Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 8


Ori 8

Léhì rí ìran igi ìyè—Ó jẹ nínú èso rẹ̀ ó sì fẹ́ kí ìdílé òun ṣe bẹ̃gẹ́gẹ́—Ó rí ọ̀pá irin kan, ọ̀nà híhá àti tõró kan, àti òkùnkùn biribiri tí ó bò ènìyàn—Sáráíà, Nífáì, àti Sãmú jẹ nínú èso nã, ṣùgbọ́n Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí a ti kó onírúurú irúgbìn oríṣiríṣi jọ lákõpọ̀, àti ti oríṣiríṣi wóró irúgbìn, àti ti oríṣiríṣi irúgbìn èso pẹ̀lú.

2 Ó sì ṣe nígbà tí bàbá mi dúró-lẹ́hìn nínú ijù ó wí fún wa, wí pé: Kíyèsĩ i, mo ti lá àlá kan, tàbí ní ọ̀nà míràn, mo ti rí ìran kan.

3 Sì kíyèsĩ i, nítorí ohun tí mo ti rí, mo ní ìdí láti yọ̀ nínú Olúwa nítorí ti Nífáì àti Sãmú pẹ̀lú; nítorí tí mo ní ìdí láti rò pé àwọn, àti púpọ̀ nínú irú-ọmọ wọn pẹ̀lú, ni a ó gbàlà.

4 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, mo bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí yín; nítorí kíyèsĩ i, mo rò pé mo ri nínú àlá mi, ijù kan tí ó ṣókùnkùn tí ó sì binújẹ́.

5 Ó sì ṣe tí mo rí ọkùnrin kan, ó sì wọ ẹ̀wù funfun kan, ó sì wá dúró níwájú mi.

6 Ó sì ṣe tí ó sọ̀rọ̀ sí mi, ó sì pè mí kí n tẹ̀lé òun.

7 Ó sì ṣe bí mo ṣe n tẹ̀lé e mo rí ara mi pé mo wá nínú ahoro kan tí ó ṣókùnkùn tí ó sì binújẹ́.

8 Lẹ́hìn tí mo sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nínú òkùnkùn, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Olúwa wí pé kí ó ní ãnú lórí mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrọnú ãnú rẹ̀.

9 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti gbàdúrà sí Olúwa mo rí pápá kan tí ó tóbi tí ó sì gbõrò.

10 Ó sì ṣe tí mo rí igi kan, èso èyí tí o yẹ ní fífẹ́ láti mú inú ẹni dùn.

11 Ó sì ṣe tí mo jáde lọ mo sì jẹ nínú èso rẹ̀; mo sì ri wí pé ó dùn rékọjá, ju gbogbo ohun tí mo ti tọ́wò rí. Bẹ̃ni, mo sì ri wí pé èso rẹ̀ jẹ́ funfun, tí ó tayọ gbogbo fífunfun tí mo ti rí rí.

12 Bí mo sì ti jẹ nínú èso rẹ̀ ó fi ayọ̀ nlá tí ó rékọjá kún ọkàn mi; nítorínã, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ìfẹ́ wí pé kí ìdílé mi kí ó jẹ nínú rẹ̀ pẹ̀lú; nítorí mo mọ̀ wí pé ó yẹ ní fífẹ́ ju gbogbo èso míràn.

13 Bí mo sì ti gbé ojú mi yíká kãkiri pé bóyá mo lè wá ìdílé mi rí pẹ̀lú, mo rí odò omi kan, ó sì n ṣàn lọ, ó sì wà nítòsí igi èyí tí mọ̀ n jẹ èso rẹ̀.

14 Mo sì wò láti rí ibi tí ó ti wá; mo sì rí orísun rẹ̀ níwájú díẹ̀; níbi orísun nã mo sì rí ìyá rẹ Sáráíà, àti Sãmú, àti Nífáì; wọ́n sì dúró bí pé wọn kò mọ́ ibi tí wọn yíò lọ.

15 Ó sì ṣe mo juwọ́ sí wọn; mo sì tún sọ fún wọn pẹ̀lú ohùn kíkan wí pé kí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọ́n jẹ nínú èso nã, èyí tí ó yẹ ní fífẹ́ ju gbogbo èso míràn.

16 Ó sì ṣe tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ mi tí wọ́n sì jẹ nínú èso nã pẹ̀lú.

17 Ó sì ṣe tí mo ní ìfẹ́ wí pé kí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì wá jẹ nínú èso nã pẹ̀lú; nítorínã, mo gbé ojú mi síhà orísun odò nã, wí pé bóyá mo lè rí wọn.

18 Ó sì ṣe tí mo rí wọn, ṣùgbọ́n wọn kò wá sí ọ̀dọ̀ mi kí wọ́n sì jẹ nínú èso nã.

19 Mo sì rí ọ̀pá irin kan, ó sì gùn lọ lẹ́gbẹ̃ bèbè odò nã, ó sì gùn dé ibi igi ní ẹ̀bá èyí tí mo dúró.

20 Mo sì tún rí ọ̀nà híhá àti tõró kan, èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̃ ọ̀pá irin nã, títí fi dé ibi igi ẹ̀bá èyí tí mo dúró; ó sì gùn kọjá orísun nã pẹ̀lú, títí dé pápá kan tí ó tóbi tí ó sì gbõrò, bí ẹni pé ó jẹ́ ayé kan.

21 Mo sì rí àjọ àìníye àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ èyí tí ó n tẹ̀ síwájú, kí wọ́n lè dé ọ̀nà nã èyí tí ó lọ sí ibi igi ni ẹ̀bá èyí tí mo dúró.

22 Ó sì ṣe tí wọ́n jáde wá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà èyí tí ó lọ sí ibi igi nã.

23 Ó sì ṣe tí òkùnkùn biribiri yọ jáde; bẹ̃ni, àní òkùnkùn biribiri nlá lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí àwọn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà nã ṣìnà, tí wọ́n ṣáko kúrò tí wọ́n sì sọnù.

24 Ó sì ṣe tí mo rí àwọn míràn tí wọ́n n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì jáde wá wọ́n sì di ìdí ọ̀pá irin nã mú; wọ́n sì tẹ̀ síwájú lãrín òkùnkùn biribiri nã, wọ́n rọ̀ mọ́ ọ̀pá irin nã, àní títí tí wọ́n fi jáde wá tí wọ́n sì jẹ nínú èso igi nã.

25 Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti jẹ nínú èso igi nã wọ́n gbé ojú wọn yíkãkiri bí ẹni pé wọ́n n tijú.

26 Mo sì tún gbé ojú mi yíká kãkiri, mo sì ṣàkíyèsí ilé nlá kan tí o sì gbõrò ní òdì kejì odò omi nã; ó sì dàbí pé ó dúró ní òfúrufú, tí ó ga lórí ilẹ̀.

27 Ó sì kún fún ènìyàn, àti ogbó àti ọ̀dọ́, àti ọkùnrin àti obìnrin; ìmúra wọn sì dára lọ́pọ̀lọpọ̀; wọ́n sì wà ní ìṣesí fífi ṣe ẹlẹ́yà àti nína ìka ọwọ́ síhà àwọn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì n jẹ èso nã.

28 Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti tọ́ èso nã wò ojú tì wọ́n, nítorí àwọn tí ó n kẹ́gàn wọn; wọ́n sì ṣáko lọ sínú àwọn ọ̀nà tí a kà lẽwọ̀ wọ́n sì sọnù.

29 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kò sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi.

30 Ṣùgbọ́n, kí n lè ké ìwé mi kúrú, kíyèsĩ i, ó rí ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn míràn tí wọ́n n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì wá wọ́n sì di ìdí ọ̀pá irin nã mú; wọ́n sì tẹ̀ síwájú lọ́nà wọn, wọ́n n di ọ̀pá irin nã mú ṣinṣin títí lọ, títí wọ́n fi jáde wá tí wọ́n wólulẹ̀ tí wọ́n sì jẹ nínú èso igi nã.

31 Ó sì tún rí ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn míràn tí wọ́n n fọwọ́wá ọ̀nà wọn síhà ilé nlá tí ó sì gbõrò nì.

32 Ó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó rì sínú omi nínú ibú orísun nã; ọ̀pọ̀ ni ó sì sọnù tí kò rí mọ́, tí wọ́n n ṣáko ní awọn ọ̀nà tí ó ṣàjèjì.

33 Ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn nã sì pọ̀ tí ó wọ inú ilé tí ó ṣàjèjì nì. Lẹ́hìn tí wọ́n sì wọ inú ilé nì wọ́n na ìka ọwọ́ ẹ̀gàn sí èmi àti àwọn tí ó n jẹ nínú èso nã pẹ̀lú; ṣùgbọ́n àwa kò kíyèsĩ wọn.

34 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi: Nítorí gbogbo àwọn tí ó kíyèsĩ wọn ni ó ti ṣáko.

35 Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kò sì jẹ nínú èso nã, bẹ̃ni bàbá mi sọ.

36 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí bàbá mi ti sọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àlá tàbí ìran rẹ̀, èyí tí ó pọ̀, ó sọ fún wa, nítorí àwọn ohun wọ̀nyí tí ó rí nínú ìran, ó bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì; bẹ̃ni, ó bẹ̀rù kí a máṣe ta wọ́n nù kúrò níwájú Olúwa.

37 Ó sì gbà wọ́n níyànjú nígbà nã pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ òbí tí ó ṣàníyàn, pé kí wọ́n fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, pé bóyá Olúwa yíò ni ãnú sí wọn, tí kì yíò sì ta wọ́n nù; bẹ̃ni, bàbá mi wãsù sí wọn.

38 Lẹ́hìn tí ó sì ti wãsù sí wọn, tí ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí wọn pẹ̀lú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun, o rọ̀ wọ́n láti pa òfin Olúwa mọ́; ó sì dẹ́kun sísọ̀rọ̀ sí wọn.