2019
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ Ni Rírí àwọn Ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti Nṣe
Oṣù Kẹfà 2019


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹfà 2019

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ Ni Rírí àwọn Ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti Nṣe

Jésù lo púpọ́ nínú àsìkò Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a rí bí ẹni tí ó yàtọ̀; Ó rí agbára wọn ti ọ̀run.

Nínú àwọn ìtiraka wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bíi ti Olùgbàlà, wọ́n lè pè wá láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkan tí ó yàtọ̀ sí wa. Èyí gbé ànfàní kan kalẹ̀ fún wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti dàgbà.

Ti-àṣà, tì-ẹ̀kọ́, ti-ẹ̀yà, ètò-ọrọ̀-ajé, ọjọ́-orí, àwọn ìwà àtẹ̀hìnwá tàbí ti ìsisìyí, tàbí àwọn ìyàtọ̀ míràn lè mú un rọrùn láti dá ẹnìkan lẹ́jọ́ ṣaájú kí a tilẹ̀ tó mọ̀ wọ́n. Dídájọ́-ṣíwájú yi wà ní oókan àyà ẹ̀tanú, àti pé Olùgbàlà kìlọ̀ ní ìlòdì sí i (wo 1 Sámúẹ́lì 16:7; Jòhánù 7:24).

Ṣe a lè wò kọjá àwọn ìyàtọ́ kí a sì rí àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti ṣe? Báwo ni a ṣe lè kọ́ láti ní ìfẹ àwọn ẹlòmíràn fún ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ẹni tí wọ́n lè dà?

Wíwò àti Fífẹ́ni

Bíbélì sọ ìtan tí a mọ̀ dáadáa ti ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀ ẹnití ó bèèrè bí òun ṣe lè ní ìyè ayérayé: “Nígbànáà ni Jésù wò ó, ó fẹ́ràn rẹ̀, ó sì wí fun un pé, Ohun kan ni ó kù fún ọ́: lọ ní ọ̀nà rẹ, ta ohunkohun tí ó ní, kí ó sì fifún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣura ní ọ̀run: sì wá, gbé àgbélèbú, kí o sì máa tọ̀ mí lẹ́hìn” (Márkù 10:21).

Nígbàtí Alàgbà S. Mark Palmer ti Àádọ́rin kọ́ ìwé-mímọ̀ yí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, apá titun kan ti ìtàn náà fi ara hàn sí i.

‘Nígbànáà Jésù wò ó, ó sì fẹ́ràn rẹ̀.’

“Bí mo ṣe gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwòrán dìdájú kan kún inú mi nípa Olúwa tí ó dúró-díẹ̀ tí ó sì wo ọ̀dọ́mọkùnrin yí. —bíi wíwò jinlẹ̀ àti wíwọ inú ẹ̀mí rẹ̀ lọ, dídá ìwàrere rẹ̀ mọ̀ àti bákannáà agbára rẹ̀, àti bíi níní òye àìní rẹ̀ tí ó tóbi jùlọ.

“Nígbànáà àwọn ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ náà—Jésù fẹ́ràn rẹ̀. Ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ bíbonimọ́lẹ̀ àti àánú fún ọ̀dọ́mọkùnrin rere yìí, àti nítorí ìfẹ́ yí àti pẹ̀lú ìfẹ́ yí, Jésù bèèrè síi lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi ojú inú wo àwòrán ohun tí ìbá ti jẹ́ fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà láti jẹ́ wíwé nípa irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, àní nígbàtí wọ́n ní kí ó ṣe ohun kan tí ó le koko bí títa gbogbo ohun tí ó ní àti kí ó fi í fún àwọn tálákà. …

“[Mo bi ara mi léèrè] ‘Báwo ni mo ṣe lè kún fún ìfẹ́ bíi ti Krístì, kí [àwọn ẹlòmíràn] lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ mi, kí wọn ó sì fẹ́ láti yípadà?’ Báwo ni mo ṣe lè wo [ẹnìkọ̀ọ̀kan ní àyíká mi] ní ọ̀nà kannáà tí Olúwa fi wo ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà, ní wíwò wọ́n fún ẹni tí wọ́n jẹ́ gan, àti ẹni tí wọ́n lè jẹ́, dípò ohun tí wọ́n nṣe tàbí tí wọn kò ṣe? Báwo ni mo ṣe le dàbí Olùgbàlà síi?”1

Kíkọ́ láti Rí àwọn Ẹlòmíràn

Kíkọ́ láti rí àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti nṣe nmú èrè tí ó ní ọ̀rọ̀ wá. Níhin ni àwọn àbá tí ó lè rànwá lọ́wọ́ bí a ṣe nṣiṣẹ́ sí ìhà ìfojúsùn yí.

  • Wá láti Mọ̀ Wọ́n
    Ṣe ìtiraka láti mọ àwọn ènìyàn náà kọjá àwọn ohun díẹ̀ tí kò jìnlẹ̀. Dáamọ̀ pé gbígbé àwọn ìbaṣepọ̀ ga ngba àkokò àti ìtiraka àtinúwa. (Wo ìwé kíkọ ti Àwọn Ẹ̀kọ́ Ipìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Iranṣẹ́ Oṣù Kẹ́jọ 2018 “Gbígbé Ibáṣepọ̀ Onítumọ̀ ga” fún ìrànlọ́wọ́.)

  • Ẹ Yẹ Ara Yín Wò
    Ẹ fi ọkàn sí àwọn ìdájọ́ tí e lè ti máa mọ̀ọ́mọ̀ ṣe tàbí síṣe ní àìmọ̀. Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ẹ nrò nípa àwọn ẹlòmíràn kí ẹ sì gbìyànjú láti ní òye ìdí tí ẹ fi ní ìmọ̀lára nípa wọn ní ọ̀nà tí ẹ nṣe.

  • Láìsí Ìdájọ́.
    Ẹ mọ̀ pé àwọn ipò kò túmọ̀ sí yíyẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ẹ fi ara yín sí ipò wọn kí ẹ sì gbèrò bí ẹ ó ti fẹ́ kí ẹnìkan rí yín bí ẹ bá wà nínú ipò kannáà. Yíya àwọn àṣàyàn àti ìhùwàsí ẹnìkan sọ́tọ̀ kúrò lára ojúlówó iyì àti agbára àtọ̀runwa wọn lè ránwá lọ́wọ́ láti rí wọn bí Olùgbàlà yíò ti ṣe.

  • Gbadúrà láti Ní Ìfẹ́ Wọn.
    Gbàdúrà fún wọn déédé nípa orúkọ àti fún sùúrù láti mú ìbádọrẹ òtítọ́ gbèrú. Wo ìṣẹ́-ìsìn rẹ pẹ̀lú àdúrà. Njẹ́ àlàfo kan wà laarin ohun tí ẹ̀ nṣe àti ohun tí wọ́n nílò nítòótọ́?

Jésù lo àkokò Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírurú ibi ní àgbáyé: ọlọ́rọ̀, tálákà, olórí, àti àwọn ènìyàn lásán. Ó máa nfi ìgbà gbogbo jẹ́ olùpalára ìdájọ́ àìpé láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn nígbàtí wọ́n bá nwo Òun àti ipò tálákà tàbí àìníyì Rẹ̀ tí ó hàn gbangban. “Nígbàtí àwa yíò ríi, kò sí ẹwà tí àwa kò bá fi fẹ́ ẹ. … A kẹ́gàn rẹ̀, àwa kò sì kàá sí” (Ìsàíáh 53:2–3).

Ìràn Bíi ti Krístì.

Arábìnrin kan ṣe àbápín ìtàn yí nípa kíkọ́ láti rí aladugbo kan pẹ̀lú ojú bíi ti Krístì:

“Júlíà (a ti yí orúkọ pada) ngbé ní ẹ̀gbẹ́ mi ó sì dàbí ẹnipé kò ní àwọn ọ̀rẹ́ kankan. Ó máa nní ìwò ìbínú àti ìrunú nígbàgbogbo. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo pinnu láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kìí ṣe ọ̀rẹ́ lásán fún àkókò kúkúrú, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ òtítọ́. Mo nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nígbàkugbà tí mo bá ri mo sì nfi ìfẹ́ hàn sí ohunkóhun tí ó bá nṣe. Díẹ̀díẹ̀, mo dá ìsopọ̀ ìbáṣọ̀rẹ́ kan sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí ó mú ayọ̀ wá sí ọkàn mi.

“Ní ọjọ̀ kan, mo pinnu láti bẹ Júlíà wò mo sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìpinnu rẹ̀ láti máṣe lọ sí ilé ìjọ́sìn.

“Mo kọ́ pé kò ní ẹbí tàbí ìbátan kankan nítòsí. Ọmọlẹ́bí rẹ̀ kanṣoṣo, arákùnrin tí ó ngbé ní ọ̀nà jíjìn, nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ọdún kan ní orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Bí mo ṣe nfi etí sílẹ̀ tí ó ntú ìkorò, ìbínú, àti àwọn ìjákulẹ̀ rẹ̀ jáde nípa ẹbí rẹ̀ àti Ìjọ, ìmọ̀lára àìlèsẹ́ ti àánú àti ìfẹ́ fún arábìnrin yí wá sí mi lárá gidi. Mo ní ìmọ̀lára ìrora àti ìjákulẹ̀ rẹ̀. Mo mọ̀ bí àdáwà ìgbé ayé rẹ̀ ti tó. Ó dàbíi pé mo gbọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ kan lẹ́hìn mi pé: ‘Mo nifẹ rẹ̀ náà. Nifẹ́ kí o sì bọ̀wọ̀ fún un.”

Mo joko mo si fetísílẹ̀ títí tí kò fi ní ohunkóhun láti sọ mọ́. Mó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àti àánú fún un. Èyí ni arábìnrin kan ẹnití kò tíì mọ̀ láé bí ó ti nrí láti jẹ́ fífẹ́ràn. Lójijì mo ní òye rẹ̀ jinlẹ̀ síi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún gbígbà mí láàyè láti ṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀, mo sì kúrò pẹ̀lú ìgbánimọ́rà àti pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ mi fún un. Òun kò le mọ láéláé bí ó ṣe fọwọ́tọ́mi tó pẹ̀lú ìbẹ̀wò náà. Bàbá Ọ̀run ti la ojú mi ó sì kọ́ mi pé mo ní agbára kan láti ni fẹ pẹ̀lú àlékún àánú. Mo múra nínú ìpinnu mi láti máṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ nìkan sí i, ṣùgbọ́n bákannáà láti jẹ́ ẹbí sí i.”

O jẹ́ ohun mímọ́ kan láti gba ìpè sí ìgbé ayé ẹlòmíràn. Pẹ̀lú àdúrà, sùúrù, àti ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí, a lè kọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìran bíi ti Krístì síi.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. S. Mark Palmer, “Then Jesus Beholding Him Loved Him,” Liahona, May 2017, 115.