2018
Nawọ́ jáde nínú Àánú
Oṣù Keje 2018


Àwòrán
Ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2018

Nawọ́ jáde nínú Àánú

Bí ẹ ṣe ntẹ̀lé àpẹrẹ àánú ti Olùgbàlà, ẹ ó ri pé ẹ lè mu ìyàtọ́ wá nínú ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn.

Àánú ni níní ìfura ìrora àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìfẹ́ láti mú u fúyẹ́ tàbí tura. Májẹ̀mú kan láti tẹ̀lé Olùgbàlà ni májẹ̀mú àánú kan láti “bá ara wa gbé àjàgà” (Mosiah 18:8). Ìfúnni-niṣẹ́ṣe kan láti bojútó àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Olúwa yío ti ṣe: pẹ̀lú “àánú, ní mímú iyàtọ́ wá” (Jude 1:22). Olúwa pàṣẹ, “Ẹ ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀” (Zechariah 7:9).

Àánú Olùgbàlà

Àánú ni kókó ìdarí nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà (wo ẹ̀gbẹ́-ìlà: “Olùgbàlà Alãnú kan) Aánú Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀ mu U nawọ́ jáde sí àwọn wọnnì ní àyíká Rẹ̀ ní àìmọye ìgbà. Ní mímòye àwọn àìní àti ìfẹ́ inú àwọn ènìyàn, O le bùkún fún wọn, kí ó sì kọ́ wọn ní àwọn ọ̀nà tí ó kanpá sí wọn jùlọ. Ìfẹ́ inú Olùgbàlà láti gbé wa sókè kọjá ìrora wa darí sí ìṣe ìgbẹ̀hìn ti àánú: Ètùtù Rẹ̀ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà ti gbogbo aráyé.

Agbara Rẹ̀ láti fèsì sí àìní àwọn ènìyàn ni ohun kan tí a lè tiraka fún bí a ṣe nsìn. Bí a ṣe ngbé ìgbé ayé òdodo tí a sì nfi etí sílẹ̀ sí àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí, a ó gba ìmísí láti nawọ́ jáde ní àwọn ọ̀nà tí ó ní ìtumọ̀.

Májẹ̀mú Àánú Wa

Bàbá Ọ̀run nfẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ alãnú (wo 1 Corinthians 12:25–27). Láti di ọmọẹ̀hìn tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbèrú si kí a sì fi àánú hàn sí àwọn ẹlòmíràn, nípàtàkì sí àwọn wọnnì nínú àìní (D&C 52:40).

Gbígba orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa nípa májẹ̀mú ìrìbọmi wa, a jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ìfẹ́ láti ṣe àánú. Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, kọ́ni pé ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀: “Ìwọ ni ọmọ ìjọ májẹ̀mú ti Ìjọ Jésù Krístì. …

“Èyínnì ni ìdí tí ẹ fi nní ìmọ̀lára láti fẹ́ láti ṣe ìranlọ́wọ́ fún ẹnìkan tí ó ntiraka láti sún síwájú ní abẹ́ ẹrù ìbànújẹ́ àti ìṣòrò. Ẹ ṣe ìlérí pé ẹ ó ran Olúwa lọ́wọ́ láti mú àjàgà [àwọn ẹlòmíràn] fúyẹ́ kí wọ́n sí ní ìtùnú. A fún un yín ní agbára láti ṣe ìranlọ́wọ́ mú àwọn ẹrù wọnnì fúyẹ́ nígbàtí ẹ gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.”1

Fún àpẹrẹ, arábìnrin kan ní Russia ní ìṣòrò ipò ẹbí tí ó dènà rẹ̀ láti lọ sí ilé ìjọsìn fún ọdún kan ó lé. Arábìnrin míràn ní ẹ̀ka náà nawọ́ jáde nínú àánú lọ́jọọjọ́ Ìsinmi nípa pípè é láti sọ fún un nípa àwọn ọ̀rọ̀, àwọn ẹ̀kọ́, àwọn ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́, àwọn ọmọ tí a bí, àti àwọn ìròhìn míràn ní ẹ̀ká. Nígbàtí ipò ẹbí arábìnrin tí ó ti wà nínú ilé náà yanjú tán, ó ní ìmọ̀lára bíìpé òun ṣì jẹ́ apákan ẹ̀ká náà nítorí ìpè ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Henry B. Eyring, “Olùtùnú Náà,” Liahona, May 2015, 18.