Àwọn Ìwé Mímọ́
Joseph Smith—Matteu 1


Joseph Smith—Matteu

Àyọkà kan láti inú ìyírọ̀padà Bíbélì bí a ṣe fihàn sí Wòlíì Joseph Smith ní 1831: Mátteu 23:39 àti orí 24.

Orí 1

Jésù sọtẹ́lẹ̀ níti ìparun ti ó nbọ̀ láìpẹ́ ní Jérusálẹ́mù—ó tún kọ́ni ní ẹ̀kọ ní orí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Ọmọ Ènìyan, àti ìparun àwọn ènìyàn búburú.

1 Nítorí mo wí fún yín, pé ẹ̀yin kì yíò sì rí mi láti ìgbà yìí lọ kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni ẹni náà tí a ti kọ nípa rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, títí tí ẹ̀yin yíò fi wípé: Ìbùkún ni fún ẹnití ó nbọ̀ ní orúkọ Olúwa, nínu àwọ sánmà ti ọ̀run, àti gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Nígbànáà ni ó yé àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ pé òun yíò tún padà wá sí orí ilẹ̀ ayé, lẹ́hìn tí a ti ṣe é logo tí a sì dé e lade ní apá ọ̀tún Ọlọ́run.

2 Jésù sì jade lọ, ó sì lọ kúrò ní tẹ́mpìlì; àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí láti gbọ́ ọ, wọ́n wípé: Olùkọ́ni, fi hàn wá nípa àwọn òrùlé tẹ́mpìlì náà, bí ìwọ ti wí—Wọ́n yíò jẹ́ wíwó lulẹ̀, a ó sì fi wọ́n sílẹ̀ fún yín ní ahoro.

3 Jésù sì wí fún wọn pé: Ẹ̀yin kò ha rí àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ ko ha sì ní òye wọn bí? Lõtọ́ ni mo wí fún yín, a kì yíò fi sílẹ̀ ní ìhín, ní orí tẹ́mpìlì yìí, òkúta kan ní orí òmíràn tí kì yíò jẹ́ wíwó lùlẹ̀.

4 Jésù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì lọ sí orí Òkè Ólífì. Bí ó sì ṣe jókòó ní orí òkè Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá ní ìkọ̀kọ̀, wípé: Wí fún wa nígbàwo ni àwọn nkan wọ̀nyí yíò ṣẹ èyítí ìwọ ti wí nípa ìparun tẹ́mpìlì náà, àti àwọn Júù; àti kínni àmì bíbọ̀ rẹ, àti òpin ayé, tàbí ìparun ti àwọn ènìyàn búburú, èyítí í ṣe òpin ayé?

5 Jésù sì dáhùn, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ sọ́ra kí ẹnikẹ́ni máṣe tàn yín jẹ;

6 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yíò wá ní orúkọ mi, wípé—Èmi ni Krístì—wọn yío sì tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ;

7 Nígbànáà ni wọn yíò jọ̀wọ́ yín láti pọ́n yín lójú, wọn yío sì pa yín, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíó sì kóríra yín, nítorí orúkọ mi;

8 Àti nígbànáà ni a ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀, wọn yíò sì dalẹ̀ ara wọn, wọn yíò sì koríra ara wọn;

9 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì èké ni yíò sì dìde, wọn yíò sì tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ;

10 Àti nítorí tí àìṣedédé yíò gbilẹ̀, ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò di tutu;

11 Ṣùgbọ́n ẹnití ó bá dúró ṣinṣin tí a kò sì borí rẹ̀, òun kannáà ni a ó gbàlà.

12 Nígbàtí ẹ̀yin, nítorínáà, yíò rí ohun ìríra ti ìsọ̀dahoro, tí a sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ẹnu wòlíì Dáníẹlì, nípa ìparun Jérúsálẹ́mù, nígbànáà ẹ̀yin yíò dúró ní ibi mímọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá kàá kí ó yé e.

13 Nígbànáà ni kí àwọn tí wọ́n wà ní Jùdéà ó sá sí inú àwọn òkè;

14 Kí ẹnití ó wà ní òkè ilé ó sá, kí ó má sì ṣe padà láti mú ohunkóhun jade ní ilé rẹ̀;

15 Bẹ́ẹ̀ni kí ẹni tí ó wà ní oko máṣe padà sẹ́hìn láti mú àwọn aṣọ rẹ̀;

16 Ègbé sì ni fún àwọn tí wọ́n ní oyún sínú, àti fún àwọn tí wọn nfi ọmú fún ọmọ ní àwọn ọjọ́ wọnnì;

17 Nítorínáà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa kí sísálọ yín kí ó máṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ní Ọjọ́ Ìsinmi;

18 Nítorí nígbànáà, ní àwọn ọjọ́ wọnnì, ni ìpọ́njú nlá yíò wá sí orí àwọn Júù, àti sí orí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù, irú èyí tí a kò rán sí orí Ísráẹ́lì rí, láti ọwọ́ Ọlọ́run, láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìjọba wọn títí di àkókò yìí; rárá, tàbí kí á rán irú rẹ̀ sí orí Ísráẹ́lì lẹ́ẹ̀kansíi láé.

19 Ohun gbogbo èyítí ó ti já lù wọ́n jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán ti àwọn ìbànújẹ́ èyítí yíò wá sí orí wọn.

20 Àti bíkòṣe pé a ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kì yíò sí èyíkéyìí nínú ẹran ara wọn tí a ó gbàlà; ṣùgbọ́n nítorí àwọn àyànfẹ́, ní ìbámu sí májẹ̀mú, a ó ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.

21 Kíyèsíi, àwọn ohun wọ̀nyí ni mo ti wí fún yín nípa àwọn Júù; àti lẹ́ẹ̀kansíi, lẹ́hìn ìpọ́njú ti àwọn ọjọ́ wọnnì èyítí yíò wá sí orí Jérúsálẹ́mù, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún yín, Wõ, Krístì wà níhĩn, tàbí lọ́hũn, ẹ máṣe gbà wọn gbọ́;

22 Nítorí ní àwọn ọjọ́ wọnnì bákannáà àwọn èké Krístì yío díde, àti àwọn èké wòlíì, wọn yíò sì fi àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ iyanu nlá hàn, tóbẹ́ẹ̀, pé, tí ó bá ṣeéṣe, wọn yíò tan àwọn àyànfẹ́ gan an jẹ, àwọn tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ ní ìbámu sí májẹ̀mú.

23 Kíyèsíi, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún yín nítorí àwọn àyànfẹ́; ẹ̀yin pẹ̀lú yíò sì gbọ́ ìró àwọn ogun, àti ìdágìrì àwọn ogun; ẹ ríi pé ẹ̀yin kò dààmú, nítorí ohun gbogbo tí mo ti wí fún yín gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ; ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin síbẹ̀.

24 Kíyèsíi, mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀;

25 Nítorínáà, bí wọn bá wí fún yín pé: Kíyèsíi, òun wà nínú aginjù; ẹ máṣe lọ: Kíyèsíi, òun wà nínú àwọn yàrá ìkọ̀kọ̀; ẹ máṣe gbàgbọ́;

26 Nítorí bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ ṣe njade wá láti ìlà oòrùn, tí yíò sì tàn àní títí dé ìwọ̀ oòrùn, tí yíò sì bo gbogbo orí ilẹ̀ ayé, bákannáà bẹ́ẹ̀ ni bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn yíò rí.

27 Àti nísisìyí èmi sọ òwe kan fún yín. Kíyèsíi, níbikíbi tí okú bá wà, níbẹ̀ ni àwọn ẹyẹ idì yíò pejọ papọ̀ sí; bẹ́ẹ̀ ni àwọn àyanfẹ́ mi yíò péjọ papọ̀ láti igun mẹ́rẹ̃rin ilẹ̀ ayé.

28 Wọn yíò sì gbọ́ ìró àwọn ogun, àti ìdágìrì àwọn ogun.

29 Kíyèsíi mo sọ̀rọ̀ nítorí àyànfẹ́ mi; nítorí orílẹ́ èdè yíò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; àwọn ìyàn yíò wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrun, àti ilẹ̀ ríri, ní onírúurú ibi.

30 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, nítorí tí àìṣedédé yíò pọ̀, ìfẹ́ àwọn ènìyàn yíò di tútù; ṣùgbọ́n ẹni náà tí a kò bá borí rẹ̀, òun kannáà ni a ó gbàlà.

31 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ìhìnrere ti Ìjọba yìí ni a ó wàásù ní gbogbo ayé, bí ẹ̀rí kan sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, nígbànáà ni òpin yíò sì dé, tàbí ìparun àwọn ènìyàn búburú;

32 Àti lẹ́ẹ̀kansíi ni àwọn ohun ìríra ibi ahoro, tí a sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì, yíò di mímúṣẹ.

33 Àti ní kété lẹ́hìn ìpọ́njú ti àwọn ọjọ́ wọnnì, oòrùn yíò ṣokùnkùn, òṣùpá kì yíò sì fúnni ní ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yíò sì já lulẹ̀ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run yíò sì mì tìtì.

34 Lõtọ́, ni mo wí fún yín, ìran yìí, nínú èyítí àwọn nkan wọ̀nyí yíò di fífihàn jade, kì yíò kọjá lọ títí tí gbogbo ohun tí mo ti wí fún yín yíò di mímúṣẹ.

35 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọjọ́ náà yíò dé, tí ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ; síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n gbogbo wọn yíò di mímúṣẹ.

36 Àti, bí mo ti sọ ṣaájú, lẹ́hìn ìpọ́njú ti àwọn ọjọ́ wọnnì, àwọn agbára ọ̀run yíó sì mì tìtì, nígbànáà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yíò fi ara hàn ní ọ̀run, àti nígbànáà ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yíò ṣọ̀fọ̀; wọn yíò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí ó nbọ̀ ní àwọ̀ sánmọ̀ ti ọ̀run, pẹ̀lú agbára àti ògo nlá;

37 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọ̀rọ mi ṣe ìṣúra, ni a kì yìò tàn jẹ, nítorí Ọmọ Ènìyàn yíò wá, òun yíò sì rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ saájú rẹ̀ pẹ̀lú ìró nlá ti fèrè, wọn yíò sì kó ìyókù àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ papọ̀ láti ibi mẹ́rẹ̃rin afẹ́fẹ́, láti òpin kan ti ọ̀run sí òmíràn.

38 Nísisìyí ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ òwe ti igi ọ̀pọ̀tọ́—Nígbàtí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá wà ní ọ̀dọ́, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ àwọn ewé jade, ìwọ mọ̀ wipe ìgbà ẹẹ̀rùn súnmọ́ itòsí;

39 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn àyànfẹ́ mi, nígbàtí wọ́n bá rí gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, wọn yíò mọ̀ pé òun wà nítosí, àní ní ẹnu àwọn ìlẹ̀kùn;

40 Ṣùgbọ́n ní ti ọjọ́ náà, àti wákàtí, kò sí ẹnití ó mọ̀; rára, àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run pàápàá kò mọ̀ọ́, ṣùgbọ́n Bàbá mi nìkanṣoṣo.

41 Ṣùgbọ́n bí ó ti rí ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ni yíò rí pẹ̀lú ní ti bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn;

42 Nítorí yíò rí pẹ̀lú wọn, bí ó ti rí ní àwọn ọjọ́ tí ó saájú ìkún omi; nítorí títí di ọjọ́ tí Nóà wọ inú ọkọ̀ náà, wọ́n njẹ wọ́n sì nmu, wọ́n ngbeyàwó wọ́n sì nfi fúnni ní ìgbeyàwó;

43 Wọn kò sì mọ̀ títí tí ìkún omi fi dé, tí ó sì mú gbogbo wọn lọ; bẹ́ẹ̀ni bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn yíò rí pẹ̀lú.

44 Nígbànáà ni èyí tí a ti kọ yíò di mímúṣẹ, pé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, àwọn méjì yíò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀;

45 Àwọn méjì yíò máa lọ ọlọ ní ibi ẹ̀rọ, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkèjì sílẹ̀;

46 Àti pé ohun tí mo wí fún ẹnikàn, mo wíi fún gbogbo ènìyàn; ẹ máa sọ́nà, nítorínáà, nítorí ẹ̀yin kò mọ wákàtí wo ni Olúwa yín yíò dé.

47 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí, bí bale ilé bá mọ wákàtí tí olè yíò wá, òun ìbá ti ṣọ́nà, òun ìbá má sì jẹ́kí ilé rẹ̀ di fífọ́, ṣùgbọ́n ìbá ti múra sílẹ̀.

48 Nítorínáà kí ẹ̀yin pẹ̀lú múra sílẹ̀, nítorí ní wákàtí náà tí ẹ̀yin kò lérò, ni Ọmọ Ènìyàn yíò dé.

49 Taani, nígbànáà, tí ó jẹ́ olõtọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́, ẹnití olúwa rẹ̀ ti fi ṣe alákóso ní orí gbogbo ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ ní àkókò tí ó yẹ?

50 Alábùkúnfún ni ìránṣẹ́ náà ẹnití olúwa rẹ̀, nígbàtí ó dé, yíò bá tí ó nṣe bẹ́ẹ̀; lõtọ́ ni mo sì wí fún yín, òun yíò fi ṣe alákóso ní orí gbogbo ohun ìní rẹ̀.

51 Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé: Olúwa mi fa bíbọ̀ rẹ̀ sẹ́hìn,

52 Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ láti lu àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àti láti jẹ àti láti mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí,

53 Olúwa ìránṣẹ́ náà yíò dé ní ọjọ́ kan nígbàtí òun kò fi ojú sọ́nà fún un, àti ní wákàtí tí òun kò mọ̀ nípa rẹ̀,

54 Yíò sì pín in sí méjì, yíò sì yan ìpín tirẹ̀ fún un pẹ̀lú àwọn àgàbàgebè; níbẹ̀ ni ẹ̀kún àti ìpahínkeke yíò wà.

55 Báyìí sì ni òpin àwọn ènìyàn búburú, gẹ́gẹ́bí àsọtẹ́lẹ̀ Mósè, wípé: A ó ké wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn náà; ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin ilẹ̀ ayé síbẹ̀, ṣùgbọ́n ní àìpẹ́.