Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 6


Orí 6

(Oṣù Kọkànlá–Oṣù Kejìlá 1830)

Irú ọmọ Ádamù ṣe ìpamọ́ ìwé ìrántí kan—Àwọn olódodo irú ọmọ rẹ̀ wàásù ironúpìwàdà—Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Énọ́kù—Énọ́kù wàásù ìhìnrere—A fi ètò ìgbàlà hàn sí Ádámù—Òun gba ìrìbọmi àti oyè àlùfáà.

1 Ádámù sì fetísílẹ̀ sí ohùn Ọlọ́run, ó sì pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti ronúpìwàdà.

2 Ádámù sì mọ ìyàwó rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́tì. Ádámù sì fi ògo fún orúkọ Ọlọ́run; nítorí ó wipe: Ọlọ́run ti yàn irú ọmọ míràn fún mi, dípò Ábẹ́lì, ẹnití Káínì pa.

3 Ọlọ́run sì fi ara rẹ̀ hàn sí Sẹ́tì, òun kò sì ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n ó rú ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà kan, tí ó dàbí ti arákùnrin rẹ̀ Ábẹ́lì. Àti sí òun pẹ̀lú ni a bí ọmọkùnrin kan, tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Énọ́sì.

4 Àti nígbànáà ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀sí ké pe orúkọ Olúwa, Olúwa sì bùkún wọn;

5 A sì pa ìwé ìrántí kan mọ́, nínú èyí tí à kọ àkọsílẹ̀, ní èdè Ádámù, nítorí a ti fi í fún iye àwọn tí ó ké pe Ọlọ́run láti kọ̀wé nípa ẹ̀mí ìmísí;

6 Àti nípasẹ̀ wọn a kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kà àti láti kọ, nípa níní èdè kan tí kò ní èérí àti tí kò tíì di àìmọ́.

7 Nísisìyí Oyè àlùfáà yìí kannáà, èyítí ó ti wà ní àtètèkọ́ṣe, yíò wà ní òpin ayé bákannáà.

8 Nísisìyí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Ádámù sọ, bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe dárí rẹ̀, a sì ṣe ìpamọ́ ìtàn ìdílé ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Èyí sì ni ìwé ìtàn àwọn ìrandíran ti Ádámù, wípé: Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní ìrí ti Ọlọ́run ni ó dá a;

9 Ní àworán ti ara rẹ̀, akọ àti abo, ni ó dá wọn, ó sì ṣúre fún wọn, ó sì pé orúkọ wọn ní Ádámù, ní ọjọ́ náà nígbàtí a dá wọn tí wọ́n di alàyè ọkàn ní ilẹ̀ ibi àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run.

10 Ádámù sì gbé fún ọgọ́rũn kan ati ọgbọ̀n ọdún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ní ìrí ara tirẹ̀, gẹ́gẹ́bí àworán tirẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́tì.

11 Àwọn ọjọ́ Ádámù, lẹ́hìn tí ó bí Sẹ́tì, jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́jọ (ẹgbẹ̀rin) ọdún, ó sì bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin;

12 Àti pé gbogbo àwọn ọjọ́ tí Ádámù gbé jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn àti ọgbọ̀n ọdún, ó sì kú.

13 Sẹ́tì sì lo ọdún márũnlélọ́gọ́run ún, ó sì bí Énọ́sì, ó sì sọtẹ́lẹ̀ ni gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ̀, òun sì kọ́ ọmọ rẹ̀ Énọ́sì ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run; Nítorináà Énọ́sì pẹ̀lú sọtẹ́lẹ̀.

14 Sẹ́tì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́jọ ọdún ó lé méje, lẹ́hìn tí ó bí Énọ́sì, ó sì bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

15 Àwọn ọmọ ènìyàn sì pọ̀ púpọ̀ ní iye ní gbogbo orí ilẹ̀ náà. Àti ní àwọn ọjọ́ wọnnì Sátánì ní agbára tí ó ga ní ààrin àwọn ènìyàn, ó sì ru sókè nínú ọkàn wọn; àti láti ìgbà náà lọ ni àwọn ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ti wá; ọwọ́ ènìyàn kan sì dojúkọ arákùnrin tirẹ̀, ní fífúnni ní ikú, nítorí àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀, ní wíwá agbára kiri.

16 Gbogbo àwọn ọjọ́ Sẹ́tì sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn ó lé méjìlá ọdún, ó sì kú.

17 Énọ́sì sì gbé ãdọ́rùn ọdún, ó sì bí Káínánì. Énọ́sì àti ìyókù àwọn ènìyàn Ọlọ́run sì jade kúrò ní ilẹ̀ náà, èyítí a pè ní Ṣúlónì, wọ́n sì gbé ní ilẹ̀ ìlérí kan, èyítí òun pè orúkọ rẹ̀ tẹ̀lé ọmọkùnrin rẹ, ẹnití òun ti pè orúkọ rẹ̀ ní Káínánì.

18 Énọ́sì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́jọ ó lé mẹ́ẹ̀dógun ọdún, lẹ́hìn tí ó bí Káínánì, ó sì bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Gbogbo àwọn ọjọ́ Énọ́sì sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn ó lé márũn ọdún, ó sì kú.

19 Káínánì sì gbé ãdọ́rin ọdún, ó sì bí Máháláléelì; Káínánì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ogójì ọdún lẹ́hìn tí ó bí Máháláléelì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Gbogbo àwọn ọjọ́ Káínánì sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn àti ọdún mẹ́wã, ó sì kú.

20 Máhalálélì sì gbé ọdún márùndínlãdọ́rin, ó sì bí Járẹ́dì; Máhálálélì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ọgbọ̀n ọdún lẹ́hìn tí ó bí Járẹ́dì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Gbogbo ọjọ́ Máhalálelì sì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn ó dín márũn ọdun, ó sì kú.

21 Járedì sì gbé ọgọ́rũn ọdún àti méjìlélọ́gọ́ta, ó sì bí Énọ́kù; Járẹ́dì sì gbé ọgọ́rũn mẹ́jọ ọdún lẹ́hìn tí ó bí Énọkù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Járẹ́dì sì kọ́ Énọ́kù ní gbogbo àwọn ọ̀nà Ọlọ́run.

22 Èyí sì ni ìtàn ìdílé ti àwọn ọmọkùnrin Ádámù, ẹnití ó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, pẹ̀lú ẹnití Ọlọ́run fúnrarẹ̀, sọ̀rọ̀.

23 Wọ́n sì jẹ́ oníwàásù ti òdodo, wọ́n sì sọ̀rọ̀ àti sọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ké pe gbogbo ènìyàn, níbigbogbo, láti ronúpìwàdà; wọ́n sì kọ́ni ní ìgbàgbọ́ sí àwọn ọmọ enìyàn.

24 Ó sì ṣe tí gbogbo àwọn ọjọ́ Járẹ́dì jẹ́ ọgọ́rũn mẹ́sãn àti ọdún méjìlélọ́gọ́ta, ó sì kú.

25 Énọ́kù sì gbé ọdún márũndínlãdọ́rin, ó sì bí Mẹ̀túsẹlà.

26 Ó sì ṣe tí Énọ́kù rìn ìrìnàjò ní ààrin ilẹ̀ náà, ní ààrin àwọn ènìyàn náà; bí òun sì ṣe nrìn ìrìnàjò, Ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ jadewá láti ọ̀run, ó sì bà lé e ní orí.

27 Ó sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, wipe: Énọ́kù, ọmọ mi, sọ̀tẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yìí, kí o sì wí fún wọn—Ẹ ronúpìwàdà, nítorí báyìí ni Olúwa wí: Èmi nbínú sí àwọn ènìyàn yìí, ìbínú gbígbóná mi sì ti ru sókè sí wọ́n; nítorí tí ọkàn wọn ti di líle, àti etí wọn ti di sí ọ̀rọ̀ gbígbọ́, ojú wọn kò sì lè rí ọ̀nà jíjìn;

28 Àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìran wọ̀nyí, láti ọjọ́ tí mo ti dá wọn, ni wọ́n ti ṣìnà, tí wọ́n sì ti sẹ́ mi, wọ́n sì ti wá ìmọ̀ràn ara wọn nínú òkùnkùn; àti nínú àwọn ohun ìríra wọn ni wọ́n ti pète ìpànìyàn, wọn kò sì pa àwọn òfin mọ́, èyítí mo fi fún bàbá wọn, Ádámù.

29 Nítorínáà, wọ́n ti fi ara wọn bú ṣaájú, àti nípa àwọn ìbúra wọn, wọ́n ti mú ikú wá sí orí ara wọn; àti pé ọ̀run àpãdì kan ni èmi ti pèsè fún wọn, bí wọn kò bá ronúpìwàdà;

30 Àṣẹ kan sì nìyí, èyítí èmi ti fi ránṣẹ́ jade ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé, láti ẹnu tèmi, láti ìpìlẹ̀ rẹ̀, àti láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn bàbá yín, ni èmi ti pa àṣẹ rẹ̀, àní bí a ó ṣe rán an jade sínú ayé, sí àwọn òpin rẹ̀.

31 Àti nígbàtí Énọ́kù ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó tẹ orí ara rẹ̀ ba sí ilẹ̀ ayé, níwájú Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, wípé: Kínni ìdí tí èmi ṣe rí ojú rere ní ojú rẹ, bí èmi sì ṣe jẹ́ ọ̀dọ́, àti pé gbogbo ènìyàn kórĩra mi; nítorí èmi lọ́ra ní ọ̀rọ̀ sísọ; nítorí kíni èmi ha ṣe jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ?

32 Olúwa sì wí fún Énọ́kù: Jáde lọ kí o sì ṣe bí èmi ti pàṣẹ fún ọ, kì yíò sì sí ènìyàn kan tí yíò gún ọ. La ẹnu rẹ, á ó sì kún un, èmi yíò sì fún ọ ní ọ̀rọ̀ sísọ, nítorí gbogbo ẹran ara wà ní ọwọ́ mi, èmi yíò sì ṣe bí ó bá ṣe dára ní ojú mi.

33 Wí fún àwọn ènìyàn yìí: Ẹ yàn ní òní yìí, láti sin Olúwa Ọlọ́run ẹnití ó dá yín.

34 Kíyèsíi Ẹ̀mí mi wà ní orí rẹ, nítorínáà gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi yíò dáláre; àwọn òkè yíò sì sá níwájú rẹ, àti àwọn odò yíò yà kúrò ni ipa ọ̀nà wọn; ìwọ yíò sì gbé nínú mi, àti èmi nínú rẹ; nítorínáà rìn pẹ̀lú mi.

35 Olúwa sì bá Énọ́kù sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un: Fi amọ̀ pa ojú rẹ, kí o sì wẹ̀ẹ́, ìwọ yíò sì rí ìran. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

36 Òun sì rí àwọn ẹ̀mí tí Ọlọ́run ti dá; bákannáà òun sì rí àwọn ohun èyítí kò hàn sí ojú ti àdánidá; àti láti ìgbà náà lọ ni ọ̀rọ̀ sísọ ti bẹ̀rẹ̀ káàkiri òde ní ilẹ̀ náà: Aríran kan ni Olúwa ti gbé dìde fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

37 O sì ṣe tí Énọ́kù jade lọ nínú ilẹ̀ náà, lààrin àwọn ènìyàn, ní dídúró ní orí àwọn òkè kékèké àti àwọn ibi gígá, ó sì kígbe ní ohùn rara, ní jíjẹ́rìí tako àwọn iṣẹ wọn; gbogbo ènìyàn sì bínú nítorí rẹ̀.

38 Wọ́n sì jade wá láti gbọ́ ọ, ní orí àwọn ibi gíga, ní wíwí fún àwọn olùtọ́jú àgọ́: Ẹ dúró ní ìhĩnyìí kí ẹ sì ṣe ìtọ́jú àwọn àgọ́, nígbàtí àwa yío lọ sí ọ̀hún láti wo aríran náà, nítorí òun sọ̀tẹ́lẹ̀, ohun àjèjì kan sì wà ní ilẹ̀ náà; ẹhànnà ọkùnrin kan ti wá sí ààrin wà.

39 Ó sì ṣe nígbàtí wọ́n gbọ́ ọ, kò sí ẹnikan tí ó fi ọwọ́ kàn án; nítorí ẹ̀rù wá sí orí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ; nítorí òun rìn pẹ̀lú Ọlọ́run.

40 Ọkùnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ẹnití orúkọ rẹ̀ njẹ́ Mahijàh, ó sì wí fún un: Sọ fún wa kedere tani ìwọ í ṣe, àti láti ibo ni ìwọ ti wá?

41 Ó sì wí fún wọn: Èmi jade wá lati ilẹ̀ Káinánì, ilẹ̀ àwọn bàbá mi, ilẹ̀ òdodo títí di òní yìí. Bàbá mi sì kọ́mi ní gbogbo àwọn ọ̀nà Ọlọ́run.

42 O sì ṣe, bí mo ṣe nrin ìrìnàjò láti ilẹ̀ Káínánì, ní ẹ̀bá òkun ihà ilà oòrun, mo rí ìran kan; sì wõ, àwọn ọ̀run ni mo rí, Olúwa bá mi sọ̀rọ̀, ó sì fún mi ní òfin kan, nítorínáà, fún ìdí èyí, láti pa òfin náà mọ́, mo sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jade.

43 Énọ́kù sì tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, wípé: Olúwa èyítí ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mi, òun kannáà ni Ọlọ́run ọ̀run, òun sì ni Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín, ẹ̀yin sì jẹ́ arákùnrin mi, kíni ṣe tí ẹ ngba ara yín ní ìmọràn, tí ẹ sì sẹ́ Ọlọ́run ọ̀run?

44 Àwọn ọ̀run ni ó dá; ilẹ̀ ayé ni àpóti ìtisẹ̀ rẹ̀; àti ìpìlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. Kíyèsíi, òun fi í lélẹ̀, ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ni òun ti mú wá sí orí rẹ.

45 Ikú sì ti wá sí orí àwọn bàbá wa; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ àwa mọ̀ wọ́n, a kò sì le sẹ́, àní àti àkọ́kọ́ ti gbogbo ẹ̀dá ni a mọ̀, àní Ádámù.

46 Nítorí ìwé ìrántí kan ni a ti kọ ní ààrin wa, gẹ́gẹ́bí àwokọ́ṣe tí a fúnni nípa ìka Ọlọ́run; tí a ṣì fi fúnni ní èdè tiwa.

47 Bí Énọ́kù sì ṣe sọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jade, àwọn ènìyàn wárìrì, wọn kò sì lè dúró ní iwájú rẹ̀.

48 Ó sì wí fún wọn: Nítorítí Ádámù ṣubú, àwa wà; àti nípa ìṣúbú rẹ̀ ní ikú wá; a sì mú wa di alájọpín òṣì àti ègbé.

49 Kíyèsíi Sátánì ti dé sí àrin àwọn ọmọ ènìyàn, ó sì dán wọn wò láti foríbalẹ̀ fún òun; àwọn ènìyàn sì di ti ara, ti ayé, àti ti èṣù, a sì tì wọ́n jade kúrò ní iwájú Ọlọ́run.

50 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti sọ di mímọ̀ sí àwọn bàbá wa pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà.

51 Òun sì pe bàbá wa Ádámù nípa ohùn ti ara rẹ̀, wípé: èmi ni Ọlọ́run; mo dá ayé, àti àwọn ènìyàn síwájú kí wọ́n tó wà ní ẹran ara.

52 Bákannáà ó sì sọ fún un: Bí ìwọ bá yípadà sí mi, tí ó sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, tí ó sì gbàgbọ́, tí ó sì ronúpìwàdà gbogbo àwọn ìrékọjá rẹ, àti tí a rì ọ́ bọmi, àní nínú omi, ní orúkọ Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, ẹnití ó kún fún ore ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, èyítí í ṣe Jesù Krístì, orúkọ kan ṣoṣo èyítí a ó fi fúnni lábẹ́ ọ̀run, nípa èyítí ìgbàlà yíò dé fún àwọn ọmọ ènìyàn, ìwọ yíò gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ní bíberè ohun gbogbo ní orúkọ rẹ̀, ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè, a ó fi fún ọ.

53 Bàbá wa Adámù sì bá Olúwa sọ̀rọ̀, ó sì wípé: Nítorí kínni àwọn ènìyàn ṣe gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí a sì rì wọ́n bọmi nínú omi? Olúwa sì wí fún Ádámù: Kíyèsíi, èmi ti dárí ìrékọ́já rẹ jì ọ́ nínú Ọgbà Édẹ́nì.

54 Láti ibi èyí ni ọ̀rọ̀ sísọ wá káàkiri ní ààrin àwọn ènìyàn, pé Ọmọ Ọlọ́run ti ṣe ètùtù fún ẹ̀bi ìpilẹ̀sẹ̀ nínú èyítí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí kì yíò le di bíbẹ̀wò ní orí àwọn ọmọ, nítorí wọ́n jẹ́ pípé láti ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé.

55 Olúwa sì sọ fún Ádámù, wípé: Níwọ̀nbí a ti lóyún àwọn ọmọ rẹ nínú ẹ̀ṣẹ̀ àní bẹ́ẹ̀ nígbàtí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀sí dàgbà sókè, èrò ẹ̀ṣẹ̀ á wà ní inú ọkàn wọn, wọ́n á sì tọ́ ìkorò wò, pé kí wọ́n ó lè mọ láti mọ iyì dídára.

56 A sì fifún wọn láti mọ rere yàtọ̀ sí búburú; nítorínáà wọ́n jẹ́ aṣojú fún ara wọn, mo sì ti fún yín ní àṣẹ àti òfin míràn.

57 Nísisìyí fi í kọ́ àwọn ọmọ rẹ, pé gbogbo ènìyàn, níbi gbogbo, gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, tàbí wọn kì yíó jogún ìjọba Ọlọ́run rárá, nítorí ohun àìmọ́ kan kì yíò lè gbé níbẹ̀, tàbí gbé ní iwájú rẹ̀; nítorí, ní èdè Ádámù, Ẹni Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, orúkọ ti Ọmọ Bíbi rẹ̀ Kanṣoṣo sì ni Ọmọ Ènìyàn, àní Jésù Krístì, Onídajọ́ òdodo, ẹnití yíò wá ní ààrin méjì àkókò.

58 Nítorínáà mo fún ọ ní òfin kan, láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní àwọn ohun wọ̀nyí pẹ̀lú òmìnira, wípé:

59 Pé nípasẹ̀ ìrékọjá ni ìṣubú wá, ìṣubú èyítí ó mú ikú wá, àti níwọ̀nbí a ti bí yín sínu ayé nípasẹ̀ omi, àti ẹ̀jẹ̀, àti ẹ̀mí, èyítí èmi ti dá, bẹ́ẹ̀ sì ni èrùpẹ̀ di alààyè ọkàn, àní bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin gbọ́dọ̀ di àtúnbí sínú ìjọba ọ̀run, ní ti omi, àti ti Ẹ̀mí, kí ẹ sì di wíwẹ̀mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀, àní ẹ̀jẹ̀ ti Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo; pé kí ẹ lè di yíyà sí mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé ní ayé yìí, àti ìyè àìnípẹ̀kun ní ayé tí ó nbọ̀, àní ogo àìkú;

60 Nítorí nípa omi ni ẹ̀yin pa òfin mọ́; nípa Ẹ̀mí ni ẹ di dídáláre, àti nípa ẹ̀jẹ̀ ni a yà yín sí mímọ́;

61 Nítorínáà a fi fúnni kí ó lè wà nínú yín; àkọsílẹ̀ ti ọ̀run; Olùtùnú náà; àwọn ohun àlãfíà ti ogo àìkú; òtítọ́ ti ohun gbogbo; èyítí ó nsọ ohun gbogbo di alààyè, èyítí ó nmú ohun gbogbo wà ní àyè; èyíinì tí ó mọ ohun gbogbo, àti tí ó ní gbogbo agbára ní ìbámu sí ọgbọ́n, àánú, òtítọ́, òdodo, àti ìdájọ́.

62 Àti nísìsìyìí kíyèsíi, mo wí fún ọ: Èyí ni èto ìgbàlà sí gbogbo ènìyàn, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ti Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, ẹnití yíò wá ní ààrin méjì àkókò.

63 Sì kíyèsíi, ohun gbogbo ní àfijọ tiwọn, àti ohun gbogbo ni a dá tí a sì ṣe láti jẹ́ ẹ̀rí mi, méjéèjì ní ti èyí tí ó jẹ́ ti ara, àti àwọn ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí; àwọn ohun èyítí ó wà ní àwọn ọ̀run lókè, àti àwọn ohun èyítí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé, àti àwọn ohun tí wọ́n wà nínú ilẹ̀, àti àwọn ohun tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, méjéèjì ní ti òkè àti ní ìsàlẹ̀: ohun gbogbo njẹ́ ẹ̀rí mi.

64 Ó sì ṣe nígbàtí Olúwa ti bá Ádámù sọ̀rọ̀, bàbá wa, tí Ádámù kígbe pe Olúwa, a sì mu un lọ kúrò nípa Ẹ̀mí Olúwa, a sì gbé e lọ sínú ìsàlẹ̀ omi, a sì tẹ́ ẹ sí abẹ́ omi, a sì mú un jade wá láti inú omi náà.

65 Àti báyìí ni òun ṣe ìrìbọmi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e, báyìí ni òun sì di bíbí nípa ti Ẹ̀mí, ó sì di alààyè ní ẹni inú.

66 Òun sì gbọ́ ohùn kan tí ó jáde láti ọ̀run wá, wípé: A ti ri ìwọ bọmi pẹ̀lú iná, àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí ni àkọsílẹ̀ ti Bàbá, àti Ọmọ, láti ìsìsìyìí lọ àti títí láé;

67 Ìwọ sì tẹ̀lé ètò ti ẹni náà tí ó wà láì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin àwọn ọdún, láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé.

68 Kíyèsíi, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú mi, ọmọ Ọlọ́run; àti báyìí ni gbogbo ènìyàn yío lè jẹ́ ọmọ mi. Àmín.