2020
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Wa, Tẹ̀lé Mi
Oṣù Kẹsan 2020


“Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Wa, Tẹ̀lé Mi,” Làìhónà, Oṣù Kẹsan 2020

Àwòrán
iṣẹ́ ìránṣẹ́

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹsan 2020

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Wa, Tẹ̀lé Mi

Báwo ni Wa, Tẹ̀lé Mi ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ láti mú ìyàtọ̀ wá nínú àwọn ẹlòmíràn?

Bóyá ẹ wà pẹ̀lú ẹbí yín, ní kíláàsì Ìlé-ìwé Ọjọ́ Ìsinmi bí olùkọ́ kan tàbí akẹkọ, tàbí ní ilé-ìwé, ibi-iṣẹ́, tàbí ibikíbi míràn, àṣàrò ìhìnrere nípasẹ̀ Wá, Tẹ̀lé Mi fúnni ní àwọn ànfàní títóbi láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Kíkọ́ni, nígbànáà, “ju dídarí ìbánisọ̀rọ̀ ní Ọjọ́-ìsinmi; ó wà pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú ìfẹ́ àti bíbùkún àwọn míràn pẹ̀lú ìhìnrere.”1

Sísopọ̀ pẹ̀lú àwọn Akẹkọ

Nígbàtí a pe Ofelia de Cádenas láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́-àgbà ní wọ́ọ̀dù rẹ̀ Ìlú Mexico , ó ní ìmọ̀lára pé níní ìbáṣepọ̀ típẹ́típẹ́ kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn akẹkọ Ilé-ìwé Ọjọ́-ìsinmi rẹ̀ yíò mú agbára rẹ̀ láti kọ́ àti láti fún wọn lókun pọ̀si.

“Bí èmi kò bá ní ìbáṣepọ̀ típẹ̀típẹ́ pẹ̀lú àwọn akẹkọ mi àti pé bí wọn kò bá ní ìmọ̀lára ìfẹ́ mi, wọ́n lè má gbà mí gbọ́ nígbàtí mo bá nkọ́ kíláàsì kan tàbí njẹ́ ẹ̀rí mi,” ni ó sọ. “Wọ́n lè rò pé èmi kàn jẹ olùkọ́ Ilé-ìwé Ọjọ́-ìsinmi lásán ni.”

Ṣùgbọ́n báwo ni Arábìnrin Cádenas ṣe lè gbèrú nínú irú ìbáṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ bí òun bá kọ́ni ní ẹ̀ẹ̀kan ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì? Ó rí ìdáhùn nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé. Lílo áàpù fóònù àgbéká KílóNṣẹlẹ̀, òun àti àwọn akẹkọ rẹ̀ láìpẹ́ nsopọ̀ lójojúmọ́ nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ sísọ. Nísisìyí, ojojúmọ́ ṣíwájú ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsìnmi tó nbọ̀, àwọn olùfarajìn kíláàsì fi ẹsẹ ìwé mímọ́ kan ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ kíláàsì míràn látinú ẹ̀kọ́ tó tẹ̀le pẹ̀lú ìbámu èrò ara ẹni. Lẹ́hìn kíka ẹsẹ àti èrò náà, àwọn ọmọ kíláàsì fèsì pẹ̀lú èrò ti ara wọn.

“Nígbàtí wọ́n ka ìwé mímọ́, wọ́n fi ojú ayọ̀ ránṣẹ́ nítorínáà mo mọ̀ pé wọ́n ti kàá tàbí ṣe àṣàrò ìwé mímọ́ àti pé wọ́n ti ronú nípa rẹ̀,” ni Arábìnrin Cárdenas sọ. Nígbàtí àkokò fún ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi tó tẹ̀le bádé, àwọn akẹkọ múrasílẹ̀ láti kópa.

Ìsopọ̀ ojojúmọ́ àìpẹ́ yí bùkún ọ̀dọ̀-àgbà kan ẹnití àwọn òbí rẹ̀ kìí wá sí Ìjọ déédé.

“Mo nifẹ rẹ̀ nígbàtí mo ri tí ó wá sí ìjọ nítorí mo mọ̀ pé láti dé bẹ̀, ó ní láti la onírurú àwọn ìpènijà kọjá,” ni Arábìnrin Cárdenas sọ. “Ó dá mi lójú pé àwọn ìwé-mímọ́ àti èrò tí àwọn akẹkọ-kíláàsì rẹ̀ ti fi ránṣẹ́ àti pé àwọn ìwé-mímọ́ àti èrò tí ó fi ránṣẹ́ jáde nígbàtí ó jẹ́ ìyípo rẹ̀ ti fun un lókun dáadáa.”

Arábìnrin Cárdenas sọ pé ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípa àwọn ìwé-mímọ́ kò dá ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi rẹ̀ dúró àti ìsopọ̀ ìwé-mímọ́ kíláàsì ojojúmọ́.

“Ìmúrasílẹ̀ mi pẹ̀lú gbígbàdúrà fún àwọn akẹkọ mi,” ni ó sọ. “Mo nronú nípa wọn kìí ṣe ní Ọjọ́-ìsinmi nìkan ṣùgbọ́n lojojúmọ́ ọ̀sẹ̀ bákannáà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wọn ní àwọn àìní pàtó àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run. Mo ronú nípa wọn nígbàtí mò nmúra àwọn ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.”

Àti pé nígbàtí ó bá nkọ́ni, ó nfetísílẹ̀—sí àwọn akẹkọ rẹ àti sí Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú.

“Olùkọ́ náà ni Ẹ̀mí,” èyí tí ó nfìgbàkugbà gbọ́ nínú ohùn àwọn akẹkọ rẹ̀. “Mo níláti fetísílẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n sọ ni ìfihàn tí Ẹ̀mí nfi fún wọn.”

Kíláàsì Wa Dà “Bí Ilé Ìrọ̀lẹ́”

Carla Gutiérrez Ortega Córdoba ní ìmọ̀lára dídi alábùkún láti jẹ́ ọmọ Ilé-ìwé Ọjọ́-ìsinmi Arábìnrin Cárdenas nítorí ti àyíká ìṣìkẹ́ àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Carla fi àyíká náà wé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun, pẹ̀lú:

  • Mímúrasílẹ̀: Ṣíṣe àbápín àwọn ìwé-mímọ́ àti èrò nrán àwọn akẹkọ lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún kíláàsì tó mbọ̀ tẹ̀le “Àwọn ìwé-mímọ́ nṣìkẹ́ wa ó sì nmú ìmọ̀ wa gbòòrò,” ni ó ṣàlàyé.

  • Kíkópa: “Gbogbo wa sọ̀rọ̀. Èyí fàyè gbà mí láti mọ àwọn ọmọ kíláàsì mi jinlẹ̀ si, bí ọ̀rẹ́ àti bí arákùnrin àti arábìnrin.”

  • Ìfẹ́: “Arábìnrin Cárdenas mú yín lọ́wọ́ dání. Kíláàsì wa dà bí ilé ìrọ̀lẹ́, pèlú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin. Ó jẹ́ pàtàkì gidi.”

  • Ẹ̀mí Mímọ́: “A ní ìrẹ́pọ̀ ẹ̀mí, aládùn nínú kíláàsì wa nítorí a wà ní ìbádọ́gba pẹ̀lú Ẹ̀mí.”

  • Ẹ̀rí: “Wá Tẹ̀lé Mi ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣetán láti ṣe àbápín ẹ̀rí mi. Mo ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti Bíbélì. Tí ó fàyè gbà mí láti ṣe àbápín ohun tí mò kọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì mi ní ilé-ìwé àti àwọn ènìyàn ní ibi iṣẹ́.”

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí àwọn Àìní ti Ẹ̀mí

Nígbàtí Greg àti Nicky Christensen, láti Kentucky, USA, kà nípa májẹ̀mú ti Ábráhámù nínú àwọn ìwé-mímọ́ pẹ̀lú ọmọkùnrin wọn mẹ́ta, wọ́n ri pé ó ṣòro láti ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Wọ́n pinnu bí ẹbí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wọn yíò ṣàṣàrò májẹ̀mú ti Ábráhámù ni àyè ara wọn àti pé wọn yíò ṣe àbápín ohun tí wọ́n bá rí.

“A gba àwọn ìsọ̀rọ̀ alárinrin,” ni Greg sọ. “Ọmọ wa ọjọ́-orí ọdún mẹ́jọ kọ́ pé orúkọ Ábráhámù tẹ́lẹ̀ jẹ́ Ábrámù. Orúkọ rẹ̀ yípadà sí Ábráhámù nítorí ó ṣe ìlérí kan sí Olúwa láti yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti láti gbé ìgbé ayé òdodo. Ó yà mí lẹ́nu gidi pé ó lè wá pẹ̀lú ìyẹn.”

Gbogbo wọn kọ́ ohunkan titun wọ́n sì ní ìbárasọ̀rọ̀ rere nípa ohun tí májẹ̀mú ti Ábráhámù jẹ́ àti ohun tí ó túmọ̀ sí fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn loni.

“A máa nyí kiri yàrá a sì máà nka ẹsẹẹsẹ ìwé-mímọ́ yípo fún àṣàrò ìwé-mímọ́ ẹbí wa,” ni Nicky sọ. “Wá, Tẹ̀lé Mi ní ó wà lórí ìkọ́ni nípasẹ̀ Ẹ̀mí. Nísisìyí nígbàtí a bá ṣàṣàrò papọ̀, mo nímọ̀lára ìfura díẹ̀ látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí láti mú kí ìbarasọ̀rọ̀ wa ní ìdarí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó dálé àwọn àìní ẹbí.”

Lílo Wá, Tẹ̀lé Mi kìí ran ẹbí lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ si àti láti fẹ́ràn àṣàrò ìhìnrere nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà ó ran Greg àti Nicky lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn àìní ẹ̀mí àwọn ọmọ wọn.

Wá, Tẹ̀lé Mi nràn mí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ mi,” ni Nicky sọ. “Bákannáà ó nràn mí lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpèníjà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí mò nní pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. Mo ní ìmọ̀lára si ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí, mo fetísílẹ̀ típẹ́típẹ́, mo sì ti gba àwọn ìṣílétí lórí bí mo ṣe lè ran ọmọ kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́.

Greg gbádùn àwọn ìbárasọ̀rọ̀ ìhìnrere gigùn si tí Wá, Tẹ̀lé Mi ti mú wá nínú ẹbí. “Àwọn ọmọ wa yàtọ̀ ní gbogbo ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú ìmọ̀ ìhìnrere,” ni ó wí.“Wa, Tẹ̀lé mi ti pèsè ọ̀nà kan fún wa láti ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ́ tó dálórí àwọn àìní wọn. Wíwò wọn tí wọ́n ndàgbà nínú ìfẹ́ wọn fún ìhìnrere àti wíwò wọ́n tí wọ́n nwá bí wọ́n ṣe lè lo ìmọ̀ ìhìnrere nínú ayé wọn ti jẹ́ ìbùkún ìyanu

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Wá, Tẹ̀lé Mi—fún Ilé-ìwé Ọjọ́-ìsinmi: Iwé ti Mọ́mọ́nì 2020 (2019), 19.