2013
Mo Lè Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Kan Sí Àwọn Ẹlòmíràn
February 2013


Àwọn Ọmọdé

Mo Lè Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Kan Sí Àwọn Ẹlòmíràn

Ààrẹ Uchtdorf wípé láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kan sí àwọn ẹlòmíràn, àwọn ọ̀rọ̀ wa gbọ́dọ̀ “mọ́lẹ̀ bíi ojú ọ̀run lọ́sán gangan kí ó sì kún fún ore ọ̀fẹ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ wa gbọ́dọ̀ jẹ́ dídùn, olótítọ́ àti onínú rere. Kí lo lè ṣe tàbí sọ láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kan sí àwọn ẹlòmíràn? O lè kọ sínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ ohun dáradára márún tí o pinu láti sọ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́.