Àwọn Ìwé Mímọ́
Abráhámù 2


Orí 2

Ábráhámù kúrò ní Úrì láti lọ sí Kénáánì—Jéhófàh fi ara hàn án ní Háránì—Gbogbo àwọn ìbùkún ìhìnrere ni a ṣe ìlérí fún irú ọmọ rẹ̀ àti nípasẹ̀ irú ọmọ rẹ̀ sí gbogbo ènìyàn—Ó lọ sí Kénáánì àti síwájú sí Égíptì.

1 Nísisìyí Olúwa Ọlọ́run mú kí ìyàn ó pọ̀ síi gidigidi ní ilẹ̀ Úrì, tó bẹ́ẹ̀ tí Háranì, arákùnrin mi, kú; ṣùgbọ́n Tẹ́rà, bàbá mi, sì gbé síbẹ̀ ní ilẹ̀ Úrì, ti àwọn ará Káldéà.

2 Ó sì ṣe tí èmi, Ábráhámù, mú Sárai bí ìyàwó, àti Nẹ́hórì, arákùnrin mi, mú Mílkà bí ìyàwó, ẹnití í ṣe ọmọbìnrin Háránì.

3 Nísisìyí Olúwa ti wí fún mi pé: Ábráhámù, jade kúrò ní ilẹ̀ rẹ, àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, àti kúrò ní ilé bàbá rẹ, sí ilẹ̀ kan tí èmi yíò fi hàn ọ́.

4 Nítorínáà mo kúrò ní ilẹ̀ Úrì, ti àwọn ará Káldéà, láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì; mo sì mú Lọ́tì, ọmọ arákùnrin mi, àti ìyàwó rẹ̀, àti Sáráì ìyàwó mi; àti bákannáà bàbá mi sì tẹ̀lé mi, sí ilẹ̀ náà èyítí a pè ní Háránì.

5 Ìyàn náà sì dínkù; bàbá mi sì dúró ní Háránì ó sì gbé níbẹ̀, nítorí àwọn agbo ẹran púpọ̀ wà ní Háránì; bàbá mi sì yípadà lẹ́ẹ̀kansíi sí ìbọ̀riṣà rẹ̀, nítorínáà òun tẹ̀síwájú ní Háránì.

6 Ṣùgbọ́n èmi, Ábráhámù, àti Lọ́tì, ọmọ arákùnrin mi, gbàdúrà sí Olúwa, Olúwa sì fi ara hàn sí mi, ó sì wí fún mi pé: Dìde, sì mú Lọ́tì pẹ̀lú rẹ; nítorí mo ní ìdí láti mú ọ́ jade kúrò ní Háránì, àti láti sọ ọ́ di òjíṣẹ́ kan láti jẹ́ orúkọ mi ní ilẹ̀ àjèjì, èyítí èmi yíò fún ìrú ọmọ rẹ lẹ́hìn rẹ fún ìní àìlópin kan, nígbàtí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí ohùn mi.

7 Nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ; èmi ngbé ní ọ̀run; ilẹ̀ ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi; èmi na ọwọ́ mi jáde lé orí òkun, wọ́n sì gbọ́ ohùn mi; èmi mú kí afẹ́fẹ́ àti iná kí ó jẹ́ kẹ̀kẹ́ mi; mo wí fún àwọn òkè—Ẹ lọ kúrò níhĩn—sì kíyèsíi, a mú wọn lọ kúrò nípa ìjì, ní kánkán, lójijì.

8 Orúkọ mi ni Jèhófàh, mo sì mọ òpin láti ìbẹ̀rẹ̀; nítorínáà ọwọ́ mi yíò wà ní orí rẹ.

9 Èmi yíò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè nlá, èmi yíò sì bùkún fún ọ tayọ ìwọ̀n, èmi ó sì sọ orúkọ rẹ di nlá lààrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yíò sì jẹ́ ìbùkún sí irú ọmọ rẹ lẹ́hìn rẹ, pé ní ọwọ́ wọn ni wọn yíò mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti Oyè Àlùfáà yìí lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;

10 Èmi yíò sì bùkún fún wọn nípasẹ̀ orúkọ rẹ; nítorí iye àwọn tí wọ́n bá gba Ìhìnrere yìí ni a ó pè tẹ̀lé orúkọ rẹ, a ó sì kà wọ́n sí irú ọmọ rẹ, wọn yío sì dìde sókè láti bùkún fún ọ, bíi bàbá wọn;

11 Èmi yíò sì bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, àti àwọn tí nfi ọ́ bú ní èmi ó fibú; nínú rẹ (èyí ni pé, nínú Oyè Àlùfáà rẹ) àti nínú irú ọmọ rẹ (èyí ni pé, Oyè Àlùfáà rẹ), nítorí èmi fún ọ ní ìlérí kan pé ẹ̀tọ́ yìí yíò tẹ̀síwájú nínú rẹ, àti nínú irú ọmọ rẹ lẹ́hìn rẹ (èyí ni láti sọ pé, irú ọmọ rẹ̀ gan an, tàbí irú ọmọ ti ara) ni gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ ayé ni yíò di alábùkúnfún, àní pẹ̀lú àwọn ìbùkún ti Ìhìnrere, èyítí ó jẹ́ àwọn ìbùkún ìgbàlà, àní ti ìyè ayérayé.

12 Nísisìyí, lẹ́hìn tí Olúwa ti dáwọ́ dúró ní sísọ̀rọ̀ sí mi, tí ó sì fá ojú rẹ̀ sẹ́hìn kúro lọ́dọ̀ mi, mo wí nínú ọkàn mi: Ìránṣẹ́ rẹ ti fi ìtara wá ọ; nísisìyí èmi ti rí ọ;

13 Ìwọ rán ángẹ́lì rẹ láti gbà mí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn òrìṣà Ẹ́lkẹ́nà, èmi yíò sì ṣe dáradára láti fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ, nítorínáà jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dìde kí ó sì lọ ní àlãfíà.

14 Nítorínáà èmi, Ábráhámù, lọ kúrò bí Olúwa ti wí fún mi, àti Lọ́tì pẹ̀lú mi; èmi, Ábráhámù, sì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta nígbàtí mo jáde lọ kúrò ní Háránì.

15 Mo sì mú Sáráì, ẹnití èmi mú ní ìyàwó nígbàtí mo wà ní Úrì, ní Káldéà, àti Lọ́tì, ọmọ arákùnrin mi, àti gbogbo ohun ìní wa tí a ti kó jọ, àti àwọn ọkàn tí a ti jèrè ní Háránì, a sì jáde wá ní ojú ọ̀nà sí ilẹ̀ Kánánì, a sì gbé nínú àwọn àgọ́ bí a ṣe lọ ní ọ̀nà wa;

16 Nítorínáà, ayérayé ni ààbò wa àti àpáta wa àti ìgbàlà wa, bí a ṣe nrin ìrìnàjò láti Háránì ní gbígba ọ̀nà Jẹ́ṣónì, láti wá sí ilẹ̀ Kénánì.

17 Nísisìyí èmi, Ábráhámù, kọ́ pẹpẹ kan ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, mo sì pèsè ẹbọ-ọrẹ sí Olúwa, mo sì gbàdúrà pé kí á lè yí ìyàn náà kúrò ní ilé bàbá mi, pé kí wọn ó má baà ṣègbé.

18 Àti lẹ́hìnnáà a la ilẹ̀ Jẹ́ṣónì kọjá lọ sí ìbi kan tí a npè ní Sékémù; ó wà ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mórè, a sì ti dé sí àwọn ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenánì, mo sì rú ẹbọ níbẹ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mórè, mo sì ké pe Olúwa pẹ̀lú ìtara, nítorítí a ti wá nísisìyí sí inú ilẹ̀ orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà yìí.

19 Olúwa sì fi ara hàn sí mi ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà mi, ó sì wí fún mi pé: Sí irú ọmọ rẹ ni èmi yíò fi ilẹ̀ yìí fún.

20 Èmi, Ábráhámù, sì dìde láti ibi pẹpẹ náà èyítí mo ti kọ́ sí Olúwa, mo sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí òkè kan ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹlì, mo sì pa àgọ́ mi síbẹ̀, Bẹ́tẹ́lì ní ìwọ̀ oòrùn, àti Háì ní ìlà oòrùn; níbẹ̀ ni èmi sì kọ́ pẹpẹ míràn sí Olúwa, mo sì tún ké pe orúkọ Olúwa lẹ́ẹ̀kansíi.

21 Àti pé èmi, Ábráhámù, rin ìrìnàjò, ní lílọ síwájú síbẹ̀ sí ìhà gúúsù; ìyàn kan sì tẹ̀síwájú ní ilẹ̀ náà; èmi, Ábráhámù, sì pinnu láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Égíptì, láti ṣe àtìpó níbẹ̀, nítorítí ìyàn náà di púpọ̀ gidigidi síi.

22 Ó sì ṣe nígbàtí mo ti wà ní itòsí láti wọ Égíptì, Olúwa wí fún mi pé: Kíyèsíi, Ṣáráì ìyàwó rẹ, jẹ́ arẹ̀wà obìnrin láti wò;

23 Nítorínáà yíó sì ṣe, nígbàtí àwọn ará Égíptì yíò rí i, wọn yíò sì wí pé—Òun ni ìyàwó rẹ̀; wọn yíò sì pa ọ́, ṣùgbọ́n wọn yíò dá òun sí ní ààyè; nítorínáà ríi pé o ṣe ohun yìí:

24 Jẹ́ kí ó wí fún àwọn ará Égíptì pé, arábìnrin rẹ ni òun í ṣe, ẹ̀mí rẹ yíò sì wà láàyè.

25 Ó sì ṣe tí èmi, Ábráhámù, sọ fún Sáráì, ìyàwó mi, gbogbo ohun tí Olúwa ti sọ fún mi—Nítorínáà wí fún wọn, èmi bẹ̀ ọ́, ìwọ ni arábìnrin mi, kí ó lè dára fún mi nítorí rẹ, ọkàn mi yíó sì wà láàyè nítorí rẹ.