2019
Bí a Ṣe Lè Ṣe Àbápín Ẹ̀rí ní Àdánidá Síi
Oṣù Kẹ́ta 2019


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹta 2019

Bí a Ṣe Lè Ṣe Àbápín Ẹ̀rí ní Àdánidá Síi

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ jẹ́ jíjẹ́ ẹ̀rí. Ìrọ̀nilọ́rùn ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ lè mú àwọn ànfàní wa pọ̀ si láti ṣe àbápín ẹ̀rí ní àwọn ọ̀nà lílàkalẹ̀ àti àìlàkalẹ̀ .

A ti dá májẹ̀mú láti “dúró bi àwọn ẹlẹri Ọlọ́run nigbàgbogbo àti nínú ohun gbogbo, àti nibi gbogbo” (Mosiah 18:9). Ṣíṣe àbápín àwọn ẹ̀rí wa jẹ́ apákan dídúró bí ẹlẹri àti pé ó jẹ́ ọ̀nà tí ó lágbára láti pe Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn ẹnìkan kí ó sì yí ìgbé ayé wọn padà.

“Ẹ̀rí—ẹ̀rí òtítọ́, tì ò wá nípasẹ̀ Ẹ̀mí àti tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀—nyí ìgbé ayé padà,” ni Ààrẹ M. Russell Ballard, Aṣojù Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ.1

Ṣùgbọ́n ṣíṣe àbápín ẹ̀rí wa lè ninilára tàbí jẹ́ àìnítùnú fún ọ̀pọ̀ lára wa. Èyíinì lè jẹ́ nítorí pé a nrò nípa ṣíṣe abápín ẹ̀rí wa bí ohun kan tì a nṣe nínú ìpàdé àwẹ̀ àti ẹ̀rí tàbí nígbàtí a bá nkọ́ni ní ẹ̀kọ́ kan. Nínú àwọn àgbékalẹ̀ lílàsílẹ̀ wọnnì, a nfi lemọ́lemọ́ lo àwọn ọ̀rọ̀ kan pàtó àti àwọn gbolóhùn ọ̀rọ̀ tì o dàbí pé kò bọ́ si rárá nínú ìbánisọ̀rọ̀ àdánidá .

Ṣíṣe àbápín àwọn ẹ̀rí wa lè di ìbùkuń déédé síi nínú ìgbé ayé wa, àti ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn, nígbàtí a bá ní òye bí ó ti rọrùn tó láti ṣe àbápín ohun tí a gbàgbọ́ nínú àwọn agbékalẹ̀ ojoojúmọ́. Ní ìhín ni àwọn èrò díẹ̀ láti mu yín bẹ̀rẹ̀:

Mú Kí Ó Rọrùn

Ẹ̀rí kan kò níláti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbolóhùn ọ̀rọ, “Mo fẹ́ láti jẹ́ ẹ̀rí mi,” àti pé kò níláti parí pẹ̀lú, “Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.” Ẹ̀rí jẹ́ ìfihàn ohun tí a gbàgbọ́ tí a sì mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́. Nítorínáà, láti ṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú aladugbo yín ní òpópó nípa wàhálà kan tí ó nní àti láti sọ pé, “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run ngbọ́ àwọn àdúrà,” lè jẹ́ ẹ̀rí tí ó lágbára bí èyíkéyìí tí a ṣe àbápín rẹ̀ láti orí pẹpẹ nínú ilé ìjọsìn. Agbára náà kìí wá láti inú èdè alárinrin; ó nwá láti inú Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó nfi ẹsẹ̀ òtítọ́ múlẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 100:7–8).

Ẹ fi Ìṣàn Ìbánisọ̀rọ̀ Àdánidá Lélẹ̀

Tí a bá nfẹ́ láti ṣe àbápín, àwọn ànfàní wà káàkiri gbogbo àyíká wa láti fi ẹ̀rí lélẹ̀ sínú àwọn ìbánisọ̀rọ̀ ojoojúmọ́. Fún àpẹrẹ:

  • Ẹnìkan bèèrè lọ́wọ́ yín nípa òpin ọ̀sẹ̀ yín. “O dára,” ẹ fèsì. “Ìlé ìjọ́sìn kàn ni ohun tí mo nílò.”

  • Ẹnìkan fi àánú hàn lẹ́hìn mímọ̀ nípa ìpènijà kan nínú ayé yín: “Mo kẹ́dùn gan ni.” Ẹ fèsì: “O ṣe fún àníyàn rẹ̀. Mo mọ̀ pé Ọlọ́run yíò mu mi làá kọjá. Ó ti wa níbẹ̀ fún mi tẹ́lẹ̀.”

  • Ẹnìkan sọ̀rọ̀: “Mo nírètí pé ojú ọjọ́ burúkú yí yíò yí padà láìpẹ́,” tàbí “Ọkọ̀-akérò náà pẹ́ dájúdájú,” tàbí “Wo súnkẹrẹ-gbakẹrẹ yí.” Ẹ lè fèsì: “Ó dámilójú pé Ọlọ́run yíò ṣèrànwọ́ láti yanjú gbogbo rẹ̀.”

Ṣe Àbápín Àwọn Ìrírí Rẹ

A máa nbá ara wa sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ nípa àwọn ìpènijà wa. Nígbàtí ẹnìkan bá sọ fún yín nípa ohun tí wọ́n ndojú kọ, ẹ lè ṣe àbápín àkokò kan nígbàtí Ọlọ́run ti ràn yín lọ́wọ́ nínú àwọn àdánwò yín ki ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ mọ̀ pé Òun lè ràn wọ́n lọ́wọ́ bákannáà. Olúwa sọ pé Òun nfún wa lókun nínú àwọn àdánwò wa “kí ẹ̀yín kí ó lè dúró bí ẹlẹ́rĩ fún mi lẹ́hìnwá, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ dájúdájú pé èmi, Olúwa Ọlọ́run nbẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú ìpọ́njú nwọn” (Mosiah 24:14). A lè dúró bí ẹlẹ́ẹ̀rí Rẹ̀ nígbàtí a bá jẹ́ ẹ̀rí nípa bí Ó ti rànwá lọ́wọ́ nínú àwọn àdánwò wa.

Ẹ Múrasílẹ̀

Fún díẹ̀ lára wa, ṣíṣe àbápín ẹ̀rí ní àsìkò kánmọ́ lè ninilára. Àwọn ọ̀nà wà tí a fi lè ṣètò ṣíwájú ki a sì “ṣetán nígbàgbogbo láti fún gbogbo ènìyàn ní ìdáhùn tí wọ́n bá bi [wá] ní èrèdí ìrètí tí ó wà nínú [wá]” (1 Peter 3:15).

Àkọ́kọ́, mímúrasílẹ̀ lè túmọ̀ sí wíwo bí a ṣe ngbé ìgbé ayé wa. Njẹ́ à npé Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ayé wa tí a sì nfún ẹ̀rí ara wa lókun lójoojúmọ́ nípa ìgbé-ayé òdodo? Njẹ́ a nfún Ẹmí ní àwọn ànfàní láti sọ̀rọ̀ sí wa kí ó sì fún wa ní àwọn ọ̀rọ̀ tí a nílò nípasẹ̀ àdúrà àti àṣàrò ìwé mímọ́? Bí Oluwa ṣe gba Hyrum Smith nímọ̀ràn, “Máṣe wá láti kéde ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ wá láti gba ọ̀rọ̀ mi, àti pé nígbànáà ni ahọn rẹ yíò di títú” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 11:21).

Èkejì, mímúrasílẹ̀ lè túmọ̀ sí wíwo iwájú àti gbígbèrò àwọn ànfàní tí ẹ lè ní lọ́jọ́ náà tàbí ní ọ̀sẹ̀ náà láti ṣe àbápín ẹ̀rí yín. Ẹ lè múrasílẹ̀ fún àwọn ànfàní wọnnì nípa ríronú nípa bí wọ́n ṣe lè fún yín ní ààyè láti ṣe àbápín ohun tí ẹ gbàgbọ́.

Ẹ Dúró ní Títẹramọ́ Olùgbàlà àti Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

Ààrẹ Ballard kọ́ni pé, “Bíótilẹ̀jẹ́pé a lè ní ẹ̀rí àwọn ohun púpọ̀ bí ọmọ Ìjọ, àwọn kókó òtítọ́ wà tí a nílò láti kọ́ ara wa léraléra kí a sì ṣe àbápín wọn.” Bí àwọn àpẹrẹ, ó tòó lẹ́sẹẹsẹ: “Ọlọ́run ni Bàbá wa àti pé Jésù ni Krístì. Ètò ìgbàlà dá lé orí Ètùtù Olùgbàlà. Joseph Smith mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìlópin ti Jésù Krístì padàbọ̀sípò, àti pé Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ni ìdánilójú pé ẹ̀rí wa jẹ́ òtítọ́.” Bí a ṣe nfi àwọn òtítọ́ àtọkànwá wọnnì hàn, à npé Ẹ̀mí láti jẹ́ ẹ̀rí pé ohun tí a ti sọ jẹ́ òtítọ́. Ààrẹ Ballard ṣe àtẹnumọ́ pé “a kò lè dá Ẹ̀mí dúró nígbàtí a bá jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì.”2

Àánú Olùgbàlà

Ní kíkãrẹ̀ láti inú ìrìnàjò kan la Samaria kọjá, Olùgbàlà dúró díẹ̀ láti simi ní ibi kànga kan, Ó sì pàdé obìrin kan níbẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀ nípa fífa omi láti inu kànga náà. Lílo iṣẹ́ ojoojúmọ́ yí tí obìnrin náà nṣe fún Jésù ní ànfàní láti jẹ́ ẹ̀rí omi ìyè àti ìyè ayérayé tí ó wà fún àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ (wo John 4:13–15, 25–26).

Ẹ̀rí Ìrọ̀rùn kan Lè Yí àwọn Ìgbé-ayé Padà.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ nípa nọ́ọ̀sì kan tí ó bèèrè ìbèèrè kan lọ́wọ́ Dokítà Nelson-nígbànáà, lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́-abẹ líle kan. “Kíni ìdí tí ìwọ kò fi dàbí àwọn oníṣẹ́-abẹ míràn?” Àwọn oníṣẹ́-abẹ kan tí ó mọ̀ le tètè ní ìkanra kí wọ́n sì tàbùkù bí wọ́n ṣe nṣe irú iṣẹ́ ìtẹmọ́ra gíga bẹ́ẹ̀.

Dókítà Nelson lè dáhùn ní àwọn onírurú àwọn ọ̀nà. Ṣùgbọ́n ó fi ìrọ̀rùn fèsì, “Nítorí mo mọ̀ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́.”

Ìdáhùn rẹ̀ ṣí nọ́ọ̀sì náà àti ọkọ rẹ̀ létí láti ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ààrẹ Nelson ṣe ìrìbọmi fún nọ́ọ̀sì náà lẹ́hìnwá. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnáà, nígbàti ó nṣe àkóso lórí ìpàdé àpapọ̀ èèkàn ní Tennessee, USA, bí Àpọ́stélì titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Ààrẹ Nelson gbádùn àtúnṣe-ìdàpọ̀ àìròtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú nọ́ọ̀sì kannáà. Ó ṣe àtúnsọ pé ìyípadà-ọkàn òun, tí ẹ̀rí ìrọ̀rùn rẹ̀ àti agbára Ìwé ti Mọ́mọ́ni mú wá, ṣèrànwọ́ láti darí ọgọ́rin ènìyàn míràn sí ìyípadà-ọkàn.3

Ìpè láti ṣe ìṣe

Ẹ máse bẹ̀rù láti ṣe àbápín ẹ̀rí yín. Ó lè bùkún àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún. Báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe lo àwọn èrò wọ̀nyí tàbí ti ara yín láti ṣe àbápín ẹ̀rí tiyín loni?

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. M. Russell Ballard, “Pure Testimony,” Liahona, Nov. 2004, 40.

  2. M. Russell Ballard, “Pure Testimony,” 41.

  3. Nínú Jason Swensen, “Ẹ ṣetán láti Ṣe àlàyé Ẹ̀rí Yín ní Lílo Ìwé ti Mọ́mọ́ni, Ààrẹ Nelson Wípé,” Church News section of LDS.org, Feb. 6, 2018, news.lds.org.