Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 1


Àwọn Àsàyàn láti inú
Ìwé ti Mósè

Àyọkà kan láti inú ìyírọ̀padà Bíbélì bí a ṣe fi hàn fún Wòlíì Joseph Smith, Oṣù Kẹfà 1830–Oṣù Kejì 1831.

Orí 1

(Oṣù Kẹfà Ọdún 1830)

Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Mósè—A pa Mósè lára dà—A kò ó lójú láti ọwọ́ Sátánì—Mósè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé tí àwọ̀n ẹ̀dá ngbé—A ṣe ẹ̀dá àwọn ayé tí wọn kò ní ònkà láti ọwọ́ Ọmọ—Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ni láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ṣẹ fún ènìyàn.

1 Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí ó sọ fún Mósè ní àkókò kan nígbàtí a gbé Mósè lọ sí orí òkè kan tí ó ga rékọjá.

2 Òun sì rí Ọlọ́run ní ojúkojú, òun sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ògo Ọlọ́run sì wà lára Mósè; nítorínáà Mósè lè fi ara da wíwà rẹ̀.

3 Ọlọ́run sì bá Mósè sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsíi, èmi ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, Àìlópin sì ni orúkọ mi; nítorí èmi kò ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ tàbí òpin àwọn ọdún; àti pé èyí kò ha jẹ́ àìlópin bí?

4 Sì kíyèsíi, ìwọ ni ọmọ mi; nísisìyí wòó, èmi yíò sì fi àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi hàn ọ́; ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo rẹ̀, nítorí àwọn iṣẹ́ mi wà lainí òpin, àti bákannáà àwọn ọ̀rọ̀ mi, nítorí wọn kò dáwọ́ dúró láé.

5 Nísisìyí, kò sí ènìyàn tí ó lè rí gbogbo àwọn iṣẹ́ mi, bíkòṣe pé òun rí gbogbo ògo mi; kò sì sí ènìyàn tí ó lè rí gbogbo ògo mi, àti lẹ́hìnnáà kí òun wà nínú ẹran ara ní orí ilẹ̀ ayé.

6 Mo sì ní iṣẹ́ kan fún ọ, Mósè, ọmọ mi; ìwọ sì jẹ́ àwòrán Ọmo Bíbí mi Kanṣoṣo; àti pé Ọmọ Bíbí mi Kan Ṣoṣo ni, òun ni yíò sì jẹ́ Olùgbàlà náà, nítorítí òun kún fún ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́; ṣùgbọ́n kò sí Ọlọ́run míràn bíkòṣe èmi, ohun gbogbo sì wà pẹ̀lú mi, nítorí èmi mọ gbogbo wọn.

7 Àti nísisìyí, kíyèsíi, ohun kan yìí ni èmi fi hàn ọ́, Mósè, ọmọ mi, nítorí ìwọ wà nínú ayé, àti nísisìyí èmi fi hàn fún ọ.

8 Ó sì ṣe tí Mósè wò, òun sì rí ayé ní orí èyítí a ti dá a; Mósè sì rí ayé àti àwọn òpin rẹ̀, àti gbogbo awọn ọmọ ènìyàn tí wọ́n wà, àti tí a ṣe ẹ̀dá wọn; nipa ti ohun kannáà ni ẹnu yà á, òun sì ní ìyàlẹ́nu gidigidi.

9 Wíwà Ọlọ́run sì fà sẹ́hìn kúrò ní ara Mósè, tí ògo rẹ̀ kò sí ní ara Mósè; a sì fi Mósè sílẹ̀ fún ara rẹ̀. Àti bí a ṣe fi òun sílẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀.

10 Ó sì ṣe pé ó jẹ́ fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí kí Mósè tó tún gba okun àdánidá rẹ̀ padà bí ènìyàn; òun sì wí fún ara rẹ̀: Nísisìyí, fún ìdí èyí ni mo mọ̀ pé ènìyàn kò jẹ́ nkan, èyítí èmi kò fi ìgbà kan rò rí.

11 Ṣùgbọ́n nísisìyí ojú mi ti wo Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kìí ṣe ojú mi ti ara, ṣugbọ́n ojú mi ti ẹ̀mí, nítorí ojú mi ti ara kì yíò lè wò; nítorí èmi ìbá ti rọ kí n sì kú níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ògo rẹ̀ wà ní ara mi; èmi sì rí ojú rẹ̀, nítorí a pa mí lára dà níwájú rẹ̀.

12 Ó sì ṣe tí nígbàtí Mósè ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsíi, Sátánì wá ní dídán an wò, wípé: Mósè, ọmọ ènìyàn, fi orí balẹ̀ fún mi.

13 Ó sì ṣe tí Mósè wo Sátánì ó sì wípé: Tani ìwọ í ṣe? Nítorí kíyèsíi, ọmọ Ọlọ́run ni èmi, ní àworán Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo; àti pé níbo ni ògo tìrẹ wà, tí èmi yíò ṣe fi orí balẹ̀ fún ọ?

14 Nítorí kíyèsíi, èmi kò lè wo Ọlọ́run, bíkòṣe pé ògo rẹ̀ wá sí ara mi, a sì pamí láradà níwájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi lè wò ọ́ nínú ara ènìyàn. Èyí kò ha rí bẹ́ẹ̀, dájú-dájú?

15 Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run mi, nítorí tí Ẹ̀mí rẹ̀ kò fà sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ mi pátápátá, bí bẹ́ẹ̀kọ́ níbo ni ògo tìrẹ wà, nítorí ó jẹ́ òkùnkùn sí mi? Èmi sì le mọ ìyàtọ̀ lààrin ìwọ àti Ọlọ́run; nítorí Ọlọ́run wí fún mi: Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run, nítorí òun nìkan ní ìwọ yíò sìn.

16 Kúrò níhĩn, Sátánì; máṣe tàn mí; nítorítí Ọlọ́run wí fún mi: Ìwọ jẹ́ àworán Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.

17 Àti bákannáà òun fúnmi ní àwọn òfin nígbàtí ó pè mí jade láti inú ìgbẹ́ tí ó njóná, wípé: Ké pe Ọlọ́run ní orúkọ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, kí o sì sìn mí.

18 Àti lẹ́ẹ̀kansíi Mósè wí pé: Èmi kì yíò dáwọ́ dúró láti ké pe Ọlọ́run, mo ní àwọn ohun mĩràn láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀: nítorí ògo rẹ̀ ti wà ní ara mi, nítorínáà èmi lè mọ ìyàtọ̀ láàrin òun àti ìwọ. Lọ kúrò níhĩn, Sátánì.

19 Àti nísisìyí, nígbátí Mósè ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sátánì kígbe pẹ̀lú ohùn rara, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ipá ní orí ilẹ̀ ayé, wípé: èmi ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo, fi orí balẹ̀ fún mi.

20 Ó sì ṣe tí Mósè bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù gidigidi; bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù, ó rí ìkorò ti ọ̀run àpáàdì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní kíké pe Ọlọ́run, ó gba okun, ó sì pàṣẹ, wípé: Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì, nítorí Ọlọ́run kanṣoṣo yìí ni èmi yíò sìn, èyítí íṣe Ọlọ́run ògo.

21 Àti nísisìyí Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì, ilẹ̀ ayé sì mì tìtì; Mósè sì gba agbára, ó sì ké pe Ọlọ́run, wípé: Ní orúkọ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo, lọ kúrò níhĩn, Sátánì.

22 O sì ṣe tí Sátánì kígbe pẹ̀lú ohùn rara, pẹ̀lú ẹkún, àti ìpòhùnréré ẹkún, àti ìpahínkeke; ó sì lọ kúrò ní ibẹ̀, àní kúrò lọ́dọ̀ Mósè, tí òun kò ríi mọ́.

23 Àti nísisìyí nipa ohun yìí ni Mósè jẹ́rìí; ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú a kò ní ohun náà ní àrin àwọn ọmọ ènìyàn.

24 Ó sì ṣe pé nígbàtí Sátánì ti lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ Mósè, tí Mósè gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ní kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó jẹ́ ẹ̀rí ti Bàbá àti ti Ọmọ;

25 Àti ní kíké pe orúkọ Ọlọ́run, òun rí ògo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, nítorí ó wà ní orí rẹ̀; òun sì gbọ́ ohùn kan, wípé: Alábùkúnfún ni ìwọ, Mósè, nítorí èmi, Alágbára Jùlọ, ti yàn ọ́, a ó sì mú ọ di alágbára ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn omi lọ; nítorí wọn yíò gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ bí ẹnipé ìwọ jẹ́ Ọlọ́run.

26 Sì wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ, àní títí dé òpin àwọn ọjọ́ rẹ; nítorí ìwọ yíò gba àwọn ènìyàn mi kúrò ní oko-ẹrú, àní Ísraẹ́lì àyànfẹ́ mi.

27 Ó sì ṣe bí ohùn náà ṣe nsọ̀rọ̀, Mósè gbé ojú rẹ̀ ó sì rí ayé, bẹ́ẹ̀ni, àní gbogbo rẹ̀; kò sì sí kékeré jùlọ nínú rẹ̀ èyítí òun kò rí, ní dídá a mọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run.

28 Ó sì rí àwọn olùgbé inú rẹ̀ bákannáà, kò sì sí ọkàn kan èyítí òun kò rí; òun sì dá wọn mọ̀ nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run; iye wọn sì pọ jọjọ, àní àìníye bíì ìyanrìn ní etí òkun.

29 Òun sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀; ọ̀kọ̀ọ̀kan ilẹ̀ ni a sì pè ní ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùgbé ni wọ́n sì wà ní orí rẹ̀.

30 Ó sì ṣe tí Mósè ké pe Ọlọ́run, wípé: Wí fún mi, èmi bẹ̀ ọ́, báwo ni àwọn nkan wọ̀nyí ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀, àti nípa ọ̀nà wo ni ìwọ́ dá wọn?

31 Sì kíyèsíi, ògo Olúwa wà lára Mósè, tó bẹ́ẹ̀ tí Mósè dúró níwájú Ọlọ́run, tí ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ojúkojú. Olúwa Ọlọ́run sì wí fún Mósè: Fún èrò tèmi ni èmi dá àwọn ohun wọ̀nyí. Ọgbọ́n ni èyí ó sì dúró sínú mi.

32 Àti nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ agbára mi, ni èmi dá wọn, èyítí í ṣe Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, ẹnití ó kún fún ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

33 Àwọn ilẹ ayé láìníye ni èmi sì ti dá; èmi sì dá wọn bákannáà fún èrò inú tèmi; àti nípasẹ̀ Ọmọ náà ni mo dá wọn, èyítí í ṣe Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo.

34 Àti ẹni àkọ́kọ́ láàrin gbogbo ènìyàn ni èmi pè ní Ádámù, èyítí í ṣe púpọ̀.

35 Ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ ti ilẹ̀ ayé yìí nìkan, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, ni èmi fi fún ọ. Nítorí kíyèsíi, púpọ̀ àwọn ayé ni wọ́n ti kọjá lọ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ agbára mi. Púpọ̀ ni ó sì wà tí wọ́n dúró nísisìyí, àti àìníye ni wọ́n jẹ́ sí ènìyàn; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni kíkà fún mi, nítorí wọ́n jẹ́ tèmi èmi sì mọ̀ wọ́n.

36 Ò sì ṣe tí Mósè bá Olúwa sọ̀rọ̀, wípé: Ṣe àánú fún ìránṣẹ́ rẹ, Ọlọ́run, kí O sì sọ fún mi nípa ilẹ̀ ayé yìí, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti àwọn ọ̀run náà pẹ̀lú, nígbànáà ni ìránṣẹ́ rẹ yíò sì ní ìtẹlọ́rùn.

37 Olúwa Ọlọ́run sì bá Mósè sọ̀rọ̀, wípé: Àwọn ọ̀run, wọ́n jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọn kò sì le ṣeé kà fún ènìyàn; ṣùgbọ́n wọ́n ṣeé kà fún mi, nítorí wọ́n jẹ́ tèmi.

38 Àti bí ilẹ̀ ayé kan yíò ṣe kọjá lọ, àti àwọn ọ̀run inú rẹ̀ àní bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yíò dé; kò sì sí òpin sí àwọn iṣẹ́ mi, tàbí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

39 Nítorí kíyèsíi, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti ṣe ìmúṣẹ àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn.

40 Àti nísisìyí, Mósè, ọmọ mi, èmi yíò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé yìí ní orí èyítí ìwọ dúró lé; ìwọ yíò sì kọ àwọn ohun èyítí èmi yíò sọ.

41 Àti ní ọjọ́ kan nígbàtí àwọn ọmọ èniyàn yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ mi sí asán àti tí wọn yío mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn kúrò láti inú ìwé náà èyítí ìwọ yíò kọ, kíyèsíi, èmi yíò gbé ẹlòmíràn bíi tìrẹ dìde; a ó sì tún ní wọn lẹ́ẹ̀kansíi ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn—ní ààrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí iye àwọn tí yíò gbàgbọ́.

42 (Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a sọ fún Mósè ní orí òkè, orúkọ èyítí a kì yíò mọ̀ ní ààrin àwọn ọmọ ènìyàn. Àti nísisìyí a sọ wọ́n fún ọ. Máṣe fi wọ́n hàn sí ẹnikẹ́ni bíkòṣe àwọn tí wọ́n gbàgbọ́. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.)