2020
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Oṣù Kẹrin 2020


“Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́rin 2020

Àwòrán
iṣẹ́ ìránṣẹ́

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹ́rin 2020

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípa Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò

Pẹ̀lú gbogbo àwọn àtúnsọ agbéniga, àṣà ẹbí, àti àwọn ìkọ́ni láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò nfún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́—ṣaájú, nínú, àti lẹ́hìn òpin-ọ̀sẹ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò!

Bí àwọn olùkọ́ kíláàsì ti mímúrasílẹ̀ fún míṣọ̀n, Susie àti Tom Mullen gba àwọn ọmọ kíláàsì wọn níyànjú léraléra láti pe ẹnìkan láti wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.

“Pípe ẹnìkan láti ṣe ohun kan jẹ́ apákan pàtàkì ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, àti pé ó wúlò sí ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bákannáà,” ni o sọ. “Àwọn akẹkọ wa a máa jíhìn padà léraléra nípa bí ó ṣe ní àbájáde dáradára fún wọn àti bákannáà fún ẹni tí wọ́n pè.”

Nihin ni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí àwọn akẹkọ wọn jíhìn pé àwọn fi nnawọ́ jáde:

  • “À ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ kan tí ó ní àwọn ohun kan tí ó ntiraka pẹ̀lú. A pe e láti fi etí sílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò fún àwọn ìdáhùn. Nígbàtí a ṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀, ó wí fún wa pé òun gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èrò tí yíò ṣe ìrànwọ́.”

  • “A ṣe ayẹyẹ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan gbogbo ènìyàn sì mú àwọn nkan wa láti pín. Ó jẹ́ alárinrin púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a pinnu láti ṣe é lẹ́ẹ̀kansíi.”

  • “Mo pe ọ̀rẹ́ kan láti wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò pẹ̀lú mi. Bí a ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, a pinnu láti wakọ̀ lọ sí ilé-ìjọsìn láti rí bí a bá lè wò ó níbẹ̀. A ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì jẹ́ ìrírí tí ó dára jùlọ láti wà níbẹ̀!”

Bí àwọn Mullen àti àwọn akẹkọ wọn ṣe kọ́ ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ni ó wà láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ó jẹ́ ọ̀nà ìyanu kan láti ṣe àbápín àwọn àtúnsọ agbéniga, àwọn àṣà ẹbí, àwọn ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀, àti àwọn ìkọ́ni ti àwọn ìránṣẹ́ Olúwa!

Ẹ Pe àwọn Míràn sí Ilé Yín

“Olùgbàlà pàṣẹ fún àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀ láti ‘nifẹ ara yín; bí mo ti nifẹ yín’ (Jòhánù 13:34). Nítorínáà a wò bí Ó ti nifẹ wa. … Bí a bá fi Òun ṣe àwòkọ́ṣe wa, a nílati máa fì ìgbàgbogbo gbìyànjú láti nawọ́ jáde sí gbogbo ènìyàn.” —President Dallin H. Oaks1

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn olùkọ́ni nílé wa yíyanilẹ́nu Mike ṣe àkíyèsí pé àwọn ọmọ mi mẹ́ta àti emi nìkan ní ayélujára kékeré kan láti wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò lórí rẹ̀. Ó pé wá lọ́gán láti wá sí ilé rẹ̀ láti wá wòó pẹ̀lú òun àti ìyàwó rẹ̀, Jackie, ní títẹnumọ́ pé wọn yíò nifẹ kí a wà pẹ̀lú wọn. Inú àwọn ọmọ mi dùn láti wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní ori ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán tòótọ́; mo fi ìmoore hàn gidigidi fún níní àtìlẹhìn náà; gbogbo wa sì fẹ́ràn akokò wa papọ̀.

Lẹ́hìn náà, wíwo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò papọ̀ di àṣà kan. Àní nígbàtí a ní amóhùnmáwórán ti ara wa, a ṣì fi ìdùnnú kọrí sí ilé Mike àti Jackie pẹ̀lú àwọn ìrọ̀rí, àwọn iwé àjákọ, àti àwọn ìpanu wa fún ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.. Gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì papọ̀ mu wọn ṣe pàtàkì síi. A di bíi ẹbí. Mike àti Jackie di díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ àti òbí-àgbà kejì sí àwọn ọmọ mi. Ìfẹ́ àti ìbáṣọ̀rẹ́ wọn ti jẹ́ ìbùkún gidigidi sí ẹbí mi. Mo ní ìmoore fún fífẹ́ wọn láti ṣí ilé wọn àti ọkàn wọn sílẹ̀ sí wa.

Suzanne Erd, California, USA

Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ láti yẹ̀wò

“Ṣe àkíyèsí”

Olùgbàlà fi tìfẹ́tìfẹ́ wá àkokò láti àwọn àìní àwọn ẹlòmíràn àti lẹ́hìnnáà Ó sì gbé ìgbésẹ̀ láti bá àwọn àìní wọnnì pàdé (wo Máttéù 9:35–36; Jòhánù 6:5; 19:26–27). A lè ṣe bákannáà.

“Pè lọ́gán”

Lẹ́hìn tí a ti ṣe àkíyèsí àwọn àìní àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí, ìpele tí ó kù ni láti gbé ìgbésẹ̀.“Gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì”

A níláti “pàdé papọ̀ nígbà gbogbo” (Mórónì 6:5) láti kọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀, dàgbà papọ̀, àti láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ẹ̀mí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ sí ẹ̀mí wa.

“Ẹ wá, fi etí sílẹ̀ sí ohùn wòlíì, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”2 lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìfipè tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a lè nawọ́ rẹ̀ sí àwọn wọnnì tí a nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí.

“Ìfẹ́ àti ìbániṣọ̀rẹ́”

Láti ṣe ìrànwọ́ àti láti ní ipá lórí àwọn ẹlòmíràn ní tòótọ, a gbọ́dọ̀ ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àánú àti “ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn” (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:41).

Ṣe àbápín lórí ẹ̀rọ ayélujára

“Àwọn ẹ̀ka ìròhìn ìbákẹ́gbẹ́ jẹ́ àwọn ohun èlò káriayé tí ó le ní ipa ti ara ẹni àti sí rere lórí púpọ̀ níye àwọn ẹnikọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí. Mo sì gbàgbọ́ pé àkoko náà ti dé fún wa bí ọmọlẹ́hìn Krístì láti lo àwọn ohun èlò onímìísí wọ̀nyí bí ó ti yẹ àti dáradára síi láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Ọlọ́run Bàbá Ayérayé, ètò ìdùnnú Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀, àti Ọmọ Bíbí Rẹ̀, Jésù Krístì, bí Olùgbàlà aráyé.” —Alàgbà David A. Bednar3

Ẹ̀rọ ayélujára fi ààyè gbà wá láti ṣe àbápín ìhìnrere pẹ̀lú gbogbo àráyé. Mo fẹ́ràn èyíinì! Mo máa nṣe àbápín àwọn ìdárayá díẹ̀ fún ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, ṣùgbọ́n jùlọ mo ngbìyànjú láti ran àwọn ẹlómíràn lọ́wọ́ láti dá àjọsọ ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Rírí àwọn ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà pùpọ̀ láti rí àwọn ohun kan nínú ìmọ́lẹ̀ titun ó sì lè jẹ́ ìfẹ̀hìntì sí àwọn ìbèèrè nlá ti àjọsọ ọ̀rọ̀ ti ara wa.

Mo ti ri pé bí ẹ ṣe nlo àwọn ìbèèrè láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò pẹ̀lú àwọn ẹbí tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí, yíó ràn yín lọ́wọ́ láti rí àwọn okun wọn àti àwọn àìní wọn bákannáà. Ọ̀kan lára àwọn ìbèèrè tí mo fẹ́ràn jù láti bèèrè ni, Kíni e rò pé ó jẹ́ akórí kan láti inú abala ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti àìpẹ́ jùlọ?

Ìdáhùn náà nígbàgbogbo fẹ́rẹ̀ jẹ́ kí ẹ rí ohun tí ó nlọ nínú ìgbé ayé wọn àti ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wọn. Ó nfi ààyè gbà yín láti di arákùnrin tàbí arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ dídárasíi nítorí ẹ ó rí wọn ní kedere síi.

Camille Gillham, Colorado, USA

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ láti Yẹ̀wò

“Ṣe àbápín ìhìnrere”

A ti dá májẹ̀mú láti “dúró bi àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ni ìgbà gbogbo àti nínú ohun gbogbo, àti ni ibi gbogbo” (Mòsíà 18:9).

“Dá ọ̀rọ̀ àjọsọ kan sílẹ̀”

Àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò lè ṣe ìmísí àwọn àjọsọ ọ̀rọ̀ alárà, tí ó bá ìgbà mú, àti ti ẹ̀mí darí. Irú àwọn àjọsọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì lè fún àwọn ìbáṣepọ̀ yín lókun, ó le ran ẹ̀rí yín lọ́wọ́ láti dàgbà, ó sì le mú ayọ̀ wá fún yín! (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 50:22).

“Lo àwọn ìbéèrè”

“Àwọn ìbèèrè rere yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ìfẹ́-inú, àwọn àníyàn, tàbí àwọn ìbèèrè tí àwọn ẹlòmíràn ní. Wọ́n lè mú ìkọ́ni yín dára síi, wọ́n le pe Ẹ̀mí wá, wọ́n sì le ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́.”4

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Dallin H. Oaks, “Ìfẹ́ àti Òfin” (video), mormonandgay.ChurchofJesusChrist.org.

  2. “Wá, Fetísílẹ̀ sí Ohùn Wòlíì,” Hymns, no. 21.

  3. David A. Bednar, “Ẹ Kún Ayé nípa Ìbákẹ́gbẹ́ Ìròhìn,” Làhónà, Oṣù Kẹ́jọ. 2015, 50.

  4. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìsìn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere (2004), 185.