Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣé A Ti Dáríjì Mí Nítòótọ́?
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ṣé A Ti Dáríjì Mí Nítòótọ́?

Ìlérí ìdáríjì àṣepé àti pípé ni a ṣe sí ẹni-gbogbo—nínú àti nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Jésù Krístì.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, Arábìnrin Nattress àti èmi kó lọ sí Idaho, níbití a ti ṣí oko-òwò titun kan. Àwọn ọjọ́ ati alẹ gígùn máa nwà ní ọ́físì. Pẹ̀lú ìdúpẹ́, a ngbé ní ibùsọ̀ díẹ̀ sí ibi iṣẹ́. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Shawna àti àwọn ọmọbìnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—gbogbo wọn tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́fà—yíò wá sí ọ́físì láti pín oúnjẹ ọ̀sán papọ̀.

Ní irú ọjọ́ náà lẹ́hìn oúnjẹ ọ̀sán ẹbí wa, mo kíyèsí i pé ọmọbìnrin wa tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, Michelle, ti fi ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ fún mi, tí wọ́n kọ sínú Ìwé Pélébé kan tí wọ́n sì so mọ́ tẹlifóònù ọ́fìsì mi.

Ó kàn kà pé, “Baba, rántí láti nífẹ̀ẹ́ mi. Ìfẹ́, Michelle.” Èyí jẹ́ ìránnilétí alágbára kan fún ọ̀dọ́ baba kan nípa àwọn nkan wọ̀nnì tí ó ṣe pàtàkì jùlọ.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́rìí pé Baba wa Ọ̀run máa nrántí wa nígbà gbogbo àti pé Ó nífẹ̀ẹ́ wa ní pípé. Ìbéèrè mi ni èyí: Njẹ́ a rántí Rẹ̀ bí? Àti pé njẹ́ a nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ bí?

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo sìn gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìjọ ìbílẹ̀. Ọ̀kan lára ​​àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa, Danny, dá yàtọ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Ó gbọràn, ó jẹ́ onínúure, ẹni rere, ó sì ní ọkàn nlá. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí ó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ giga, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ tí ó nira. Ó ṣe alábápín nínú àwọn egbòogi olóró, ní pàtó methamphetamine, ó sì rin ìrìn-àjò sí ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè yíyọ̀ ti bárakú àti ìparun. Láìpẹ́, ìrísí rẹ̀ yípadà pátápátá. A fẹ́rẹ̀ má damọ̀. Àyípadà tó ṣe pàtàkì jùlọ wà ni ojú rẹ̀—ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ní ojú rẹ̀ ti di bàìbàì. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà mo gbìyànjú láti kàn sí i, ṣùgbọ́n kò ṣeéṣe. Kò nífẹ̀ẹ́ si.

Ó ṣòro láti rí ọ̀dọ́mọkùnrin àgbàyanu yìí tó njìyà tó sì ngbé ìgbésí ayé tí kì í ṣe tirẹ̀! O ní agbára láti ṣe púpọ̀ sii.

Nígbànáà ní ọjọ́ kan, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ bẹrẹ.

Ó lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa níbi tí àbúrò rẹ̀ ti pín ẹ̀rí rẹ̀ ṣáájú kí ó tó lọ fún míṣọ́n. Lákokò ìpàdé náà, Danny ní ìmọ̀lára ohun kan tí kò tíì ní fún ìgbà pípẹ́. Ó nìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa. Níkẹhín ó ní ìrètí.

Bótilẹ̀jẹ́pé ó ní ìfẹ́-inú láti yípadà, ó ṣòro fún Danny. Àwọn bárakú rẹ̀ àti ìdálẹ́bi tí ó tẹ̀lé fẹ́rẹ̀ pọ̀ díẹ̀ si ju ohun tí ó lè faradà lọ.

Ní ọ̀sán kan pàtó, nígbàtí mo jáde láti gé pápá oko wa, Danny dé nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ láìsọtẹ́lẹ̀. Ó ntiraka gidigidi. Mo pa gékogéko náà, a sì jókoó papọ̀ ní ibòji àtẹ̀gùn ìlóro. Ìgbà náà gan-an ló sọ ìmọ̀lára ọ́kàn rẹ̀. Nítòótọ́ ni ó fẹ́ padà. Síbẹ̀síbẹ̀, yíyí kúrò nínú àwọn bárakú àti ìgbésí ayé rẹ̀ nira púpọ̀. Ní àfikún sí èyí, ó nímọ̀lára ìdálẹ́bi tó bẹ́ẹ̀, ojú tì í gan-an fún síṣubú jìnnà tóbẹ́ẹ̀. Ó béèrè pé, “Ṣé a lè dárí jì mí nítòótọ́? Njẹ́ ọ̀nà kan wà padà nítõtọ́ bí?

Lẹ́hìn tí ó tú ọkàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú àwọn àníyàn wọ̀nyí, a ka Álmà orí 36 papọ̀:

“Bẹ́ẹ̀ni, èmi rántí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedéédéé mi. …

“Bẹ́ẹ̀ni,…èrò wíwá síwájú Ọlọ́run mi gbò ẹ̀mí mi pẹ̀lú ìbẹ̀rù tí a kò lè máa sọ” (ẹsẹ 13–14).

Lẹ́hìn àwọn ẹsẹ wọnnì, Danny sọ pé, “Bí mo ṣe ní ìmọ̀lára gan-an nìyí!”

A tẹ̀síwájú:

“Bí mo sì ṣe wà nínú ìnira ọkàn nípa ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, kíyèsi i, mo rántí pẹ̀lú pé mo gbọ́ tí baba mi sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn nã nípa bíbọ̀wá ẹnìkan tí à npè ní Jésù Krístì, tí íṣe Ọmọ Ọlọ́run, láti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. …

“Àti áà, irú ayọ̀ wo, àti irú ìmọ́lẹ̀ yíyanilẹ́nu wo ni èmi rí” (ẹsẹ 17, 20).

Bí a ṣe nka àwọn àyọkà wọ̀nyí, omijé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn. Ayọ̀ Álmà ni ayọ̀ tí ó ti nwá!

A jíròrò pé Álmà ti jẹ́ ènìyàn búburú lọ́pọ̀lọpọ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́ẹ̀kannáà tí ó ronúpìwàdà, kò wo ẹ̀hìn wò mọ́. Ó di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tó jẹ́ olùfọkànsìn. Ó di wòlíì kan! Ojú Danny là. “Wòlíì kan?” ni ó sọ,

Mo kàn fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ni, wòlíì kan. Kò sí títẹ̀ lórí rẹ!”

A jíròrò pé níwọ̀n bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò tíì dé ipele ti Álmà, ìlérí kannáà ti ìdáríjì pípé àti píparí ni a ṣe fún gbogbo ènìyàn—nínú àti nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin ti Jésù Krístì.

Ó yé Danny báyìí. Ó mọ ohun tí ó nílò láti ṣe: ó nílò láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa àti dídáríji ara rẹ̀!

Ìyípadà nlá ti ọkàn Danny kìí ṣe ohunkohun tò kéré jù ìṣẹ́ ìyanu lọ. Bí àkókò ti nlọ, ìrísí rẹ̀ yípadà, ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀ sì padà dé. Ó sì di yíyẹ fún tẹ́mpìlì! Ó ti padàdé nígbẹ̀hìn!

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, mo béèrè lọ́wọ́ Danny bóyá yíò fẹ́ fi ohun elo kan sílẹ̀ láti sìn míṣọ̀n ìgbà-kíkún. Ìdáhùn rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu àti ẹ̀rù.

Ó wípé, “Èmi yíò fẹ́ láti sin míṣọ̀n, ṣùgbọ́n o mọ ibití mo ti wá àti àwọn ohun tí mo ti ṣe! Mo rò pé mo ti di aláìyẹ.”

Mo fèsì, “O lè sọ òótọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ohun tí ó ṣe ìdíwọ́ fún wa láti bẹ̀bẹ̀ kan. Bí wọ́n bá dá ẹ lẹ́bi, ó kéré tán, wàá mọ̀ pé o fi ìfẹ́ àtọkànwá láti sin Olúwa hàn.” Ojú rẹ̀ tàn. Inú rẹ̀ dùn sí àbá yìí. Fún un èyí jẹ́ ohun gígùn kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó fẹ́ láti gbé.

Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, sì ìyàlẹ́nu rẹ̀, iṣẹ́ ìyanu míràn tún ṣẹlẹ̀. Danny gba ìpè kan láti sin míṣọ̀n ìgbà-kíkún.

Oṣù díẹ̀ lẹ́hìn tí Danny dé sí pápá míṣọ̀n, mo rí ìpè tẹlifóònù gbà. Ààrẹ rẹ̀ kàn sọ pé, “Kíni pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin yìí? Òun ni ìránṣẹ́ ìhìnrere àgbàyanu jù lọ tí mo tíì rí rí!” Ẹ wòó, ààrẹ yìí ti gba Álmà Kékeré kan ti òde òní.

Ọdún méjì lẹ́hìnnáà, Danny padà sí ilé pẹ̀lú ọlá, lẹ́hìn sísin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, inú, àti agbára Rẹ̀.

Lẹ́hìn èsì iṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀ nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa, mo padà sílé, kìkì láti gbọ́ ìkanlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé. Níbẹ̀ ni Danny dúrò pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀. Ó wípé, “Njẹ́ a lè sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú kan?” A lọ sí ìta sí ibi àtẹ̀gùn ìlóro kannáà.

Ó wípé, “Ààrẹ, ṣé o rò pé a ti dáríjì mi nítõtọ́?”

Báyíì omijé mi tẹ̀lé tirẹ̀. Ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì olùfọkànsìn kan dúró níwájú mi, ẹni tí ó ti fi gbogbo rẹ̀ fún kíkọ́ni àti láti jẹ́rìí nípa Olùgbàlà. Ôun jẹ́ àpẹrẹ ti ìwòsàn àti agbára fífún lókun ti Ètùtù Olùgbàlà.

Mo wípé, “Danny! Njẹ́ o ti wo inú dígí bí? Njẹ́ o ti ri ojú rẹ? Wọ́n kún fún ìmọ́lẹ̀, ìwọ sì ntàn fún Ẹ̀mí Olúwa. Dájúdájú a ti dáríjì ọ́! O jẹ́ oníyanu! Báyíì ohun tí o nílò láti ṣe ni títẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ. Máṣe wo ẹ̀hìn! Máa fojú sọ́nà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí ìlànà tó kàn.”

Iṣẹ́ ìyanu Danny tẹ̀síwájú lónìí. Ó ṣe ìgbéyàwó ní tẹ́mpìlì ó sì padà sí ilé-ìwé, níbití ó ti gba oyè gíga. Ó nbá a lọ láti sin Olúwa pẹ̀lú ọlá àti iyì nínú àwọn ìpè rẹ̀. Ní pàtàkì jù lọ, ó ti di ọkọ àgbàyanu àti baba olõtọ́. Ó jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì olùfọkànsìn

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, “Láìsí Ètùtù àìlópin [Olùgbàlà], gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni yíó sọnù láìṣeé gbà padà.”1 Danny kò sọnù, àti pé àwa kò sọnù sí Olúwa. Ó dúró sí ẹnu ọ̀nà láti gbé wa sókè, láti fún wa lókun, àti láti dáríjì wá. Ó nrántí láti nífẹ̀ẹ́ wa nigbagbogbo!

Àfihàn ìyàlẹ́nu ti ìfẹ́ Olùgbàlà fún àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a kọ sílẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì: “Nígbàtí Jésù ti sọ báyìí, ó tún gbé ojú rẹ̀ yíká sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà, ó sì ríi pé wọn nsọkún, wọ́n sì wõ ní ìtẹjúmọ́ bí ẹnipé kí wọn ó rọ̃ láti dúró tì wọn fún ìgbà díẹ̀ si” (3 Néfì 17:5).

Olùgbàlà ti lo ọjọ́ kíkún tẹ́lẹ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Síbẹ̀síbẹ̀ Ó ní púpọ̀ láti ṣe—Ó níláti bẹ àwọn àgùtàn Rẹ̀ míràn wò; Ó ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ Baba Rẹ̀.

Láìbìkítà àwọn ọ̀ranyàn wọ̀nyí, Ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn nfẹ́ kí Ó dúró díẹ̀ síi. Lẹ́hìnnáà, pẹ́lù ọkàn Olùgbàlà tí ó kún fún àánú, ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ̀ ìyanu nlá jùlọ nínú ìtàn àgbáyé ṣẹlẹ̀:

Ó dúró.

Ó bùkún wọn.

Ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ó gbàdúrà fún wọn; Ó sì sọkún pẹ̀lú wọn.

Ó wò wọ́n sàn. (Wo 3 Nẹ́fì 17.)

Ìlérí Rẹ̀ jẹ́ ti ayérayé: Yìó wòwá sàn.

Fún àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ní ọ̀nà májẹ̀mú, jọ̀wọ́ mọ̀ pé ìrètí máa nwà nígbàgbogbo, ìwòsàn máa nwà nígbàgbogbo, ọ̀nà pípada kan sì máa nwà.

Ọ̀rọ̀ ìrètí ayérayé rẹ̀ ni ìkunra ìwòsàn fún gbogbo àwọn tí wọ́n ngbé nínú ayé tí ó ní ìṣòro. Jésù wípé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè.” (Jòhánnù 14:6).

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ jẹ́ kí a rántí láti wá A, láti fẹ́ràn Rẹ̀, kí á sì rántí Rẹ̀.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà láàyè Ó sì fẹ́ràn wa. Mo tún jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà ayé. Òun ni olùwòsàn alágbára. Mo mọ̀ pé Olùràpadà mi wà láàyè! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Múrasílẹ̀ fún àwọn Ìbùkún Tẹ́mpìlì,” Ensign, Mar. 2002, 21.