Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 17


Orí 17

Álmà gba ọ̀rọ̀ Ábínádì gbọ́, ó sì kọ nwọ́n sílẹ̀—Ábínádì kú ikú iná—Ó sọtẹ́lẹ̀ àrùn àti ikú iná lórí àwọn tí ó pa á. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Ábínádì ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí ọba pã láṣẹ kí àwọn àlùfã mú u kí nwọ́n sì pa á.

2 Ṣùgbọ́n ẹnìkan wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Álmà, òun nã sì jẹ́ àtẹ̀lé ìdílé Nífáì. Ó sì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, ó sì gba ọ̀rọ̀ tí Ábínádì ti sọ gbọ́, nítorítí ó mọ̀ nípa àìṣedẽdé èyítí Ábínádì ti jẹ́rĩ sí nwọn; nítorínã ó bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ọba pé kí ó máṣe bínú sí Ábínádì, ṣùgbọ́n kí ó gbà á lãyè kí ó jáde lọ ní àlãfíà.

3 Ṣùgbọ́n ọba bínú sí i, ó sì ní kí nwọ́n ju Álmà sóde kúrò lãrín nwọn, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, kí nwọ́n lè pa á.

4 Ṣùgbọ́n ó sá kúrò níwájú nwọn, ó sì sá pamọ́ kí nwọn má bã rí i. Nígbàtí ó sì ti sá pamọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ó sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ábínádì ti sọ.

5 Ó sì ṣe, tí ọba pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ ka Ábínádì mọ́, kí nwọ́n sì múu; nwọ́n sì dĩ, nwọ́n sì gbée jù sínú túbú.

6 Lẹ̀hìn ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́hìn tí ó ti bá àwọn àlùfã a rẹ̀ dámọ̀ràn, ó pàṣẹ kí nwọ́n tún mú u wá síwájú òun.

7 Ó sì wí fún un pé: Ábínádì, àwa ti fi ẹ̀sùn kàn ọ́, ikú sì tọ́ sí ọ.

8 Nítorítí ìwọ ti sọ wípé kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá sí ãrín àwọn ọmọ ènìyàn; àti nísisìyí, fún ìdí èyí a ó pa ọ́, àfi tí ìwọ bá sẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ búburú tí ìwọ ti sọ nípa mi àti àwọn ènìyàn mi.

9 Nísisìyí, Ábínádì wí fún un pé: Mo wí fún ọ, èmi kò lè sẹ́ ọ̀rọ̀ tí èmi ti wí fún ọ nípa àwọn ènìyàn yí, nítorípé òtítọ́ ni nwọ́n; kí ìwọ kí ó sì lè ní ìdánilójú nípa nwọn ni èmi ṣe gbà kí èmi kí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀ rẹ.

10 Bẹ̃ni, èmi yíò jìyà àní títí dé ikú, èmi kò sì ní sẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, nwọn yíò sì dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ. Tí ìwọ bá si pa mí, ìwọ yíò ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, èyí yíò sì tún dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ ní ọjọ́ ìkẹhìn.

11 Àti nísisìyí, ọba Nóà sì ṣetán láti tú u sílẹ̀, nítorítí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorítí ó bẹ̀rù pé ìdájọ́ Ọlọ́run yíò de sórí òun.

12 Ṣùgbọ́n àwọn àlùfã gbé ohùn nwọn sókè ta kò ó, nwọ́n bẹ̀rẹ̀ síi fi ẹ̀sùn kàn án, wípé: Ó ti kẹ́gàn ọba. Nítorínã, a rú ọba sókè ní ìbínú síi, òun sì jọ̀wọ́ ọ rẹ̀ sílẹ̀ fún pípa.

13 Ó sì ṣe tí nwọ́n múu, nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì jẹ ẹran ara rẹ̀ níyà, pẹ̀lú ẹ̀rú igi, àní títí dé ojú ikú.

14 Àti nísisìyí, nígbàtí ọ̀wọ́ iná nã bẹ̀rẹ̀ sí jó o, ó kígbe sí nwọn lóhùn rara, wípé:

15 Ẹ kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti ṣe sí mi, bẹ̃ni yíò rí tí àwọn irú-ọmọ nyín yíò ṣe tí ọ̀pọ̀ ènìyàn yíò jẹ ìrora oró ikú nípa iná bí èmi ti njẹ ìrora; èyí sì rí bẹ̃ nítorítí nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìgbàlà Olúwa Ọlọ́run nwọn.

16 Yíò sì ṣe, tí a ó fi onírurú àrùn bẹ̀ yín wò nítorí àìṣedẽdé nyín.

17 Bẹ̃ni, a ó kọlũ yín ní gbogbo ọ̀nà, a ó sì fọ́n nyín ká kiri síwá àti sẹ́hìn, àní gẹ́gẹ́bí ọ̀wọ́ ẹran ti ẹranko búburú inú ìgbẹ́ nfọ́n-ká.

18 Àti ní ọjọ́ nì, a ó dọdẹ nyín àwọn ọ̀tá yíò sì mú nyín, nígbànã àní ẹ̀yin yíò jìyà, bí èmi ti jìyà pẹ̀lú, ìrora oró ikú nípa iná.

19 Báyĩ, ni Ọlọ́run san ẹ̀san fún àwọn tí ó pa àwọn ènìyàn rẹ̀ run. A! Ọlọ́run, gba ẹ̀mí mi.

20 Àti nísisìyí, nígbàtí Ábínádì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó ṣubú lulẹ̀, nítorítí ó ti kú ikú iná; bẹ̃ni, nítorítí a ti pa á nítorípé kò ní sẹ́ àṣẹ Ọlọ́run, tí ó sì ti fi èdìdì di òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ikú rẹ̀.