2018
Mímú Àwọn Ìbáṣepọ̀ tí ó Nítumọ̀ Dàgbà sóké
August 2018


Àwòrán
Ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹ́jọ 2018

Mímú Àwọn Ìbáṣepọ̀ tí ó Nítumọ̀ Dàgbà sóké

Agbára wa láti ṣe ìtọ́jú àwọn ẹlómíràn npọ̀si nígbàtí a bá ní ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ pẹ̀lú wọn.

Ìfipè láti ṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ànfàní kan láti mú àwọn ìbáṣepọ̀ onítọ̀ọ́jú dàgbàsókè pẹ̀lú wọn—irú ìbáṣepọ̀ tí yíò rọ̀ wọ́n lọ́rùn ní bíbèèrè fún tàbí ní títẹ́wọ́gba ìrànlọ́wọ́ wa. Nígbàtí a bá ti tiraka láti mú irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ gbèrú, Ọlọ́run ní agbára láti yí ìgbé ayè padà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìbáṣepọ̀ náà.

“Nítòótọ́ mo gbàgbọ́ pé kò sí ìyípadà pàtàkì kankan láìsí àwọn ìbáṣepọ̀ pàtàkì,” ni Sharon Eubank sọ, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Àti pé fún àwọn ìṣe iṣẹ́ ìsìn wa láti jẹ́ olùyínipadà nínú ayé àwọn ẹlòmíràn, ó sọ pé, wọ́n gbọ́dọ̀ “ní gbòngbò nínú ìfẹ́ òdodo láti wòsàn àti láti fetísílẹ̀ àti láti fọwọ́-sowọ́pọ̀ àti láti bọ̀wọ̀ fún.”1

Àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ kìí ṣe àwọn àlùmọ̀kọ́rọ́yí. Wọ̀n dá lé orí àánú, àwọn ìtiraka tòótọ́, àti “ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn” (D&C 121:41).2

Àwọn ọ̀nà láti Ṣe Ìmúdàgbà àti Ìfúnlókun Àwọn Ìbáṣepọ̀

“À nmú [àwọn ìbáṣepọ̀]dàgbà sókè, ẹnìkan ní àkókò kan,” ni Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ.3 Bi a ṣe nlàkàkà láti mú àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ dàgbàsókè pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí, Ẹ̀mí Mímọ́ lè tọ́ wá sọ́nà. Àwọn àbá wọ̀nyí dá lórí àwòṣe kan tí Alàgbà Uchtdorf fúnni.4

  • Kọ́ nípa wọn.

    Ààrẹ Ezra Taft Benson (1899-1994) kọ́ni, “Ẹ kò lè sìn wọ́n dáadáa àwọn wọ̀nni tí ẹ kò mọ̀ dáadáa.” O dá àbá mímọ àwọn orúkọ ìkọ̀ọ̀kan ọmọ ẹbí àti mímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bíi ọjọ́ ìbí, àwọn ìbùkún, àwọn ìrìbomi, àti àwọn ìgbeyàwó. Èyí npèsè ànfàní láti kọ àkọsílẹ̀ ránpẹ́ kan tàbí ṣe ìpè kan láti kí ọmọ ẹbí kan kú oríre lórí aṣeyege kan tàbí àṣeyọrí .5

  • Lo àkokò papọ̀.

    Ìbáṣepọ̀ máa ngba àkokò láti mú gbèrú. Wá àyè fún àwọn ànfàní láti rí wọn déédé. Àwọn àṣàrò ṣíṣe fi hàn pé jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé ẹ̀ nṣe àníyàn jẹ́ pàtàkì sí ìlera àwọn ìbáṣepọ̀.6 Ẹ ṣe àbẹwò nígbà gbogbo sí àwọn wọnnì tí a pè yín láti sìn. Ẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ilé ìjọsìn. Lo àfikún eyikeyi tí ó fa ọgbọ́n yọ—bíi ìfiwéránṣẹ́ ayélujára, Fesibúùkù, Ínsítágrámù, Twííítà, Síkáìpù, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, tàbí fifi káàdì kan ránṣẹ́. Alàgbà Richard G. Scott (1928-2015) ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ̀rọ̀ nípa agbára fífi ìfẹ́ àti àtìlẹ̀hìn hàn ní ìrẹ̀lẹ̀ àti àtọwọ́dá: “Nígbà gbogbo èmi yíò ṣí àwọn ìwé mímọ́ mi, … èmi yíò sì rí àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìfìfẹ́hàn àti ìtinilẹ́hìn kan tí [ìyàwó mi] Jeanene ti fi há inú àwọn ojú-ewé. … Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́ oníyebíye wọ̀nnì … tẹ̀síwájú láti jẹ́ ìṣura àìdíyelé ti ìtùnú àti ìmísí.”7

    Bákannáà, ẹ rántí pé ìbáṣepọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ẹni méji. Ẹ lè fi ìfẹ́ àti ìbáṣọ̀rẹ́ fúnni, ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ náà kò ní dàgbà àyàfi tí ìfifúnni náà bá jẹ́ títẹ́wọ́gbà àti dídápadà. Bí ẹni kejì bá dàbí ẹnipé kò fẹ́ gbà, máṣe fi tipátipá ṣe ìbáṣọ̀rẹ́ náà. Ẹ fún ọkùnrin tàbí obìnrin náà ní àkókò láti rí àwọn ìtiraka yín tòótọ́, bí ó bá sì ṣe pàtàkì, ẹ dámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn olórí yín nípa boyá ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ ṣì dàbíí ohun tí ó ṣeéṣe tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.

  • Bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ṣíṣe ìtọ́jú.

    Mímu àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ dàgbàsókè nfẹ́ kí a lọ kọjá àṣehàn. Àwọn ìbánisọ̀rọ̀ aláṣehàn kún fún ọ̀rọ̀ sísọ kékèké nípa ìṣètò, ojú ọjọ́, àti awọ̀n ìṣẹ̀lẹ̀ míràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n kò sí ṣíṣé àbápín àwọn ìmọ̀ara, àwọn ìgbàgbọ́, àwọn àfojúsùn, àti àwọn àníyàn tí ó ṣe dandan láti mú àwọn ìfarakọ́ra tí ó nítumọ̀ pọ̀ si. Bàbá Ọ̀run ti ṣe àfihàn ìrú ìbánisọ̀rọ̀ tí ó nítumọ̀ síi yí nípa ṣíṣe àbápín àwọn ìmọ̀lára àti àwọn ètò Rẹ̀ pẹ̀lú Ọmọ Rẹ̀ (wo John 5:20) àti pẹ̀lú wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ (wo Amos 3:7). Nípa ṣíṣe àbápín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́-dé-ọjọ́ àti àwọn ìpèníjá ti ìgbé ayé pẹ̀lú ara wa bí Ẹ̀mí bá ṣe tọ́wasọ́nà, a njèrè ìmọyì fún ara wa bí a ṣe nrí àwọn ohun tí a jùmọ̀ ní ìfé sí tí a sì nṣe àbápín àwọn ìrírí.

    Fífi etí sílẹ̀ jẹ́ apákan bíbánisọ̀rọ̀ pé ẹ̀ nṣe ìtọ́jú.8 Nígbàtí ẹ bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fi etí sílẹ̀, ànfàní yín láti ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì npọ̀ si, bí ẹ ṣe njèrè níní òye àti ìmòye sí inú àwọn ìnílò wọn àti bí wọn ṣe nní ìmọ̀lára pé a fẹ́ràn wọn, pé a gbọ́ wọn yé, àti wíwà ní ààbò.

  • Mọ iyì àwọn ìyàtọ̀ àti àwọn ìwọ́pọ̀ bákannáà.

    “Àwọn kan … gbàgbọ́ pé Ìjọ nfẹ́ láti ṣe ẹ̀dá gbogbo ọmọ ìjọ láti inú ipò mímọkalẹ̀ kanṣoṣo—pé ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ wò, ní ìmọ̀lára, ronú, àti hùwà bíi ti gbogbo àwọn míràn,” ni Alàgbà Uchtdorf sọ, “Èyí yíò tako mímọ̀ọ́ṣe Ọlọ́run, ẹni tí ó dá gbogbo ènìyàn yàtọ̀ sí arákùnrin rẹ̀. …

    “Ìjọ nní ìgbéga nígbàtí a bá lo ànfàní ti yíyàtọ̀ yí tí a sì gba ara wa níyànjú láti mú àwọn ẹ̀bùn wa gbèrú kí a sì lò wọ́n láti ṣe ìgbéga àti ìfúnlókun ti àwọn ọmọẹ̀hìn ẹlẹgbẹ́ wa.”9

    Láti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmiràn ní ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ni ìfẹ́ wa bèèrè fún pé kí a gbìyànjú láti rí àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí Ọlọ́run fi rí wọn. Ààrẹ Thomas S. Monson (1927–2018) kọ́ni pé, “A gbọ́dọ̀ mú agbára wa dàgbà láti rí [àwọn ẹlòmíràn] kìí ṣe bí wọ́n ṣe wà nísisìyìí ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe lè dà.”10 A lè gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlòmíràn bi Ọlọ́run ti rí wọn. Bí a ṣe nṣe sí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú dídá lórí agbára wọn fún ìdàgbàsokè, ó ṣeéṣe kí wọ́n ó dìde sí ipò náà.11

  • Sìn wọ́n.

    Ẹ ní ìfúra sí ìnílò àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí, kí ẹ sì ní ìfẹ́ láti fi lára àkokò àti àwọn ẹ̀bùn yín fúnni, bóyá ní ìgbà àìní tàbí nítorípé ẹ nṣe ìtọ́jú. Ẹ lè wà níbẹ̀ láti pèsè ìtùnú, àtìlẹ́hìn, àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò nígbàtí ìdágìrì, àìsàn, tàbí ipò ìrànlọ́wọ́ kíákíá kan bá wà. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ ni a ti nṣi aápọn ṣe. Ọlọ́run fún wa ní agbára láti yàn kí a lè ṣe dípò kí wọ́n ṣe lé wá lórí (wo 2 Nephi 2:14). Gẹ́gẹ́ bí Àpọ́stélì Jòhánù ṣe kọ́ni pé a fẹ́ràn Ọlọ́run nítorí Òun kọ́kọ́ fẹ́ràn wa (wo 1 John 4:19), nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ wa nípasẹ̀ àwọn ìṣe ti iṣẹ́ ìsin wa, ó lè mú àwọn ọkàn rọ̀ kí ó sì mú ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pọ̀ síi.12 Eléyí nṣe ẹ̀dá lílọsókè ìlà ti irú àwọn ìṣe àánú tí ó lè mú àwọn ìbáṣepọ̀ dàgbàsókè.

Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Olùgbàlà ti Ṣe

Jésù Krístì mú àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ dàgbàsókè pẹ̀lú àwọn ọmọẹ̀hìn (wo John 11:5). Ó mọ wọ́n (wo John 1:47–48). Ó lo àkokò pẹ̀lú wọn (wo Luke 24:13–31). Ìbánisọ̀rọ̀ Rẹ̀ kọjá tayọ àṣehàn (wo John 15:15). Ó mọyì àwọn ìyàtọ̀ wọn (wo Matthew 9:10) ó sì rí agbára wọn (wo John 17:23). Ó sin gbogbo ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé Òun ni Olúwa gbogbo ènìyàn, ní wíwípé Òun kò wá láti jẹ́ síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí, ṣùgbọ́n láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ síni (wo Mark 10:42–45).

Kíni ẹ̀yin yíò ṣe láti mú ìbáṣepọ̀ tí ó ní agbára síi dàgbàsókè pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a pè yín láti sìn?

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Sharon Eubank, in “Àwọn Ìṣe Àánú Gbọdọ̀ Ní Gbòngbò Nínú Ìbáṣọ̀rẹ́, Sharon Eubank Sọ,” mormonnewsroom.org.

  2. Wo “Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ ti Síṣe Ìṣẹ́ Ìrànṣẹ́: Nawọ́ Jáde nínú Àánú,” Liahona, July 2018, 6–9.

  3. Dieter F. Uchtdorf, “Ti Àwọn Ohun tí Wọ́n Ṣe Pàtàkì Jùlọ,” Liahona, Nov. 2010, 22.

  4. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Ti Àwọn Ohun tí Wọ́n Ṣe Pàtàkì Jùlọ,” 22.

  5. Wo Ezra Taft Benson, “To the Home Teachers of the Church,” Ensign, May 1987, 50.

  6. Wo Charles A. Wilkinson and Lauren H. Grill, “Expressing Affection: A Vocabulary of Loving Messages,” in Making Connections: Readings in Relational Communication, ed. Kathleen M. Galvin, 5th ed. (2011), 164–73.

  7. Richard G. Scott, “Àwọn Ìbùkún Ayérayé ti Ìgbeyàwó,” Liahona, May 2011, 96.

  8. Wo “Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Síṣe Ìṣẹ́ Ìrànṣẹ́: Àwọn Ohun Márũn tí Olùfetísílẹ̀ Dáradára Nṣe,” Liahona, June 2018, 6–9.

  9. Dieter F. Uchtdorf, “Àwọn Àkọlé Mẹ́rin,” Liahona, May 2013, 59.

  10. Thomas S. Monson, “Rí Àwọn Míràn bí Wọ́n Ṣe Lè Dà,” Liahona, Nov. 2012, 69.

  11. Wo Terence R. Mitchell and Denise Daniels, “Motivation,” in Handbook of Psychology, vol. 12, ed. Walter C. Borman and others (2003), 229.

  12. Wo Edward J. Lawler, Rebecca Ford, and Michael D. Large, “Unilateral Initiatives as a Conflict Resolution Strategy,” Social Psychology Quarterly, vol. 62, no. 3 (Sept. 1999), 240–56.