Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 13


Orí 13

A dãbò bò Ábínádì pẹ̀lú agbára Ọlọ́run—Ó nkọ́ni ní Òfin Mẹ́wã—Ìgbàlà kò wá nípa òfin Mósè nìkan—Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yíò ṣe ètùtù kan yíò sì ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, nígbàtí ọba ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sì wí fún àwọn àlùfã rẹ̀ pé: Ẹ mú arákùnrin yĩ kúrò, kí ẹ sì pã; nítorípé kíni àwa ní íṣe pẹ̀lú rẹ̀ nítorípé aṣiwèrè ni íṣe.

2 Nwọ́n sì tẹ̀ síwájú, nwọ́n sì gbìyànjú láti gbé ọwọ́ nwọn lé e; ṣùgbọ́n ó dojúkọ nwọn, ó wí fún nwọn pé:

3 Ẹ máṣe fọwọ́kàn mí, nítorítí Ọlọ́run yíò lù yín tí ẹ bá fọwọ́ bà mí, nítorítí èmi kò ì tĩ jíṣẹ́ ti Olúwa rán mi; bákannã ni èmi kò ì tĩ sọ fún un yín èyítí ẹ̀yin bí mí; nítorínã Ọlọ́run kò ní gbà pé kí ẹ pa mí run ní àkokò yĩ.

4 Ṣùgbọ́n èmi gbọ́dọ̀ mu àwọn òfin èyítí Ọlọ́run pã láṣẹ fún mi ṣẹ; àti nítorípé èmi ti sọ òtítọ́ fún un yín, ẹ̀yin nṣe ìbínú mi. Àti pẹ̀lú, nítorípé èmi sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ẹ̀yin ti pè mí ní aṣiwèrè.

5 Nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ọba Nóà kò fi ọwọ́ kàn án, nítorítí Ẹ̀mi Olúwa wà lórí rẹ̀; ojú rẹ̀ sì ndán fún ìtànmọ́lẹ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀, àní gẹ́gẹ́bí ti Mósè ṣe rí nígbàtí ó wà ní orí-òkè Sínáì, nígbàtí ó nbá Olúwa sọ̀rọ̀.

6 Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; ó si tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wípé:

7 Ẹ̀yin ríi pé ẹ kò ní agbára láti pa mí, nítorínã èmi parí ọ̀rọ̀ mi. Bẹ̃ni, èmi sì wòye pé ó mú ọkàn an yín gbọgbẹ́, nítorítí èmi sọ òtítọ́ fún un yín nípa àìṣedẽdé e yín.

8 Bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ mi sì mú u yín kún fún ìyanu àti ìtagìrì, àti pẹ̀lú ìbínú.

9 Ṣùgbọ́n èmi parí ọ̀rọ̀ mi; bẹ̃ sì ni kò já mọ́ ohun kan ibití èmi lè lọ, bí èmi bá ti di ẹni-ìgbàlà.

10 Ṣùgbọ́n ohun yĩ ni èmi wí fún yín, ohun tí ẹ̀yin yíò fi mí ṣe, lẹ́hìn èyí, yíò dàbí irú ohun àti ẹ̀ya àwọn ohun tí mbọ̀ wá.

11 Àti nísisìyí mo ka èyítí ó kù nínú àwọn òfin Ọlọ́run síi yín, nítorítí mo wòye pé a kò kọ nwọn sí ọkàn nyín; èmi wòye pé ẹ̀yin ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àìṣedẽdé, ẹ̀yin sì ti fi kọ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé nyín.

12 Àti nísisìyí, ẹ̀yin rántí pé mo wí fún nyín wípé: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya ère-kére fún ara rẹ, tàbí àwòrán ohun kan tí mbẹ lókè ọ̀run, tàbí ohun kan tí mbẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí èyítí mbẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

13 Àti pẹ̀lú: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ orí ara rẹ bá fún nwọn, tàbí kí ìwọ sìn nwọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run owú, tí mbẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wò lára àwọn ọmọ, títí dé ìran kẹ́ta àti ìran kẹ́rin àwọn tí ó korira mi;

14 Tí èmi sì nfi ãnú hàn sí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn tí nwọn fẹ́ràn mi, tí nwọ́n sì npa awọn òfin mi mọ́.

15 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ lásán; nítorítí Olúwa kí yíò ka àwọn tí ó pe orúkọ rẹ̀ lásán sí aláìlẹ́ṣẹ̀.

16 Rántí ọjọ́ ìsinmi, láti yà á sí mímọ́.

17 Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yíò fi ṣe iṣẹ́, tí ìwọ yíò sì ṣe iṣẹ́ rẹ gbogbo;

18 Ṣùgbọ́n ọjọ́ kéje, ti íṣe ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́, ìwọ, tàbí ọmọ rẹ okùnrin, tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin, tàbí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin, tàbí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí màlũ rẹ, tàbí àlejò rẹ ti mbẹ nínú ibodè rẹ̀;

19 Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run òun ayé, àti òkun, àti gbogbo ohun tí mbẹ nínú rẹ̀; nítorí-èyi ni Olúwa ṣe bùsí ọjọ́ ìsinmi, tí ó sì yã sí mímọ́.

20 Bọ̀wọ̀ fún bàbá òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

21 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn.

22 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.

23 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀rí èké sí ẹnìkéjì rẹ.

24 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, tàbí sí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, tàbí sí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, tàbí sí akọ-màlũ rẹ, tàbí sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí sí ohunkóhun tĩ ṣe ti ẹnìkẹjì rẹ.

25 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún nwọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ti kọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé kí nwọ́n ṣe ohun wọ̀nyí láti lè pa àwọn òfin wọ̀nyí mọ́?

26 Mo wí fún nyín, Rárá; nítorítí tí ẹ̀yin bá ti ṣe eleyĩ, Olúwa kì bá ti mú kí èmi jáde wá ati lati sọ asọtẹ́lẹ̀ búburú nípa àwọn ènìyàn yí.

27 Àti nísisìyí ẹ̀yin ti wípé ìgbàlà wá nípa òfin Mósè. Mo wí fún nyín pé ó tọ́ fún nyín pé kí ẹ̀yin kí ó pa òfin Mósè mọ́ síbẹ̀síbẹ̀; ṣùgbọ́n mo wí fún nyín, pé àkokò nã yíò dé tí kò ní tọ́ mọ́ láti pa òfin Mósè mọ́.

28 Àti pãpã, mo wí fún nyín, pé ìgbàlà kò wá nípa òfin nìkan; àti pé tí kò bá ṣe nítorí ètùtù nã, èyítí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé àwọn ènìyàn rẹ̀, pé nwọ́n níláti parun dandan, l’áìṣírò òfin Mósè.

29 Àti nísisìyí mo wí fún nyín pé ó tọ́ pé kí a fi òfin kan fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, bẹ̃ni, àní òfin tí ó le jọjọ; nítorítí nwọ́n jẹ́ ènìyàn ọlọ́rùn líle, tí nwọ́n yára ṣe àìṣedẽdé, tí nwọ́n sì lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn;

30 Nítorínã òfin kan nbẹ tí a fi fún nwọn, bẹ̃ni, òfin nípa ṣíṣe iṣẹ́ àti ìlànà, òfin tí nwọ́n níláti pamọ́ fínni-fínni láti ọjọ́ kan dé ọjọ́ òmíràn, kí nwọ́n lè wà ní ìrántí Ọlọ́run àti iṣẹ́-ìsìn nwọn sĩ.

31 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo wí fún nyín, àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀yà àwọn ohun tí mbọ̀ wá.

32 Àti nísisìyí, njẹ́ nwọ́n ní òye òfin nã bí? Mo wí fún nyín, Rárá, gbogbo nwọn kọ́ ní ó ní òye òfin nã; èyí rí bẹ̃ nítorí líle àyà nwọn; nítorítí nwọn kò ní òye wípé kò sí ẹnìkan tí a lè gbalà bíkòṣe nípasẹ̀ ìràpadà Ọlọ́run.

33 Nítorí kíyèsĩ, njẹ́ Mósè kò sọtẹ́lẹ̀ sí nwọn nípa bíbọ̀ Messia, àti pé Ọlọ́run yíò ra àwọn ènìyàn rẹ padà bí? Bẹ̃ni, àní gbogbo àwọn wòlĩ tí nwọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé—njẹ́ nwọn kò ha ti sọ̀rọ̀ lọ, sọ̀rọ̀ bọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí bí?

34 Njẹ́ nwọn kò ti wípé Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yíò sọ̀kalẹ̀ lãrín ọmọ-ènìyàn, yíò sì gbé àwòrán ènìyàn wọ̀, yíò sì lọ lórí ilẹ̀ ayé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára?

35 Bẹ̃ni, njẹ́ nwọn kò sì ti wí pẹ̀lú pé yíò mú àjĩnde òkú wá ṣẹ, àti pé kí òun tìkararẹ̀ lè jẹ́ ẹni-ìnilára àti ẹni ìfiyàjẹ?