2020
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́
Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2020


“Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2020

Àwòrán
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Àwọn fọ́tò láti ọwọ́ Tom Garner, Isaac Darko-Acheampong, Alexander K. Boateng, àti Jonas Rebicki

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹwa 2020

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ nípasẹ̀ Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́

Pípe àwọn ẹlòmíràn láti dàgbà àti ríràn wọ́n lọ́wọ́ lẹgbẹ ọ̀nà ni àkójá ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Àwọn ànfàní wà fún ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípasẹ̀ ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ̀. Bóyá ẹ ní àwọn ọmọdé tàbí ọ̀dọ́ ti ara yín ní ilé. Bóyá ẹ jẹ́ olórí kan nínú ètò náà tàbí ẹ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹbí pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́. Tàbí bóyá ó ṣẹlẹ̀ pé ẹ mọ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ (tí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ààbò nípa gbogbo wa). Èyíówù kí ipò yín lè jẹ́, àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti lo ètò náà tàbí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ láti bùkún ìgbé ayé ti àwọn ẹlòmíràn.

Gbígbèrú Arawa Papọ̀

Lórí ọkàn àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ ni ìdojúkọ kan lórí ìgbìyànjú ojoojúmọ́ láti dàbí Olùgbàlà si, ẹnití ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní pípé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni tí wọ́n ti kópa nínú ètò náà ti kọ́ pé bí ẹ ti nní ìlọsíwájú si nínú onírurú àwọn ìgbé ayé yín, ni ẹ̀ nṣe ìpèsè dáadáa si láti ṣèrànwọ́ tàbí láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn.

Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́, bíbùkún àwọn ẹlòmíràn kò níláti dúró títí tí ẹ ó fi kọ́ ohunkan. Ìṣe ìkọ́ni fúnrarẹ̀ npèsè àwọn ànfàní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a pè ní Wòlíì tí ó ngbé ní Ghana, gbígbé ìlépa kalẹ̀ nínú àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ láti kọ́ bí wọn ó ṣe tẹ dùrù nìkan jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀. “Ó jẹ́ ìlépa mi bákannáà láti ran àwọn ènìyàn míràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí mò nkọ́,” ni Wòlíì wí.

Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe olùkọ́ síbẹ̀síbẹ̀, ìlépa rẹ̀ ti dàgbà tẹ́lẹ̀ sí inú ohunkan tí ó tóbi gan ju bí òun ti rò láé. Àwọn àádọ́ta akẹkọ ní ó ngba kíláàsì dùrù nísisìyí ní ilé-ìjọsìn pẹ̀lú Wòlíì. Àti pé tani ẹni tí ó nkọ́ Wòlíì àtì àwọn àádọ́ta akẹkọ míràn? Alexander M. àti Kelvin M., àwọn méjèèjì ọjọ́ orí ọdún mẹ́tàlá. “A fẹ́ fi àwọn ìṣe inúrere hàn sí àwọn ènìyàn míràn,” ni Kelvin wí.

Ní ọjọ́ mẹ́tà laarin ọ̀sẹ̀ kan àwọn ọ̀dọ́ méjì náà kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ dùrù lọfẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá kẹkọ. Àfikún èrè kan sí àwọn ẹ̀kọ́ ti wà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn akẹkọ tí a ṣàfihàn sí Ìjọ nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ dùrù lẹ́hìnnáà ṣe àṣàrò ìhìnrere wọ́n sì pinnu láti ṣe ìrìbọmi.

Bí a ṣe nṣe akitiyan láti tún arawa ṣe, a lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlómíràn nípa pípè wọ́n láti darapọ̀ pẹ̀lú wa.

Ohunelò Ìṣẹ́gun Kan fún Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Gẹ́gẹ́bí ààrẹ èèkàn Alakọbẹrẹ kan ní, Sabrina Simões Deus Augusto ti Curitiba, Brazil, ti rí bí ìwò ìgbèrú araẹni ti ètò náà ṣe bùkún àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ní èèkan rẹ̀. Ṣùgbọ́n bákannáà òun ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà láti lo ohun tí ó kọ́ nípa ìgbèrú araẹni nínú iṣẹ́ ìyànsílẹ̀ rẹ̀ bí arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ kan.

“Ní ìgbà tí mo bá gbèrú ẹ̀bùn Ọlọ́run kan,” Arábìnrin Augusto wípé, “mo lè lo ẹ̀bùn Ọlọ́run láti bùkún ẹnìkan tí mò nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí.”

Arábìnrin Augusto kọ́ ọ̀kan lára àwọn arábìnrin ẹnití wọ́n yansílẹ̀ fun bí yíò ti ṣe ṣokoleti trúfísì. Nísisìyí arábìnrin náà nṣe ó sì nta àwọn trúfísì náà láti ṣèrànwọ́ àfikún fún owó-ọya ti ẹbí rẹ̀. “Ní àwọn oṣù lẹ́hìnnáà, mo di alábùkúnfún nígbàtí arábìnrin míràn kọ́ mi bí èmí ó ti ṣe búrẹ́dì oyin tí èmi lè tà,” Ni Augusto wí. “Gbígbèrú àti pípín àwọn ẹ̀bùn-Ọlọ́run wa lè bùkún ìgbé-ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan kí ó sì mú àwọn ìbáṣepọ̀ wa jinlẹ̀ bí àwọn arábìnrin òníṣẹ́ ìránṣẹ́.”