2019
Èrò Tí yíò yí Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ wa Padà
Oṣù Kínní (ṣẹrẹ)2019


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kínní 2019

Èrò Tí yíò yí Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ wa Padà

Nígbàtí àwọn èrò púpọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ wà, àwọn ìtiraka wa gbọ́dọ̀ gba ìfẹ́ ìtọ́nisọ́nà láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyege ìyípadà araẹni tó jinlẹ̀ àti láti dà bí Olùgbàlà si.

Nígbàtí a bá fẹ́ràn àwọn míràn bí Olùgbàlà ti ṣe, à fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ bí Ó ti ṣe. Bí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, Òun ni àpẹrẹ ìgbẹ̀hìn ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó nítumọ̀.

Ní títẹ̀lé àwòṣe Rẹ̀ nípa ṣíṣé iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ní ìfẹ́, gbéga, sìn, àti bíbùkún ní ìfojúsùn tó ga jù bíbá àìní ẹ̀sẹ̀kẹ̀sẹ̀ pàdé. Dájúdájú Ó mọ nípa àwọn àìní ojoojúmọ́ wọn Ó sì ní ìyọ́nú sí ìjìyà wọn lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítorínáà Ó wò sàn, bọ́, dáríjì, Ó sì kọ́ wọn. Ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti ṣe ju títọ́jú óhúngbẹ òní lọ (wo Jòhánù 4:13–14). O fẹ ki awọn tio yika tẹ̀le E(wo Lúkù 18:22; Jòhánù 21:22), Mọ̀ Ọ́ (wo Jòhánù 10:14; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 132:22–24), kí wọ́n sì dé ipò ọ̀run wọn (wo Máttéù 5:48). Bákannáà ni ní òní (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 67:13).

Àwọn áílónkà ọ̀nà ni a lè fi ṣèrànwọ́ láti bùkún àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n nígbàtí òpin ìfojúsùn ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti mọ Olùgbàlà àti láti dà bíi Rẹ̀ si, a ó máa ṣiṣẹ́ síwájú ọjọ́ náà nígbàtí a kò ní láti kọ́ áwọn aladugbo wa láti mọ Olúwa nítorí gbogbo wa ni a ó mọ̀ Ọ́ (wo Jeremiah 31:34).

Ìdojúkọ Olùgbàlà lọ kọjá àìní ẹsẹ̀kẹsẹ̀

  • Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ kọjá agbára láti mú àwọn ọ̀rẹ̀ wọn wá sọ́dọ̀ Jésù láti gbà ìwòsàn àrùn ẹ̀gbẹ̀. Ní ìgbẹhin Olùgbàlà wo ọkùnrin náà sàn, ṣugbọ́n Ó nifẹ jùlọ sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀(wo Luke 5:18–26).

  • Nígbàtí àwọn ènìyàn mú obìnrin tí a mú nínú ìwà àgbèrè wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà, dídá ìparun rẹ̀ dúró gba ayé rẹ̀ là níti-ara. Ṣùgbọ́n Òun fẹ́ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là níti-ẹ̀mí bákannáà, ní sísọ fún láti “lọ, kí ó má sì dẹ́ṣẹ̀ mọ́” (wo John 8:2–11).

  • Máríà àti Mártà ránṣẹ́ sí Jésù pé kí Ó wá wo ọ̀rẹ́ Rẹ̀ Lásárù, sàn. Jésù, tí ó ti wo àwọn míràn sàn ní àìmoye ìgbà, dá bíbọ̀ rẹ̀ dúró títí lẹ́hìn tí Lásárù ti kú. Jésù mọ ohun tí ẹbí náà fẹ́, ṣùgbọ́n ní jíjí Lasárù dìde, Ó fún ẹ̀rí wọn nípa àtọ̀runwá Rẹ̀ lókun(wo John 11:21–27).

Àpẹrẹ míràn wo ni ẹ lè fikún ìdárúkọ yí?

Kíni A Lè Ṣe?

Tí èrò wa bá jẹ́ láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti dàbí Olùgbàlà, yíò yí bí a ṣe nṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Padà Nihin ni àwọn ọ̀nà kan tí níní-òye yí fi lè tọ́ àwọn ìtiraka wa sọ́nà láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Èrò Kínní: So Iṣẹ́-ìsìn papọ̀ mọ́ Olùgbàlà

Gbogbo àwọn ìtiraka wa láti ṣe rere dára, ṣùgbọ́n a lè wá àwọn ànfàní láti mú iṣẹ́ ìsìn wa gbèrú nípa sísopọ̀ mọ́ Olùgbàlà. Fún àpẹrẹ, tí ẹbí tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún bá ṣàárẹ̀, oúnjẹ kan yíò ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n ìfihàn ìfẹ́ jẹ́jẹ́ lè di ìlọ́po nípa ẹ̀rí ìfẹ́ Olùgbàlà yín fún wọn. Ìrànlọ́wọ́ yín pẹ̀lú iṣẹ́-ọgbà yíò lọ́pẹ́, ṣùgbọ́n bóyá ó lè nítumọ̀ si pẹ̀lú ìfúnni ní ìbùkún oyèàlùfáà.

Alàgbà Neil L. Andersen ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá kọ́ni: “Ẹnìkan pẹ̀lú ọkàn rere lè ràn ènìyàn kan lọ́wọ́ láti tún táyà ṣe, mu alábàágbé lọ rí dókítà, jẹ oúnjẹ-ọ̀sán pẹ̀lú ènìyàn kan tí ó nbanújẹ́, tàbí rẹrin kí ẹ sọ báwo ni láti mú ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ si.

“Ṣùgbọ́n àtẹ̀lé òfin àkọ́kọ́ níbẹ̀rẹ̀-pẹ̀pẹ̀ yíò fikún àwọn iṣe iṣẹ́-ìsìn pàtàkì wọ̀nyí.”1

Èrò Kejì: Dojúkọ Ipá Ọ̀nà Májẹ̀mú

Lórí bíbá àwọn ọmọ ìjọ sọ̀rọ̀ lakọkọ bí Ààrẹ Ìjọ, Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, “Tẹramọ́ ipá ọ̀nà májẹ̀mú.” Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ “yíò ṣí ilẹ̀kùn fun gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí àti ànfàní tó wà.”2

Bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a ṣe ìrìbọmi, ìfẹsẹ̀múlẹ̀, a sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ọkùnrin olùkàyẹ̀ gba oyèàlùfáà. À nlọ sí tẹ́mpìlì fún ìfúnni-lẹ́bùn àti làti ṣe èdidì papọ̀ bí àwọn ẹbí titilai. Àwọn ìlànà ìgbàlà wọ̀nyí àti àwọn májẹ̀mú tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣe pàtàkì fún wa láti dàbíi Rẹ̀ kí a lè wà pẹ̀lú Rẹ̀.

A lè ní ojúṣe tó ṣe pàtàkì nínú ríran àwọn míràn lọ́wọ́ ní ipá-ọ̀nà bí a ṣe nràn wọn lọ́wọ́ láti pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ àti láti dá àwọn májẹ̀mú ọjọ́-ọ̀la.3 Báwo ni ẹ ṣe lè ran ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ẹbí tí ẹ̀ nsìn lọ́wọ́ láti gba ìlànà tó kàn tí wọ́n nílò? Èyí lè túmọ́ sí ṣíṣe ìrànwọ́ láti múra bàbá kan sílẹ̀ láti ṣe ìrìbọmi fún ọmọbìnrin rẹ̀, ṣíṣe àlàyé àwọn ìbùkún májẹ̀mù tó kàn láti dá, tàbí pípín àwọn ọ̀nà láti ní ìrírí onítumọ̀ si ní títún àwọn májẹ̀mú wa dá nígbàtí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa.

Èrò Kẹta: Ẹ Pe kí ẹ sì Gbani-níyànjú

Nígbàtí ó bá wà nibamu, dámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ẹ̀ ntọ́jú nípa ìyípada-ọkàn wọn àti àwọn ìtiraka wọn láti dàbíiti Krístì si. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn okun tí ẹ rí tí ẹ sì fẹ́ràn lára wọn. Wáàdí ibi tí wọ́n lérò pé wọ́n lè túnṣe kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Fún díẹ̀ sí lòrí ìdámọ̀ràn papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí, wo Dámọ̀ràn nípa àwọn Àìní Wọn,” Liahona, Sept. 2018, 6–9.)

Máṣe bẹ̀rù láti pè wọ́n láti tẹ̀lé Olùgbàlà àti fífi àyè gbà Á láti ràn wọ́n lọ́wọ́ dé ipò agbára tọ̀run wọn. Ìfipè yí lè jẹ́ ìyípadà tó pẹ́ títí, nígbàtí o ba sopọ pẹ̀lú ìfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú wọn àti ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀.

Àwọn Ọ̀nà Mẹ́fà Tí A Fi Lè Ran àwọn Míràn lọ́wọ́ láti Nilọsíwájú lọ́dọ̀ Krístì.

Ìwọ̀nyí ni àwọn àbá fún àtìlẹhìn àwọn míràn ní mímú ayé gbèrú àti títẹ̀síwájú ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú. (Wo Waasu Ìhìnrere Mi Ori 11, fun awọn ero sii.)

  1. Pín Ẹ jẹ́ olootọ àti olùgboyà nígbàtí ẹ bá nṣe àbápín bí Olùgbàlà ṣe ran yín lọ́wọ́ bí ẹ ṣe nlàkàkà láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ si nípa gbígbé ìgbé ayé ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ìfàsẹ́hìn.

  2. Àwọn ìlérí ìbùkún Àwọn ènìyàn nílò èrèdí láti yípadà tí ó pọndandan ju àwọn èrèdí tí wọn kò ní láti yípadà. Ṣíṣe àlàyé àwọn ìbùkún tó wà pẹ̀lú ìṣe kan lè pèsè ìwúrí alágbára (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 130:20–21).

  3. Ìfipè Gbígbé ìgbé-ayé ípìlẹ̀ ẹ̀kọ́ nmú ẹ̀rí tí ó jẹ́ òtítọ́ wá (see John 7:17) ó sì ndarí sí ìyìpadà-ọkàn tó jinlẹ gidi.4 Bíi gbogbo ìbánisọ̀rọ̀ lè wà pẹ̀lú ìfìpè jẹ́jẹ́ kan láti ṣe ohunkan tí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti nílọsíwájú.

  4. Ṣètò papọ̀. Kíni ó nílati ṣẹlẹ̀ fún wọn láti fi àṣeyege pa ìfarasin wọn láti yípadà? Báwo ni ẹ ṣe lè ṣè irànlọwọ́? Ṣe àsìkò tó lópin wà níbẹ̀?

  5. Àtìlẹhìn Nígbàtí è bá rannilọ́wọ́, dá ìsopọ̀ àtìlẹhìn àwọn ènìyàn tí wọ́n lè ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti dúró nínú ìwúrí àti àṣeyege sílẹ̀. Gbogbo wa la nílo olórí-amúnúdù

  6. Bojúto Ṣe àbápín ìlọsíwájú déédé. Dúró ṣinṣin lórí ètò ṣúgbọ́n ṣe àtúnṣe tí ó bá ṣe pàtàkì. Ṣe sùúrù, ìforitì ati ìgbìyànjú. Ìyípadà máa n gba àkokò.

Ìpè láti ṣe ìṣe

Gbèrò àwọn ọ̀nà tí àwọn akitiyan rẹ tí ṣí ṣe ìránṣẹ́—ni kekere ati nla —fi le ran awọn míràn lọ́wọ́ láti mu ìyípadà wọn gbilẹ̀ àti láti lè dàbíi Kristi sii.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Neil L. Andersen, “Ọ̀nà Kan Mímọ́ jùlọ si Iṣẹ Ìránṣẹ́” (Brigham Young University devotional, Apr. 10, 2018), 3, speeches.byu.edu.

  2. Russell M. Nelson, “Bí A Ṣe N Tẹsiwaju Papọ̀,” Liahona, Apr. 2018, 7

  3. Wo Henry B. Eyring, “Awọn ọmọ obinrin ninu Majẹmu

  4. Wo David A. Bednar, “Tí a Yípadà sí Olúwa,” Lìáhónà,Oṣù Kọkànlá Ọdún 2012, 109