Àwọn Ìwé Mímọ́
Joseph Smith—Ìwé ìtàn 1


Ìtàn Joseph Smith

Àwọn àyọkà láti inú ìtàn Joseph Smith, Wòlíì náà

Orí 1

Joseph Smith sọ nípa ìran rẹ̀, àwọn ẹbí, àti àwọn ibùgbé wọn ní ìbẹ̀rẹ̀—Ìtara tí kò wọ́pọ̀ gbilẹ̀ nípa ẹ̀sìn ní ìwọ̀ oòrùn New York—Ó pinnu láti wá ọgbọ́n bí Jámésì ṣe darí—Baba àti Ọmọ fi ara hàn, a sì pe Joseph sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí a ti sọtẹ́lẹ̀. (Àwọn ẹsẹ 1–20.)

1 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìròhìn èyítí a ti fọ́n káàkiri òde láti ọwọ́ àwọn ẹ̀ni ibi àti àwọn eléte ènìyàn, nípa ìdìde àti ìtẹ̀síwájú Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, gbogbo èyítí a ti pète láti ọwọ́ àwọn olùkọ̀wé ibẹ̀ láti gbógun ti orúkọ rere rẹ̀ bíi Ìjọ àti ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nínú ayé—Àwọn ìròhìn irọ́ wọ̀nyí mú mi kọ ìtàn yìí, láti fi òye kún ọkàn àwọn ará ìlú, àti láti mú kí gbogbo àwọn olùwádĩ òtítọ́ kí wọn ó ní àwọn òtítọ́ náà ní ìkáwọ́, bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀, méjéèjì ní ti èmi fúnrami àti Ìjọ, níwọ̀nbí irú àwọn òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe wà ní ọwọ́ mi.

2 Nínú ìtàn yìí èmi yíò ṣe àgbékalẹ̀ onírúurú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa Ìjọ yìí, ní òtítọ́ àti òdodo, bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀, tàbí bí wọ́n ṣe wà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ní ìsìsìyìí (1838) ọdún kẹjọ láti ìgbà ìdásílẹ̀ Ìjọ náà.

3 A bí mi ní ẹgbẹ̀sán ó lé marũn nínú ọdún Olúwa wa, ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kejìlá, ní ìlú Sharon, Ìjọba Ìbílẹ̀ Windsor, Ìpínlẹ̀ Vermont. … Bàbá mi, Joseph Smith Àgbà, fi ìpínlẹ̀ Vermont sílẹ̀, ó sì ṣípòpadà lọ sí Palmyra, ìjọba ìbílẹ̀ Ontario, (Wayne nísisìyí) ní ìpínlẹ̀ New York, nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́wã, tàbí ni àyíká rẹ̀. Ní nkan bí ọdún mẹ́rin lẹ́hìn tí bàbá mi dé sí Palmyra, ó ṣipòpadà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ lọ sí Manchester ní ìjọba ìbílẹ̀ Ontario kannáà—

4 Ẹbí rẹ̀ ní àwọn ènìyàn mọ́kànlá nínú, ní dídárúkọ wọn, bàbá mi, Joseph Smith; ìyá mi, Lucy Smith, (ẹnití orúkọ rẹ̀, saájú ìgbéyàwó jẹ́ Mack, ọmọbìnrin Solomon Mack); àwọn arákùnrin mi, Alvin (ẹnití ó kú ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kọkànlá 1823, nínú ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n ọjọ́ orí rẹ̀), Hyrum, èmi náà, Samuel Harrison, William, Don Carlos; àwọn arábìnrin mi, Sophronia, Catherine, àti Lucy.

5 Ní ìgbà kan nínú ọdún keji lẹ́hìn ìṣípòpadà wa lọ sí Manchester, ìyágágá ara kan tí kò wọ́pọ̀ wà ní ibití à ngbé ní orí kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ìjọ Elétò, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ó di gbogbogbò láàrin àwọn oríṣiríṣi ẹ̀sìn gbogbo ní agbègbè orílẹ̀-èdè náà. Nítòótọ́, gbogbo ẹkùn orílẹ̀-èdè ni ó dábí pé wọ́n mọ̀ ọ́ lara, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n sì fi ìmọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọ̀n lọ sí oríṣiríṣi àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn náà, èyítí ó dá ìdàrúdàpọ̀ àti ìyapa tí kò kéré sílẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn, àwọn kan nkígbe, “wòó, níhĩn!” àti àwọn míràn, “wòó, lọ́hũn!” Àwọn kan njìjàdù fún ìgbàgbọ́ ti ìjọ Elétò, àwọn kan fún Ìjọ àwọn Àgbà, àti àwọn kan fún Ìjọ Onítẹ̀bọmi.

6 Nítorí, láì ṣe àkàsí ìfẹ́ nlá tí àwọn tí wọ́n yípadà sí oríṣĩríṣĩ àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyí fi hàn ní àkókò ìyípadà wọn, àti ìtara nlá tí a fihàn láti ọwọ́ àwọn àlùfáà kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n ṣe aápọn ní dídìde àti pípolongo ìsẹ̀lẹ̀ tí kò wọ́pọ̀ ti ìmọ̀lára ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn yìí, ní ọ̀nà láti mú kí á yí olúkúlùkù ènìyàn padà, bí ó ṣe dùn mọ́ wọn láti pè é, pé kí wọn ó darapọ̀ mọ́ èyíkéyìí ẹgbẹ́ tí ó bá wù wọ́n; síbẹ̀ nígbàtí àwọn tí wọ́n yípadà náà bẹ̀rẹ̀ sí tò jáde, àwọn kan sí ẹ́gbẹ́ kan àti àwọn kan sí òmíràn; a rí i pé ohun tí ó dàbí ìmọ̀lára rere sí àwọn àlùfáà àti àwọn tí wọ́n yípadà jẹ́ ojú ayé ṣíṣe ju òtítọ́ lọ; nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdàrúdàpọ̀ nlá àti ìkórĩra ara ẹni tẹ̀lée—àlùfáà njà tako àlùfáà, àwọn tí a yípadà sì ntako àwọn tí a yípadà; tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn èrò rere tí ẹnìkan ní fún ẹlòmíràn, bí wọ́n bá tilẹ̀ ní ọ̀kan rí, ní ó sọnù pátápátá ní ojú ìjà àwọn ọ̀rọ̀ sísọ àti àríyànjiyàn nípa àwọn èrò ọkàn.

7 Ní àkókò yìí mo wà ní ọdún kẹ̃dógún mi. Ẹbí bàbá mi ni a wàásù fún sí inú ìgbàgbọ́ ti àwọn Àgbà, àwọn mẹ́rin sì darapọ̀ mọ́ ìjọ náà, orúkọ wọn ni, ìyá mi, Lucy; àwọn arákùnrin mi Hyrum àti Samuel Harrison; àti arábìnrin mi Sophronia.

8 Ní àkókò ìyágágá ara nlá yìí, ọkàn mi ni a pè sí síṣe àṣàrò ìjìnlẹ̀ àti àìbalẹ̀ ara tí ó ga; ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn ìmọ̀lára mi jìnlẹ̀ tí ó sì wọra nígbà púpọ̀, síbẹ̀ mo pa ara mi mọ́ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpàdé wọn ní ìgbà púpọ̀ bí àyè ṣe gbà mí sí. Bí àkókò ṣe nlọ ọkàn mi fà díẹ̀ sí ẹgbẹ́ ìjọ Elétò, mo sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ díẹ̀ láti darapọ̀ pẹ̀lú wọn; ṣùgbọ́n ìdàrúdàpọ̀ àti ìjà nlá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lààrin àwọn onírúurú ẹlẹ́sìn, tí kò fi ṣeéṣe fún ẹnití ó jẹ́ ọ̀dọ́ bí mo ṣe wà, àti tí kò ní àjọṣepọ̀ kankan rárá pẹ̀lú àwọn ènìyàn àti àwọn ohun, láti ṣe ìpinnu kan pàtó nipa ẹnití ó tọ́ àti ẹnití kò tọ́.

9 Ní ìgbà míràn ọkàn mi máa nyá gágá púpọ̀ gidi, ariwo àti ìrúkèrúdò náà pọ̀ kò sì dáwọ́ dúró. Àwọn ìjọ Àgbà ni wọ́n ṣe ìpinnu jùlọ ní títako àwọn Onítẹ̀bọmi àti àwọn Elétò, wọ́n sì lo gbogbo agbára ọgbọ́n ìronú àti ìṣini lọ́nà láti fi ìdí àwọn àṣìṣe wọn múlẹ̀, tàbí, ó kéré jù, láti mú kí àwọn ènìyàn rò pé wọ́n ní àsìṣe. Ní ìdà kejì, àwọn Onítẹ̀bọmi àti àwọn Elétò ní ọ̀dọ̀ tiwọn náà ní ìtara ní gbígbìyànjú láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ tiwọn kí wọn ó sì ṣáátá gbogbo àwọn míràn.

10 Ní ààrin gbùngbùn ogun àwọn ọ̀rọ̀ àti ìrúkèrúdò àwọn èrò ọkan yìí, mo máa nfi ọ̀pọ̀ ìgbà wí fún ara mi pé: Kínni ṣíṣe? Taani nínú àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí ni ó tọ̀nà; tàbí, njẹ́ gbogbo wọn ni kò tọ̀nà lápapọ̀? Bí èyíkéyìí nínú wọn bá tọ́, èwo ni, àti báwo ni èmi yíò ṣe mọ̀?

11 Ní àkókò tí mo nṣe làálàá ní abẹ́ àwọn ìṣoro tí ó le jù èyítí ó wáyé nípasẹ̀ ìfigagbága ti àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn wọ̀nyí, ní ọjọ́ kan mo nkà nínú Èpístélì ti Jámésì, orí ìkinni àti ẹsẹ ìkarũn, èyítí ó kà pé: Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni nínú yín, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹnití nfi fún gbogbo ènìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀, tí kìí sì bá-ni-wí; a ó sì fi fún un.

12 Kò sí ìgbà kan rí tí ẹsẹ ìwé mímọ́ wá pẹ̀lú agbára nlá sí ọkàn ènìyàn ju bí èyí ti ṣe ní àkókò yìí sí tèmi. Ó dàbí pé ó wọlé pẹ̀lú ipá nlá sí inú gbogbo ìmọ̀lára ọkàn mi. Mo ronú jìnlẹ̀ ní orí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi àti lẹ́ẹ̀kansíi, ní mímọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá nílò ọgbọ́n lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èmi ni; nítorí bí èmi yíò ti ṣe èmi kò mọ̀, àti bíkòṣe pé mo gba ọgbọ́n síi ju bí mo ṣe ní nígbànáà lọ, èmi kì yíò mọ̀ láé; nítorí àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn ti onírúurú ẹgbẹ́ ní òye àwọn ẹsẹ kannáà nínú ìwé mímọ́ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ gidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ṣe ìparun gbogbo ìgbẹ́kẹ̀lé ní yíyanjú ìbéèrè náà nipa wíwá inú Bíbélì.

13 Lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ mo wá sí ìpinnu pé èmi gbọ́dọ̀ dúró bóyá nínú òkùnkùn àti ìdàrúdàpọ̀, tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ èmi gbọdọ̀ ṣe bí Jámésì ṣe darí, èyí ni pé, béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Èmi, lẹ́hìn ìgbà díẹ̀ wá sí síṣe ìpinnu láti “béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,” ní píparí pé bí ó bá fi ọgbọ́n fún àwọn tí kò ní ọgbọ́n, tí yío sì fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀, kì yíò sì bániwí, èmi lè gbìyànjú.

14 Nítorínáà, ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ìpinnu mi láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, mo lọ jinnà sí inú igbó láti gbìyànjú. Ó jẹ́ òwúrọ̀ ọjọ́ dáradára kan, tí ó mọ́ gaara, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé ti ọdún ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ogún. Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ní ayé mi tí èmi ti gba ìrú ìyànjú bẹ́ẹ̀, nítorí nínú gbogbo àwọn àníyàn mi, síbẹ̀ èmi kò tíì gbìdánwò bẹ́ẹ̀ rí láti gbàdúrà pèlú ohùn òkè.

15 Lẹ́hìn tí mo ti lọ jinnà sí ibi tí mo ti pèrò tẹ́lẹ̀ láti lọ, lẹ́hìn wíwo àyíká mi, tí mo sì rí pé èmi nìkan ni mo wà, mo kúnlẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí tú àwọn ìfẹ́ ọkàn mi jade sí Ọlọ́run. Mo fẹ́rẹ̀ má tíì ṣe bẹ́ẹ̀, nígbàtí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ a fi ipá mú mi pẹ̀lú agbára kan tí ó borí mi pátápátá, tí ó sì ní ipá yíyanilẹ́nu kan ní orí mi bíi láti di ahọ́n mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi kò lè sọ̀rọ̀. Òkùnkùn biribiri kórajọ pọ̀ yí mi ká, àti sí mi fún àkókò díẹ̀ kan ó dàbí ẹnipé a ti dámi lẹ́bi fún ìparùn òjijì.

16 Ṣùgbọ́n, ní lílo gbogbo àwọn agbára mi láti ké pe Ọlọ́run láti gbà mí kúrò lọ́wọ́ agbára ọ̀tá yìí èyítí ó fi ipá mú mi, àti ní ìṣẹ́jú gan an nígbàtí mo ti ṣetán láti rì sínú àìnírètí kí nsì kọ ara mi sílẹ̀ sí ìparun—kìí ṣe sí ìparun àfinúrò, ṣùgbọ́n sí agbára ti ẹ̀dá tòótọ́ kan láti inú ayé àìrí, ẹnití ó ní irú agbára yíyanilẹ́nu bẹ́ẹ̀ bí èyí tí èmi kò mọ̀ lára rí láé ní ara ẹ̀dá kankan—ní ìṣẹ́jú ìdágìrì nlá yìí, mo rí ọ̀wọ̀n ìmọ́lẹ̀ kan ní ọ̀gangan òkè orí mi, ó tayọ dídán oòrùn, èyítí ó sọ̀kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi balẹ̀ lé mi ní orí.

17 Lọ́gán ti ó fi ara hàn ni mo ríi pé a ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá èyítí ó ti dè mi ní ìgbèkùn. Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ náà sì simi lé orí mi mo rí àwọn Ẹ̀dá Ènìyàn méjì, tí dídán àti ògo wọn kọjá gbogbo àpèjúwe, tí wọ́n nduró ní òkè mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kan nínú wọn bá mi sọ̀rọ̀, ní pípè mí ní orúkọ tí ó sì wí pé, ní títọ́ka sí ìkejì—Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ tirẹ̀!

18 Èròngbà lílọ mi láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa ni láti mọ èwo nínú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ni ó tọ́, pé kí èmi lè mọ̀ èyítí èmi yíò darapọ̀ mọ́. Ní kété, nítorínáà, tí mo gba ara mi kalẹ̀, kí nlè ni agbára láti sọ̀rọ̀, ni mo béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹ̀dá Ènìyàn náà tí wọ́n dúró ní òkè orí mi nínú ìmọ́lẹ̀, èwo nínú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ni ó tọ́ (nítorí ni àkókò yìí kò tíì wá sí ọkàn mi rí pé gbogbo wọn ni kò tọ́)—àti èyítí èmi yío darapọ̀ mọ́.

19 A dá mi lóhùn pé èmi kò gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ ọ̀kankan nínú wọn, nítorípé gbogbo wọn ni kò tọ́; Ẹ̀dá Ènìyàn tí ó bá mi sọ̀rọ̀ sì wí pé gbogbo ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ ohun ìríra ní ojú rẹ̀; pé àwọn ọjọ̀gbọ́n wọnnì jẹ́ oníbàjẹ́ gbogbo; pé: “wọ́n súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jinnà sí ọ̀dọ̀ mi, wọ́n nkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ti àwọn òfin ènìyàn, ti níní ìwò ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ agbára rẹ̀.”

20 Lẹ́ẹ̀kansíi òun tún kàá léèwọ̀ fún mi láti darapọ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí wọn; àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan míràn ni ó sọ fún mi, èyítí èmi kò leè kọ sílẹ̀ ní àkókò yìí. Nígbàtí ara mi padà wá sípò lẹ́ẹ̀kansíi, mo rí ara mi ní fífi ẹ̀hìn lélẹ̀, tí mo nwo òkè ọ̀run. Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ náà ti lọ tán, èmi kò ní okun; ṣùgbọ́n láipẹ́ tí mo ní okun ní ìwọ̀n díẹ̀ kan, mo lọ sí ilé. Bí mo sì ti fi ara ti ibi ìyáná, ìyá mi béèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Mo fèsì pé, “Ẹ má ṣe ìyọnu, ohun gbogbo dára—àlãfíà ni mo wà.” Nígbànáà ni mo wí fún ìyá mi, “mo ti mọ̀ fún ara mi pé Ìjọ àwọn Àgbà kìí ṣe òtítọ́.” Ó dàbí pé ọ̀tá ti mọ̀, ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé mi, pé a ti yàn án mọ́ mi láti jẹ́ ayọnilẹ́nu àti amúnibínú nínú ìjọba rẹ̀; bíbẹ́ẹ̀kọ́ báwo ni àwọn agbára òkùnkùn yíò ṣe dìmọ̀pọ̀ dojúkọ mí? Nítorí kínni àtakò àti inúnibíni tí ó dìde dojúkọ mí, tí ó fẹrẹ̀ jẹ́ ìgbà èwe mi?

Àwọn oníwàásù kan àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n mĩràn ti ẹ̀sìn ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ti àkọsílẹ̀ Ìran Àkọ́kọ́—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnúnibíni ni wọ́n gbé dìde sí Joseph Smith—Òun jẹ́rìí jíjẹ́ òtítọ́ ti ìran náà. (Àwọn ẹsẹ 21–26.)

21 Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìn tí mo rí ìran yìí, mo wà ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn oníwàásù ti Ìjọ Elétò, ẹnití ó jẹ́ akíkanjú nínú ìtara ẹ̀sìn tí a ti sọ síwájú; àti, ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní orí kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, mo lo ànfàní náà láti fún un ní ìròhìn ìran náà èyítí mo ti rí. Ó yà mí lẹ́nu púpọ̀ ní ti ìwà rẹ̀; òun ṣe sí ìbánisọ̀rọ̀ mi náà kìí ṣe ní eréfèé nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkẹ́gàn púpọ̀, ní wíwípé ti èṣù ni gbogbo rẹ̀, pé kò sí irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ bí àwọn ìran tàbí àwọn ìfihàn mọ́ ni àwọn ọjọ́ wọ̀nyí; pé gbogbo irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ ti dáwọ́dúró pẹ̀lú àwọn àpóstélì, àti pé kì yío tún sí èyíkéyìí irú wọn mọ́ láé.

22 Kò pẹ́ ti mo ríi pé, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí mo ṣe sọ ìtàn náà ti mú kí ẹ̀tanú ó ru sókè takò mí lọ́pọ̀lọpọ̀ lààrin àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀sìn, òun ni ó sì dá inúnibíni nlá sílẹ̀, èyítí ó tẹ̀síwájú láti máa pọ̀ síi; àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a kò mọ̀, ní ààrin ọ̀dún mẹ́rìnlá sí mẹ̃dógún péré ní ọjọ́ orí, àti tí àwọn ipò mi ní ìgbé ayé jẹ́ irú èyí tí ó lè mú kí ọ̀dọ́mọkùnrin jẹ́ àìníláárí nínú ayé, síbẹ̀ àwọn ènìyàn nlá lè ṣe àkíyèsí tí ó pọ̀ tó láti mú ọkàn àwọn ará ìlú ru sókè sí mi, àti láti dá inúnibíni kikan sílẹ̀; èyí sì wọ́pọ̀ lààrin gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn—gbogbo wọn parapọ̀ láti ṣe inúnibíni sí mi.

23 Ó mú kí èmi ṣe àṣàrò ìjìnlẹ̀ nígbànáà, àti nígbà gbogbo lati ìgbànáà, ó ha ti ṣe àjèjì púpọ̀ tó pé ọ̀dọ́mọkùnrin tí a kò mọ̀, tí í ṣe ẹni ọdún mẹ́rìnlá ó lé díẹ̀ ní ọjọ́ orí, àti ẹnìkan, bákannáà, tí a ti dá lẹ́bi sí ojúṣe rírí ìtọ́jú tí kò tó nkan nípa iṣẹ́ ojojúmọ́ rẹ̀, níláti jẹ́ ríronú sí bíi ẹ̀dá kan tí ó ṣe pàtàkì tó láti pe àkíyèsí àwọn ẹni nlá ní ààrin àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sin tí wọ́n jẹ́ olókìkí jùlọ ní àwọn ọjọ́ náà, àti ní ọ̀nà láti dá ẹ̀mí ìnúnibíni kíkorò jùlọ àti ìkẹ́gàn sí inú wọn. Ṣùgbọ́n bóyá ó jẹ́ àjèjì tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí, ó sì máa nfi ìgbà gbogbo jẹ́ ẹ̀dùn-ọkàn nlá sí mi.

24 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀ pé mo ti rí ìran kan. Mo ti ronú láti ìgbà náà, tí mo fi ní ìmọ̀lára dídàbíi Paulù, nígbàtí ó nwí àwíjàre rẹ̀ níwájú Ọbá Agríppà, tí ó sì sọ ìròhìn ìran tí òun ní nígbàtí ó rí ìmọ́lẹ̀ kan, àti tí ó gbọ́ ohùn kan; ṣùgbọ́n síbẹ̀ díẹ̀ ni àwọn ẹnití ó gbà á gbọ́; àwọn kan sọ pé òun jẹ́ aláìṣõtọ́, àwọn miràn sì sọ pé ó jẹ́ aṣiwèrè; wọ́n sì fi òun ṣe ẹlẹ́yà wọ́n sì kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò pa òtítọ́ ìran rẹ̀ run. Òun ti rí ìran kan, òun mọ̀ pé òun ti ríi, gbogbo inúnibíni ní abẹ́ ọ̀run kò sì le mú u yàtọ̀; àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nílati ṣe inúnibíni rẹ̀ dé ojú ikú, síbẹ̀ òun mọ̀, òun yíò sì mọ̀ títí dé ẽmí rẹ̀ ìkẹhìn, pé òun ti rí ìmọ́lẹ̀ kan òun sì gbọ́ ohùn kan tí ó bá a sọ̀rọ̀, àti pé gbogbo aráyé kì yíò lè mú kí ó ronú tàbí gbàgbọ́ nínú ohun tí ó yàtọ̀.

25 Bẹ́ẹ̀ ni ó rí pẹ̀lú mi. Èmi ti rí ìmọ́lẹ̀ kan nítòótọ́, àti ní ààrin ìmọ́lẹ̀ náà mo rí àwọn Ẹ̀dá Ènìyàn méjì, àti nítòótọ́ wọ́n bámi sọ̀rọ̀; àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kórĩra mi tí a sì ṣe inúnibíni sí mi fún sísọ̀ pé mo rí ìran kan, síbẹ̀ ó jẹ́ òtítọ́; bí wọn sì ti nṣe inúnibíni sí mi, ti wọ́n npẹ̀gàn mi, tí wọn sì nsọ gbogbo onírúurú ohun búburú ní pípa irọ́ takò mí fún sísọ bẹ́ẹ̀, a darí mi láti sọ nínú ọkàn mi pé: Kíníṣe tí wọn nṣe inúnibíni mi fún sísọ òtítọ́? Mo ti rí ìran kan ní tòótọ́; àti pé tani èmi tí èmi yíò lè dojúkọ Ọlọ́run, tàbí kíníṣe tí aráyé fi lérò láti fẹ́ kí emi sẹ́ ohun tí mo ti rí ní tòótọ́? Nítorí èmi ti rí ìran kan; èmi mọ̀ ọ́, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́, èmi kò sì lè sẹ́ ẹ, tàbí kí èmi tilẹ̀ dán ṣíṣe rẹ̀ wò; bí ó ti wù kí ó mọ, èmi mọ̀ pé nípa síṣe bẹ́ẹ̀ èmi yíò ṣẹ Ọlọ́run, èmi sì wá sí abẹ́ ìdálẹ́bi.

26 Èmi ti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọkàn mi nísisìyí níwọ̀nbí ó ṣe kan ayé àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn—pé kìí ṣe ojúṣe tèmi láti darapọ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí nínú wọn, ṣùgbọ́n láti tẹ̀síwájú bí mo ṣe wà títí tí a ó tún darí mi. Mo ti rí ẹ̀rí Jámesì pé ó jẹ́ òtítọ́—pé ènìyàn tí ó bá ṣe àìní ọgbọ́n lè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí ó sì gbà, kí ó má sì jẹ́ bíbáwí.

Mórónì fi ara hàn sí Joseph Smith—orúkọ Joseph ni a ó mọ̀ fún rere àti ibi lààrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè—Mórónì sọ fún un nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti nipa àwọn ìdájọ́ Olúwa tí ó nbọ̀ ó sì ṣe àtúnwí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé mímọ́—Ibi ìpamọ́ ti àwọn àwo wúrà di fífihàn—Mórónì tẹ̀síwájú ní síṣe ìdánilẹ́kọ̃ fún Wòlíì. (Àwọn ẹsẹ 27–54.)

27 Mo tẹ̀síwájú láti máa lépa àwọn iṣẹ́ àtìgbàdégbà mi nínú ayé títí di ọjọ́ kọkànlélógún Oṣù Kẹsãn, ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ọdún mẹ́tàlélógún, ní gbogbo ìgbà nínú ìjìyà inúnibíni tí ó nira púpọ̀ ní ọwọ́ gbogbo àwọn ènìyàn ní oríṣirísi ipò, àti ẹlẹ́sìn àti aláìlẹ́sìn, nítorítí mo tẹ̀síwájú ní fífi múlẹ̀ pé mo ti rí ìran kan.

28 Ní àlàfo àkókò tí ó wà lààrin àkókò tí mo rí ìran náà àti ọdún ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rũn méjọ ó àti mẹ́tàlélógún—nítorí tí a ti kàá léèwọ̀ fún mi láti darapọ̀ mọ́ èyíkéyìí àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn ti ìgbà náà, àti nítorí tí mo sì wà ní àwọn ọdún ọ̀dọ́ gidi, tí a sì nṣe inúnibíni sí nípasẹ̀ àwọn tí ó yẹ kí wọ́n ó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi kí wọ́n ó sì ṣe sí mi pẹ̀lú inú rere, àti bí wọ́n bá ríi pé mo ti kùnà kí wọ́n ó gbìyànjú ní ọ̀nà tí ó yẹ àti pẹ̀lú ìfẹ́ láti gbà mí padà—A fi mí sílẹ̀ sí orísiríṣi àwọn ìdánwò; àti, ní dídàpọ̀ pẹ̀lú gbogbo orísiríṣi àwùjọ, mo ti ṣubú sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsìṣe aláìlọ́gbọ́n léraléra, mo sì fi áìlágbára ti ọ̀dọ́mọdé hàn, àti àwọn àìpé tí ó jẹ́ àdánidá ti ẹ̀dá ènìyàn; èyítí, mo kẹ́dùn láti sọ pé, ó darí mí sí onírúurú àwọn ìdánwò, tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní ojú Ọlọ́run. Ní ṣíṣe ìjẹ́wọ́ yìí, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó nílò lati rò pé mo jẹ̀bi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nlá tàbí búburú kankan. Ìfẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kò sí nínú àdánidá mi. Ṣùgbọ́n mo jẹ̀bi ti àìní àkàsí, àti nígbà míràn mo ní ìbánikẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn aláwàdà, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, èyítí kò baramu pẹ̀lú ìwà tí ẹni tí Ọlọ́run bá pè níláti ní, bí a ti pèmi. Ṣùgbọ́n èyí kì yíò dàbí àjèjì sí ẹnikẹ́ni tí ó bá rantí ìgbà èwe mi, tí ó sì mọ̀ mí díẹ̀ pẹ̀lú ọ̀yàyà tí ó jẹ́ ìwà àdánidá mi.

29 Ní ìyọrísí àwọn nkan wọ̀nyí, mo nní ìmọ̀lára dídá lẹ́bi nígbà gbogbo fún àìlágbára àti àwọn àbùkù mi; nígbànáà, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún Oṣù Kẹsãn tí a mẹ́nubà lókè yìí, lẹ́hìn tí mo ti simi sí ibùsùn mi fún alẹ́, mo fi ara mi sílẹ̀ fún gbígbàdúrà àti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Alágbára Jùlọ fún ìdáríjì ti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìmòye mi, àti bákannáà fún ìṣípayá kan sí mi, pé kí èmi ó lè mọ̀ ipò mi àti ìdúró mi ní iwájú rẹ̀; nítorí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún ní gbígba ìṣípayá àtọ̀runwá, bí mo ṣe ti gba ọ̀kan tẹ́lẹ̀.

30 Bí mo ti wà nínú ìṣe kíké pe Ọlọ́run bẹ́ẹ̀, mo wòye ìmọ́lẹ̀ kan tí ó nfarahàn nínú yàrá mi, èyítí ó tẹ̀síwájú láti máa pọ̀ síi títí tí yàrá náà fi mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán ọjọ́ lọ, lọ́gán nígbànáà ni ẹ̀dá ènìyàn kan fi ara hàn ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi, ní dídúró nínú afẹ́fẹ́, nítorí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò kan ilẹ̀.

31 Òun wọ ẹ̀wù kan tí ó ṣòó lára ti fífunfun rẹ̀ dára jùlọ. Ó jẹ́ fifunfun kan tí ó kọjá ohunkóhun ní ilẹ̀ ayé tí èmi tí rí rí; bẹ́ẹ̀ni èmi kò gbàgbọ́ pé a lè mú kí ohunkóhun ti ayé kan ó fi ara hàn ní funfun àti títàn jùlọ bẹ́ẹ̀. Àwọn ọwọ́ rẹ̀ wà ní ìhòhò, àti àwọn apá rẹ̀ pẹ̀lú, ní òkè ọrùn ọwọ́ díẹ̀; bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, ni àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ wà ní ìhòhò, ní òkè ọrùn ẹsẹ̀ díẹ̀. Orí rẹ̀ àti ọrùn jẹ́ àìbò bákannáà. Mo lè ríi pé òun kò wọ aṣọ mĩràn bíkòṣe ẹ̀wù yìí, nítorípé ó ṣí, tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè rí àyà rẹ̀.

32 Kìí ṣe pé ẹ̀wù rẹ̀ funfun rékọjá nìkan, ṣùgbọ́n òun gan bí ènìyàn jẹ́ ológo kọjá àpèjúwe, àti ìwò rẹ̀ lõtọ́ dàbíi mọ̀nàmọ́ná. Yàrá náà mọ́lẹ̀ rékọjá, ṣùgbọ́n kò tàn gan an to bẹ́ẹ̀ bíi àyíká ara rẹ̀. Nígbàtí mo kọ́kọ́ wòó, ẹ̀rù bà mí; ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù náà fi mí sílẹ̀ láìpẹ́.

33 Ó pè mí ní orúkọ mi, ó sì sọ fún mi pé òun jẹ́ ìránṣẹ́ kan tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí mi, àti pé orúkọ òun ni Mórónì; pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe; àti pé orúkọ mi ni a ó gbọ́ fún rere àti ibi lààrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, àti èdè, tàbí pé a ó sọ nipa rẹ̀ ní rere àti ibi ní ààrin gbogbo ènìyàn.

34 Ó ní ìwé kan wà tí a fi pamọ́, tí a kọ sí orí àwọn àwo wúrà, tí ó fúnni ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn olùgbé ìpín ilẹ̀ ayé yìí tẹ́lẹ̀, àti orisun láti ibití wọ́n ti dìde. Ó sọ bákannáà pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ìhìnrere àìlópin wà nínú rẹ̀, bí a ṣe fifúnni láti ọwọ́ Olùgbàlà sí àwọn olùgbé àtijọ́ náà;

35 Bákannáà, pé àwọn òkúta méjì kan wà nínú àwọn ọpọ́n idẹ—àti àwọn òkúta wọ̀nyí, tí a so mọ́ àwo-ìgbàyà kan, ní wọ́n jẹ́ ohun tí a pè ní Úrímù àti Túmímù—tí a fi pamọ́ pẹ̀lú àwọn àwo náà; àti níní àti lílò àwọn òkúta wọ̀nyí ní ó jẹ́ “àwọn aríran” ní àtijọ́ tàbí ní àwọn ìgbà ìṣaájú; àti pé Ọlọ́run ti pèsè wọn sílẹ̀ fún èrò ti títúmọ̀ ìwé náà.

36 Lẹ́hìn tí ó sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún mi, ó bẹrẹ̀ sí ṣe àtúnsọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti Májẹ̀mú Láéláé. Ó kọ́kọ́ tún apákan ti orí kẹ̃ta ìwé Málákì sọ; ó sì tún orí kẹrin tàbí orí ìwé tí ó parí ti àsọtẹ́lẹ̀ kannáà sọ pẹ̀lú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀ sí ọ̀nà tí ó fi kà nínú àwọn Bíbélì wa. Dípò kí ó ṣe àtúnsọ ẹsẹ kínní bí ó ṣe kà nínú àwọn ìwé wa, ó tún un sọ báyìí:

37 Nítorí kíyèsíi, ọjọ́ náà nbọ̀wá tí yíò jóná bí ààrò, àti gbogbo àwọn agbéraga, bẹ́ẹ̀ni, àti gbogbo àwọn olùṣebúburú, yíò jóná bíi àkékù koríko; nítorí àwọn tí yíó wá yíò jó wọn, ni Olúwa àwọn Ọmọ Ogún wí, pé kì yíò fi gbòngbò tàbí ẹ̀ka sílẹ̀ fún wọn.

38 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ó ṣe àtúnwí ẹsẹ karũn báyìí: Kíyèsíi, èmi yíò fi Oyè àlùfáà hàn fún yín, nípa ọwọ́ wòlíì Èlíjah, ṣaájú dídé ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù tí Olúwa.

39 Bákannáà ó ṣe àtúnwí ẹsẹ tí ó tẹ̀lée ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀: Òun yíò sì gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ, àwọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn bàbá, ọkàn àwọn ọmọ náà yíò sì fà sí ọ̀dọ̀ àwọn bàbá wọn. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé ni yíò di fífiṣòfò ní bíbọ̀ rẹ̀.

40 Ní àfikún sí ìwọ̀nyí, ó ṣe àtúnwí orí ìkọkànlá ti Ìsaíah, wípé ó ti fẹ́rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ. Ó ṣe àtúnwí orí ẹ̀kẹta ti Ìṣe Àwọn Àpóstélì pẹ̀lú, àwọn ẹsẹ ìkejìlélógún àti ìkẹtàlélógún, gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe wà nínú Májẹ̀mú Titun wa. Ó sọ pé wòlíì èyínnì ni Krístì; ṣùgbọ́n ọjọ́ náà kò tĩ dé síbẹ̀ nígbàtí “àwọn ẹnití kò gbọ́ ohùn rẹ̀ yíò di kíké kúrò láàrin àwọn ènìyàn,” ṣùgbọ́n yíò dé láìpẹ́.

41 Bákannáà ó ṣe àtúnwí orí kejì ti Jóélì, láti ẹsẹ ìkejìdínlọ́gbọ̀n sí èyí tí ó kẹ́hìn. Ó sọ pẹ̀lú pé èyí kò tíì wá sí ìmúṣẹ síbẹ̀, ṣùgbọ́n yíò rí bẹ́ẹ̀ láìpẹ́. Ó sì tún sọ síwájú síi pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti àwọn Kèfèrí kì yíò pẹ́ wọlé wá mọ́. Ó ṣe àtúnwí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abala mĩràn ti ìwé mímọ́, ó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlàyé èyítí a kò lè mẹ́nubà ní ìhín yìí.

42 Lẹ́ẹ̀kansíi, ó sọ fún mi, pé nígbàtí mo bá gba àwọn àwo wọnnì èyítí ó ti sọ nipa rẹ̀—nítorí àkókò tí a níláti gbàá kò tíì wá sí ìmúṣẹ síbẹ̀—èmi kò gbọdọ̀ fi wọ́n hàn sí ẹnikẹ́ni; tàbí àwo-ìgbàyà pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù náà; bíkòṣe sí àwọn wọnnì nìkan tí a ó pàṣẹ fún mi láti fi wọ́n hàn; bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ a ó pa mí run. Bí ó ṣe nbá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn àwo náà, a ṣí ìran náà sí ọkàn mi tí mo sì rí ibití a fi àwọn àwo náà pamọ́ sí, àti èyíinì ní kedere àti láìsí àṣìṣe tóbẹ́ẹ̀ tí mo mọ ibẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi nígbàtí mo bẹ̀ ẹ́ wò.

43 Lẹ́hìn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yìí, mo rí tí ìmọ́lẹ̀ inú yàrá bẹ̀rẹ̀sí gbára jọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí àyíka ara ẹnì náà tí ó ti nba mi sọ̀rọ̀, ó sì tẹ̀síwájú ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ títí tí yàrá náà tún fi padà ṣókùnkùn, bíkòṣe ní àyíká rẹ̀ gan; nígbàtí, lójúkannáà mo ríi, bí ó ṣe wà, ihò kan ṣí tààrà sókè lọ sí inú ọ̀run, ó sì gun òkè títí tí ó fi parẹ́ tan pátápátá, yàrá náà sì padà sí bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ síwájú kí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run náà tó ṣe ìfarahàn rẹ̀.

44 Mo dùbúlẹ̀ ní ríronú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ náà, tí mo sì nní ìyanu nlá nípa ohun tí a ti sọ fún mi nípasẹ̀ òjíṣẹ ayanilẹ́nu náà; nígbàtí, ní ààrin àṣàrò mi, lójijì mo ríi pé yàrá mi tún bẹ̀rẹ̀sí mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, àti lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ó ṣe wà, òjíṣẹ́ kannáà láti ọ̀run tún ti wà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi.

45 Ó bẹ̀rẹ̀, ó sì tún sọ àwọn ohun kannáà gan an èyítí òun ti ṣe ní àbẹ̀wò rẹ̀ àkọ́kọ́, láì sí ìyípadà tí ó kéré jùlọ; èyítí nígbàtí tí ó ṣe tán, ó sọ fún mi nípa àwọn ìdájọ́ nlá tí ó nbọ̀ sí orí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àwọn ìsọdahoro nlá nípa ìyàn, idà, àti àjàkálẹ̀ àrùn; àti pé àwọn ìdájọ́ kíkorò wọ̀nyí yíò wá sí orí ilẹ̀ ayé nínú ìran yìí. Lẹ́hìn tí ó sọ àwọn nkan wọ̀nyí, ó gòkè lọ lẹ́ẹ̀kansíi bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀.

46 Ní àkókò yìí, jíjinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni àwọn àmì tí a ṣe sí ọkàn mi, tí oorun fi sálọ kúrò ní ojú mi, mo sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu tí ó bò mí mọ́lẹ̀ nípa ohun tí mo ti rí àti gbọ́. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu mi ti pọ̀ tó nígbàtí mo rí òjíṣẹ́ kannáà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi lẹ́ẹ̀kansíi, tí mo sì gbọ́ ọ tí ó tún ṣe àlàyé tàbí àtúnwí àwọn ohun kannáà fún mi lẹ́ẹ̀kansíi bí tí ìṣaájú; ó sì fi ìkìlọ̀ kan kún un fún mi, ní sísọ fún mi pé Sátánì yíò gbìyànjú láti dán mi wò (ní ìyọrísí ipò tálákà tí ẹbí bàbá mi wà), láti gba àwọn àwo náà fún èrò àti ní ọrọ̀. Èyí ni ó kà lẽwọ̀ fún mi, ní wíwí pé èmi kò gbọ́dọ̀ ní àfojúsùn míràn fún gbígba àwọn àwo náà bíkòṣe láti yin Ọlọ́run logo, èrò míràn kò sì gbọdọ̀ ní ipá ní orí mi ju kíkọ́ ìjọba rẹ̀ lọ; bíbẹ́ẹ̀kọ́ èmi kì yíò lè rí wọn gbà.

47 Lẹ́hìn àbẹ̀wò ẹlẹ́ẹ̀kẹta yìí, òun tún gòkè lọ sí ọ̀run lẹ́ẹ̀kansíi bí ti ìṣaájú, a sì tún fi mí sílẹ̀ láti ronú nípa bí ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìrírí rẹ̀ ṣe jẹ́ àjèjì; nígbàtí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́hìn tí òjíṣẹ́ láti ọ̀run náà gòkè kúrò lọ́dọ̀ mi fún ìgbà kẹta, ni àkùkọ kọ, mo sì ríi pé ọjọ́ ti súnmọ́, tí ó jẹ́ pé àwọn ìbánisọ̀rọ̀ wa ti gba gbogbo òru náà.

48 Láìpẹ́ lẹ́hìn náà ni mo dìde kúrò ní orí ibùsùn mi, àti, bíi ìṣe mi, mo lọ sí ibi àwọn iṣẹ òòjọ́ mi; ṣùgbọ́n, ní gbígbìyànjú láti ṣiṣẹ́ bíi ti àwọn ìgbà míràn, mo rí i pé okun mi ti lọ débi tí ó sọ mí di aláìlè ṣe ohunkóhun rárá. Bàbá mi, ẹnití ó nṣiṣẹ́ pẹ̀lú mi, ṣe àkíyèsí pé ó níláti jẹ́ pé ohun kan nṣe mí, ó sì sọ fún mi láti lọ sí ilé. Mo múra pẹ̀lú èrò láti lọ sí ilé; ṣùgbọ́n, ní gbígbìyànjú láti kọjá ọgbà jade kúrò ní oko ní ibití a wà, okun mi jámi kulẹ̀ pátápátá, mo sì ṣubú lulẹ̀ láìsí ìrànwọ́, àti fún àkókò kan mo wà láì mọ ohunkóhun.

49 Ohun àkọ́kọ́ tí mo lè rantí ni ohùn tí ó nbá mi sọ̀rọ̀, ní pípe mí ní orúkọ. Mo wò òkè, mo sì rí ìránṣẹ́ kannáà ní dídúró lókè orí mi, tí ìmọ́lẹ̀ sì yí i ká bíi ti ìṣaájú. Lẹ́ẹ̀kansíi òun tún ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ó ti sọ fún mi tẹ́lẹ̀ ní alẹ́ ti ìṣaájú, ó sì pàṣẹ fún mi láti lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá mi kí èmi ó sì sọ fún un nipa ìran àti àwọn òfin tí mo ti gbà.

50 Mo gbọ́ràn; mo padà sí ọ̀dọ̀ bàbá mi nínú oko, mo sì tún gbogbo ọ̀rọ̀ náà sọ fún un. Òun dá mi lóhùn pe ti Ọlọ́run ni, ó sì sọ fún mi láti lọ kí èmi sì ṣe bí ìránṣẹ́ náà ti pàṣẹ. Mo kúrò ní oko, mo sì lọ sí ibití ìránṣẹ́ náà sọ fún mi pé a fi àwọn àwo náà pamọ́ sí; àti nítorí àìrújú ìran náà èyítí mo ti ní nípa rẹ̀, mo mọ ibẹ̀ lójúkannáà tí mo dé ibẹ̀.

51 Ní àìjìnnà púpọ̀ sí ìletò Manchester, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ontario, New York, ni òkè nlá kan wà, òun ni ó sì ga jù èyíkéyìí lọ ní àdúgbò náà. Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè yìí, tí kò jìnà sí orí rẹ̀, ní abẹ́ òkúta nlá kan ni àwọn àwo kan wà, tí a fi pamọ́ sí inú àpótí òkúta kan. Okúta yìí nípọn ó sì yí róbótó ní àrin ní ibi apá òkè rẹ̀, tí ó sì fẹ́lẹ́ ní awọn ìgbátí, tí ibi ààrin rẹ̀ lè hàn sí òde ní orí ilẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbátí rẹ̀ yíká wà ní bíbò pẹ̀lú erùpẹ̀.

52 Lẹ́hìn tí mo ti mú erùpẹ̀ kúrò, mo mú ohun èlò kan bíi ọ̀pá, èyítí mo fi sí abẹ́ etí òkúta náà, àti pẹ̀lú lílo agbára kékeré mo gbé e sókè. Mo wo inú rẹ̀, àti níbẹ̀ nítòótọ́ ni mo rí àwọn àwo náà, Úrímù àti Túmímù, àti àwo-ìgbàyà, bí á ṣe sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ náà. Àpótí náà nínú èyítí a gbé wọ́n sí ni a mọ nípa fífi àwọn òkúta lélẹ̀ papọ̀ nínú irú amọ̀ líle kan. Ní ìsàlẹ̀ àpótí náà ni a gbé àwọn òkúta méjì sí ní dídábùú sí inú àpótí náà, ní orí àwọn òkúta wọ̀nyí ni a sì gbé àwọn àwo wọ̀nyí lé àti àwọn ohun míràn pẹ̀lú wọn.

53 Mo gbìdánwò láti gbé wọn jade, ṣùgbọ́n a kàá léèwọ̀ fún mi láti ọwọ́ ìránṣẹ́ náà, a sì tún sọ fúnmi pe akókò fún gbígbé wọn jade wá kò tíì tó síbẹ̀, bẹ́ẹ̀ni kì yíò tó, títí ọdún mẹ́rin sí àkókò náà; ṣùgbọ́n ó sọ fúnmi pé èmi níláti wá sí ibẹ̀ ní ọdún kan gééré sí àkókò náà, àti pé òun yíò pàdé pẹ̀lú mi níbẹ̀, àti pé èmi yíò tẹ̀síwájú láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí tí àkókò náà yíò dé fún gbígba àwọn àwo náà.

54 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí a ṣe pàṣẹ fún mi, mo lọ ní òpin ọdún kọ̀ọ̀kan, àti ní ìgbà kọ̀ọ̀kan mo rí ìránṣẹ́ kannáà níbẹ̀, mo sì gba ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀mí òye láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbánisọ̀rọ̀ wa, nípa ohun tí Olúwa fẹ́ ṣe, báwo àti irú ọ̀nà wo ni a ó sì gbà ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.

Joseph Smith fẹ́ Emma Hale—Ó gba àwọn àwo wúrà náà lọ́wọ́ Mórónì ó sì túmọ̀ díẹ̀ nínú àwọn ohun kíkọ rẹ̀—Martin Harris fi àwọn ohun kíkọ àti ìtumọ̀ náà hàn sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Anthon, ẹnití ó sọ pé, “Èmi kò lè ka ìwé tí a fi èdídí dì.” (Àwọn ẹsẹ 55–65.)

55 Nítorítí ìpò bàbá mi láyé wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì gidi, a wà ní abẹ́ pé ó jẹ́ dandan láti fi ọwọ́ wa ṣiṣẹ́, nípa ṣíṣe ọ̀yà bíi iṣẹ́ òòjọ́ àti bíbẹ́ẹ̀kọ́, bí a bá ṣe rí ànfààní. Nígbàmíràn a nwà ní ilé, àti nígbàmíràn ní òkèrè, àti nípa iṣẹ síṣe léraléra ó ṣeéṣe fúnwa láti ní ìtọ́jú tí ó tura.

56 Ní ọdún 1823 ẹbí bàbá mi bá ìpọ́njú nlá kan pàdé nípasẹ̀ ikú arákùnrin mi tí ó dàgbàjùlọ, Alvin. Ní oṣù Kẹwã, 1825, mo gba iṣẹ́ ọ̀yà pẹ̀lú onínú rere ọkùnrin àgbàlagbà kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Josiah Stoal, ẹnití ó gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Chenango, Ìpínlẹ̀ New York. Òun ti gbọ́ nkankan nípa ihò kan tí a ti nwa fàdákà tí ó ti jẹ́ ṣíṣí nípasẹ̀ àwọn ará ilẹ̀ Spain ní Harmony, ní ìjọba ìbílẹ̀ Susquehanna, Ìpínlẹ̀ Pennsylvania; òun sì ti nwalẹ̀, ṣíwájú kí á tó gbà mí ní ọ̀ya iṣẹ́ fún un, ní ọ̀nà, bí ó bá ṣèéṣe, láti ṣe àwárí ihò àlùmọ́nì náà. Lẹ́hìn tí mo lọ láti gbé pẹ̀lú rẹ̀, ó mú mi, pẹ̀lú ìyókù àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, láti wa ilẹ̀ fún ihò àlùmọ́nì fàdákà náà, níbi èyítí mo tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ fún bíi oṣù kan, láì sí àṣeyọrí nínú ìdáwọ́lé wa, àti ní ìparí mo yí ọkùnrin onínúre àgbàlagbà náà lọ́kàn padà láti dáwọ́ dúró nínú gbígbẹ́ ilẹ̀ náà ní wíwá ihò àlùmọ́nì náà. Níbẹ̀ ni ìròhìn díde tí ó tàn kálẹ̀ gidi pé èmi jẹ́ awalẹ̀-wá-owó.

57 Ni ààrin ìgbà tí a gbà mí sí iṣẹ́ báyìí, a mú mí làti gbé pẹ̀lú Ọgbẹ́ni kan Isaac Hale, ti àdúgbò ibẹ̀; ní ibẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ rí ìyàwó mi (ọmọbìnrin rẹ̀), Emma Hale. Ní ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù Kínní, 1827, a ṣe ìgbéyàwó, nígbàtí mo sì wà ní ibi iṣẹ́ Ọ̀gbẹ́ni Stoal.

58 Nítorí tí mo tẹ̀síwájú láti máa tẹnumọ́ pé mo ti rí ìran kan, inúnibíni tẹ̀lé mi síbẹ̀, àwọn ẹbí bàbá ìyàwó mi sì lòdì gidigidi sí ìgbéyàwó wa. Èmi, nítorínáà, wà lábẹ́ẹ jíjẹ́ dandan láti mú òun lọ sí ibòmiràn; nítorínáà a lọ a sì ṣe ìgbéyàwó ní ilé Squire Tarbill, ní South Bainbridge, ní ìjọba ìbílẹ̀ Chenango, New York. Ní kété lẹ́hìn ìgbéyàwó mi, mo fi ọ̀dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Stoal sílẹ̀, mo sì lọ sí ọ̀dọ̀ bàbá mi, mo sì ṣiṣẹ́ oko pẹ̀lú rẹ̀ fún àkókò náà.

59 Nígbàtí ó yá, àkókò tó fún gbígba àwọn àwo, Úrímù àti Túmímù, àti àwo-ìgbàyà náà. Ní ọjọ́ kejìlélógún Oṣù Kẹsãn, ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, ní lílọ bí ìṣe mi ní òpin ọdún mĩràn sí ibití a fi wọ́n pamọ́ sí, ìránṣẹ́ kannáà láti ọ̀run fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: pé èmi yíò dáhùn fún wọn; pé bí mo bá jẹ́ kí wọ́n lọ láìkíyèsára, tàbí nípasẹ̀ èyíkéyìí àìbìkítà tèmi, a ó ké mi kúrò; ṣùgbọ́n pé bí èmi bá lo gbogbo ìgbìyànjú mi láti pa wọ́n mọ́, títí òun, ìránṣẹ́ náà, yíò fi pè fún wọn, a ó dá ààbò bò wọ́n.

60 Kò pẹ́ tí mo rí ìdí tí mo fi gba irú àwọn ìkìlọ̀ líle bẹ́ẹ̀ láti pa wọ́n mọ́ láìléwu, àti ìdí rẹ̀ tí ìránṣẹ́ náà fi sọ pé nígbàtí mo bá ṣe ohun tí a béèrè lọ́wọ́ mi, òun yíò wá láti gbà wọ́n. Nítorí kò pẹ́ tí wọ́n mọ̀ pé mo ní wọn, tí agbára tí ó pọ̀ jùlọ jẹ́ lílo láti gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ mi. Gbogbo àrékérekè tí wọ́n lè ṣe ni ó jẹ́ lílò fún èrò yìí. Ìnúnibíni náà di kíkorò àti gbígbóná ju ti ìṣaájú lọ, ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ sì ti wà ní ìsọ́ra nígbà gbogbo láti gbà wọ́n lọ́wọ́ mi bí ó bá ṣeéṣe. Ṣùgbọ́n nípa ọgbọ́n Ọlọ́run, wọ́n wà láìléwu ní ọwọ́ mi, títí tí mo fi ṣe àṣeparí àwọn ohun tí a béèrè lọ́wọ́ mi nípa wọn. Nígbàtí, ní ìbámu sí àwọn ètò, ìránṣẹ́ náà béèrè wọn, mo fàá lé e lọ́wọ́; òun sì ní wọn ní ìkáwọ́ rẹ̀ títí di òní yìí, tí í ṣe ọjọ́ kejì Oṣù Karũn, ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ọdún méjìdínlógójì.

61 Ìtara náà, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, tẹ̀síwájú síbẹ̀, àti àhesọ pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún ahọ́n rẹ̀ ni wọ́n fi gbogbo ìgbà bẹ̀ ní iṣẹ́ ní ṣíṣe ìtànkálẹ̀ àwọn irọ́ pípa nípa ẹbí bàbá mi, àti nípa èmi tìkarami. Bí èmi bá ròhìn ìdá kan nínú ẹgbẹ̀rún wọn, yíò kún inú àwọn ìwé. Inúnibíni, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, di ohun tí kò ṣe é múmọ́ra mọ́ tí ó fi di dandan fúnmi láti kúrò ní Manchester, kí èmi sì lọ pẹ̀lú ìyàwó mi sí ìjọba ìbílẹ̀ Susquehanna, ní Ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Nígbàtí mo nmúra láti bẹ̀rẹ̀—ní jíjẹ́ aláìní gidi, àti tí inunibíni sì wúwo ní orí wa tó bẹ́ẹ̀ tí kò jọ pé nkan lè yípadà fúnwa láé—ní ààrin àwọn ìpọ́njú wa, a rí ọ̀rẹ́ nínú ọkùnrin onínú rere kan tí orúkọ rẹ́ njẹ́ Martin Harris, ẹnití ó wá sí ọ̀dọ̀ wa tí ó sì fún mi ní àádọ́ta owó dọ́là láti ràn wá lọ́wọ́ ní ìrìnàjò wa. Ọgbẹ́ni Harris jẹ́ olùgbé ìlú Palmyra, ìjọba ìbílẹ̀ Wayne, ní Ìpínlẹ̀ New York, ó sì jẹ́ àgbẹ̀ kan tí a nbu ọlá fún.

62 Nípa àtìlẹ́hìn tí ó bọ́ sí àkókò yìí ni ó ṣeéṣe fún mi láti dé òpin ìrìnàjò mi ní Pennsylvania; àti lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́hìn tí mo dé sí ibẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀sí ṣe àdàkọ àwọn ohun kíkọ náà kúrò nínú àwọn àwo. Mo ṣe àdàkọ púpọ̀ nínú wọn, àti nipa lílò Úrímù àti Túmímù mo túmọ̀ díẹ̀ nínú wọn, èyítí mo ṣe ní ààrin àkókò tí mo dé sí ilé bàbá ìyáwó mi, nínú Oṣù Kejìlá, àti Oṣù Kejì tí ó tẹ̀lé e.

63 Ní ìgbà kan nínú oṣù Kejì yìí, Ọ̀gbẹ́ni Martin Harris tí a mẹ́nubà tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa, ó gba àwọn ohun kíkọ èyítí mo ti dàkọ kúrò ní orí àwọn àwo náà, ó sì lọ pẹ̀lú wọn sí ìlú nlá New York. Fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nipa òun àti àwọn ohun kíkọ náà, mo tọ́ka sí àkọsílẹ̀ tirẹ̀ nípa àwọn nkan tí ó ṣẹlẹ̀, bí ó ti sọ wọ́n fún mi lẹ́hìn ìpadàbọ̀ rẹ̀, èyítí ó lọ báyìí:

64 “Mo lọ́ sí ìlú nlá New York, mo sì gbé àwọn ohun kíkọ èyítí wọ́n ti túmọ̀ kalẹ̀, pẹ̀lú ìtúmọ̀ rẹ̀, sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Anthon, ọkùnrin onínú rere kan tí ó lókìkí nítorí ọgbọ́n tí ó ti ní nínú ìwé kíkà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Anthon sọ pé ìtúmọ̀ náà pé, jù èyíkéyìí tí òun ti rí lọ tí a túmọ̀ láti ọwọ́ àwọn ará Égíptì. Nígbànáà ni mo fi àwọn wọnnì èyítí wọn kò tíì túmọ̀ síbẹ̀ hàn án, òun sì wí pé wọ́n jẹ́ èdè ti àwọn Égíptì, ti àwọn Kaldéà, ti àwọn Assùrí, àti ti àwọn Arabíà; òun sì wí pé wọ́n jẹ́ àwọn ọnà tòótọ́. Ó fún mi ní ìwé ẹ̀rí, ní fífi hàn sí àwọn ènìyàn Palmyra pé wọ́n jẹ́ àwọn ọnà tòótọ́, àti pé ìtúmọ̀ ti irú wọn bí a ṣe túmọ̀ wọn jẹ́ pípé pẹ̀lú. Mo mú ìwé ẹ̀rí náà mo sì fi sínú àpò mi, mo ti fẹ́ fi ilé náà sílẹ̀, nígbàtí Ọ̀gbẹ́ni Anthon pè mí padà, ó sì béèrè lọ́wọ́ mi bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ṣe mọ̀ pé àwọn àwo wúrà wà ní ibití òun ti rí wọn. Mo dá a lóhùn pé ángẹ́lì Ọlọ́run ti fi hàn sí i.

65 Nígbànáà ni ó sọ fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi rí ìwé ẹ̀rí nnì.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ mo mú un jade láti inú àpò mi mo sì fún un, nígbàtí ó gbàá tí ó sì ya á sí wẹ́wẹ́, ní sísọ pé kò sí irú nkan bẹ́ẹ̀ nísisìyí bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti pé bí èmi bá mú àwọn àwo náà wá fún un, òun yíò túmọ̀ wọn. Mo wí fún un pé apákan àwọn àwo náà ní a fi èdídí dì, àti pé a kã léèwọ̀ fún mi láti mú wọn wá. Ó fèsì, ‘Èmi kò lè ka ìwé tí a fi èdídí dì.’ Mo fi í sílẹ̀ mo sì lọ bá Ọ̀mọ̀wé Mitchell, ẹnití ó fi ọwọ́ sí ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Anthon ti sọ nípa àwọn ohun kíkọ àti ìtumọ̀ náà.”

· · · · · · ·

Oliver Cowdery ṣiṣẹ́ bíi akọ̀wé ní títúmọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì—Joseph àti Oliver gba Oyè-àlùfáà ti Áárónì láti ọ̀dọ̀ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi—A rì wọ́n bọmi, a yàn wọ́n, wọ́n sì gba ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀. (Àwọn ẹsẹ 66–75.)

66 Ní ọjọ́ Karũn Oṣù Kẹrin 1829, Oliver Cowdery wá sí ilé mi, títí di àkókò èyítí èmi kò rí i rí. Ó sọ fún mi pé ní kíkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ ní àdúgbò ibití bàbá mi gbé, tí bàbá mi sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí a rán sí ilé ẹ̀kọ́ náà, ó lọ láti gbé fún sáà kan ní ilé rẹ̀, tí ó sì wà níbẹ̀, ẹbí náà ṣe àláyé ìṣẹ̀lẹ̀ bí mo ṣe gba àwọn àwo náà, àti nítorínáà òun wá láti ṣe ìwádìí ní ọ̀dọ̀ mi.

67 Ọjọ́ méjì lẹ́hìn tí Ọ̀gbẹ́ni Cowdery dé (tí í ṣe ọjọ́ keje Oṣù Kẹrin) mo bẹ̀rẹ̀ láti ṣe ìtúmọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, òun sì bẹ̀rẹ̀sí kọ̀wé fún mi.

· · · · · · ·

68 À tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ títúmọ̀ náà síbẹ̀, nígbàtí, nínú oṣù tí ó tẹ̀lée (Oṣù Karũn, 1829), a lọ sí inú igbó láti gbàdúrà àti láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ìrìbọmi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀, tí a rí tí ó jẹ́ mímú ẹnu bà nínú ìtúmọ̀ àwọn àwo náà. Bí ọwọ́ wa ṣe dí báyìí, ní gbígbàdúrà àti ní kíké pe Olúwa, ìránṣẹ́ kan láti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ nínú ikũkù ìmọ́lẹ̀, àti ní gbígbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí wa, ó yàn wá, ní wíwí pé:

69 Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Messíah, mo fún yín ní Oyè-àlùfáà ti Áárónì, èyí tí ó ní kọ́kọ́rọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì, àti ti ìhìnrere ti ìrònúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírìbọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀; a kì yíò sì tún mú èyí kúrò ní orí ilẹ̀ ayé mọ́ láé títí tí àwọn ọmọ Léfì yíò fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan síi sí Olúwa nínú òdodo.

70 Ó wí pé Oyè-àlùfáà ti Áárónì yìí kò ní agbára ti ìgbọ́wọ́lé fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ṣùgbọ́n pé a ó fi èyí fún wa lẹ́hìnwá; òun sì pàṣẹ fún wa láti lọ kí á sì rì wá bọmi, ó sì fún wa ní àwọn ìdarí pé kí èmi ó ri Oliver Cowdery bọmi, àti pé lẹ́hìnnáà kí òun kí ó rì èmi bọmi.

71 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ a lọ a sì rì wá bọmi. Èmi kọ́kọ́ ri òun bọmi, àti lẹ́hìnnáà òun rì èmi bọmi—lẹ́hìn èyítí mo gbé ọwọ́ mi lée ní orí tí mo sì yàn án sí ipò Oye-àlùfáà ti Áárónì, àti léhìnnáà ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé mi ó sì yàn mí sí ipò Oyè àlùfáà kannáà—nítorí bẹ́ẹ̀ ni a pàṣẹ fún wa.*

72 Ìránṣẹ́ tí ó bẹ̀ wá wò ní àkókò yìí tí ó sì fi Òyè Àlùfáà yìí fún wa, sọ pé orúkọ òun ni Jòhánnù, òun kannáà tí a pè ní Jòhánnù Onítẹ̀bọmi nínú Májẹ̀mú Titun, àti pé òun ṣe iṣẹ́ labẹ́ ìdarí ti Petérù, Jákọ́bù àti Jòhánnù, ẹnití ó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyè-Àlùfáà ti Melkisedekì, Oyè-àlùfáà èyítí, ó wí pé, a ó fi fún wa bí àkókò bá tó, àti pé kí á pè mí ní Alàgbá àkọ́kọ́ ti Ìjọ, àti òun (Oliver Cowdery) èkejì. Ó jẹ́ ọjọ́ kẹ̃dógún Oṣù Karũn, 1829, tí a yàn wá ní abẹ́ ọwọ́ ìránṣẹ́ yìí, àti tí a rì wá bọmi.

73 Lọ́gán ní jíjáde wa sókè láti inú omi lẹ́hìn tí a ti rì wá bọmi, a ní ìrírí àwọn ìbùkún nlá àti ológo láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run. Kò pẹ́ tí mo ri Oliver Cowdery bọmi, tí Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé e, ó sì dìde sókè ó sì sọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan èyítí yíò wá sí ìmúṣẹ láìpẹ́. Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ní kété tí a rì mí bọmi láti ọwọ́ rẹ̀, èmi pẹ̀lú ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nígbàtí, ní ìdúró sókè, mo sọtẹ́lẹ̀ nípa ìdìde ti Ìjọ yìí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun míràn èyítí ó jẹ mọ́ Ìjọ, àti ìran yìí ti àwọn ọmọ ènìyàn. A kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, a sì yọ̀ nínú Ọlọ́run ìgbàlà wa.

74 Ọkàn wa níwọ̀n bí ó ti ní òye nísisìyí, a bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn ìwé mímọ́ ní ṣíṣí kalẹ̀ sí ìmọ̀ wa, ìtúmọ̀ òtítọ́ àti èrò àwọn abala wọn tí ó jẹ́ ìjìnlẹ̀ jùlọ sì jẹ́ fífi hàn sí wa ní ọ̀nà tí kò lè dé àrọ́wọ́tó wa ní ìṣaájú, tàbí tí a kò tilẹ̀ ronú rẹ̀ láé tẹ́lẹ̀. Fún ìgbà díẹ̀ ná, a fi ipá mú wa láti fi pamọ́ ní àṣírí ọ̀rọ̀ nípa gbígba Oyè-àlùfáà àti bí a ṣe ti rì wá bọmi, nítorí ẹ̀mí inúnibíni èyítí ó ti fi ara rẹ̀ hàn ní àdúgbò.

75 A ti halẹ̀ mọ́ wá pẹ̀lú ìyọlẹ́nu láti ọwọ́ àgbáríjọ àwọn jàndùkú ènìyàn, láti ìgbà dé ìgbà, àti èyí pẹ̀lú, láti ọwọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀sìn. Tí èrò wọn fún kíkọlù wá sì jẹ́ èyí tí a já kulẹ̀ nípasẹ̀ agbára ẹbí bàbá ìyàwó mi (lábẹ́ ìpèsè-sílẹ̀ Àtọ́runwá), ẹnití ó ti di bí ọ̀rẹ́ sí mi, tí ó sì lòdì sí ìkọlù àwọn jàndùkú náà, tí ó sì fẹ́ pé kí a gbàmí ní ààyè láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìtúmọ̀ láì sí ìdádúró; àti nítoríáà, ó fúnni, ó sì ṣe ìlérí ààbò fún wa lọ́wọ́ gbogbo àwọn ìwọ́de tí kò bá òfin mu, níwọ̀nbí wọ́n ti lè ṣe tó.

  • Oliver Cowdery ṣe àpèjúwe àwọn ìṣẹlẹ̀ náà báyìí: Ìwọ̀nyí ni àwọn ọjọ́ tí kò ṣe é gbàgbé láé—láti jókòó lábẹ́ dídún ohùn pípè nípasẹ̀ ìmísí ọ̀run, ó ṣe ìtají ìmore gígajùlọ ti oókan àyà yìí! Ọjọ́ lẹ́hìn ọjọ́ mo tẹ̀síwájú, láìsí ìdádúró, láti kọ̀wé láti ẹnu rẹ̀, bí ó ṣe túmọ̀ pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù, tàbí, bí àwọn ará Néfì ìbá ṣe sọ, ‘àwọn Olùtúmọ̀,’ ìwé ìtàn tàbí àkọsílẹ̀ tí a pè ní ‘Ìwé ti Mọ́mọ́nì.’

    “Láti ṣe àkíyèsí, àní ní àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀, àkọsílẹ̀ dídùnmọ́ni tí a fi fúnni láti ọwọ́ Mọ́mọ́nì àti olõtọ́ ọmọ rẹ̀, Mórónì, nípa àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti fi ìgbàkan jẹ́ àyànfẹ́ àti ẹni ojú rere ti ọ̀run, yíò ju iṣẹ́ mi ní àkókò yìí lọ; nítorínáà èmi yíò dá èyí dúró di ìgbà míràn ní ọjọ́ iwájú, àti, bí mo ṣe wí nínú ọ̀rọ̀ ìṣaájú, èmi ó lọ tààrà sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ díẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ìdìde Ìjọ yìí, èyítí ó lè jẹ́ ìdárayá fún àwọn bíi ẹgbẹ̀rún díẹ̀ tí wọ́n ti bọ́ síwájú, ní ààrin ìfajúro ti àwọn aláìmòye àti ìṣátá ti àwọn àgàbàgebè, tí wọ́n sì gba Ìhìnrere Krístì mọ́ra.

    “Kò sí àwọn ènìyàn, nínú iyè àròjìnlẹ̀ wọn, tí ó lè túmọ̀ àti kọ àwọn ìdarí tí a fi fún àwọn ará Néfì láti ẹnu Olùgbàlà, nípa ọ̀nà pàtó nínú èyí tí àwọn ènìyàn yíò kọ́ Ìjọ rẹ̀, àti ní pàtàkì nígbàtí ìdíbàjẹ́ ti tan iyèméjì sí orí gbogbo àwọn ètò àti àwọn ìlànà tí ó jẹ́ ṣíṣe ní ààrin àwọn ènìyàn, láì ní ìfẹ́ inú sí ànfàní kan ti fífi ìfẹ́ ọkàn hàn nípa kí wọ́n jẹ́ sísin sí inú ibojì olómi, láti dáhùn ‘ẹ̀rí ọkàn rere nípasẹ̀ àjínde ti Jésù Krístì.’

    “Lẹ́hìn kíkọ ìròhìn tí a fi fúnni nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà sí ìyókù àwọn irú ọmọ Jákọ́bù, ní orí ìpín ilẹ̀ ayé yìí, ó rọrùn láti rí wa, bí wòlíì ṣe sọ pé yíò jẹ́, pé òkùnkùn borí ilẹ̀ ayé àti òkùnkùn biribiri sí ọkàn àwọn ènìyàn. Ní ṣíṣe àgbéyẹ̀wò síwájú ó jẹ́ ìrọ̀rùn láti rí pé, láàrin ìjà nlá àti ariwo nípa ẹ̀sìn, ẹnikẹ́ni kò ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe àmójútó àwọn ìlànà Ìhìnrere. Nítorí ìbéèrè lè jẹ́ bíbéèrè, njẹ́ àwọn ènìyàn ní àṣẹ láti ṣe àmójútó àwọn ìlànà ní orúkọ Krístì, ẹnití ó sẹ́ àwọn ìfihàn, nígbàtí ẹ̀rí Rẹ̀ kò kéré ju ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ lọ, àti tí ẹ̀sìn Rẹ̀ dúró ní orí, tí a kọ́ọ, àti tí a ṣe ìmúdúró rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìfihàn tààrà, nínú gbogbo àwọn ìgbà ayé nígbàtí Òun ti ní àwọn ènìyàn kan ní órí ilẹ̀ ayé? Bí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí bá jẹ́ sísin, àti tí a fi ìṣọ́ra bòó mọ́lẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ènìyàn, àwọn ẹnití àrékérekè wọn ìbá wà nínú ewu, bí níwọ̀nbí a bá gbà wọ́n láàyè láti tàn ní ojú àwọn ènìyàn, wọn kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ sí wa mọ́; àti pé àwa sáà dúró de òfin náà láti di fífúnni ‘Ẹ dide kí a sì rì yín bọmi.’

    “Èyí kò jẹ́ ìfẹ́ ọkàn pẹ́ títí kí ó tó di rírí. Olúwa, ẹnití ó pọ̀ ní àánú, tí ó sì ní ìfẹ́ láti dáhùn àdúrà àìyẹsẹ̀ ti onírẹ̀lẹ̀, lẹ́hìn tí a ti ké pè É nínú ìgbóná ara, bí ó tilẹ̀ jinnà sí ìbùgbé àwọn ènìyàn, Ó rẹ ara sílẹ̀ láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí wa. Ní òjijì, bíi láti àárin ayérayé, ohùn Olùràpadà sọ ọ̀rọ̀ àlãfíà sí wa, nígbàtí aṣọ ìkéle pínyà tí ángẹ́lì Ọlọ́run sì sọ̀kalẹ̀ tí a wọ̀ ní asọ pẹ̀lú ògo, tí ó sì jẹ́ ìhìn tí a ti nfi ìtara wo ọ̀nà fún, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ ti Ìhìnrere ironúpìwàdà. Irú ayọ̀ wo! Irú ìyanu wo! Irú ìyalẹ́nu wo! Nígbàtí ayé wà nínú ìrora àti ìdàámú—nígbàtí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ntáràrà bí afọ́jú fún ògiri, àti nígbàtí gbogbo ènìyàn nsìmi ní orí iyèméjì, bíi àgbájọ kan, ojú wa rí, etí wa gbọ́, bíi ní ‘ọ̀sán gangan ọjọ́’; bẹ́ẹ̀ni, jù bẹ́ẹ̀ lọ—tayọ dídán ti ìtànsán oòrùn inú Oṣu Karũn, èyítí ó nfi títàn rẹ̀ ìgbà náà sí ojú gbogbo àdánidá! Nígbànáà ohùn rẹ̀, bí ó tilẹ̀ ṣe jẹ́jẹ́, wọ inú sí ààrin gbùngbùn, àti àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ‘Èmi ni ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ yín,’ lé gbogbo ẹ̀rù lọ. Àwa tẹ́tí sílẹ̀, a tẹjú mọ́ọ, ó jọwá lójú! Ó jẹ́ ohùn ángẹ́lì kan láti inú ògo, ó jẹ́ iṣẹ́ rírán kan láti ọ̀dọ̀ Ẹni Gíga jùlọ! Àti bí a ṣe gbọ́ọ a yọ̀, nígbàtí ìfẹ́ Rẹ̀ rú sókè nínú ọkàn wa, tí a sì ró wa sínú ìran Alágbára Jùlọ! Níbo ni ààyè wà fún iyèméjì? Kò sí ibìkankan; àìdánilójú ti sá lọ, ìyèméjì ti wọlẹ̀ ti kì yíò dìde mọ́, nígbàtí ọ̀rọ̀ lásán àti ìtànjẹ ti sá lọ títí láé!

    “Ṣùgbọ́n, arákùnrin ọ̀wọ́n, ronú, ronú síwájú síi fún ìgbà díẹ̀, irú ayọ̀ tí ó kún ọkàn wa, àti pẹ̀lú irú ìyàlẹ́nu tí a gbọdọ̀ ti tẹ orí wa ba, (nítorí taani kò ní tẹ eékún ba fún irú ìbùkún bẹ́ẹ̀?) nígbàtí a gba Oyè-àlùfáà Mímọ́ ní abẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bí ó ṣe wí pé, ‘Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Mèssíà, mo fi Oyè-àlùfáà yìí àti àṣẹ yìí fún yín, èyítí yíò wà ní orí ilẹ̀ ayé, pé kí àwọn Ọmọ Lefí ó lè tún rú ẹbọ sí Olúwa nínú òdodo!’

    “Èmi kì yíò gbìdánwò láti ya àwòrán àwọn ìmọ̀lára ti ọkàn yìí sí yín, tàbí ẹwà àti ògo tí ó ní ọlá èyítí ó yí wa ká ní àkókò yìí; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò gbà mí gbọ́ nígbàtí mo wí, pé ilẹ̀ ayé, tàbí àwọn ènìyàn, pẹ̀lú mímọ̀ọ́ṣe inú àkókò, kì yíò lè bẹ̀rẹ̀sí wọṣọ fún èdè ní ọ̀nà tí ó fanimọ́ra tí ó sì ní ìmísí bíi ti ẹni nlá mímọ́ yìí. Rárá, tàbí kí ilẹ̀ ayé yìí ní agbára láti fúnni ní ayọ̀ náà, láti fi àlãfíà náà fúnni, tàbí ní òye ọgbọ́n èyítí ó wà nínú gbolóhùn kọ̀ọ̀kan bí a ṣe fi wọ́n sílẹ̀ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́! Ènìyàn lè tan ènìyàn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ, ìtànjẹ lè tẹ̀lé ìtànjẹ, àwọn ọmọ ènìyàn búburú sì lè ní agbára láti rọ̀ àwọn òpè àti aláìlẹ́kọ̀ọ́, títí tí asán, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ lásán, yío bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí èso èké nínú sísàn rẹ̀ ngbé àwọn balógun lọ sí inú ibojì; ṣùgbọ́n ìfọwọ́kàn kan pẹ̀lú ika ìfẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, ìtànsán ògo kan láti ayé ti òkè wá, tàbí ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu Olùgbàlà, láti oókan àyà ayérayé, lù gbogbo rẹ̀ sí yẹpẹrẹ, ó sì paárẹ́ títí láé kúrò nínú ọkàn. Ìdánilójú náà pé a wà níwájú ángẹ́lì kan, dídánilójú náà pé a gbọ́ ohùn ti Jésù, àti òtítọ́ náà àìníèérí bí ó ti ṣàn wá láti ọ̀dọ̀ àìlábàwọ́n ẹni nlá kan, tí a pè fúnni nípasẹ̀ ìfẹ́ inú Ọlọ́run, sí èmi ó kọjá àpèjúwe, èmi ó sì máa fi ìgbàgbogbo wo ire Olùgbàlà tí ó fi hàn yìí pẹ̀lú ìyanu àti fífi ọpẹ́ fún níwọ̀n ìgbàtí a bá gbà mí láàyè láti dúró; àti nínú àwọn ibùgbé wọnnì níbití àṣepé ngbé tí ẹ̀ṣẹ̀ kìí sìí wá láé, mo ní ìrètí láti bu ọlá ní ọjọ́ náà èyítí kò ní dáwọ́dúró láé.”—Messenger and Advocate, vol. 1 (October 1834), pp. 14–16.