Àwọn Ẹgbẹ́ àti Iyejú àwọn Alàgbà
Ikẹkọ, Ìkọ́ni, àti Lílo Àwọn Ọ̀rọ̀ Látinú Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò


Wá, Tẹ̀lé Mi

Ikẹkọ, Ìkọ́ni, àti Lílo Àwọn Ọ̀rọ̀ Láti Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò

Àwọn iyejú alàgbà àti Àwọn Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nsa ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga. Ní àwọn ìpàdé ọjọ́ ìsinmi wọn, wọ́n njíròrò bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ gbogbogbò láìpẹ́ sí ìsapá wọn nínú iṣẹ́ yìí. Iyejú àwọn alàgbà àti àwọn àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ yan ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ kan láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìpàdé Ọjọ́ Ìsinmi kọ̀ọ̀kan, tí ó dá lórí àwọn àìní ti àwọn ọmọ ìjọ àti ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí. Nígbàmíràn, bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ èèkàn bákannáà lè daba ọ̀rọ̀ kan. Nínú gbogbo rẹ̀, àwọn olórí gbọ́dọ̀ yan àwọn ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, wọ́n le bára-wọn sọ̀rọ̀kọrọ̀ látinú ìpàdé àpapọ̀ àìpẹ́.

Àwọn olùkọ́ dojúkọ bí wọ́n ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ ìjọ láti lo àwọn ẹ̀kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ gbogbogbò ní ayé wọn. Àwọn olórí àti olùkọ́ wá àwọn ọ̀nà láti gba àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti kà àti láti yan ọ̀rọ̀ ṣíwájú ìpàdé.

Fún àlàyé si nípa ìpàdé iyejú àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ Ìrànlọ́wọ́, wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 8.2.1.2, 9.2.1.2, ChurchofJesusChrist.org.

Ṣíṣètò láti Kọ́ni

Àwọn ìbèèrè wọ̀nyí lè ran àwọn olùkọ́ lọ́wọ́ bí wọ́n ti nṣètò láti lo ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ láti kọ́ni. Bí a ṣe nílò, àwọn olùkọ gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú iyejú àwọn alàgbà tàbí àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ bí wọ́n ṣe njíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

  • Kínìdí ti iyejú àwọn alàgbà tàbí àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ fi nyan ọ̀rọ̀ yí láti jíròrò? Kíni wọ́n nírètí pé àwọn ọmọ ìjọ yìó mọ̀ àti ṣe lẹ́hìn sísọ ọ̀rọ̀ yí?

  • Kíní olùsọ̀rọ̀ fẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ ní ìmọ̀ rẹ̀? Kíní ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere tí ọkùnrin tàbí obìnrin náà nkọ́ni? Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ yi ṣe kan iyejú alàgbà tàbí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ mi?

  • Kíni àwọn ìwé-mímọ́ tí olùsọ̀rọ̀ fi ti ọ̀rọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin náà lẹhìn? Ṣe àwọn ìwé-mímọ́ míràn wà tí àwọn ọmọ ìjọ lè kà tí yíò mú ìmọ̀ wọn jinlẹ̀ si? (Ẹ lè rí àwọn kan nínú àkọsílẹ̀-ìparí ti ọ̀rọ̀ náà tàbí nínú Àkórí Ìtọ́ni [scriptures.ChurchofJesusChrist.org].)

  • Kíni àwọn ìbèèrè tí mo lè bèèrè tí yíò ràn àwọn ọmọ-ìjọ lọ́wọ́ láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà? Kíni àwọn ìbèèrè tí yíò rànwọ́nlọ́wọ́ láti rí pàtàkì ọ̀rọ̀ náà nínú ìgbé-ayé wọn, nínú ẹbí wọn, àti nínú iṣẹ́ Olúwa?

  • Kíni mo lè ṣe láti pe Ẹ̀mí wá sínú ìpàdé wa? Kíni mo lè lò láti mú ìbárasọ̀rọ̀ náà gbòòrò, pẹ̀lú àwọn ìtàn, àwọn àfiwé, orin, tàbí iṣẹ́-ọnà? Kí ni olùsọ̀rọ̀ ṣe láti ran àwọn ọmọ ìjọ lọ́wọ́ láti lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀?

  • Njẹ́ olùsọ̀rọ̀ nawọ́ ìpè kankan? Báwo ni mo ṣe lè ran àwọn ọmọ ìjọ lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ ìmọ̀lára láti ṣe ìṣe lórí àwọn ìpè wọnnì?

Àwọn èrò Ìṣeré

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ni àwọn olùkọ́ lè gbà láti ran àwọn ọmọ-ìjọ lọ́wọ́ láti kẹ́ẹ̀kọ́ àti láti lo àwọn ọ̀rọ̀ látinú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Nihin ni àwọn àpẹrẹ díẹ̀; àwọn olùkọ́ lè ní àwọn èrò míràn tí yíò ṣíṣẹ́ dáadáa si nínú iyejú àwọn alàgbà wọn tàbí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́.

  • Lo awọn otitọ si aye wa. Pe àwọn ọmọ ìjọ láti ṣe àtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ ní wíwá àwọn òtítọ́ tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti fifún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí iyejú àwọn alàgbà tàbí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, kí la rí kọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́? Bí àwọn òbí? gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọ ìránṣẹ́ ìhìnrere? Báwo ni ọ̀rọ̀ yí ṣe nípa lórí àwọn èrò, ìmọ̀lára, àti ìṣe wa?

  • Ẹ bárasọ̀rọ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́. Pín àwọn ọmọ-ìjọ sí àwọn ẹgbẹ́ kékèké, kí o sì fún ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ìpín tó yàtọ̀ láti kà nípa ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ àti láti bárasọ. Lẹ́hìnnáà ní kí ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kàn ṣe àbápín òtítọ́ kan tí wọ́n ti kọ́ àti bí o ṣe kàn wọ́n. Tàbí o lè dá àwọn ẹgbẹ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe àṣàrò àwọn ìpín tóyàtọ̀ kí o sì jẹ́ kí wọ́n ṣe àbápín pẹ̀lú ara wọn ohun tí wọ́n ti rí.

  • Wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè. Pe àwọn ọmọ ìjọ láti dáhùn àwọn ìbèèrè ìsàlẹ̀yí nípa ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ náà: Kíní àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí ẹ rí nínú ọ̀rọ̀ yí? Báwo ni a ṣe lè lo àwọn òtítọ́ wọ̀nyí? Kíni àwọn ìpè àti ìlérí ìbùkún tí wọn fúnni? Kíni ọ̀rọ̀ yí kọ́ wa nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run nfẹ́ kí a ṣe? Tàbí ṣe àwọn ìbéèrè díẹ̀ ti ararẹ tí ó gba àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà tàbí lo àwọn òtítọ́ tí ó kọ́ni. Gba àwọn ọmọ ìjọ láàyè láti yan ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kí o sì wa àwọn ìdáhùn nínú ọ̀rọ̀ náà.

  • Ṣe àbápín àwọn àlàyé látinú ọ̀rọ̀ náà. Pe àwọn ọmọ ìjọ láti ṣe àbápín àwọn àyọsọ látinú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ tí ó fún wọn ní ìmísí láti mú àwọn ojúṣe wọn ṣẹ nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga. Gbà wọ́n níyànjú láti gbèrò bí wọ́n ṣe lè ṣe àbápín àwọn àyọsọ wọ̀nyí láti bùkún ẹnìkan, pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọnnì àti àwọn ènìyàn tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí.

  • Ṣe àbápín kókó ẹ̀kọ́ kan. Ní ìṣíwájú, pe àwọn ọmọ ìjọ díẹ̀ láti mú àwọn nkan wá látilé tí wọ́n lè lò láti kọ́ nípa ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀. Lákokò ìpàdé, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ láti ṣe àlàyé bí àwọn nkan náà ṣe bá ọ̀rọ̀ náà mu àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kan ìgbé-ayé wọn.

  • Múra ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ láti kọ́ ní ilé. Ní kí àwọn ọmọ ìjọ ṣiṣẹ́ ní méjì-méjì láti ṣètò ẹ̀kọ́ ilé ìrọ̀lẹ́ kan tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀. Wọ́n lè dáhùn àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ní ìtumọ̀ sí ẹbí wa? Báwò ni a ṣe lè ṣe àbápín ọ̀rọ̀ yí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí à nṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ sí?

  • Ṣe àbápín àwọn ìrírí. Ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọ̀rọ̀ látinú ìpàdé àpàpọ̀ papọ̀. Ní kí àwọn ọmọ ìjọ ṣe àbápín àwọn àpẹrẹ látinú àwọn ìwé-mímọ́ àti látinú ìgbé-ayé wọn tí ó júwe tàbí tún ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a ti kọ́ nínú àwọn ìsọ̀rọ̀ yí sọ.

  • Wá gbólóhùn-ọ̀rọ̀ kan. Pe àwọn ọmọ ìjọ láti ṣàwárí ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ ní wíwo àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó nítumọ̀ sí wọn. Ní kí wọ́n ṣe àbápín gbólóhùn-ọ̀rọ̀ àti ohun tí wọ́n kọ́ látinú wọn. Ní kí wọn ṣe àbápín bí àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ṣe nrànwọ́nlọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ Olúwa.

Fún àwọn èrò síi bí a ó ti kà àti láti kẹkọ látinú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, wo “Àwọn èrò fún Ikẹkọ àti Ikọni látinú Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò” Tẹ “Àwọn èrò fún Àṣàrò” lábẹ́ “Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò” nínú Yàrá-ìkàwé Ìhìnrere.)