Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 2


Orí 2

(Oṣù Kẹfà–Oṣù Kẹwã 1830)

Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé—Gbogbo àwọn onírúurú ẹ̀yà ni a dá—Ọlọ́run dá ènìyàn Ó sì fún un ní ìjọba ní orí ohun gbogbo tí ó kù.

1 Ó sì ṣe tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀, wipe: Kíyèsíi, èmi fi hàn fún ọ nípa ti ọ̀run yìí, àti ilẹ̀ ayé yìí; kọ àwọn ọ̀rọ̀ èyítí mo sọ. Èmi ni Ìbẹ̀rẹ̀ àti Òpin, Ọlọ́run Alágbára Jùlọ; nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo ni mo dá àwọn ohun wọ̀nyí; bẹ́ẹ̀ni, ní àtètèkọ́ṣe mo dá ọ̀run, àti ayé ní orí èyítí ìwọ dúró lé.

2 Ayé sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo; mo sì mú kí òkùnkùn kí ó wá sí ojú ibú; Ẹ̀mí mi sì nkáàkiri ojú omi; nítorí èmi ni Ọlọ́run.

3 Èmi, Ọlọ́run, sì wípé: Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà; ìmọ́lẹ̀ sì wà.

4 Èmi, Ọlọ́run, sì rí ìmọ́lẹ̀ náà; ìmọ́lẹ̀ náà sì dára. Èmi, Ọlọ́run, sì pín ìmọ́lẹ̀ náà kúrò lára òkùnkùn.

5 Èmi, Ọlọ́run, sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní Ọ̀sán, àti òkùnkùn náà, ni mo pè ní Òru; èyí ni èmi sì ṣe nípa ọ̀rọ̀ agbára mi, ó sì jẹ́ ṣíṣe bí mo ṣe sọ̀rọ̀; àti àsálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ ìkínní.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi, Ọlọ́run, wípé: Jẹ́ kí òfurufú kan kí ó wà ní ààrin omi náà, ó sì rí bẹ́ẹ̀, àní bí mo ṣe sọ; mo sì wípé: Jẹ́ kí ó pín àwọn omi kúrò lára àwọn omi; ó sì rí bẹ́ẹ̀;

7 Èmi, Ọlọ́run, sì dá òfurufú mo sì pín àwọn omi, bẹ́ẹ̀ni, àwọn omi nlá ní abẹ́ òfurufú kúrò ní ara àwọn omi èyítí ó wà ní òkè òfurufú náà, ó sì rí bẹ́ẹ̀ àní bí mo ṣe sọ.

8 Èmi, Ọlọ́run, sì pe òfurufú náà ní Ọ̀run; àti àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kejì.

9 Èmi, Ọlọ́run, wípé: Jẹ́ kí àwọn omi ábẹ́ ọ̀run kí ó kójọpọ̀ sí ojú kan, ó sì rí bẹ́ẹ̀; èmi, Ọlọ́run sì wípé: Jẹ́ kí ìyàngbẹ ilẹ̀ kí ó wà; o sì rí bẹ́ẹ̀.

10 Èmi, Ọlọ́run, sì pe ìyàngbẹ ilẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé; àti àkójọpọ̀ àwọn omi, ni mo pè ní Òkun; èmi, Ọlọ́run, sì ríi pé ohun gbogbo èyítí mo ti dá ni wọ́n dára.

11 Èmi, Ọlọ́run, sì wípé: Jẹ́ kí ilẹ̀ ayé kí ó mú koríko jade wá, ewéko tí yíò máa so èso, igi eléso tí yíò máa so èso, ní irú tirẹ̀, àti igi tí yío mú èso wá, tí yíó ní irúgbìn nínú fúnrarẹ̀ ní orí ilẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀ àní bí mo ti sọ.

12 Ilẹ̀ ayé sì mú koríko jade wá, olukúlùkù ewéko tí nmú èso wá bí irú tirẹ̀, àti igi tí nmú èso wá, tí yíó ní irúgbìn nínú fúnrarẹ̀, bí irú tirẹ̀; èmi, Ọlọ́run, sì ríi pé ohun gbogbo tí mo ti dá ni wọ́n dára;

13 Àti àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.

14 Èmi, Ọlọ́run, sì wípé: Jẹ́ kí àwọn ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní òfurufú ọ̀run, láti pín ọjọ́ kúrò nínú òru, sì jẹ́ kí wọn kí ó wà fún àwọn àmì, àti fún àwọn ìgbà, àti fún àwọn ọjọ́, àti fún àwọn ọdún;

15 Kí wọ́n ó sì wà fún àwọn ìmọ́lẹ̀ nínú òfurufú ọ̀run láti fi ìmọ́lẹ̀ fún orí ilẹ̀ ayé; ó sì rí bẹ́ẹ̀.

16 Èmi, Ọlọ́run, sì dá àwọn ìmọ́lẹ̀ nlá méjì; ìmọ́lẹ̀ títóbijù láti ṣe àkóso ọ̀sán, àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéréjù láti ṣe àkóso òru, ìmọ́lẹ̀ títóbijù sì jẹ́ òòrùn, àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéréjù jẹ́ òṣùpá; àti àwọn ìràwọ̀ bákannáà ni a dá, àní gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi.

17 Èmi, Ọlọ́run, sì fi wọ́n sínú òfurufú ti ọ̀run láti fí ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀ ayé,

18 Àti òòrùn láti ṣe àkóso ọ̀sán, àti òṣùpá láti ṣe àkóso òru, àti láti pín ìmọ́lẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn; èmi, Ọlọ́run, sì ríi pé gbogbo àwọn ohun èyítí èmi ti dá ni ó dára;

19 Àti àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

20 Èmi, Ọlọ́run, sì wípé: Kí àwọn omi ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá wá tí ó nrìn tí ó ní ìyè, àti ẹyẹ èyítí ó lè fò ní òkè ilẹ̀ ayé nínú òfurufú títẹ́jú ti ọ̀run.

21 Èmi, Ọlọ́run, sì dá àwọn ẹja nlá, àti ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀dá alàyè tí ó nrìn, èyítí àwọn omi mú jade lọ́pọ̀lọpọ̀, ní irú tiwọn, àti olukúlùkù ẹyẹ abìyẹ́ bí irú tirẹ̀; èmi, Ọlọ́run, sì ríi pé gbogbo àwọn ohun tí èmi dá ní ó dára.

22 Èmi, Ọlọ́run, sì súre fún wọn, wípé: Ẹ máa so èso, kí ẹ sì máa bí síi, kí ẹ sì kún inú gbogbo àwọn omi inú òkun; àti kí ẹyẹ kí ó bí síi ní orí ilẹ̀ ayé;

23 Àti àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kaàrún.

24 Èmi, Ọlọ́run, sì wipe: Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó mú ẹ̀dá alààyè jade wá bí irú tirẹ̀, ẹran ọ̀sìn, àti àwọn ohun tí nrákòrò, àti àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé bí irú tiwọn, ó sì rí bẹ́ẹ̀;

25 Èmi, Ọlọ́run, sì dá àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé bí irú tiwọn, àti àwọn ẹran ọ̀sìn bí irú tiwọn, àti ohun gbogbo tí nrákòrò ní orí ilẹ̀ ayé bí irú tiwọn; èmi, Ọlọ́run, sì rí pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí dára.

26 Èmi, Ọlọ́run, sì wí fún Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, èyítí ó wà pẹ̀lú mi láti àtètèkọ́ṣe: Jẹ́ kí á dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, bí ìrí wa; ó sì rí bẹ́ẹ̀. èmi, Ọlọ́run, sì wípé: Jẹ́ kí wọn kí ó jọba ní orí àwọn ẹja òkun, àti ní orí ẹyẹ inú afẹ́fẹ́, àti ní orí ẹran ọ̀sìn, àti ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti ní orí olukúlùkù ohun tí nrákòrò ní orí ilẹ̀ ayé.

27 Èmi, Ọlọ́run, sì dá ènìyàn ní àworán ara mi, ní àworán Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo ni mo dá a; akọ àti abo ni mo dá wọn.

28 Èmi, Ọlọ́run, sì súre fún wọn, mo sì wí fún wọn: Ẹ so èso, ẹ bí síi, kí ẹ sì gbilẹ̀ ní ayé, kí ẹ sì ṣe àkóso rẹ̀, kí ẹ sì jọba ní orí ẹja òkun, àti ní orí ẹyẹ inú afẹ́fẹ́, àti lorí olukúlùkù ohun abẹ̀mí tí ó nrìn ní orí ilẹ̀ ayé.

29 Èmi, Ọlọ́run, sì wí fún ènìyàn: Kíyèsíi, èmi ti fún yín ní olukúlùkù ewéko tí nso èso, èyítí ó wà ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti olukúlùkù igi nínú èyítí èso igi ti ó nso èso yío wà; tí yíò jẹ́ oúnjẹ fún yín.

30 Àti sí olukúlùkù ẹranko ilẹ̀ ayé, àti sí olukúlùkù ẹyẹ ojú ọ̀run, àti sí ohun gbogbo tí nrákòrò ní orí ilẹ̀ ayé, nínú èyí tí mo fún ní ìyè, níbẹ̀ ni a ó fi olukúlùkù ewéko tí ó mọ́ fúnni fún oúnjẹ; ó sì rí bẹ́ẹ̀, àní bí mo ṣe sọ.

31 Èmi, Ọlọ́run, sì rí ohun gbogbo tí mo dá, sì kíyèsíi, gbogbo àwọn ohun èyítí èmi dá ni wọ́n dára púpọ̀; àti àṣálẹ̀ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹfà.