Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dìde! Ó Npè Ọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2024


Dìde! Ó Npè Ọ́

Ìhìnrere kìí ṣe ọ̀nà láti yẹra fún àwọn ìpèníjà àti àwọn ìdààmú ṣùgbọ́n ojutu kan láti ṣe àlékún ìgbàgbọ́ wa kí a sì kọ́ bí a ó ti ṣe pẹ̀lu wọn.

Ní ìgbà kan sẹ́hìn mo bi ìyàwó mi léèrè pé, “Njẹ́ o le sọ ìdí rẹ̀ fún mi, bí mo ti lè rántí tó, tí a kò fi ní àwọn ìdàmú tó ṣe kókó kankan rí ní ìgbésí ayé wa?”

Ó wò mí ó sì wípé, “Dájúdájú. Èmi ó sọ ìdí rẹ̀ fún ọ tí a kò fi ní àwọn ìdàmú tó ṣe kókó rí; ó jẹ́ nítorí ó ní ìrántí kúkurú gan!”

Ìdáhùn rẹ̀ kíákíá àti jíjáfáfá mu mi ríi lẹ́ẹ̀kansíi pé gbígbé ìgbésí ayé ìhìnrere Jésù Krístì kò mú ìrora àwọn àdánwò kúrò, èyítí ó ṣe dandan láti dàgbà.

Ìhìnrere kìí ṣe ọ̀nà láti yẹra fún àwọn ìpèníjà àti àwọn ìdààmú ṣùgbọ́n ojútùú kan láti fi kún ìgbàgbọ́ wa kí a sì kọ́ ẹ̀kọ́ bí a ó ti ṣe pẹ̀lu wọn.

Mo ní ìmọ̀ òtítọ́ yi ní bíi oṣù melo kan sẹ́hìn nigbàtí mo nrìn ní ọjọ́ kan lójijì tí ojú mi sì di bàìbàì, ó dúdú, tí ó sì nṣẹ́ àṣẹ́lé. Ẹ̀rù bà mí. Lẹ́hìnnáà, àwọn dókítà sọ fúnmi pe, “Bí o kò bá bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, o le pàdánù ìríran rẹ láàrin àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀.” Àní ẹ́rù tún túbọ̀ bàmí síi.

Àti pé lẹ́hìnnáà wọ́n wí pé, “O nílò àwọn abẹ́rẹ́ intirfitirílì—àwọn abẹ́rẹ́ ní inú ojú gan-an, ojú lílà sílẹ̀ní , ọ̀sẹ̀ mẹ́rin-mẹ́rin, fun ìyókù ìgbésí ayé rẹ.”

Èyíinì jẹ́ ìpè ìtanijí kan tí kò tunilára.

Lẹ́hìnnáà ìrònú kan wá ní ìwo ìbéèrè kan. Mo béèrè lọ́wọ́ ara mi pe, “Ó dára! Ìríran ti àfojúrí mi kò dára, ṣùgbọ́n báwo ni ìríran mi ti ẹ̀mí? Njẹ́ mo nílò ìtọ́jú kankan níbẹ̀ bí? Kíni ó sì túmọ́sí láti ní ìríran kedere kan ti ẹ̀mí?”

Mo ronújinlẹ̀ nipa ìtàn ọkùnrin afọju kan ti a pè ní Bartíméù, tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ ninu ìhìnrere ti Markù. Ìwé mímọ́ sọ pé, “Nígbàtí ó sì gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀sí kígbe lóhùn rara, ó sì wípé, Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”1

Bí ó ti rí, ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀, Jésù kàn jẹ́ ọmọ Jósẹ́fù, nítorínáà kínni ìdí ti Bartíméù fi pè é ní “Ọmọ Dáfídì”? Ó kàn jẹ́ nìtorípé ó dáa mọ̀ pé Jésù ni Messia nitòótọ́, ẹnití wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ láti jẹ́ bíbí bíi àtẹ̀lé kan ti Dáfídì.2

Ó jẹ́ ohun tó dùnmọ́ni pé ọkùnrin afọ́jú yi, ẹnití kò ní ìríran ti ara, dá Jésù mọ̀. Ó rí ní ti ẹ̀mí ohun tí kò le rí ni ti ara, nigbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn le rí Jésù ní ti ara, ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú pátápátá ni ti ẹ̀mí.

Láti inú ìtàn yí a kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ìrìran kedere ti ẹ̀mí.

A kà pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì bá a wí pé kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe síi jù bẹ́ẹ̀ lọ pé,ÌÍwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”3

Gbogbo ènìyàn ní àyíká rẹ̀ nsọ fún un láti dákẹ́, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ kigbe síi nítorípé ó mọ ẹnití Jésù í ṣe nítòótọ́. Kò ka àwọn ohùn wọnnì sí ó sì han àní bí ó ti pariwo síi.

Ó gbé ìgbésẹ̀ dípò kí ó jẹ́ gbígbé ìgbésẹ̀ lé lórí. Láìka àwọn ipò rẹ̀ tó dínkù sí, ó lo ìgbàgbọ́ rẹ̀ láti lọ tayọ àwọn ìdínkùn rẹ̀.

Nitorínáà, ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ àkọ́kọ́ ti a kọ́ ni pé a nní ìríran kedere ti ẹ̀mí nigbàtí a bá fojúsùn sórí Jésù Krístì tí a sì dúró nítòótọ́ sí ohun tí a mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, lati pa ìríran ti ẹ̀mí wa mọ́ ní pípé, a nílò láti pinnu láti máṣe fetisí àwọn ohùn ti aráyé ní àyíká wa. Ni ayé tó ndani-láàmú àti tí ó ti dàmú yí, a gbọ́dọ̀ dúró nínú òtítọ́ sí ohun tí a mọ̀, nínú òtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú wa, pẹ̀lú òtítọ́ ní pípa àwọn òfin mọ́, kí a sì tún fi ẹsẹ̀ àwọn ohun ìgbàgbọ́ wa múlẹ̀ àní kí ó lágbára síi, bí ọkùnrin yi ti ṣe. A nílò láti túbọ̀ kigbe ẹ̀rí wa nípa Olúwa sí aráyé Ọkùnrin yi mọ Jésù, ó dúró pẹ̀lú òtítọ́ sí àwọn ohun tó gbàgbọ́, kò sì jẹ́kí àwọn ohùn ní àyíká rẹ̀ ó dí òun lọ́wọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohùn ló wà ní òní tó ngbìyànjú láti rẹ àwọn ohùn tiwa sílẹ̀ bíi ọmọẹ́hìn Jésù Krístì. Àwọn ohùn ti aráyé ngbìyànjú láti pa wá lẹnu mọ́, ṣugbọ́n èyí jẹ́ ìdí gan-an tí a fi gbọ́dọ̀ kéde ẹ̀rí wa nípa Olùgbàlà sókè síi kí ó sì lágbára síi. Láàrin àwọn ohùn aráyé, Olúwa ngbẹ́kẹ̀ lé èmi àti ìwọ láti kéde àwọn ẹ̀rí wa, láti gbé ohùn wa sókè, àti láti di ohùn Rẹ̀. Bí a kò bá ṣe é, taani yíò jẹ́ri nípa Jésù Krístì? Tani yío sọ̀rọ̀ orúkọ Rẹ̀, tí yío sì kéde iṣẹ́ ìránṣẹ́ àtọ̀runwá Rẹ̀?

A ni àṣẹ ti ẹ̀mí kan tí ó nwá láti inú ìmọ̀ wa nípa Jésù Krístì.

Ṣùgbọ́n kínni Bartíméù ṣe lẹ́hìn eyí?

Ní àṣẹ Olúwa làti dìde, ó tún gbé ìgbésẹ̀ ninú ìgbàgbọ́.

Ìwé mímọ́ wípé, “Ó sì bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ sọnù, ò dìde, ó sì tọ Jésù wá.”4

Ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti olõtọ́ yí ní òye pé òun le dìde sí ìgbé ayé dídára síi ní àṣẹ Jésù. Ó mọ̀ pé òun dára ju àwọn ipò rẹ̀ lọ, ohun àkọ́kọ́ tí ó sì ṣe gan-an nigbàtí ó gbọ́ tí Jésù pè é ni láti ju kóòtù alágbe rẹ̀ nù.

Lẹ́ẹ̀kansi ó gbé ìgbésẹ̀ dípò kí ó jẹ́ gbígbé ìgbésẹ̀ lé lórí.

Ó le ti rò ó pé, “Emi kò nílò èyí mọ́, nísisìyí tí Jésù ti wá sinu ìgbé ayé mi. Ọjọ́ titun kan ni èyí jẹ́. Mo ti parí pẹ̀lú ìgbé ayé òṣì yí. Pẹ̀lú Jésù mo le bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun ti ìdùnnú àti ayọ̀ ninu Rẹ̀, pẹ̀lú Rẹ̀, àti nípasẹ̀ Rẹ̀. Èmi kò bìkítà ohun tí aráyé bá rò nípa mi. Jésù npè mí, Òun yío sì rànmí lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé titun.”

Irú ìyípada tó lápẹrẹ wo!

Bí ó ti ju kóòtù alágbe rẹ̀ nù, ó da gbogbo àwọn àwáwí nù.

Èyí sì ni ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kejì: a nní ìríran kedere ti ẹ̀mí nigbàtí a bá fi àdánidà ènìyàn sílẹ̀ sẹ́hìn, tí a ronúpìwàdà, tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé titun nínú Krístì.

Ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni nipa ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ láti dìde sí igbé ayé dídara síi nípasẹ̀ Jésù Krístì.

Níwọ̀n ìgbà tí a bá nṣe àwọn àwáwí láti ní ìmọ̀lára àbámọ̀ fún ara wa, àbámọ̀ fún àwọn ipò àti àwọn ìdààmú wa àti fun gbogbo àwọn ohun búburú tí ó nṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé wa àti pàápàá gbogbo àwọn ènìyàn búburú tí a rò pé wọn kò mú inù wa dùn, a nfi kóòtu alágbe kọ́ èjìká wa. Òtítọ́ ni pé ní àwọn ìgbà míràn àwọn ènìyàn máa nṣẹ̀ wá, ní àmọ̀ọ́mọ̀ ṣe tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n a nílò láti pinnu láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì nipa mímú kóòtù ti ọpọlọ àti ti ẹ̀dùn ọkàn tí a ṣì le máa gbé lati fi àwọn àwáwí tàbí ẹ̀ṣẹ̀ pamọ́ kúrò kí a sì sọ ọ́ nù, ní mímọ̀ pé Òun le àti pé yíò wò wá sàn.

Kò sí àwáwí kan tí ó dára rí láé láti sọ pe, “Mo wà bí mo ti wà nitori àwọn ipò àìlóríire áti àìdùnmọ́ni kan. Àti pé èmi kò le yípadà, mo sì rí nkan wí.”

Nígbàtí a bá ronú ní ọ̀nà yí, a pinnu lati jẹ́ ṣíṣe ìṣe lé lórí.

A nmu kóòtù alágbe lọ́wọ́.

Ṣíṣe ìṣe ninu ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà wa, ní gbígbàgbọ́ pé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, a le dìde kọjá ohun gbogbo, ní àṣẹ Rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kẹta ni àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́rin tó gbẹ̀hìn, “[ó] tọ Jésù wá.”

Báwo ni òun ṣe lè tọ Jésù lọ bí ó ti jẹ́ afọ́jú? Ọ̀nà kanṣoṣo náà ni láti rìn síwájú Jésù nípa gbígbọ́ ohùn Rẹ̀.

Èyí sì ni ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kẹta: à nní ìríran kedere ti ẹ̀mí nigbàtí a bá gbọ́ ohùn Olúwa tí a sì fi àyè gba Á láti tọ́ wa.

Gẹ̀gẹ̀bí ọkùnrin yi ti gbé ohùn rẹ̀ sókè tayọ àwọn ohùn ní àyíká rẹ̀, ó ṣeéṣe fún un láti fetísílẹ̀ sí ohùn ti Olúwa ní ààrin gbogbo àwọn ohùn míràn.

Èyí ni ìgbàgbọ́ kannáà tí ó fi àyè gba Pétérù láti rìn lórí omi níwọ̀n ìgbà tí ó fi ojú ẹ̀mí rẹ̀ sùn sí ara Olúwa tí kò sì jẹ́ yíyọlẹ́nu nipa àwọn ìjì àyíka rẹ̀.

Lẹ́hìnáà, ìtàn ọkùnrin afọ́jú yí parí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ pé “ó sì ríran, ó sì tọ Jésù lẹ́hìn ní ọ̀nà.”5

Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ninu ìtan yí ni pé ọkùnrin yi lo ìgbàgbọ́ òtítọ́ ninu Jésù Krístì ó sì gba iṣẹ́ ìyanu nítorípé ó béèrè pẹ̀lú èrò ọkàn tòótọ́, èrò ọkàn tòótọ́ láti tẹ̀lé E.

Èyí sì ni èrèdí ìgbẹ̀hìn fún àwọn ìbùkún tí a ngbà ninu ayé wa, èyítí í ṣe láti tẹ̀lé Jésù Krístì, Ó jẹ́ nípa dídámọ̀ Rẹ̀, ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ nitori Rẹ̀, yíyí ìwà àdánidá wa gan-an padà nipasẹ̀ Rẹ̀, àti fífi ara dà dé òpin nipa títẹ̀lé E.

Fún èmi, níní ìríran kedere ti ẹ̀mí jẹ́ nípa fífi ojú sùn sára Jésù Krístì.

Nitorínáà njẹ́ ìríran mi ti ẹ̀mí jẹ́ kedere bí mo ti ngba àwọn abẹ́rẹ́ ojú mi bí? Ó dára, tani èmi lati sọ? Ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ fún ohun tí mo rí.

Mo rí ọwọ́ Olúwa kedere nínú iṣẹ́ mímọ́ yí àti nínú ayé mi.

Mo ri ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níbikíbi ti mo lọ tí wọ́n nfún ìgbàgbọ́ ti ara mi lókun.

Mo nri àwọn angẹ́lì ní gbogbo àyíká mi.

Mo nrí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àwọn ẹnití kò rí Olúwa ní àfojúrí ṣùgbọ́n tí wọ́n dá A mọ̀ ní ti ẹ̀mí, nítorípé wọ́n mọ̀ Ọ́ tímọ́tímọ́.

Mo jẹ́rìí pé ìhìnrere yi ni ìdáhùn fún ohun gbogbo, nitorípé Jésù Krístì ni ìdáhùn fún gbogbo ènìyàn. Mo fi ìmoore hàn fún ohun tí mo le rí bí mo ti ntẹ̀lé Olùgbàlà mi.

Mo ṣe ìlérí pé bí a ti ngbọ́ ohùn Olúwa tí a sì nfi àyè gbà Á láti tọ́ wa sọ́nà lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú Olùgbàlà, a yíò di alábùkún pẹ̀lú ìríran kedere, lílóye ti-ẹ̀mí, àti àláfíà ọkàn àti inú ní gbogbo ayé wa.

Njẹ́ kí a le kígbe ẹ̀rí wa nipa Rẹ̀ sókè ju àwọn ohùn àyíka wa lọ ninu ayé kan tí ó nílò láti gbọ́ nipa Jésù Krístì síi àti tí kìí ṣe dídínkù. Njẹ́ kí a le mú kóòtù alágbe tí a ṣì le máa wọ̀ kurò kí a sì dìde kọjá ayé sí ìgbé ayé dídára síi ninu àti nipasẹ̀ Krístì. Njẹ́ kí a le da gbogbo àwọn àwáwí nù lati máṣe tẹ̀lé Jésù Krístì ki a sì rí gbogbo àwọn èrèdí dáradára láti tẹ̀lé E bí a ti ngbọ́ ohùn Rẹ̀. Èyí ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.