Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 10


Ori 10

Àwọn Jũ yíò kan Ọlọ́run wọn mọ́ àgbélẽbú—A ó tú wọn ká títí dìgbà tí wọn ó bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú rẹ̀—Ilẹ̀ Amẹ́ríkà yíò jẹ́ ilẹ̀ òmìnira níbití kò sí ọba tí yíò ṣe àkóso—Ẹ ṣe ìlàjà ara yín sí Ọlọ́run kí ẹ sì jèrè ìgbàlà nípa ore ọ̀fẹ́ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, tún bá yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin árákùnrin mi àyànfẹ́, nípa ẹ̀ká òdodo yí nipa èyítí mo ti sọ̀.

2 Nítorí kíyèsĩ i, àwọn ìlérí èyítí àwa ti rí gbà jẹ́ àwọn ìlérí sí wa gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara; nítorí-èyi, bí a ti fi hàn sí mi pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ wa yíò parun ní ẹran ara nítorí ti àìgbàgbọ́, bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run yíò ni ãnú sí ọ̀pọ̀lọpọ̀; àwọn ọmọ wa ni a ó sì mú padà sípò, kí wọ́n lè wá sí èyí nì tí yíò fún wọn ní ìmọ̀ òtítọ́ ti Olùràpadà wọn.

3 Nítorí-èyi, bí mo ṣe wí fún yín, o di yíyẹ dandan pé Krístì—nítorí ní òru àná angẹ́lì nã wí fún mi pé èyí ni yíò jẹ́ orúkọ rẹ̀—yíò wá lãrín àwọn Jũ, lãrín àwọn wọnnì tí ó jẹ́ ẹ̀yà tí ó burú jùlọ ní ayé; àwọn yíò sì kàn án mọ́ àgbélẽbú—nítorí báyĩ ni ó tọ́ sí Ọlọ́run wa, kò sì sí orílẹ̀-èdè míràn ní ayé tí yíò kan Ọlọ́run wọn mọ́ àgbélẽbú.

4 Nítorí bí a bá ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu alágbára lãrín àwọn orílẹ̀-èdè míràn wọn yíò ronúpìwàdà, wọn ó sì mọ̀ pé òun jẹ́ Ọlọ́run wọn.

5 Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn oyè àlùfã àrékéreke àti àwọn àìṣedẽdé, àwọn ti Jerúsálẹ́mù yíò sé ọrùn wọn le sí i, pé kí á kàn án mọ́ àgbélẽbú.

6 Nítorí-èyi, nítorí ti àwọn àìṣedẽdé wọn, ìparun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ yíò wá sórí wọn; àwọn tí a kì yíò sì parun ni a ó túká lãrín gbogbo àwọn orílẹ èdè.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbàtí ọjọ́ nã yíò dé tí wọn yíò gbàgbọ́ nínú mi, pé èmi ni Krístì, nígbànã ni èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn bàbá wọn pé a ó mú wọn padà sípò ní ẹran ara, lórí ilẹ̀ ayé, sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn.

8 Yíò sì ṣe tí a ó kó wọn jọ pọ̀ láti ìfúnká pípẹ́ wọn, láti àwọn erékùsù òkun, àti láti àwọn ìpín mẹ́rin ayé; àwọn orílẹ̀ èdè àwọn Kèfèrí yíò sì tóbi ní ojú mi, ni Ọlọ́run wí, ní gbígbé wọn jádewá sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn.

9 Bẹ̃ni, àwọn ọba àwọn Kèfèrí yíò jẹ́ bàbá olùtọ́jú sí wọn, àwọn ayaba wọn yíò sì di ìyá olùtọ́jú; nítorí-èyi àwọn ìlérí Olúwa tóbi sí àwọn Kèfèrí, nítorí òun ti sọ ọ́, tãni o sì lè jiyàn si?

10 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ilẹ̀ yí, ni Ọlọ́run wí, yíò jẹ́ ilẹ̀ ìní yín, àwọn Kèfèrí ni a ó sì bùkún-fún lórí ilẹ̀ nã.

11 Ilẹ̀ yí yíò sì jẹ́ ilẹ̀ òmìnira sí àwọn Kèfèrí, kì yíò sì sí àwọn ọba lórí ilẹ̀ nã, tí yíò gbé sókè sí àwọn Kèfèrí.

12 Ẹ̀mì yíò sì dábõbò ilẹ̀ yí láti dojúkọ gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè míràn.

13 Ẹni tí ó bá sì bá Síónì jà yíò parun, ni Ọlọ́run wí.

14 Nítorí ẹni tí ó gbé ọba kan sókè sí mi yíò parun, nítorí èmi, Olúwa, ọba ọ̀run, yíò jẹ́ ọba wọn, èmi yíò sì jẹ́ ìmọ́lè sí wọn títí láé, tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi.

15 Nítorí-èyi, nítorí ìdí èyí, kí a lè mu àwọn májẹ̀mú mi ṣẹ èyí tí mo ti ba àwọn ọmọ ènìyàn dá, tí èmi yíò ṣe sí wọn níwọ̀n bí wọ́n ṣe wà nínú ẹran ara, èmi kò lè ṣe àìpá àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ ti òkùnkùn, àti ti ìpànìyàn, àti ti ẹ̀gbin run.

16 Nítorí-èyi, ẹni tí ó bá bá Síónì ja, àti Jũ àti Kèfèrí, àti tí ó wà ní ìdè àti ní òmìnira, àti ọkùnrin àti obìnrin, yíò parun; nítorí àwọn ni àwọn tí nṣe àgbèrè obìnrin ayé gbogbo; nítorí àwọn tí kò bá wà fún mi nlòdì sí mi, ni Ọlọ́run wa wí.

17 Nítorí èmi yíò mú àwọn ìlérí mi ṣẹ èyí tí mo ti ba àwọn ọmọ ènìyàn dá, tí èmi yíò ṣe sí wọn níwọ̀n bí wọ́n ṣe wà nínú ẹran ara—

18 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, báyĩ ni Ọlọ́run wa wí: Èmi yíò pọ́n irú ọmọ yín lójú nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò mú ọkàn àwọn Kèfèrí rọ̀, tí àwọn yíò jẹ́ bí bàbá sí wọn; nítorí-èyi, àwọn Kèfèrí ni a ó bùkún-fún tí a ó sì kà mọ́ ará ilé Isráẹ́lì.

19 Nítorí-èyi, èmi yíò ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún irú ọmọ yín, àti àwọn tí a ó kà mọ́ irú ọmọ yín, títí láé, fun ilẹ̀ ìní wọn; nítorí ó jẹ́ àṣàyàn ilẹ̀, ni Ọlọ́run wí fún mi, ga ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn lọ, nítorí-èyi èmi yíò mú gbogbo ènìyàn tí ngbé lórí ilẹ̀nã ki wọn ó sìn mí, ni Ọlọ́run wí.

20 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ bí ó ti ṣe pé Ọlọ́run wa aláanú ti fi irú ìmọ̀ nlá fún wa nípa àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ jẹ́kí á rántí rẹ̀, kí á sì pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tì sí ápákan, kí á má sì ṣe sọ orí wa kodò, nítorí a kò gé wa kúrò; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a ti lé wa jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní wa; ṣùgbọ́n a ti tọ́ wa lọ sí ilẹ̀ tí ó dárajù, nítorí Olúwa ti ṣe òkun ní ọ̀nà wa, a sì wà lórí erékùṣù òkun kan.

21 Ṣùgbọ́n títóbi ni àwọn ìlérí Olúwa sí àwọn tí mbẹ lórí àwọn erékùṣù òkun; nítorí-èyi bí ó ti sọ pé àwọn erékùṣù, o di dandan ki o ju èyí lọ, àwọn arákùnrin wa sì ngbé nínú wọn pẹ̀lú.

22 Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa Ọlọ́run tí tọ́ kúrò láti ìgbà dé ìgbà kúrò ní ará ilé Isráẹ́lì, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inú dídùn rẹ̀. Àti nísisìyí kíyèsĩ i, Olúwa rántí gbogbo wọn tí a ti ṣẹ́ kúrò, nítorí-èyi ó rántí wa pẹ̀lú.

23 Nítorínã, ẹ mú ọkàn yín yọ̀, kí ẹ sì rántí pé ẹ̀yin ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tìkarãyín—láti yan ọ̀nà ikú àìlópin tàbí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun.

24 Nítorí-èyi, ẹyin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ ṣe ìlàjà ara yín sí ìfẹ́ Ọlọ́run, kì í sì ṣe sí ìfẹ́ ti èṣù àti ẹran ara; ẹ sì rántí, lẹ́hìn tí ẹ bá ti ṣe ìlàjà sí Ọlọ́run, pé nínú àti nípa ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan ni a gbà yín là.

25 Nítorí-èyi, kí Ọlọ́run jí yín sókè kúrò nínú ikú nípa agbára àjínde òkú, àti pẹ̀lú kúrò nínú ikú àìlópin nípa agbára ètùtù nì, kí á lè gbà yín sí ìjọba ayérayé Ọlọ́run, kí ẹ̀yin kí ó lè yìn ín nípa ore ọ̀fẹ́ ti Ọlọ́run. Àmín.