Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 14


Ori 14

Angẹ́lì kan sọ fún Nífáì nípa awọn ìbùkún àti awọn ègún tí yíò wá sí órí àwọn Kèfèrí—Àwọn ìjọ onígbàgbọ́ méjì péré ni ó wà: ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run àti ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù—Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti Ọlọ́run ní gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì ṣe inúnibíni sí—Àpóstélì Jòhánnù yíò kọ̀wé nípa òpin ayé. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Yíò sì ṣe, tí bí àwọn Kèfèrí bá fetí sí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ní ọjọ́ ná à tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ninu ọ̀rọ̀, àti pẹ̀lú ninu agbára, ní ìṣe gbogbo, sí mímú kúrò àwọn ohun ìkọsẹ̀ wọn—

2 Tí wọn kò sì sé àyà wọn le sí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, a ó sì kà wọ́n mọ́ irú-ọmọ bàbá rẹ; bẹ̃ni, wọn a ó sì kà wọ́n mọ́ ìdílé Isráẹ́lì; wọn yíò sì jẹ́ ẹni ìbùkún ní orí ilẹ̀ ìlérí titi; lae a kò ní rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ mọ́ sínú ìgbèkun; àti pé a kò ní fọn ìdílé Isráẹ́lì ká mọ́.

3 Àti ọ̀gbun nlá nì, èyí tí a ti gbẹ́ fún wọn nípasẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí a dásílẹ̀ nípa ọwọ́ èṣù àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí òun kí ó lè tọ́ ọkàn àwọn ènìyàn kúrò sísàlẹ̀ ọ̀run àpãdì—bẹ̃ni, ọ̀gbun nlá nì èyí tí a ti gbẹ́ fún ìparun àwọn ènìyàn ni a ó kún pẹ̀lú àwọn ẹni tí ó gbẹ́ ẹ, sí ìparun wọn pátápátá, ni Ọ̀dọ-àgùtàn Ọlọ́run wí; kì í ṣe ìparun ti ọkàn, bíkòṣe ti jíjù rẹ̀ sínú ọ̀run àpãdì nì, èyí tí kò ní òpin.

4 Nítorí kíyèsĩ, èyí jẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbèkun ti èṣù, àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí àìṣègbè Ọlọ́run, lórí gbogbo àwọn ẹni tí yíò ṣe iṣẹ́ ìwà búburú àti ẹ̀gbin níwájú rẹ̀.

5 Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún èmi, Nífáì, wípé: Ìwọ ti kíyèsĩ pé tí àwọn Kèfèrí bá ronúpìwàdà yíò dara fún wọn; ìwọ sì mọ̀ pẹ̀lú nípa awọn májẹ̀mú Olúwa sí ará ilé Isráẹ́lì; ìwọ sì ti gbọ́ pẹ̀lú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà kò lè ṣàì ṣègbé.

6 Nítorínã, ègbé ni fún àwọn Kèfèrí bí ó bá rí bẹ́ ẹ̀ pé wọ́n sé ọkàn wọn le sí Ọ̀dọ-àgùtàn Ọlọ́run.

7 Nítorí ìgbà ná à mbọ̀ wa, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run wí, tí èmi yíò ṣiṣẹ́ nlá àti iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; iṣẹ́ èyí tí yíò jẹ́ títí ayé, yálà ni ọ̀nà kan tàbí ní ti òmíràn—yálà sí yíyí wọn lọ́kàn padà sí àlãfíà àti ìyè ayeraye, tàbí sí jíjọ̀lọ́wọ́ wọn sí líle ọkàn wọn àti fífọ́lójú ọkàn wọn sí mímú wọn wá sílẹ̀ sínú ìgbèkùn, àti pẹ̀lú sínú ìparun, ní ti ayé yí àti ní ti ẹ̀mí pẹ̀lú, ní ìbámu pẹ̀lú ìgbèkùn èṣù, nípa èyí tí mo ti sọ̀.

8 Ó sì ṣe nígbàtí angẹ́lì ná à ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún mi: Ìwọ rántí awọn májẹ̀mú Baba sí ará ilé Isráẹ́lì bí? Mo wí fún un: Bẹ̃ni.

9 Ó sì ṣe tí ó wí fún mi: Wò ó, sì kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí i ṣe ìyá àwọn ìríra, tí olùdásílẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ èṣù.

10 Ó sì wí fún mi: Kíyèsĩ ìjọ onígbàgbọ́ méjì péré ni ó wà; ọ̀kan jẹ́ ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, ìkejì sì jẹ́ ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù; nítorí-èyi, ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nṣe ti ijọ onígbàgbọ́ nlá nì, èyí tí ó jẹ́ ìyá àwọn ìríra; òun sì ni àgbèrè gbogbo ayé.

11 Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì kíyèsí àgbèrè gbogbo ayé, ó sì jókò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi; ó sì ní ìjọba lórí gbogbo ayé, lãrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn gbogbo.

12 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, iye rẹ̀ sì jẹ́ díẹ́, nítorí ti ìwà búburú àti awọn ohun ìríra àgbèrè tí ó jókò lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi; bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo kíyèsĩ pé ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, wà pẹ̀lú lórí gbogbo ojú àgbàyé; àwọn ìjọba wọn lórí gbogbo ojú àgbáyé sì jẹ́ kékeré, nítorí ti ìwa búburú àgbèrè nlá nì ẹni tí èmi rí.

13 Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ i tí ìyá nlá awọn ìríra nì jùmọ̀ kó ọ̀pọ̀ ènìyàn jọ sórí ojú gbogbo àgbáyé, lãrín gbogbo àwọn orílè-èdè àwọn Kèfèrí, láti dojú ìjà kọ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run.

14 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, àwọn tí a túká sórí gbogbo ojú àgbáyé; wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.

15 Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ pé a tú ìbínú Ọlọ́run jáde sórí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, tóbẹ̃ tí ogun àti ìró ogun wà lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ìbátan ayé.

16 Bí ogun àti ìró ogun sì ti bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí nṣe ti ìyá awọn ohun ìríra nì, angẹ́lì ná à wí fún mi, wípé: Kíyèsĩ i, ìbínú Ọlọ́run nbẹ lórí ìyá àwọn panṣágà obìnrin; sì kíyèsĩ i, ìwọ rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí—

17 Nígbàtí ọjọ́ ná à bá sì dé tí a ó tú ìbínú Ọlọ́run jáde sórí ìyá àwọn panṣágà obinrin nì, èyí tí ó jẹ́ ìjọ onígbàgbọ nlá tí o sì rínilára ti gbogbo ayé, tí ẹni tí ó ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ èṣú, nígbànã, ní ọjọ́ ná à, iṣẹ́ Bàbá yíò bẹ̀rẹ̀, ní pípa ọ̀nà mọ́ fún mímú awọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ, èyí tí ó ti ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì.

18 Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi, wípé: Wò ó!

19 Mo sì wò mo sì kíyèsí ọkùnrin kan, ó sì wọ asọ̀ funfun.

20 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Ṣá wo ọ̀kan nínú àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn.

21 Kíyèsĩ i, òun yíò rí yíò sì kọ ìyókù àwọn ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èyí tí ó ti wà.

22 Òun yíò sì kọ̀wé pẹ̀lú nípa òpin ayé.

23 Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí òun yíò kọ jẹ́ àìṣègbè àti òtítọ́; sì kíyèsĩ i a kọ wọ́n sínú ìwé èyí tí ìwọ kíyèsí tí ó njáde wá láti ẹnu àwọn Jũ; ní ìgbà tí wọ́n sì jáde wá láti ẹnu àwọn Jũ, tàbí, ní ìgbà tí ìwé ná à jáde wá láti ẹnu àwọn Jũ, àwọn ohun èyí tí a kọ tẹ́jú, wọ́n sì dá ṣáká, wọ́n sì jẹ́ iyebíye jùlọ, wọ́n sì ní-rọ̀rùn sí ìmọ̀ gbogbo ènìyàn.

24 Sì kíyèsĩ i, àwọn ohun èyí tí àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn yí yíò kọ jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èyí tí ìwọ ti rí; sì kíyèsĩ i, ìyókù ni ìwọ yíò rí.

25 Ṣùgbọ́n àwọn ohun èyí tí ìwọ yíò rí lẹ́hìn èyí ìwọ kì yíò kọ; nítorí Olúwa Ọlọ́run ti yan àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run nì pé òun yíò kọ wọ́n.

26 Àti pẹ̀lú àwọn míràn tí ó ti wà, ó ti fi ohun gbogbo hàn sí wọn, a sì fi èdìdì dì wọ́n láti jáde wá ní mímọ wọn, gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyí tí mbẹ nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn, ní àkókò tí o yẹ níti Olúwa, sí ará ilé Isráẹ́lì.

27 Èmi, Nífáì, sì gbọ́ mo sì jẹ́rĩ, pé orúkọ àpóstélì Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à ni Jòhánnù, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ angẹ́lì ná à.

28 Sì kíyèsĩ i, Èmi, Nífáì, ni a dá lẹ́kun láti kọ ìyókù àwọn ohun èyí tí mo rí tí mo sì gbọ́; nítorí-èyi àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tẹ̀mi lọ́rùn; èyí tí mo kọ sìjẹ́ apákan díẹ̀ ti àwọn ohun èyí tí mo rí.

29 Mo sì jẹ́rĩ pé mo rí àwọn ohun èyí tí bàbá mi rí, angẹ́lì Olúwa ná à sì ṣe wọ́n ní mímọ̀ sí mi.

30 Àti nísisìyí mo ṣe òpin ti ìsọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun èyí tí mo rí nígbàtí a mú mi lọ nínú ẹ̀mí, bí nkò tilẹ̀ sì kọ gbogbo àwọn ohun èyí tí mo rí, àwọn ohun èyí tí mo ti kọ jẹ́ òtítọ́. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín.