2020
Kíkó Ísráẹ́lì Jọ Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́
Oṣù Kínní (ṣẹrẹ)2020


Àwòrán
ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kínní 2020

Kíkó Ísráẹ́lì Jọ Nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ànfàní láti tẹ̀lé àmọ̀ràn wòlíì láti kó Ísráẹ́lì jọ.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè wá láti ṣèrànwọ́ kíkó Ísráẹ́lì jọ—“ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ nṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní òní.”1

Fún àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti jẹ́ ara iṣẹ́ ti kíkó Ísráẹ́lì jọ yí, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ lè jẹ́ ànfàní oníyanu. Ó jẹ́ ọ̀nà ìmísí kan láti yí àwọn ìgbé ayé ènìyàn padà. Bóyá à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ìjọ tí kìí wá déédé tàbí pípè wọ́n láti rànwálọ́wọ́ bí a ṣe nsìn àwọn wọnnì níta ìgbàgbọ́ wa, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ npèsè àwọn ànfàní láti kó Ísráẹ́lì jọ.

Gbígba àwọn Ọmọ Ìjọ Olùpadawá Là

“Pẹ̀lú ifẹ́ gẹ́gẹ́bí ohun ìwúnilórí, àwọn iṣẹ́ ìyanu yíò ṣẹlẹ̀, a ó sì rí àwọn ọ̀nà láti mú àwọn arábìnrin àti arákùnrin wa tí wọ́n ti ‘ṣákolọ’ wá sínú àpapọ̀ ìgbanimọ́ra ti ìhìnrere Jésù Krístì.” —Jean B. Bingham2

“Mo ti di aláìwádéédé fún ọdún mẹ́fà ó kérétán nígbàtí ọkọ mi àti èmí kó lọ sí ìlú titun. Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ mi titun wá bẹ̀ mí wò, ó bèèrè tí òun bà lè rán arábìnrin kan láti wá bẹ̀ mí wò. Pẹ̀lú àìbaralẹ̀ díẹ̀, mo faramọ. Arábìnrin yí bẹ̀ mí wò lóṣooṣù, pẹ̀lú aìfẹ́rán àwọn ajá rẹ̀—mo sì ní ajá kan tó wuni gan an! Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tẹ̀síwájú fún ọdún méjì, ó sì ní ipá títóbi lórí mi.

“Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ìbẹ̀wò rẹ̀ máa njẹ́ ìbákẹgbẹ́ dáadáa, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó máa nbi mi ní àwọn ìbèèrè tí ó darí sí ìbárasọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí. Ìwọ́nyí mú mi ní àìbalẹ̀-ọkàn díẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣímilétí láti pinnu bóyá láti tẹ̀síwájú nínú ìhìnrere tàbí dúró níbi tí mo wà. Ìpinnu yí jẹ́ ìlàkàkà fún mi, ṣùgbọ́n mo yàn láti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú àwọn arábìnrin ìránṣẹ́ ìhìnrere.

“Ní ọjọ́ tí mo lọ sí ìpàdé oúnjẹ́ Olúwa fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún mẹ́fà, ẹ̀rù bà mí láti wọlé. Nígbàtí mo rìn wọnú ìjọ, arábìnrin ojíṣẹ iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi dúró fún mi, ó sì rìn pẹ̀lú mi sínú ilé ìjọsìn. Lẹ́hìnwá, ó rìn pẹ̀lú mi padà síbi ọkọ̀ mi, ó bèèrè lọ́wọ́ mi ohun tí òun lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́ jùlọ bí mo ṣe nsúnmọ́ Olùgbàlà si.

“Àkokò arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ mi àti ìfẹ́ ṣèrànwọ́ láti tọ́ mi sọ́nà sínú aápọn, mo sì di àwọn ìtiraka rẹ̀ mú bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbi jùlọ tí a fún mi rí. Mo fìmoore hàn pé ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ mi nínú ìrìnàjò mi padà sí Ìjọ Olùgbàlà.”

A di orúkọ mú, British Columbia, Canada

Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ láti yẹ̀wò

“Bẹ̀ mí wò lóṣooṣù”

Báwo ni ẹ ṣe lè tọ́jú àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ju àwọn ohun míràn lọ? (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:44).

“Àwọn ìbèèrè”

Bíbèèrè àwọn ìbèèrè tótọ́ lè ṣèrànwọ́ láti mú ìyẹ̀wò-araẹni wá. Ẹ rántí pé ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa ní èrò kan tí ó kọjá ṣíṣe ìbákẹ́gbẹ́.3

“Dídúró fún mi”

Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀lárá ìkínni-káàbọ̀ (wo 3 Nephi 18:32).

“Níbẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ mi ní ìrìnàjò padà”

Àtìlẹhìn wa lè ṣe ìyàtọ̀ pàtàkì sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti kọsẹ̀ láti padà sọ́dọ̀ Olùgbàlà àti láti gbàwòsàn (wo Hebrews 12:12–13).

Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti Ìkójọ

“Ní ọ̀nàkọnà tí ó fi dàbí àbínibí àti bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́ síi yín, ẹ ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìdí tí Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ fi ṣe pàtàkì síi yín.

“… Ojúṣe yín ni láti ṣe àbápín ohun tí ó wà lọ́kan yín kí ẹ sì gbé ìgbàgbọ́ yín léralérá .” —Elder Dieter F. Uchtdorf4

Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ṣíṣe àbápín ìhìnrere rí bákannáà. Nihin ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a fi lè kó àwọn ọ̀rẹ́ wa àti aladugbo jọ nígbàtí a bá nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́—tàbí kí a ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nígbàtí a bá kó àwọn ọ̀rẹ́ àti aladugbo wa jọ:

  • Sìn papọ̀. Wá àwọn ànfàní láti pe àwọn ọ̀rẹ́ tàbí aladugbo láti darapọ̀ mọ́ọ yín ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkan nínú àìní. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ wọn láti ràn yín lọ́wọ́ láti múra oúnjẹ kan sílẹ̀ fún ìyá titun, bẹ aladugbo àgbàlagbà kan wò, tàbí nu ilé ẹnìkan tí ó nṣàárẹ̀.

  • Kẹkọ papọ̀. Gbèrò pípé ọ̀rẹ́ kan tàbí aladugbo tí kìí lọ ilé ìjọsìn lemọ́lemọ́ láti gbàlejò ẹ̀kọ́ ìhìnrere nínú ilé wọn fún ẹnìkan tí ó nwápàdé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere. Tàbí ọ̀rẹ́ yín lè ṣàtìlẹhìn yín ní fífàyègbà ẹ̀kọ́ kan ní ilé yín tàbí lílọ pẹ̀lú yín fún ẹ̀kọ́ kan ní ilé ẹlòmíràn.

  • Ẹ nawọ́ jáde sí àwọn ẹlòmíràn nígbàtí ẹ bá rí àìní kan. Ẹ gbà láti ṣètò ìrìnsẹ̀ lọ sílé ìjọsìn. Ẹ pe àwọn ọmọ sí àwọn ìṣeré ọ̀dọ́ tàbí Alakọbẹrẹ. Àwọn ọ̀nà míràn wo ní ẹ fi lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ kí ẹ sì ṣàkójọ?

  • Lo àwọn ohun èlò tí Ìjọ ti pèsè. Ìjọ fúnni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò fún àwọn ọmọ ìjọ láti rànwọ́nlọ́wọ́ pẹ̀lú ṣíṣe àbápín ìhìnrere. Ẹ lè wò káàkiri nínú abala “Iṣẹ́ Ìhìnrere” nínú ààpù Ìkówejọ Ìhìnrere kí a sì bẹ ComeUntoChrist.org wò fún àwọn èrò lórí bí a ó ṣe kó Ísráẹ́lì jọ ní àwọn ìletò wa.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Russell M. Nelson, “Ìrètí Ísráẹ́lì” (ìfọkànsìn àwọn ọ̀dọ́ ní àgbáyé, Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹfà, 2018), HopeOfIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  2. Jean B. Bingham, “Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìranṣẹ Bí Olùgbàlà ti Ṣe,” Liahona, May 2018, 106.

  3. Wo “Àwọn Ẹ̀kọ́ Ipinlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Iranṣẹ: Èrò Tí Yíò Yí Ṣíṣe Iṣẹ́ Iránṣẹ́ Wa Padà,” Jan. 2019.

  4. Dieter F. Uchtdorf, “Íṣẹ́ Ihìnrere: Ṣíṣe Àbápín Ohun Tí Ó Wà Lọ́kàn Rẹ,” Liahona, May 2019, 17.