2018
Gbígba Irànlọ́wọ́ láti Ran àwọn Míràn lọ́wọ́
Oṣù Kẹwa 2018


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2018

Gbígba Irànlọ́wọ́ láti Ran àwọn Míràn lọ́wọ́

Báwo ni a ṣe lè gba àwọn míràn láàyè nígbàtí a bá nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìtiraka wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́? Kópa nínú àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ Ọjọ́ ìsinmi-àkọ́kọ́.

Nígbàtí onírurú àrùn agbénidé de Kathy mọ́ orí kẹ̀kẹ́-ìjóòkó kan, ó ri pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ ní alaalẹ́ láti dìde dé orí ibùsùn òun láti orí ìjóòkó. Iṣẹ́ náà ti pọ̀jù fún ọmọ ìjọ kanṣoṣo. Nítorínáà àwọn iyejú alàgbà dámọ̀ràn nípa ipò rẹ̀ wọ́n sì gbèrò láti ṣe ètò kan làti ràn án lọ́wọ́ ní ìrọ̀ọ̀rọ̀lẹ́.1

Bí a ṣe nwá láti mọ àwọn àìní tí a sì nfún àwọn wọnnì tí à nsìn lókun, a lè ri pé a nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ bá àwọn àìní wọn pàdé. Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ Ọjọ́ ìsinmi-àkọ́kọ́ jẹ́ àwọn ànfàní méjì láti sọ̀rọ̀ bí a ṣe lè gba àwọn míràn láàyè déédé.

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò oṣù mẹ́ta-mẹ́ta wọ̀nyí ní àárín àwọn arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tàbí àwọn arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àjọ ààrẹ àwọn iyejú alàgbà nìkan ni ìjìhìn ti a ṣe ní ìkàsí sí àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà jẹ́ ànfàní kan ní oṣù mẹ́ta-mẹ́ta ó kérétán láti ekíní: dámọ̀ràn nípa àwọn okun, àìní, àti ìpèníjà àwọn ẹbí àti ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a yàn; èkejì: ṣe ìpinnu irú àwọn àìní tí iyejú, Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, tàbí ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù lè ṣe ìrànlọ̀wọ́ pẹ̀lú; àti ẹkẹ́ta: ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí kí ẹ si gba ìgbàniníyànjú nínú ìtiraka iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Ààrẹ àwọn iyejú alàgbà àti ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nbánisọ̀rọ̀ pàtàkì nípa àwọn àìní tààrà sí bíṣọ́ọ̀pù àti pé wọn yíò gba àmọ̀ràn àti ìdarí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ lè wá ìwífúnni si nípa àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ministering.lds.org.

Mímú Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Nítumọ̀

Ní àtìlẹhìn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russel M. Nelson pé ètò iṣẹ́ ìránṣẹ́ gbé lé orí àmì èyí tí ọ̀ràn Ìjọ yíò darí sí, Alàgbà Gary E. Stevenson ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá kọ́ni pé, Níní òye ìran rẹ̀ … lè jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ lórí bi a ṣe kọ́ àwọn òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin dáradára sí àti láti tẹramọ́ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́.”2

Àwọn àkórí máárún fún àwọn ojíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin:

  • Ẹ lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àmọ̀ràn àwárí . Ẹ ṣetán láti kọ́ ẹ̀kọ́

  • Ẹ múrasílẹ̀ láti sọ̀ àwọn àìní tí ẹ lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti bá pàdé.

  • Ní àfojúsùn lórí àwọn okun ẹnìkọ̀ọ̀kan àti agbára, kìí ṣe àwọn àìní nìkan.

  • Ẹ dámọ̀ràn nípa àwọn àbájáde tí yíò nítumọ̀ pé ẹ ṣe àṣeyege iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín.

  • Ẹ dé ọ̀dọ̀ àwọn àjọ ààrẹ láti dámọ̀ran ní àárín ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò oṣù mẹ́ta-mẹ́ta bí ẹ ti nílò sí.

Àwọn àkórí máàrún fún awọ́n olórí:

  • Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kò níláti gùn lọ títí, ṣùgbọ́n ṣe ètò àsíkò tó tó láti ṣe ìbẹ̀wò ní ibìkan tí ó fi àyè gba ìbánisọ̀rọ̀ tó nítumọ̀.

  • Lo ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin.

  • Máṣe bèèrè ìbèèrè tí yíò mú ìtẹ̀mọ́ra pé ẹ kàn nka ìbẹ̀wò ni tàbí ṣe àmì sí dídé ọ̀dọ̀ ẹni kan (“Ṣé ẹ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín). Ẹ bèèrè àwọn ìbèèrè tí yíò tún ìfẹ́ àwọn ìwà ṣe (Kíni ìṣílétí tí ẹ ní ìmọ̀lára rẹ̀ bí ẹ ṣe ngbàdúrà fún ẹbí náà? Kíni o ṣẹlẹ̀ nígbàtí ẹ ṣe ìṣé lórí àwọn ìṣílétí wọnnì?”)

  • Fifi etísílẹ̀ lódodo àti kìkọ àkọsílẹ̀ ranpẹ́.

  • Ẹ dámọ̀ràn papọ̀. Awọn ojúgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ẹtọ́ sí ìfihàn fún àwọn wọnnì tí a yàn fún wọn láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí.

Àwọn ìbèèrè àti àwọn ìdáhùn nípa àwọn Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Iṣẹ́ Irànṣẹ́

Kíní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́?

O jẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ ní àárín àwọn ojíṣẹ ìránṣẹ́ arákùnrin àti àjọ ààrẹ awọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú alàgbà tàbí ní àárín àwọn arábìnrin òjíṣẹ ìránṣẹ́ àti ọmọ ajọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nínú àgbékalẹ̀ tí ó fi àyè gbà wọ́n láti wá àti láti gba ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ẹmí Mímọ́. Gẹ́gẹ́bí àbájáde, àwọn òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin lè gba ìmísí láti ṣe ìtọ́jú lorí, fẹ́ni, kọ́ni, àti tuni nínú ní ọ̀nà Olùgbàlà.

Njẹ́ àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wọ̀nyí ní láti jẹ́ ojúkojú?

Nígbàgbogbo à nṣe wọ́n ní ojúkojú, ṣùgbọ́n a lè ṣe wọ́n lorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tàbí ayélujára nígbàtí ìpàdé ojúkojú kò bá ṣeéṣe. Nígbàgbogbo, àwọn ojúgbà lè kópa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nígbà tó bá tọ́.

Kíní èrò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́?

Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ ànfàní fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ipò lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣe àwọn ètò ọjọ́ iwájú, àti láti gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ẹbí tí wọn nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún. Ó jẹ́ ààyè kan láti sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ohun èlò tí iyejú àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ lè pèsè.

Báwo ni a ṣe lè dojúkọ àwọn ohun ẹlẹgẹ́ àti ìkọ̀kọ̀?

Àwọn òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin nṣe àbápín ìwífúnni ìkọ̀kọ̀ Pẹ̀lú àwọn iyeju alàgbà nìkan tàbí ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́—tàbí tààra pẹ̀lú Bíṣọ́ọ̀pù. A ko gbọ́dọ̀ ṣe àbápín ìwífúnni ẹlẹgẹ́ tàbí ìkọkọ̀ nínú àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ Ọjọ́ ìsinmi-àkọ́kọ́.

Àwọn Ìpàdé Ìgbìmọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi-Akọ́kọ́

Ní àfikún sí àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò iṣẹ́ ìránṣẹ́, àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ Ọjọ́ ìsinmi-àkọ́kọ́ jẹ́ ọ̀nà míràn láti fi àyè gba àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Nínú àwọn ìpàdé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti iyejú àwọn alàgbà, ìmísí lè wá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ìjóòkó nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn nínu ẹgbẹ́.

Èrò ìpàdé ìgbìmọ̀ ni láti:

  • “Dámọ́ràn papọ̀ nípa àwọn ojúṣe ìbílẹ̀, ànfàní, àti àwọn ìpèníjà;

  • “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ látinú òye ara yín àti àwọn ìrírí; àti

  • “Ṣe ètò àwọn ọ̀nà látí ṣe ìṣe lórí àwọn ìtẹ̀mọ́ra tí ẹ gbà láti ọwọ́ ẹ̀mí.”3

Àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ ju àwọn ìsọ̀rọ̀ lọ: àwọn ìpàdé náà ndarí wa sí ìṣe bí ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí bí ẹgbẹ́ kan bá ṣe ní ìmísí nípasẹ̀ Ẹ̀mí. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ kan láti ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́bí èsì àwọn ìpàdé wọ̀nyí.

Ìpè láti ṣe ìṣe

“Àdúrà wa ní òní,” ni Alàgbá Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá,” ni pé kí gbogbo ọkùnrin àti obìnrin—àti àwọn àgbà ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin—yíò [jẹ́] àgbọ́kànlé tó jinlẹ̀ sí ìkẹ́ àtọkànwá fún ara wa, mú ìwúrí nìkan nípasẹ̀ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Krístì láti ṣe bẹ́ẹ̀.”4

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  • See Mormon Messages video “Lift,” lds.org/media-library.

  • Gary E. Stevenson, in “Ministering Interviews” (video), ministering,lds.org.

  • Wa, Tẹ̀lé Mi—Fún Oyè-àlùfáà Mẹlkizédékì àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, nínú Ensign or Liahona, Nov. 2017, 140; tí ó wà bákannáà ní comefollowme.lds.org.

  • Jeffrey R. Holland, “Wà Pẹ̀lú kí o sì Fún Wọn Lókun,” Ensign or Liahona, May 2018, 103.