Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 28


Ori 28

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìjọ onígbàgbọ́ èké ní a o dá sílẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Wọn yíò kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú, tí ó wà lásán, àti tí ó jẹ́ tí aláìgbọ́n—Ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ yíò di púpọ̀ nítorí àwọn ayédèrú olùkọ́—Èṣù yíò rú ní ọkàn àwọn ènìyàn—Òun yíò kọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ sí yín, gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí ti rọ̀ mí; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé wọn kò lè ṣe àìṣẹ.

2 Àwọn ohun èyí tí a ó sì kọ láti inú ìwé nã yíò jẹ́ tí iye nlá sí àwọn ọmọ ènìyàn, àti pãpã sí irú-ọmọ wa, èyí tí i ṣe ìyókù ará ilé Ísráẹ́lì.

3 Nítorí yíò ṣe ní ọjọ́ nã tí àwọn ìjọ onígbàgbọ́ tí a fi lélẹ̀, tí kì í sì í ṣe sí Olúwa, nígbàtí ọ̀kan yíò wí fún òmíràn: Kíyèsĩ i, èmi, èmi ni ti Olúwa; àwọn òmíràn yíò sì wí pé: Èmi, èmi ni ti Olúwa; báyĩ sì ni olúkúlùkù ẹni yíò sọ tí ó ti fi àwọn ìjọ onígbàgbọ́ lélẹ̀, ti kì í sì í ṣe sí Olúwa—

4 Wọn yíò sì bá ara wọn jiyàn; àwọn àlùfã wọn yíò sì bá ara wọn jiyàn, wọn yíò sì kọ́ni pẹ̀lú ẹ̀kọ́ wọn, wọn yíò sì sẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí nfi ọ̀rọ̀-sísọ fún ni.

5 Wọ́n sì sẹ́ agbára Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì; wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn: Ẹ fetísílẹ̀ sí wa, kí ẹ sì gbọ́ ìlànà wa; nítorí kíyèsĩ i kò sí Ọlọ́run ní òní, nítorí Olúwa àti Olùràpadà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó sì ti fi agbára rẹ̀ fún ènìyàn;

6 Kíyèsĩ i, ẹ fetísílẹ̀ sí ìlànà mi; bí wọn yíò bá wípé iṣẹ́ ìyanu wà tí a ti ṣe nípa ọwọ́ Olúwa, ẹ máṣe gbà á gbọ́; nítorí ní ọjọ́ yí òun ki í ṣe Ọlọ́run ti iṣẹ́ ìyanu; òun ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

7 Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà tí yíò wípé: Ẹ jẹ́, ẹ mu, kí ẹ sì máa yọ̀, nítorí ní ọ̀la àwa yíò kú; yíò sì dára fún wa.

8 Ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà pẹ̀lú tí yíò wípé; ẹ jẹ, ẹ mu, kí ẹ sì máa yọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run—òun yíò dá yín láre ni dídá ẹ̀ṣẹ̀ kékeré; bẹ̃ni, purọ́ kékeré, jẹ ànfàní ẹnìkan nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, gbẹ́ kòtò fún aládũgbò rẹ; kò sí ibi nínú èyí; sì ṣe gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, nítorí ní ọ̀la àwa yíò kú; bí ó bá sì jẹ́ pé àwa jẹ̀bi, Ọlọ́run yíò nà wá pẹ̀lú pàṣán díẹ̀, ní ìgbẹ̀hìn a ó sì gbà wá là ní ìjọba Ọlọ́run.

9 Bẹ̃ni, ọ̀pọ̀ ni yíò sì wà tí yíò kọ́ni bí irú èyí, àwọn ẹ̀kọ́ ayédèrú àti tí ó wà lásán àti tí ó jẹ́ ti aláìgbọ́n, wọn yíò sì fẹ̀ sókè ní ọkàn wọn, wọn yíò sì gbìyànjú gidi láti pa ìmọ̀ràn wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ Olúwa; iṣẹ́ wọn yíò sì wà ní òkùnkùn.

10 Ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò sì kígbe látí ilẹ̀ wá sí wọn.

11 Bẹ̃ni, gbogbo wọ́n tí jáde kúrò ní ọ̀nà nã; wọ́n ti dibàjẹ́.

12 Nítorí ìgbéraga, àti nítorí àwọn ayédèrú olùkọ́, àti ayédèrú ẹ̀kọ́, àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn ti dibàjẹ́, àwọn ìjọ onígbàgbọ́ wọn sì gbé sókè; nítorí ti ìgbéraga wọ́n ní wọ́n fẹ̀ sókè.

13 Wọ́n ja tálákà ní olè nítorí ti ibi mímọ́ dídára wọn; wọ́n ja tálákà ní olè nítorí aṣọ dídára wọ́n; wọ́n sì ṣe inúnibíni sí ọlọ́kàn tútù àti oníròbìnújẹ́-ọkàn-ènìyàn, nítorí nínú ìgbéraga wọ́n ní wọ́n fẹ̀ sókè.

14 Wọ́n wọ ọrùn líle àti orí gíga; bẹ̃ni, àti nítorí ìgbéraga, àti ìwà búburú, àti ohun ìríra, àti ìwà àgbèrè, gbogbo wọn ti ṣáko lọ àfi tí ó jẹ́ díẹ̀, tí wọn jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Krístì tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a tọ́ wọn, pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà wọ́n ṣìnà nítorí a kọ́ wọn nípasẹ̀ ìlànà ti ènìyàn.

15 A! àwọn ọlọgbọ́n, àti àwọn amòye, àti àwọn ọlọ́rọ̀, tí wọ́n fẹ̀ sókè ní ìgbéraga ọkàn wọn, àti gbogbo àwọn tí nwãsù àwọn ayédèrú ẹ̀kọ́, àti gbogbo àwọn tí wọ́n nhu ìwà àgbèrè, tí wọ́n nyí òtítọ́ ọ̀nà Olúwa padà, ègbé, ègbé, ègbé ni fún wọn, ni Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè wí, nítorí a ó tì wọ́n sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì!

16 Ègbé ni fún àwọn tí nyí èyítí ó tọ́ sí ápákan fún ohun asán tí wọ́n sì nkẹ́gàn sí èyí tí ó dára, tí wọ́n sì nsọ pé kò ní iye lórí! Nítorí ọjọ́ nã yíò dé tí Olúwa Ọlọ́run yíò bẹ àwọn olùgbé ayé wò kíákíá; ní ọjọ́ nã tí wọ́n bá sì ti gbó nínú àìṣedẽdé ní kíkún wọn yíò parun.

17 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, bí àwọn olùgbé ayé bá ronúpìwàdà níti ìwà búburú àti ìríra wọn a kì yíò pa wọ́n run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

18 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára, àgbèrè gbogbo ayé, kò lè ṣe àìsubú sí ilẹ̀, títóbi sì ni ìṣubú rẹ̀ yíò jẹ́.

19 Nítorí ijọba èṣù gbọdọ̀ mì, àwọn tí ó bá sì jẹ́ tirẹ̀ ni ó di dandan pé kí á rú sókè sí ìrònúpìwàdà, bíbẹ̃kọ́ èṣù yíò gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n àìlópin rẹ̀, a ó sì rú wọn sókè sí ìbínú, wọn yíò sì parun;

20 Nítorí kíyèsĩ i, ní ọjọ́ nã ní òun yíò rú ní ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, tí yíò sì rú wọn sókè sí ìbínú sí èyí tí ó dára.

21 Àwọn míràn sì ni òun yíò rọ̀, tí yíò sì mú wọn dákẹ́ sínú àbò ti ara, tí wọn yíò wípé: Gbogbo rẹ̀ dára ní Síónì; bẹ̃ni Síónì ṣe rere, gbogbo rẹ̀ dára—báyĩ sì ni èṣù nyan ọkàn wọn jẹ, ó sì tọ́ wọn lọ sísàlẹ̀ lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sí ọ̀run àpãdì.

22 Sì kíyèsĩ i, àwọn míràn ni ó tàn lọ, tí ó sì sọ fún pé kò sí ọ̀run-àpãdì; òun sì wí fún wọn: Èmi kì í ṣe èṣù, nítorí kò sí ọ̀kan—báyĩ sì ni ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́ ní etí wọn, títí o fi gbá wọn mú pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n rẹ̀ tí ó báni lẹ́rù, láti ibi tí kò sì ìdásílẹ̀.

23 Bẹ̃ni, a gbá wọn mú pẹ̀lú ikú, àti ọ̀run àpãdì; àti ikú, àti ọ̀run àpãdì, àti èṣù, àti gbogbo èyí tí a mú ní ipá níbẹ̀ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, kí á sì dá wọn léjọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, láti ibi tí wọn gbọ́dọ̀ lọ sínú ibi tí a pèsè fún wọn, àní adágún iná àti imí ọjọ́, èyí tí nṣe oró àìnípẹ̀kun.

24 Nítorí-èyi, ègbé ni fún ẹni nã tí ó wà ní ìrọra ní Síónì!

25 Ègbé ni fún ẹni nã tí ó nkígbe: Gbogbo rẹ̀ dára!

26 Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni nã tí ó fetísílẹ̀ sí ìlànà àwọn ènìyàn, tí ó sì sẹ́ agbára Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́!

27 Bẹ̃ni, égbé ni fún ẹni nã tí ó wípé: Àwa ti gbà, àwa kò sì fẹ́ mọ́!

28 Àti ní àkópọ̀, ègbé ni fún gbogbo àwọn tí nwárìrì, tí wọ́n sì nbínú nítorí òtítọ́ Ọlọ́run! Nítorí kíyèsĩ i, ẹni tí a kọ́ sórí àpáta gbà á pẹ̀lú inúdídùn; ẹni tí a sì kọ́ sórí ìpìlẹ̀ tí ó ní yanrìn nwárìrì kí ó má bá a ṣubú.

29 Ègbé ni fún ẹni nã tí yíò wípé: Àwa ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwa kò sì fẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sĩ; mọ́, nítorí a ní tó!

30 Nítorí kíyèsĩ i, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èmi yíò fi fún àwọn ọmọ ènìyàn lẹ́sẹ lẹ́sẹ ilànà lé ìlànà, díẹ̀ níhin, díẹ̀ lọ́hún; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ó bá fetísílẹ̀ sí ẹ̀kọ́ mi, tí wọ́n sì ya etí wọn sí ìmọ̀ràn mi, nítorí wọn yíò kọ́ ọgbọ́n; nítorí ẹni tí ó gbà ni èmi yíò fi fún sĩ; àti láti ọwọ́ àwọn tí yíò wípé, Àwa ní tó, láti ọwọ́ wọn ni a ó ti gba àní èyí tí wọ́n ní kúrò.

31 Ìfibú ni ẹni tí o gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn, tàbí tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀, tàbí tí yíò fetísílẹ̀ sí ìlànà àwọn ènìyàn, àfi tí a bá fi ìlànà wọn fún ni nípa Ẹ̀mí Mímọ́.

32 Ègbé ni fún àwọn Kèfèrí, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí! Nítorí l’áìṣírò èmi yíò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọn yíò sẹ́ mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi yíò ní ãnu sí wọn, ni Olúwa Ọlọ́run wí, bí wọ́n yíò bá ronúpìwàdà tí wọn wá sọ́dọ̀ mi; nítorí ọwọ́ mi nà sóde ní gbogbo ọjọ́, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí.