Àwọn Ìwé Mímọ́
Abráhámù 3


Orí 3

Ábráhámù kọ́ nípa oòrùn, òṣùpá, àti àwọn ìràwọ̀ nípasẹ̀ Úrímù àti Túmímù—Olúwa fi hàn sí i pé àwọn ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀dá ayérayé—Ó kọ́ nípa wíwà ṣaájú ilẹ̀ ayé, ìyàn tẹ́lẹ̀, Ìṣẹ̀dá, yíyàn Olùràpadà, àti ipò ẹ̀ẹ̀kejì ènìyàn.

1 Èmi, Ábráhámù, sì ní Úrímù àti Túmímù náà, èyítí Olúwa Ọ́lọ́run mi ti fi fún mi, ní Úrì ti àwọn Káldéà;

2 Mo sì rí àwọn ìràwọ̀, pé wọ́n tóbi gidigidi, àti pé ọ̀kan nínú wọn súnmọ́ ìtẹ́ Ọlọ́run jùlọ; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn títóbi kan sì wà tí wọ́n wà nítòsí rẹ̀;

3 Olúwa sì wí fún mi pé: Ìwọ̀nyí ni àwọn alákoso; orúkọ èyí tí ó tobi jùlọ ni Kolóbù, nítorítí òun súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ti gbé èyí kalẹ̀ láti ṣe àkóso gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ètò kannáà bíi èyíinì tí ìwọ dúró lé.

4 Olúwa sì wí fún mi, nípasẹ̀ Úrímù àti Túmímù, pé Kólóbù wà ní àfijọ ìṣe ti Olúwa, ní ìbámu sí àwọn àkókò àti àwọn ìgbà nínú àwọn ìyípo ibẹ̀; pé ìyípo kan jẹ́ ọjọ́ kan sí Olúwa, ní àfijọ ṣíṣe ìṣírò rẹ̀, tí òun jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ọdún ní ìbámu sí àkókò tí a yàn sí èyíinì níbití ìwọ dúró lé. Èyí ni ìṣírò àkókò ti Olúwa, ní ìbámu sí ìṣirò ti Kólóbù.

5 Olúwa sì wí fún mi pé: Ohun náà tí nyípo òòrùn èyítí ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kékeré, tí ó kéré ju èyítí yíò ṣe àkóso ọjọ́, àní òru, ó tayọ tàbí tóbi ju èyíinì tí ìwọ̀ dúró lé nipa ṣíṣe ìṣirò, nítorí ó nsún ní ètò lílọ́ra síi; èyí bá ètò mu nítorí tí ó dúró ní òkè ilẹ̀ ayé ní órí ibití ìwọ dúró lé, nítorínáà ṣíṣe ìṣirò àkókò rẹ̀ kìí ṣe púpọ̀ bíi sí iye àwọn ọjọ́, àti ti àwọn oṣù, àti àwọn ọdún tirẹ̀.

6 Olúwa sì wí fún mi pé: Nísisìyí, Ábráhámù, àwọn àrídájú méjì wọ̀nyí wà, kíyèsíi ojú rẹ rí i; a fi í fún ọ láti mọ àwọn àkókò ìṣirò, àti àkókò tí a ti yàn, bẹ́ẹ̀ni, àkókò tí a ti yàn ti ilẹ̀ ayé ní orí èyítí ìwọ dúró lé, àti àkókò tí a ti yàn ti ìmọ́lẹ̀ títóbi jù èyítí a yàn láti ṣe àkóso ọ̀sán, àti àkókò tí a ti yàn ti ìmọ́lẹ̀ kékeré èyítí a yàn láti ṣe àkóso òru.

7 Nísisìyí àkókò tí a yàn ti ìmọ́lẹ̀ kékeré jẹ́ àkókò tí ó gùn ní ṣíṣe ìṣirò rẹ̀ ju ṣíṣe ìṣírò àkókò ti ilẹ̀ ayé ní orí èyítí ìwọ dúró lé.

8 Àti níbití àwọn àrídájú méjì wọ̀nyí bá wà, àrídájú míràn yíó wà tí ó tayọ wọn, èyí ni pé, ohun tí nyípo òòrùn míràn yíò wà èyítí ìṣirò àkókò rẹ̀ yíò gùn jù síbẹ̀ síi;

9 Àti báyìí ni ìṣirò àkókò yíò wà fún ohun tí nyípo òòrùn kan ní orí òmíràn, títí tí ìwọ yíò fi súnmọ́ itòsí Kólóbù, Kólóbù èyítí ó jẹ́ bíi ìṣirò àkókò ti Olúwa; Kólóbù èyítí a gbé kalẹ̀ súnmọ́ itòsí ìtẹ́ Ọlọ́run, láti ṣe àkóso gbogbo àwọn ohun tí nyípo òòrùn wọnnì èyítí ó jẹ́ ti ètò kannáà bí irú èyíti ìwọ dúró lé.

10 A sì fi fún ọ láti mọ àkókò ti a gbé kalẹ̀ fún gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí a yàn láti fi ìmọ́lẹ̀ fúnni, títí tí ìwọ yíò fi wá sí itòsí ìtẹ́ Ọlọ́run.

11 Báyìí ni èmi, Ábráhámù, sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Olúwa, ní ojúkojú, bí ẹnìkan ti í sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn; òun sì sọ fún mi nipa àwọn iṣẹ́ èyítí ọwọ́ rẹ̀ ti ṣe;

12 Ó sì wí fúnmi pé: Ọmọ mi, ọmọ mi (ọwọ́ rẹ̀ sì nà jade), kíyèsíi èmi yíò fi gbogbo ìwọ̀nyí hàn ọ́. Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ojú mi, èmi sì rí àwọn ohun wọnnì tí ọwọ́ rẹ̀ ti dá, èyítí ó pọ̀ púpọ̀; wọ́n sì di ìlọ́po níwájú mi, èmi kò sì le rí òpin wọn.

13 Ó sì wí fún mi pé: Èyí ni Ṣìnẹ́hà, èyítí í ṣe oòrùn. Ó sì wí fún mi: Kókóbù, èyítí í ṣe ìràwọ̀. Ó sì wí fún mi: Óléà, èyítí í ṣe òṣùpá. Ó sì wí fún mi: Kókábímù, èyítí ó dúró fún àwọn ìràwọ̀, tàbí gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ títóbi, èyítí ó wà ní òfurufú ọ̀run.

14 Ó sì jẹ́ àkókò òru nígbàtí Olúwa sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún mi: Èmi yíò sọ ọ́ di púpọ̀, àti irú ọmọ rẹ lẹ́hìn rẹ, bíi àwọn wọ̀nyí; bí ìwọ kò bá sì lè ka iye iyanrìn, bẹ́ẹ̀ni iye àwọn irú ọmọ rẹ yíò rí.

15 Olúwa sì wí fún mi pé: Ábráhámù, èmi fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn fún ọ saájú kí ìwọ tó lọ sí Égíptì, pé kí ìwọ ó le kéde gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

16 Bí àwọn ohun méjì bá wà, tí ọ̀kan sì wà ní orí òmíràn, àwọn ohun tí ó tóbi jù gbọ́dọ̀ wà ní orí wọn; nítorínáà Kólóbù ni ó tóbi jùlọ nínú gbogbo Kokabímù tí ìwọ ti rí, nítorítí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi jùlọ.

17 Nísisìyí, bí àwọn ohun méjì bá wà, tí ọ̀kan ga ju òmíràn lọ, àti tí òṣùpá ga ju ilẹ̀ ayé lọ, nígbànnáà ó lè jẹ́ pé ohun tí ó nyípo oọ̀run kan tàbí ìràwọ̀ kan wà lókè rẹ̀; kò sì sí ohun kan tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yíò fi sí ọkàn rẹ̀ láti ṣe bíkòṣe pé òun yíò ṣe é.

18 Bí ó tilẹ̀ ríbẹ́ẹ̀ pé òun dá ìràwọ̀ tí ó tóbijù náà; bíi, bákannáà, bí àwọn ẹ̀mí méjì bá wà, tí ọ̀kan sì ní òye ju òmíràn, síbẹ̀ àwọn ẹ̀mí méjì wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan ní òye ju èkejì lọ, wọn kò ní ìbẹ̀rẹ̀; wọ́n ti wà saájú, wọn kì yíò ní òpin, wọn yíò wà lẹ́hìnwá, nítorí wọ́n jẹ́ àìlópin, tàbí ayérayé.

19 Olúwa sì wí fún mi pé: Àwọn ohun àrídájú méjì yìí wà, pé àwọn ẹ̀mí méjì wà, tí ọ̀kan ní òye ju èkejì lọ; òmíràn yíò wà tí ó ní òye jù wọ́n lọ; èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, èmi ní òye ju gbogbo wọn lọ.

20 Olúwa Ọlọ́run rẹ rán ángẹ́lì rẹ̀ láti gbà ọ́ kúrò ní ọwọ́ àlùfáà Ẹ́lkẹ́nà.

21 Èmi gbé ní ààrin wọn gbogbo; èmi nísisìyí, nítorínáà, ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti kéde sí ọ àwọn iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti dá, nínú èyítí ọgbọ́n mi ju gbogbo wọn lọ, nítorí èmi ṣe àkóso nínú àwọn ọ̀run lókè, àti ní ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀, ní gbogbo ọgbọ́n àti ìwòye, ní orí gbogbo àwọn ẹ̀mí òye tí ojú rẹ ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀; èmi sọ̀kalẹ̀ wá ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ààrin gbogbo àwọn ẹ̀mí òye tí ìwọ ti rí.

22 Nísisìyí Olúwa ti fi hàn sí èmi, Ábráhámù, àwọn ẹni ẹ̀mí òye tí a ti ṣètò saájú kí ayé tó wà; àti láàrin gbogbo ìwọ̀nyí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́là áti àwọn ẹni nlá wà;

23 Ọlọ́run sì rí àwọn ọkàn wọ̀nyí pé wọ́n dára, òun sì dúró ní ààrin wọn, ó sì wí pé: Ìwọ̀nyí ni èmi yíò fi ṣe àwọn alákoso mi; nítorí ó dúró lààrin àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí, ó sì ríi pé wọ́n dára; ó sì wí fún mi pé: Ábráhámù, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú wọn; a ti yàn ìwọ saájú kí á to bí ọ.

24 Ọ̀kan sì dìde lààrin wọn tí ó dàbí Ọlọ́run, ó sì wí fún àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: Àwà yíò lọ sí ìsàlẹ̀, nítorí ààyè wà níbẹ̀, àwa ó sì mú lára àwọn ohun èlò wọ̀nyí, a ó sì dá ilẹ̀ ayé kan ní orí ibití àwọn wọ̀nyí yíò lè gbé;

25 Àwa yíò sì dán wọn wò pẹ̀lú èyí, láti ríi bí wọn yíò ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíò pàṣẹ fún wọn;

26 Àti pé àwọn tí wọ́n bá pa ipò àkọ́kọ́ wọn mọ́ ni a ó fi kún fún; àwọn tí wọn kò bá pa ipò àkọ́kọ́ wọn mọ́ kì yíò ní ògo nínú ìjọba kannáà pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n pa ipò àkọ́kọ́ wọn mọ́; àti àwọn tí wọ́n bá pa ipò ẹ̀ẹ̀kejì wọn mọ́ yíò ní àfikún ògo ní orí wọn láé àti títí láé.

27 Olúwa sì wí pé: Tani èmi yíò rán? Ọ̀kan sì dáhùn bíi Ọmọ Ènìyàn: Èmi nìyí, rán mi. Òmíràn sì dáhùn ó sì wí pé: Èmi nìyí, rán mi. Olúwa sì wí pé: Èmi yíò rán ẹni àkọ́kọ́.

28 Ẹni ìkejì sì bínú, kò sì pa ipò àkọ́kọ́ rẹ̀ mọ́; àti, ní ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì tẹ̀lé e.