Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Síṣe Ẹ̀dá Ìgbé Ayé kan Tí ó ní Àtakò sí Ọtá
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Síṣe Ẹ̀dá Ìgbé Ayé kan Tí ó ní Àtakò sí Ọtá

Mo gbàdúrà pé kí a le tẹ̀síwájú láti gbé ìgbésí ayé wa ga ní títẹ̀lé àwọn ètò àti àwọn àwórán ìdámọ̀ ẹ̀rọ ti ọnà àtọ̀runwá tí a kọ nípasẹ Baba Ọ̀run.

Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn láti pẹpẹ rírẹwà yìí ní Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀, a ti gba ìmọ̀ràn àgbàyanu, ìmísí, ìtọ́ni, àti ìfihàn. Ní àwọn ìgbà míràn, àwọn olùsọ̀rọ̀ ti lo àwọn àfiwé tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn irú ìmọ̀ àti ìrírí láti ṣàpèjúwe ní kedere àti pẹ̀lú agbára ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì kan.

Ní ọ̀nà yìí, fún àpẹẹrẹ, a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọkọ̀ òfuurufú àti àwọn ọkọ̀ bàlúù nínú èyí tí yíyapa àkọ́kọ́ kékeré kan lè mú wa lọ sí ibì kan tí ó jìnnà sí ibi tí a kọ́kọ́ nlọ.1 Bákannáà ní ọ̀nà yìí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àfiwé iṣẹ́ ti ọkàn-ara wa pẹ̀lú ìyípadà ọkàn alágbára tí a nílò láti dáhùn sí ìfipè Olúwa láti tẹ̀ lé E.2

Ní àkokò yí, èmi yíò fẹ́ láti fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe àfikùn àfiwé tí ìmísí rẹ̀ wá láti inú ààyè kan níbi ìgbáradì fún ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mi. Mo ntọ́ka sí ayé ti ìmọ̀-ẹ̀rọ ilé kíkọ́. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ mi ní yunifásítì, mo lá àlá ọjọ́ tí èmi yíò parí àwọn ohun tí a nílò láti lè kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí yíò kọ́ mi bí a ṣe nṣe ọnà àwọn ilé àti àwọn ohun kíkọ́ mìíràn tí a lè kà sí “ìlòdì-sí omi-ilẹ̀.”

Níkẹhìn ọjọ́ náà dé fún kíláàsì àkọ́kọ́ mi lórí àkòrí yí. Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n náà ni ìwọ̀nyí: “Ó dájú pé ẹ nṣe àníyàn láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí kí ẹ sì kọ́ bí a ṣe nṣe ọnà ìṣètò àwọn ohun kíkọ́ tí ó lòdì-sí omi-ilẹ̀,” sí èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ​​wa fi ìtara mi orí wa sí bẹ́ẹ̀ni. Lẹ́hìnnáà, ọ̀jọ̀gbọ́n náà wípé, “Ó dùn mí láti sọ fún yín pé èyí kò lè ṣeéṣe, nítorí èmi kò lè kọ́ yín bí ẹ ṣe lè ṣe ọnà ilé kan tí ó tako, tí ó ‘lòdì-’ tàbí tí ó jẹ́ ìdojúkọ sí ilẹ̀ ríri. Èyí kò mọ́gbọ́n wá,” ni ó wí, ”nítorí àwọn ìṣẹ́lẹ̀ yíò ṣẹlẹ̀ lọ́nàkọnà, bóyá a fẹ́ tàbí a kò fẹ́.”

Ó ṣe àfikún lẹ́hìnnáà, “Ohun tí mo le kọ́ yín ni bí ẹ ṣe lè ṣe ọnà àwọn ohun kíkọ́ tí yío le ta omi-ilẹ̀ dànù, àwọn ohun kíkọ́ tí ó le kojú àwọn ipa tí ó nbọ̀ láti ibi ilẹ̀ ríri kan, kí ohun kíkọ́ náà ó le wa ní ìdúró láìjìyà èyíkéyì ìbàjẹ́ nlá àti lẹ́hìnnáà tẹ̀síwájú láti fúnni ní iṣẹ́ náà èyí tí a ti lóyún rẹ̀.”

Onímọ̀-ẹ̀rọ náa ṣe àwọn ìṣirò tí ó tọ́ka sí àwọn ìwọ̀n, àwọn dídára, àti àwọn àbùdá ti àwọn ìpìlẹ̀, àwọn kọ́lúmù, àwọn òpó, àwọn síláàbù kankéré, àti àwọn èròjà ohun kíkọ́ míràn tí a nṣe ọnà fún. Àwọn àbájáde wọ̀nyí ni a túmọ̀ sí àwọn èrò àti àwọn àlàyé ìmọ̀-ẹ̀rọ, èyítí kọ́lékọ́lé gbọdọ̀ tẹ̀lé fínífíní kí iṣẹ́ náà lè di síṣe àti nípa bẹ́ẹ̀kí ó mú ìdí tí a fi ṣe ọnà rẹ̀ àti tí a fi kọ́ ọ ṣẹ.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ó lé ní ogójì ọdún tí ó ti kọjá láti kíláàsì àkọ́kọ́ náà lórí ẹ̀kọ́ imọ̀-ẹ̀rọ ìlòdì sí omi-ilẹ̀, mo rántí àkokò náà ní pípé nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní òye jíjìnlẹ̀, àti pípé síi nípa kókó síṣe pàtàkì pé èrò yí yíò wà nínú àwọn ohun kíkọ́ ti èmi yíò ṣe ọnà wọn ní ọjọ́ iwájú nínú ayé ìmòye mi. Èyi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n ní pàtàkì jù lọ—pé yíò wà pẹ́ títí nínú ìmúdàgbà ìgbésí ayé mi àti nínú àwọn tí mo lè ní ipa rere lé lórí.

A ti jẹ́ alábùkún fún tó láti gbára lé ìmọ̀ ètò ìgbàlà tí a dá láti ọwọ́ Baba wa Ọ̀run, láti ní ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò, àti láti gbára lé ìdarí ìmísí ti àwọn wòlíì alààyè! Gbogbo àwọn ti ìṣaájú jẹ́ “àwọn ètò” ọnà àtọ̀runwá àti “àwọn àlàyé ìmọ̀-ẹ̀rọ” tí ó kọ́ wa ní kedere bí a ṣe lè ṣe ẹ̀dá àwọn ìgbési ayé aláyọ̀—àwọn ìgbésí ayé tí ó tako ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tako ìdánwò, tí ó tako àwọn ìkọlù láti ọ̀dọ̀ Sàtánì, ẹni tí ó nfi taratara wá láti da àyànmọ́ ayérayé wa rú pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run àti lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí wa ọ̀wọ́n.

Olùgbàlà fúnra Rẹ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, “a fi sílẹ̀ láti dán an wò lọ́wọ́ èṣù.”3 Ṣùgbọ́n Jésù jáde pẹ̀lú àṣeyọrí nínú àdánwò nlá náà. Báwo ni níní ìwà ìlòdì sí Sátánì tàbí ìlòdì sí ìdánwò ti ṣiṣẹ́ fún Un? Ohun tí ó mú kí Jésù farahàn bí olúborí láti inú àwọn àkokò tí ó nira jùlọ wọnnì ní ìgbáradì Rẹ̀ nípa ti ẹ̀mí, èyítí ó jẹ́ kí Ó wà ní ipò láti kojú àwọn ìdánwò ti ọ̀tá náà.

Kí ni díẹ̀ lára ​​àwọn ohun tí ó ran Olùgbàlà lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àkokò pàtàkì náà?

Lákọ̀ọ́kọ́, Ó ti gbààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ààwẹ̀ tí ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ pẹ̀lú àdúrà ìgbà gbogbo. Nítorínáà, bíótilẹ̀jẹ́pé kò lágbára nípa ti ara, ẹ̀mí Rẹ̀ lágbára gidigidi. Bíótilẹ̀jẹ́pé, lọ́nà rere, a kò ní kí a gbààwẹ̀ fún irú àkokò bẹ́ẹ̀—ṣùgbọ́n fún wákàtí mẹ́rìnlélógún àti ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù—àwẹ̀ nfún wa lókun nípa ti ẹ̀mí ó sì nmúra wa sílẹ̀ láti tako àwọn ìdánwò ìgbésí-ayé.

Ní ààyè kejì, nínú àkọọ́lẹ̀ ti àwọn ìdánwò tí a fi dán Olùgbàlà wò, a ri pé Ó dá Sátánì lóhùn nígbàgbogbo nípa níní àwọn ìwé-mímọ́ nínú ọkàn Rẹ̀, sísọ nípa wọn, àti ṣíṣe wọ́n ní àkokò tí ó tọ́.

Nígbà tí Sátánì dán An wò láti sọ àwọn òkúta náà di àkàrà kí Ó lè tẹ́ ebi Rẹ̀ lọ́rùn nínú ààwẹ̀ gígùn Rẹ̀, Olúwa sọ fún un pé, “A ti kọ ọ́ pé, Ènìyàn kì yíò wà nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọrun wá.”4 Nígbànáà, nígbà tí Olúwa wà lórí òkè tẹ́mpìlì, èṣù gbìyànjú láti dán An wò láti fi agbára Rẹ̀ hàn, sí èyí tí Olúwa dáhùn pẹ̀lú àṣẹ pé: “A tún kọ̀wé rẹ̀ pé, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.”5 Àti sí ìgbìyànju kẹ́ta Sátánì, Olúwa dáhùn pe, “A ti kọ ọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí o sìn, òun nìkanṣoṣo ni kí ìwọ kí o máa sìn.”6

Ìṣẹ̀lẹ̀ ti ìsẹ́lẹ̀ kan fi àmì rẹ̀ sílẹ̀ àní lórí àwọn ohun kíkọ́ tí a ṣe ọnà tí a sì kọ́ ní pípé—àwọn àbájáde bíi bóyá àwọn lílanu díẹ̀, àga tàbí òrùlé síṣubú, àti àwọn fèrèsé fífọ́. Ṣùgbọ́n ohun kíkọ́ tí a ṣe ọnà rẹ̀ dáradára àti tí a kọ́ dáradára yíò mú èrèdí ìdábòbò àwọn olùgbé inú rẹ̀ ṣẹ, àti pẹ̀lú àwọn àtúnṣe díẹ̀, yíò ṣeé túnṣe sí ipò àtilẹ̀wá rẹ̀.

Nínú àṣà tí ó jọra, àwọn ìhàlẹ̀ ọ̀tá bákannáà lè fa “àwọn lílanu” tàbí abala ìbàjẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ìgbésí ayé wa, láìka àwọn ìgbìyànjú wa sí láti ṣe àwọn ìgbésí ayé wà ní ìbámu sí ọnà àtọ̀runwá pípé náà. Àwọn “lílà” wọ̀nyí lè fi ara wọn hàn nípasẹ̀ àwọn ìmọ̀lára ìbànújẹ́ tàbí aròkan fún ṣíṣe àwọn àṣìṣe kan àti fún àìṣe ohun gbogbo ní pípé, tàbí fún ìmọ̀lára pé a kò dára bí a ṣe fẹ́.

Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́ ni pé fún títẹ̀lé àwọn ètò àti àwọn àpéjúwe ọnà àtọ̀runwá kan, èyí ni, ìhìnrere Jésù Kristi, a ṣì wà ní dídúró síbẹ̀. Ìlànà àwọn ìgbésí ayé wa kò tíì di wíwó nítorí àwọn ìgbìyànjú ọ̀tá tàbí fún àwọn ipò ìṣòro tí a ní láti kojú; dípò bẹ́ẹ̀, a ṣetán láti tẹ̀síwájú.

Ayọ̀ tí a ṣèlérí nínú àwọn ìwé-mímọ́ gẹ́gẹ́bí èrèdí ìgbé ayé wa7 kò yẹ kí á ní òye rẹ̀ pé ó túmọ̀ sí pé a kò ní ní àwọn ìṣòro tàbí àwọn ìbànújẹ́, pé a kì yíò ní “àwọn lílà” bíi àwọn àbájáde àwọn àdánwò, ti àwọn ìpọ́njú, tàbí láti inú àwọn ìdánwò ti ìgbésí ayé wa lgan órí ilẹ̀.

Ayọ̀ yìí ní í ṣe pẹ̀lú ìwòye ti Néfì lórí ìgbésí ayé nígbà tí ó sọ pé, “Níwọ̀n bí mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní inú àwọn ọjọ́ ayé mi, bíó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí mo ti rí ojú rere Olúwa ní gbogbo ọjọ́ mi.”8 Ní gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ! Àní ní àwọn ọjọ́ tí Néfì jìyà lákòókò àìlòye àti ìkọ̀sílẹ̀ àwọn arákùnrin tirẹ̀, àní nígbàtí wọ́n kọlù ú nínú ọkọ̀ ojú omi, àní ní ọjọ́ tí baba rẹ̀, Léhì, kọjá lọ, àní nígbà tí Lámánì àti Lémúẹ́lì di ọ̀tá kíkú ti àwọn ènìyàn rẹ̀. Àní ní àwọn ọjọ́ tí ó nira wọ̀nyí, Néfì ní ìmọ̀lára ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.

A lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn ti mímọ̀ pé Olúwa kò ní jẹ́ kí a dán wa wò rékọjá ohun tí a lè dojúkọ. Álmà rọ̀ wá láti “máa ṣọ́nà kí a sì máa gbàdúrà nígbàgbogbo, kí a má bàa dán [wa] wò ju èyí tí [a] lè faradà, àti nípa báyìí kí a máa darí wa nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́, ní dídi onírẹ̀lẹ̀, onínútútù, onítẹríba, onísùúrù, tí ó kún fún ìfẹ́ àti ìpamọ́ra ohun gbogbo.”9

Èyí kanáà ni a le múlò sí àwọn àdánwò ìgbésí ayé. Ámọ́nì rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa: “Ẹ lọ… kí ẹ sì fi sùúrù farada ìpọ́njú yín, èmi yíò sì fi àṣeyọrí sí rere fún yín.”10

Olúwa máa npèsè àbáyọ fún wa nígbàgbogbo nígbà tí a bá dojú kọ ìpọ́njú, àdánwò, àìlóye, àìlera, àní àti ikú pàápàá. Ó ti wí pé, “Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ohun tí mo sì sọ fún ẹnìkan ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, ẹ tújú ká, ẹ̀yin ọmọ kékeré; nítorí èmi wà ní àárín yín, èmi kòì fi yín sílẹ̀.”11 Kò ní fi wá sílẹ̀ láéláé!

Mo gbàdúrà pé kí a le tẹ̀síwájú láti ṣe àwọn ìgbésí ayé wa ní títẹ̀lé àwọn èrò àti àwọn àwórán ìmọ̀-ẹ̀rọ ti ọnà àtọ̀runwá tí a kọ lati ọwọ́ Baba wa tí a sì le ṣe àṣeyọrí rẹ̀ nípasẹ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Nípa báyìí, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí ó dé ọ̀dọ̀ wa nípasẹ̀ Ètùtù ti Olùgbàlà wa, a ó ṣe àṣeyọrí nínú síṣe ẹ̀dá ìgbé ayé tí ó lodì sí ẹ̀ṣẹ̀, tí ó lòdì sí ìdánwò, àti tí a fún wa lókun láti fara da àwọn àkókò ìbànújẹ́, tí ó nira nínú ìgbésí ayé wa. Àti pẹ̀lúpẹ̀lù, àwa yíò wà ní àwọn ipò láti rí àyè sí gbogbo àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí nípasẹ̀ ìfẹ́ ti Baba àti Olùgbàlà wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.