di Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí ìpè rẹ̀ sí Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti ní ìbámu pẹ̀lú ètò Ìjọ, Ààrẹ M. Russell Ballard, tí ó tẹ̀lé ní ipò àgbà, yíò sìn bí Aṣojú Ààrẹ ti Iyejú náà. Àjọ Ààrẹ̀ Ìkínní yíò ṣíṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn Méjìlá láti dáìfẹ́ Olúwa mọ̀ àti láti ti iṣẹ́ mímọ́ rẹ̀ síwájú.

A dúpẹ́ fún àwọn àdúrà yín. Wọ́n ti jẹ́ gbígbà jákèjádò àgbáyé fún wa. Ní àárọ̀ tí ó tẹ̀lé ikú Ààrẹ Monson, irú àdúrà bẹ́ẹ̀ jẹ́ gbígbà láti ẹnu ọmọdékùnrin ọmọ ọdún mẹ́rin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Benson. Mo ṣe àyọsọ láti inú lẹ́ta tí ìyá rẹ̀ kọ sí ìyàwó mi, Wendy. Benson gbàdúrà, “Bàbá Ọ̀run, e ṣé pé Ààrẹ Thomas S. Monson yíò rí ìyàwó rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi. E ṣe fún Wòlíì wa tuntun. Ẹ ràn án lọ́wọ́ láti ní ìgboyà àti láti máṣe bẹ̀rù pé òun jẹ́ tuntun. Ẹ ràn án lọ́wọ́ láti dàgbà sókè láti ní ìlera àti okun. Ẹràn án lọ́wọ́ láti ní agbára nítorí ó ní oyè-àlùfáà. Kí ẹ sì ràn wá lọ́wọ́ nígbàgbogbo láti jẹ́ rere.”

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọdé bí èyí àti fún àwọn òbí tí wọ́n tẹramọ́ ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wọn sí òdodo, ipò-òbí àfọkànṣe—fún gbogbo òbí, olùkọ́, àti ọmọ ìjọ tí wọ́n nru ẹ̀rù wúwo àti síbẹ̀síbẹ̀ tí wọ́n nfi tìfẹ́tìfẹ́ sìn. Ní ọ̀nà míràn, fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín, mo fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ dúpẹ́.

Olúwa wà ní Ìdarí

Bí a ṣe nlọ síwájú papọ̀, mo pè yín láti ronú nípa irú ọlánlá nípa èyí tí Olúwa ndarí Ìjọ Rẹ̀. Nígbàtí Ààrẹ Ìjọ kan bá kọjá lọ, kò sí ohun àìmọ̀ kankan nípa ẹni tí a ó pè tẹ̀le láti sìn ní ipò náà. Kò sí ìdìbò, kò sí ìpolongo, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ṣíṣé jẹ́jẹ́ ti ètò ìyípòpadà àtọ̀runwá, tí a gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa Fúnrarẹ̀.

Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti iṣẹ́ ìsìn Àpọ́stélì kan jẹ́ ọjọ́ ikẹ́kọ̀ọ́ kan àti mímurasílẹ̀ fún ojúṣe tí ó pọ̀ síi ní ọjọ́ ọ̀la. O gba ọ̀pọ̀ ọdún ti iṣẹ́ ìsìn fún Àpọ́stélì kan láti kúrò ní àga kékeré lọ sí àga àgbà ní àyíká náà. Ní ààrin àkókò náà, òun njèrè ìrírí ojú ẹ̀sẹ̀ ní abala kọ̀ọ̀kanti iṣẹ́ ìjọ. Bákannáà ó di olùbárìn dáadáa pẹ̀lú àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àwọn ìwé ìtàn wọn, àwọn àṣà, àwọn èdè bí ìfiṣẹ́lénilọ́wọ́ ṣe nmú un lọ léraléra káàkiri àgbáyé. Ètò ìyípòpadà yí níṣíṣe olórí Ìjọ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Èmi ko mọ nípa ohunkóhun míràn bíi rẹ̀. Èyí kò gbọ́dọ̀ yà wá lẹnu, nítorí èyí ni Ìjọ Olúwa. Òun kìí ṣe iṣẹ́ bíi irú ti àwọn ènìyàn.

Mo ti sìn nínú Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá lábẹ́ àwọn Ààrẹ̀ ti Ìjọ marun sẹ́hìn. Mo ti wo Ààrẹ kọ̀ọ̀kan bí wọ́n ti ngba ìfihàn àti bí wọ́n ti nfèsì sí ìfihàn náà. Olúwa ti fi ìgbàgbogbo, yíò sì máa fi ìgbàgbogbo kọ́ àti mísí àwọn wòlíì Rẹ̀. Olúwa wà ní ìdarí Àwa tí a ti yàn láti jẹ́ ẹ̀rí orúkọ mímọ́ Rẹ̀ jákèjádò àgbáyé yíò tẹ̀síwájú láti lépa láti mọ ìfẹ́ Rẹ̀ àti láti tẹ̀le e.

Dúró ní Ipá Ọ̀nà Májẹ̀mú

Nísisìnyí, sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ Ìjọ mo sọ pé, ẹ tẹramọ́ ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ yín láti tẹ̀lé Olùgbàlà nípa dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì mọ́ yíò ṣí ilẹ̀kùn sí gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí àti ànfàní tí ó wà fùn àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé níbigbogbo.

Bí Àjọ Ààrẹ tuntun, a fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òpin ní inú ọkàn wa. Fún ìdí èyí, à nbá yín sọ̀rọ̀ ní òní láti inú tẹ́mpìlì kan. Òpin fún èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa ntiraka ni láti gba ẹ̀bùn agbára nínú ilé Olúwa, láti ní ìsopọ̀ bí ẹbí, láti jẹ́olõtọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì tí ó mú wa yege fún ẹ̀bùn nlá ti Ọlọ́run—ti ìyè ayérayé. Àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá níbẹ̀ jẹ́ kókó sí ìfùnlókun ìgbé ayé yín, ìgbéyàwó àti ẹbí yín, àti agbára yín láti tako àwọn ìjà èṣù. Ìjọ́sìn yín nínù tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìsìn yín níbẹ̀ fún àwọn bàbánlá yín yíò bùkún yín pẹ̀lú ìfihàn araẹni púpọ̀ síi àti àláfíà yíò sì dà ààbò bo ìfẹsẹ̀múlẹ̀ yín láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Nísisìnyí, tí ẹ bá ti yẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà náà, njẹ́ kí npè yín pẹ̀lú gbogbo ìrètí tí ó wà ní ọ̀kàn mi láti jọ̀wọ́ padà wá. Èyíkèyí àníyàn yín, èyíkèyí ìpènijà yín, ìbì kan wà fún yín nínú Ìjọ Olúwa yí. Ẹ̀yin àti àwọn ìràn tí a kò tíì bí yíò di alábùkún fún nípa àwọn ìṣe yín nísisìnyí láti padà sí ipá ọ̀nà májẹ̀mú Bàbá wa ní Ọ̀run nṣìkẹ́ àwọn ọmọ Rẹ̀, Ó sì fẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa pada sílé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Èyí ni àṣekágbá àfojúsí kan ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn—láti ran ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti padà wá sílé.

Mo fi ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ mi hàn fún yín—ìfẹ́ tí ó ti dàgbà lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti pípádé yín, jíjọ́sìn pẹ̀lú yín, àti sísìn yín. Àṣẹ àtọ̀runwá wa ni láti lọ sí gbogbo orílẹ̀ èdè, ìbátàn, èdè, àti ènìyàn, ní ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa. Èyí ni a ó ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì, ní mímọ̀ pé Òun wà ní àmójútó. Èyí ni iṣẹ́ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀. Àwa ni Ìránṣẹ́ Rẹ̀.

Mo kéde ìfọkànsìn mi sí Ọlọ́run Bàbá wa Ayérayé àti sí Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Mo mọ̀ Wọ́n, mo ní ìfẹ́ Wọn, mo sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn Wọ́n—àti ẹ̀yin—pẹ̀lú gbogbo èémí tí ó kù nínú ayé mi. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín