2019
Ṣe Mo Lè Ran Ẹnìkan Lọ́wọ́ Láti Yípadà?
Oṣù Kẹ́jọ 2019


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹ́jọ 2019

Njẹ́ Mo Lè Ran Ẹnìkan Lọ́wọ́ Láti Yípadà?

Bẹ́ẹ̀ni. Ṣùgbọ́n ojúṣe yín lè yàtọ̀ jú bí ẹ ṣe ri lọ.

A dá wa pẹ̀lú agbára láti yípadà. Dídàgbà sí ipa-ọ̀nà agbára àtọ̀runwá ni èrò ìrírí ti ayé-ikú wa. Ọ̀kan lára àwọn ìfojúsùn ìgbẹ̀hìn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ṣíṣe ni láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì àti láti ṣe àwọn ìyípadà to ṣeéṣe sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí agbára wọn láti yàn, ojúṣe wa ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàbíi Krístì lópin.

Nihin ni àwọn ẹ̀kọ́ méje lílágbára látọ̀dọ̀ Olùgbàlà lórí bí a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú àwọn ìtiraka wọn láti yípadà àti láti dà bíi Rẹ̀ si.

  1. Máṣe Bẹ̀rù Láti Ṣe Ìfipè Fún Ìyípadà.

    Olùgbàlà kò bẹ̀rù láti pe àwọn ẹlòmíràn láti fi àwọn ọ̀nà àtẹ̀hìnwá sílẹ̀ àti láti rọ̀mọ́ àwọn ìkọ́ni Rẹ̀. Ó pe Pétérù àti Jákọ́bù láti fi àwọn iṣẹ́ wọn sílẹ̀ àti “láti di apẹja àwọn ènìyàn” (Marku 1:17). Ó pe obìnrin tí a mú nínú àgbèrè láti “lọ, kí ó má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́” (Jòhánù 8:11). Ó pe ọlọ́rọ̀ ọmọdékùnrin náà láti fi àtàmọ́ rẹ̀ fún ohun ayé sílẹ̀ àti láti tẹ̀lé Òhun (wo Marku 10:17–22). Àwa náà lè jẹ́ olùgboyà àti olùfẹ́ni bákannáà bí a ṣe npe àwọn ẹlòmíràn láti ṣe àwọn ìyípadà àti láti tẹ̀lé Olùgbàlà.

  2. Rántí pé Àṣàyàn wọn ni láti yípadà.

    Irú ìyípada tí Olùgbàlà fi pè kìí ṣe tipátipá. Olùgbàlà kọ́ni ó sì ṣe ìfipè, ṣùgbọ́n Òun kò múni nípá. Ọmọdékùnrin ọlọ́rọ̀ náà “lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́” (Máttéù 19:22). Ní Kápérnáùm, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn yàn láti “padà lọ,“ Ó sì bi àwọn méjìlá tí àwọn náà yíò bá lọ kúrò (wo John 6:66–67). Díẹ̀ lára àwọn àtẹ̀lé Jòhánù onírìbọmi yàn láti tẹ̀lé Olùgbàlà, áwọn míràn kò ṣe bẹ́ẹ̀ (wo John 1:35–37; 10:40–42). A lè pe àwọn ẹlòmíràn láti dàbíi Rẹ̀ síi, ṣùgbọ́n a kò lè ṣe ìpinnu láti yípadà fún wọn. Àti pé tí wọn kò bá tíì yàn láti yípadà, a kò gbọ́dọ̀ dáwọ́dúró—tàbí kí a rò pé a ti kùnà

  3. Ẹ Gbàdúrà Agbára fún àwọn Ẹlòmíràn láti Yípadà.

    Nínú Àdúrà Ẹ̀bẹ̀ Rẹ̀, Jésù ní kí Ọlọ́run pa àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, kí wọ́n ó dàbíi Òun àti Bàbá síi, kí wọ́n sì kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run (wo John 17:11, 21–23, 26). Àti pé ní mímọ̀ pé Pétérù yíò nílò okun nínú ìtiraka rẹ̀ láti dàgbà sínú ojúṣe rẹ̀, Olùgbàlà gbàdúrà fún un (wo Luke 22:32). Àwọn àdúrà wa fún àwọn ẹlòmíràn lè mu ìyàtọ̀ wá (wo James 5:16).

  4. Kọ́ Wọn láti Gbára lé AgbáraRẹ.

    Nípasẹ̀ Olùgbàlà nìkan ni a fi lè yípadà nítòótọ́ kí a sì dàgbà sí ipa agbára àtọ̀runwá tí gbogbo wa ní. Òun “ni ọ̀nà, ati òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ [mi]” (Jòhánù 14:6 Agbára Rẹ̀ ni ó lè “mú àwọn ohun aláìlera lókun” (Ẹ́térì 12:27). Ìgbàgbọ́ nínú agbára ètùtù Rẹ̀ ni ó mú kí Álmà Kékere yípadà (wo Álmà 36:16–23). A lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti gbára lé Olùgbàlà kí àwọn bákannáà lè ní agbára àtúnṣe Rẹ̀ nínú ayé wọn.

  5. Ẹ Hùwà Sí Wọn Bí Wọ́n Ṣe Lè Dà.

    Ifẹ́ àti ìtẹ́wọ́gbà lè jẹ́ alágbára aṣojú ti ìyípadà. Obìnrin ibi kanga ngbé pẹ̀lú ọkùnrin kan tí kì í ṣe ọkọ rẹ̀. Àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù “ní ìyàlẹ́nu pé ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà” (Jòhánù 4:27), ṣugbọ́n ohun tí ó kan Jésù jù ni irú ẹni tí ó lè dà. Ó kọ́ọ ó sì fún un ní ànfàní láti yípadà, èyí tí ó ṣe. (Wo Jòhánù 4:6–30

    Nígbàtí a bá hùwà dáadáa sí àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀rí dípò bí wọ́n ṣe lè dà, a lè mú wọn dúró. Dípò bẹ́ẹ̀, a lè dáríjì kí a sì gbàgbé àwọn àṣiṣe àtẹ̀hìnwá. A lè gbàgbọ́ pé àwọn ẹlòmíràn lè yípada. A lè fojú fo àìlera kí a sì fi àwọn ìwà rere hàn tí wọn lè ṣe àìrí nínú arawọn. ”A ní ojúṣe láti rí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan kìí ṣe bí wọ́n ṣe wà ṣùgbọ́n bí wọn ṣe lè dà.”1

  6. Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Rìn ní Ìṣísẹ̀ Ara Wọn.

    Ìyípadà ngba àkokò. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ “tẹ̀síwájú nínú sùúrù títí tí [a] ó fi dì pípé” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 67:13). Jésù ní sùúrù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn Ó sì tẹ̀síwájú láti kọ àwọn wọnnì tí wọ́n tàkòó, jíjẹ́ẹ̀rí nípa ojúṣe Rẹ̀ tí Bàbá Rẹ̀ fifun àti dídáhùn àwọn ìbèèrè wọn (wo Máttéù 12:1–13; Jòhánù 7:28–29). A lè ní sùúrù pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kí a sì gbà wọ́n níyànjú láti ní sùúrù pẹ̀lú ara wọn.

  7. Máṣe Dáwọ́dúró Tí Wọ́n Bá Padàsẹ́hìn sí àwọn Ọ̀nà Àtijọ́.

    Lẹ́hìn tí Krístì kú, Pétérù àti díẹ̀ lára àwọn Àpọ́stélì míràn padà lọ sí oun tí wọ́n mọ̀ọ́ ṣe (wo John 21:3). Krístì rán Pétérù létí pé ó nílò lati “bọ́ àwọn àgùtàn [Rẹ̀]” (wo Jòhánù 21:15–17), Pétérù padà sí iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ó lè rọ̀rùn jùlọ láti padà sí àwọn ọ̀nà àtijọ́. A lè tẹ̀síwájú láti ṣàtìlẹhìn pẹ̀lú ìgbani-níyànjú jẹ́jẹ́ àti àwọn ìfipè ìmísí láti tẹ̀lé Olùgbàlà àti láti tiraka lati dàbíi Rẹ̀ si.

Ẹ Fi Àyè Gba àwọn Ẹlòmíràn Láti Dàgbà.

Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ ìtàn yí nípa fífi àyè gba àwọn ẹlòmíràn láti dàgbà: “A ti sọ fún mi nígbàkan rí nípa ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹnití ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún jẹ́ oníyẹ̀yẹ́ nílé ìwé rẹ̀. O ní àwọn àlébù díẹ̀, ó sì rọrùn fún àwọn ọ̀gbà rẹ̀ láti yọọ́ lẹ́nu. Lẹ́hìnáà nínú ayé rẹ̀ ó kúrò níbẹ̀. Nígbẹ̀hìn ó darapọ̀ mọ́ ológun ó sì ní àwọn ìrírí àṣeyege níbẹ̀ ní gbígba ẹ̀kọ́ àti pé nínú gbogbo rẹ̀ ó kúrò nínú ìwà àtijọ́ rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ológun ti nṣe, ó ṣàwàrí ẹwà àti ọlánlá Ìjọ àti dídi aláápọn àti líláyọ̀ nínú rẹ̀.

“Nígbànáà, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó padà sí ìlú ábínibí rẹ̀. Púpọ̀jù lára ìran rẹ̀ ti lọsíwájú ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo wọn. Ó hàn gbàngba, nígbàtí ó padàdé pẹ̀lú àṣeyege àti àtúnbí, pé irú èrò-inú àtijọ́ náà ṣì wa níbẹ̀, tó ndúró dèé. Sí àwọn ènìyàn ní ìlú-àbínibí rẹ̀, ó ṣì jẹ́ àgbà síbẹ̀ ‘báyìí-àti-báyìí.’ …

“Díẹ̀díẹ̀ ọkùnrin Pauline yí ní ìtiraka lati fi èyí tí ó wà lẹ́hìn sílẹ̀ kí ó si di ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ tó ndínkù díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi kú nípa ọ̀nà tí ó ti gbe nígbà èwe rẹ̀. … O burújáì, ó burújáì pé ó tún wà ní àyíká … àwọn wọnnì tí wọ́n rò wípé ìwà àtijọ́ rẹ̀ dára ju ọjọ́-ọ̀la rẹ̀ lọ. Wọ́n rọra yọ kúrò nínú àdìmọ́ra rẹ̀ èyí tí Krístì ti dì ì mú. Ó sì kú nínú ìbànújẹ́, bíótilẹ̀jẹ́pé nípa ẹbi díẹ ti ara rẹ̀, …

“Ẹ jẹ kí àwọn ènìyàn ronúpìwàdà. Ẹ jẹ́ kí àwọn ènìyàn dàgbà. Ẹ gbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn lè yípadà kí wọ́n sì gbèrú si.”2

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Thomas S. Monson, “Rí Àwọn Míràn bí Wọ́n Ṣe Lè Dà,” Liahona, Nov. 2012, 69.

  2. Jeffrey R. Holland, “Èyí Tó Dárajùlọ Ṣì Nbọ̀,” Liahona, Jan. 2010, 19, 20.