2018
Àwọn Ohun Marun Tí Olùfetísílẹ̀ Rere Nṣe
June 2018


Àwòrán
Two young women talking

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2018

Àwọn Ohun Marun Tí Olùfetísílẹ̀ Rere Nṣe

Fífetísílẹ̀ ní tòótọ́ yíò ràn yín lọ́wọ́ láti bá àìní ti ẹ̀mí àti ti ara àwọn ẹlòmíràn pàdé bí Olùgbàlà yíò ti ṣe.

Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Apọ́stélì Méjìlá wípé: Àní bóyá fífetísílẹ̀ ṣe pàtàkì ju sísọ̀rọ̀ lọ. … Tí a bá fi etísílẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́, a kò ní nílò láti ronú ohun tí a ó sọ. A ó fifún wa—nípasẹ̀ Ẹ̀mí.”1

Fifetísílẹ̀ jẹ́ iṣe mímọ̀ọ́ṣe kan tí a lè kọ́. Fífetísílẹ̀ nfi ifẹ́ wa fún àwọn ẹlòmíràn hàn, ó nṣèrànwọ́ láti gbè lílókun ìbáṣepọ̀ ga, ó sì npe Ẹ̀mí láti bùkún wa pẹ̀lú ẹ̀bùn òye láti rànwá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ àìní àwọn ẹlòmíràn.2 Níhín ni àwọn ọ̀nà marun ti a fi lè gbèrú sí nínú bi a ṣe nfetísílẹ̀.

1. Fún Wọn ní Àkókò

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nílò àkókò láti kó àwọn èrò wọn papọ̀ ṣíwájú sísọ̀rọ̀. Fún wọn ní àkókò láti ronú ṣíwájú àti lẹ́hìn tí wọn ti sọ ohun kan (wo James 1:19). Nítorí wọ́n ti sọ̀rọ̀ tán kò túmọ̀ sí pé wọ́n ti sọ gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti sọ. Maṣe bẹ̀rù ìdákẹ́ (wo Jóbù 2:11–3:1 àti Álmà 18:14–16).

2. Fi Etísílẹ̀

À nronú kíákíá ju bí àwọn míràn ti nsọ̀rọ̀ lọ. Kọ ìdánwò láti dédé ro ìparí tàbí ronú ṣaájú sí ohun tí ẹ̀yin yíò sọ nígbàtí wọ́n bá ṣetán (wo Àwọn Ìwé Òwe 18:13). Dípò bẹ́ẹ̀, fí etí sílẹ̀ pẹ̀lú èrò inú láti ní ìmọ́. Ìfèsì yín yíò dárajù nítorí yíò ní ìwífúnni nípasẹ̀ ìmọ̀ gígajù.

3. Sọ àsọyé kedere

Máṣe bẹ̀rù láti bèèrè ìbèèrè tí yíò fí àwọn ohun kan hàn kedere tí ẹ kò ní òye (wo Mark 9:32). Fífi hàn kedere nṣe àdínku èdè àìyédè ó sì nfi ìfẹ́ yín nínú ohun tí wọ́n nsọ hàn.

4. Ṣe àtúnrò

Ẹ tún ohun tí ẹ gbọ́ sọ àti bí ẹ ṣe ní ìmọ̀ irú ìmọ̀lára tí ẹlòmíràn ní. Èyí nràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ tí ọ̀rọ̀ wọ́n bá yéni a sì fún wọn ní ànfàní kan láti sọ àsọyé kedere.

5. Wá ìbáramu

Ẹ lè má faramọ́ gbogbo ohun tí wọ́n sọ, ṣùgbọ́n ẹ faramọ́ ohun tí ẹ lè ṣe láì ṣi àwọn ìmọ̀lára tiyín mọ̀. Níní ìfaramọ́ lè rànwá lọ́wọ́ láti yanjú àníyàn àti dídojúkọ àtakò (wo Matthew 5:25).

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé a gbọ́dọ̀ “kọ́ láti fetísílẹ̀, àti kí á fetísílẹ̀ láti kẹkọ láti ọ̀dọ̀ ara wa.”3 Bí ẹ ṣe nfetísílẹ̀ pẹ̀lú èrò inú ti kíkọ́ nípa àwọn ẹlòmíràn, ẹ ó wà ní ipò dídárajù láti ní ìmọ̀ àwọn àìní wọn àti láti gbọ́ àwọn ìṣílétí nípa bí ẹ̀yin yíò ti lè ṣe tójú àwọn wọnnì ní àyíká yín gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà yíò ti ṣe.

Fífietísílẹ̀ Ni Fífẹ́nì

Ìtàn kan láti ẹnu Alàgbà Holland júwe agbára fífietísílẹ̀:

“Ọ̀rẹ́ mi Troy Russell gbé ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀ jáde díẹ̀díẹ̀ kúrò ní gárájì rẹ. … Ó ní ìmọ̀lára pé táyà ẹhìn rẹ̀ gun orí òkè kékeré kan. … O jáde ṣùgbọ́n láti rii pé ọmọdékùnrin iyebíye rẹ̀ ọmọ ọdún mẹsan , Austen, dubùlẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀ lórí pèpéle. … Austen ti kú.

“Láìlè sùn, láì ní àláfíà, Troy kò ṣeé parọwà sí. … Ṣùgbọ́n nínú ìrora náà ni … John Manning wá. …

“Èmi kò mọ nítòótọ́ lórí ohun tí John àti ojúgbà rẹ̀ kékeré ṣe wá sí ilé Russell fún ìbẹ̀wò. … Ohun tí mo mọ̀ ni pé ní ìgbà ìrúwé tó kọjá Arákùnrin Manning wá ó sì gbe Troy Russell sókè láti inú àjálù tí ọ̀nà ọkọ̀ náà bíi pé ó ngbé Auten kékeré fúnrarẹ̀. Bíi ti … arákùnrin nínú ìhìnrere tí ó yẹ kí ó jẹ́, John fi ìrọ̀rùn gba fífi oyèàlùfáà ṣe ìtọ́jú àti pípa Troy Russell mọ́. O bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ wípé, “Troy, Austen nfẹ́ kí ó padà lórí ẹsẹ̀ rẹ—pẹ̀lú ilé bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá—nítorináà èmi yíò wà nihin ní àrààárọ̀ ní aago marun kọjá ìṣẹ́jú mẹẹdogun. Wà ní síṣetán. …’

“‘Èmi ko fẹ́ láti lọ,’ Troy sọ fún mi lẹ́hìnnáà, nítorí mo máa nmú Austen lọ pẹ̀lú mi nígbàgbogbo. … Ṣùgbọ́n Johánnù ṣe àtẹnumọ, nítorínáà mo lọ, Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ náà wá sẹ́hìn, a sọ̀rọ̀—tàbí bóyá mo sọ̀rọ̀ àti pé Jòhánù fetísílẹ̀. … Ní àkọ́kọ́ ó ṣòro, ṣùgbọ́n ní ẹ̀hìn ìgbà díẹ mo ri pé mo ti rí okun mi nínú àra [John Manning], ẹnití ó fẹ́ràn mi tí ó sì nfetísílẹ̀ sí mi títí tí òòrùn fi tàn lẹ́ẹ̀kansi ní ilé ayé mi nígbẹ̀hìn.’”4

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Jeffrey R. Holland, “Witnesses unto Me,” Liahona, July 2001, 16.

  2. See David A. Bednar, in “Panel Discussion” (worldwide leadership training meeting, Nov. 2010), broadcasts.lds.org.

  3. Russell M. Nelson, “Listen to Learn,” Ensign, May 1991, 23.

  4. Jeffrey R. Holland, “Emissaries to the Church,” Liahona, Nov. 2016, 62, 67.