Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwọn Ọ̀rọ̀ ti Mọ́mọ́nì 1


Àwọn Ọ̀rọ̀ ti Mọ́mọ́nì

Ori 1

Mọ́mọ́nì ṣe ìkékúrú àwọn àwo nlá ti Nífáì—Ó fi àwọn àwo kékeré pẹ̀lú àwọn àwo yókù—Ọba Bẹ́njámínì fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdun 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, èmi Mọ́mọ́nì, tí mo fẹ́rẹ̀ gbé ìwé ìrántí èyítí èmi ti nkọ sí ọwọ́ ọmọ mi Mórónì, kíyèsĩ, èmi rí púpọ̀ nínú ìparun àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì.

2 Ó sì jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̃rún ọdún lẹ́hìn bíbọ̀ Krístì tí mo gbé àwọn ìwé ìrántí yĩ lé ọwọ́ ọmọ mi; èmi sì lérò wípé òun yíò rí gbogbo ìparun àwọn ènìyàn mi. Ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run jẹ́ kí ó lè wà lãyè, kí ó lè kọ nípa Krístì, wípé, ní ọjọ́ kan, yíò ṣe nwọ́n ní ànfàní.

3 Àti nísisìyí, èmi sọ̀rọ̀ nípa èyítí mo ti kọ; nítorí lẹ́hìn tí èmi ti ṣe ìkékúrú láti inú àwọn àwo ti Nífáì, títí dé ìjọba ọba Bẹ́njámínì yìi, èyítí Ámálẹ́kì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mo ṣe àyẹ̀wò nínú àwọn ìwé ìrántí èyítí a ti gbé lé mi lọ́wọ́, èmi sì rí àwọn àwo yĩ, èyítí ó ní àkọsílẹ̀ kékeré lórí àwọn wòlĩ, láti Jákọ́bù, títí dé ìjọba ọba Bẹ́njámínì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì.

4 Àwọn ohun tí ó sì wà ní orí àwọn àwo yĩ dùn mọ́ mi nínú, nítorí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti bíbọ̀ Krístì; àwọn bàbá mi sì mọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn ni a ti múṣẹ; bẹ̃ni, èmi sì tún mọ̀ wípé gbogbo àwọn ohun tí a ti sọtẹ́lẹ̀ nípa wa títí di òni ni a ti múṣẹ, gbogbo àwọn tí ó sì kù tayọ akoko yĩ ni yíò di mimuṣẹ.

5 Nítorí-èyi, èmi yan àwọn ohun wọ̀nyí láti parí àkọsílẹ̀ tèmi lórí nwọn, nínú àwọn èyí tí ó kù nínú ìwé ìrántí mi ni èmi yíò mú nínú àwọn àwo ti Nífáì; èmi kò sì lè kọ ìdákan nínú ọgọ̃rún àwọn ohun nípa àwọn ènìyàn mi.

6 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò mú àwọn àwo wọ̀nyí, tí wọ́n ní àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn nínú, èmi ó sì mú nwọn pọ̀ mọ́ ìyókù nínú àkọsílẹ̀ mi, nítorítí nwọ́n jẹ́ àṣàyàn fún mi; èmi sì mọ̀ wípé nwọn yíò jẹ́ àṣàyàn fún àwọn arákùnrin mi.

7 Èmi sì ṣe èyí fún ipa ọgbọ́n; nítorítí a bámi sọ̀rọ̀ ní ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, gẹ́gẹ́bí awọn iṣẹ ti Ẹ̀mí Olúwa èyítí ó wà nínú mi. Àti nísisìyí, èmi kò sì mọ́ ohun gbogbo; ṣùgbọ́n Olúwa mọ́ ohun gbogbo tí nbọ̀wá; nítorí-èyi, ó nṣiṣẹ́ nínú mi lati ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú rẹ̀.

8 Àdúrà mi sí Ọlọ́run ni nípa àwọn arákùnrin mi, pé nwọn lè padà wá lẹ̃kan si sí ìmọ̀ Ọlọ́run, bẹ̃ni, ìràpadà Krístì; pé nwọn lè padà jẹ́ ènìyàn rere lẹ̃kan si.

9 Àti nísisìyí, èmi Mọ́mọ́nì, tẹ̀síwájú láti parí ìwé ìrántí mi, èyítí mo mú láti inú àwọn àwo ti Nífáì; èmi sì kọọ́ gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ àti òye ti Ọlọ́run fún mi.

10 Nítorí-èyi, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámálẹ́kì ti gbé àwọn àwo wọ̀nyí lé ọwọ́ ọba Bẹ́njámínì, ó mú nwọn pẹ̀lú àwọn àwo míràn, èyítí ó ní ìwé ìrántí èyítí a ti gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọba, láti ìran dé ìran títí dé ìgbà ọba Bẹ́njámínì.

11 A sì gbe kalẹ̀ láti ọwọ́ ọba Bẹ́njámínì láti ìran dé ìran, títí nwọ́n fi dé ọwọ́ mi. Èmi, Mọ́mọ́nì, sì gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé kí a lè pa nwọ́n mọ́ láti ìsisìyí lọ. Èmi sì mọ̀ wípé a ó pa nwọ́n mọ́; nítorí àwọn ohun nlá ni a kọ lé wọn lórí, nínú èyítí àwọn ènìyàn mi àti àwọn arákùnrin nwọn yíò gba ìdájọ́, ní ọjọ́ ìkẹhìn nã tí ó lágbára, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ti kọ sílẹ̀.

12 Àti nísisìyí, nípa ọba Bẹ́njámínì yĩ—ó ní ohun kan bí ìjà lãrín àwọn ènìyàn tirẹ̀.

13 Ó sì ṣe bakannã, tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ará Lámánì jáde wá kúrò ní ilẹ̀ Nífáì, láti dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọba Bẹ́njámínì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì dojúkọ nwọ́n; ó sì bá wọn jà nínú agbára ọwọ́ rẹ̀, pẹ̀lú idà Lábánì.

14 Pẹ̀lú agbára Olúwa ni nwọ́n sì bá àwọn ọ̀tá nwọn jà, títí nwọ́n fi pa ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n bá àwọn ará Lámánì jà títí nwọ́n fi lé nwọn jáde kúrò nínú gbogbo ilẹ̀ ìní nwọn.

15 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí àwọn Krístì ayédèrú ti kọjá lọ, tí a sì ti pa nwọ́n lẹ́nu mọ́, tí nwọ́n sì ti jìyà gẹ́gẹ́bí ìwà búburú nwọn;

16 Lẹ́hìn tí àwọn wòlĩ èké, àti oníwãsù àti olùkọ́ni èké lãrín àwọn ènìà nã ti wà, tí a sì ti fi ìyà jẹ gbogbo àwọn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́bí ìwà búburú nwọn; lẹ́hìn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà àti ìyapa lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì ti wà, kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọba Bẹ́njámínì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn wòlĩ mímọ́ tí nwọ́n wà lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

17 Sì kíyèsĩ, ọba Bẹ́njámínì jẹ́ ẹni mímọ́, ó sì jọba lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí nínú ìwà òdodo; àwọn ẹni mímọ́ sì pọ̀ nínú ilẹ̀ nã, nwọ́n sì nsọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú agbára àti pẹ̀lú àṣẹ; nwọ́n si lo ọ̀rọ̀ líle nítorí èrèdí ọrùnlíle àwọn ènìyàn nã—

18 Nítorí-èyi, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn wọ̀nyí, ọba Bẹ́njámínì, nípa ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ àti gbogbo ìyè ẹ̀mí rẹ̀, àti àwọn wòlĩ pẹ̀lú, sì tún dá àlãfíà padà sínú ìlú nã lẹ̃kan si.