Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 25


Orí 25

Ní àkokò Bíbọ̀ kejì, a ó jó gbogbo àwọn agbéraga àti àwọn olùṣe búburú níná bí àkékù koríko—Èlíjàh yíò padà wá kí ọjọ́ nlá èyítí ó ní ẹ̀rù nã ó tó dé—A fi orí ìwé yìi wé Málákì 4. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Nítorí ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ nbọ̀ èyítí ó rí bí iná ìléru, àti tí yíò jó gbogbo àwọn agbéraga, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú, yíò dàbí àkékù koríko; ọjọ́ nã tí nbọ̀ yíò sì jó wọn run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, tí kì yíò fi ku gbòngbò tàbí ẹ̀ka fún wọn.

2 Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, ni Ọmọ Òdodo nã yíò dìde pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; ẹ̀yin ó sì jáde lọ, ẹ̀yin ó sì máa dàgbà bí àwọn ẹgbọrọ màlũ inú agbo.

3 Ẹ̀yin ó sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀; nítorí wọn ó já sí eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ nã tí èmi yíò ṣe ohun yĩ, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

4 Ẹ rántí òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, èyítí mo pa ní àṣẹ fún un ní Hórébù fún gbogbo Ísráẹ́lì, pẹ̀lú àwọn ìlànà àti ìdájọ́ wọnnì.

5 Kíyèsĩ, èmi yíò rán wòlĩ Èlíjàh sí yín kí ọjọ́ Olúwa nã èyítí íṣe nlá tí ó sì ní ẹ̀rù tó dé.

6 Òun yíò sì yí ọkàn àwọn bàbá padà sí ti àwọn ọmọ wọn, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ti àwọn bàbá wọn, kí èmi kí ó má bá wá kí èmi ó sì fi ayé bú.