Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 25


Orí 25

Àwọn àtẹ̀lé Múlẹ́kì tí nwọ́n wà ní Sarahẹ́múlà di ará Nífáì—Nwọ́n kọ́ nípa àwọn ará Àlmà, àti nípa Sẹ́nífù—Álmà rì Límháì bọmi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀—Mòsíà fi àṣẹ fún Álmà fún ìdásílẹ̀ Ìjọ-Ọlọ́run. Ní ìwọ̀n ọdún 120 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ọba Mòsíà sì mú kí a kó àwọn ènìyàn nã jọ.

2 Nísisìyí àwọn ọmọ Nífáì kò pọ̀ púpọ̀, tàbí pé àwọn tí nwọ́n jẹ́ àtẹ̀lé Nífáì, kò tó bí àwọn ará Sarahẹ́múlà ṣe pọ̀ tó, tí nwọn íṣe ọmọ-àtẹ̀lé Múlẹ́kì, àti àwọn tí nwọ́n jáde pẹ̀lú rẹ̀ sínú aginjù.

3 Àwọn ará Nífáì pẹ̀lú àwọn ará Sarahẹ́múlà kò sì pọ̀ tó àwọn ará Lámánì; bẹ̃ni, nwọn kò pọ̀ tó ìdásíméjì nwọn.

4 Àti nísisìyí, a kò gbogbo àwọn ará Nífáì jọ pọ̀, àti gbogbo àwọn ará Sarahẹ́múlà pẹ̀lú, a sì kó nwọ́n jọ pọ̀ sí apá ọ̀nà méjì.

5 Ó sì ṣe tí Mòsíà kã, tí ó sì pàṣẹ pé kí a ka ìwé ìrántí Sẹ́nífù sí àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, ó ka ìwé ìrántí àwọn ará Sẹ́nífù, láti ìgbàtí nwọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà títí tí nwọ́n tún padà wá.

6 Ó sì tún ka àkọsílẹ̀ nípa Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpọ́njú nwọn, láti ìgbà tí nwọ́n kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà títí dé ìgbà tí nwọ́n tún padà.

7 Àti nísisìyí, nígbàtí Mòsíà ti parí kíka ìwé ìrántí nã, àwọn ènìyàn rẹ̀ tí nwọ́n dúró lẹ́hìn ní ilẹ̀ nã kún fún ìyanu, hã sì ṣe nwọ́n.

8 Nítorí nwọn kò mọ́ ohun tí àwọn ìbá rò; nítorí nígbàtí nwọ́n rí àwọn tí Olúwa ti kó yọ kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n kún fún ayọ̀ gidigidi.

9 Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa àwọn arákùnrin nwọn, èyítí àwọn ará Lámánì pa, nwọ́n kún fún ìrora-ọkàn, àní nwọ́n sọkún púpọ̀ nítọrí ìrora-ọkàn nwọn.

10 Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa õre Ọlọ́run, àti agbára rẹ̀ èyítí ó fi gba Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì àti kúrò nínú oko-ẹrú, nwọ́n gbé ohùn nwọn sókè, nwọ́n sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.

11 Ẹ̀wẹ̀, nígbàtí nwọ́n ronú nípa àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n jẹ́ arákùnrin nwọn, nípa ipò ẹ̀ṣẹ̀ àti ìbàjẹ́ nwọn, nwọ́n kún fún ìrora àti àròkàn fún àlãfíà ọkàn nwọn.

12 Ó sì ṣe, tí àwọn tí íṣe ọmọ Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti fẹ́ aya nínú àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì, banújẹ́ lórí ìwà àwọn bàbá nwọn, nwọn kò sì jẹ́ orúkọ àwọn bàbá nwọn mọ́, nítorínã nwọ́n gbé orúkọ Nífáì, pé kí a lè pè nwọ́n ní àwọn ọmọ Nífáì, kí a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn tí à npè ní ará Nífáì.

13 Àti nísisìyí gbogbo àwọn ará Sarahẹ́múlà ni a kà pẹ̀lú àwọn ará Nífáì, a sì ṣe èyí nítorípé nwọn kò gbé ìjọba lé ọwọ́ ẹnìkẹ́ni bí kò bá íṣe àtẹ̀lé Nífáì.

14 Àti nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí Mòsíà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ àti kíkà sí àwọn ènìyàn nã, ó fẹ́ kí Álmà nã bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀.

15 Álmà sì bá nwọn sọ̀rọ̀, nígbàtí nwọ́n ti péjọ pọ̀ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ó sì lọ láti ìsọ̀rí kan dé òmíràn, ó sì nwãsù sí àwọn ènìyàn fún ìrònúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.

16 Ó sì gba àwọn ènìyàn Límháì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, gbogbo àwọn tí a ti yọ nínú oko-ẹrú níyànjú, pé kí nwọ́n rántí pé Olúwa ni ó kó nwọn yọ.

17 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ohun púpọ̀, tí ó sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó bá nwọn sọ, ọba Límháì ní ìfẹ́ láti ṣe ìrìbọmi; gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ nã sì ní ìfẹ́ láti ṣe rìbọmi pẹ̀lú.

18 Nítorínã, Álmà jáde lọ sínú omi ó sì rì nwọn bọmi; bẹ̃ni, ó rì nwọn bọmi gẹ́gẹ́bí ó ṣe ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nínú omi Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí ó sì ṣe ìrìbọmi ni nwọ́n jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run; nítorí ìdí ìgbàgbọ́ nwọn nínú ọ̀rọ̀ Álmà.

19 Ó sì ṣe, tí ọba Mòsíà fún Álmà ní ẹ̀tọ́ láti dá àwọn ìjọ-Ọlọ́run sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ó sì fún un ní àṣẹ kí ó yan àwọn àlùfã, àti olùkọ́ni lórí ìjọ-Ọlọ́run kọ̃kan.

20 Nísisìyí, a ṣe eleyĩ nítorípé àwọn ènìyàn pọ̀ púpọ̀ tí a kò lè ṣe àkóso fún nípasẹ̀ olùkọ́ni kanṣoṣo; bẹ̃ sì ni nwọ́n kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àpéjọ kanṣoṣo;

21 Nítorínã, nwọ́n kó ara nwọn jọ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, tí à npè ní ìjọ; ìjọ kọ̃kan sì ní àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni tirẹ̀, àlùfã kọ̃kan sì nwãsù ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí a ṣe fi lée lọ́wọ́ láti ẹnu Álmà.

22 Àti bayi, l’áìṣírò àwọn ìjọ pọ̀ púpọ̀, gbogbo nwọn jẹ́ ìjọ kanṣoṣo, bẹ̃ni, àní ìjọ-Ọlọ́run; nítorítí kò sí ohun kan tí a wãsù nínú gbogbo ìjọ wọ̀nyí bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

23 Àti nísisìyí ìjọ méje ni ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà. Ó sì ṣe pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́ láti gba orúkọ Krístì, tàbí ti Ọlọ́run, ni nwọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn ìjọ-Ọlọ́run.

24 A sì pè nwọ́n ní ènìyàn Ọlọ́run. Olúwa sì da Ẹ̀mí i rẹ̀ lé nwọn lórí, nwọ́n sì di alábùkún-fún, nwọ́n sì ṣe rere lórí ilẹ̀ nã.