2013
Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa
November 2013


Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kọkànlá Ọdún 2013

Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa

Láìka àwọn ipò rẹ sí, ìwé ìtàn ara rẹ, tàbí agbára ẹ̀rí rẹ, àyé wà fún ọ nínú Ìjọ yí.

Nígbà kan ọkùnrin kan wà tí ó lá àlá pé óun wà ní yàrá ńlá kan níbi tí gbogbo àwọn ẹ̀sìn àgbáyé kórajọ papọ̀ sí. Ó wòye pé olukúlùkù ẹ̀sìn ni ó ní ọ̀pọ̀ ohun tí ó dàbí pé ó yẹ ní fífẹ́ tí o sì pé.

Ó pàdé àwọn tọkọtayà tí wọn ń ṣojú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn ó sì bèèrè, “Kíni ohun tí bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ yín?”

A kò bèèrè ohunkóhun,” wọ́n fèsì “Ṣùgbọ́nOlúwa bèèrè pé kí a ya gbogbo rẹ̀ sọ́tọ̀.”

Tọkọtayà náà tẹ̀síwájú láti ṣe àlàyé nípa àwọn ìpè ìjọ, abẹniwò ìdílé ati kíkọ́ni, àwọn míṣọ̀n ìgbà kíkún, ìpàdé ìrọ̀lẹ́ ẹbí ọ̀sọ̀sẹ̀, iṣẹ́ tẹ́mpìlì, iṣẹ́ ìsìn àláfíà àti inúrere, àti àwọn iṣẹ́ yíyàn lé lọ́wọ́ láti kọ́ni lẹ́kọ́.

“Njẹ́ ò ńsanwó fún àwọn ènìyàn rẹ fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ọkùnrin náà bèèrè

“Óò, rárá,” tọkọtayà náà ṣe àlàyé. “Wọ́n ńfi àsìkò wọn sílẹ̀ lọ́fẹ́.”

“Bákannáà,”tọkọtayà náà tẹ̀síwájú, “ní oṣù mẹ́fà mẹ́fà àwọn ọmọ Ìjọ ma ńlo ìparí ọ̀sẹ̀ kan láti wá sí tàbí láti wo wákàtí mẹ́wá ti ìpàdé gbogboògbò.”

“Wákàtí mẹ́wá ti kí awọn ènìyàn báni sọ̀rọ̀?” Ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu

“Báwo ni iṣẹ́ ìsìn ìjọ́sìn yín ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Báwo ni wọ́n ṣe ńpẹ́ sí?

“Wákàtí mẹ́ta, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀

“Óò, èmi,” ọkùnrin náà sọ. Njẹ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ máa ńṣe ohun tí o sọ dájúdájú?”

“Eyĩnì àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. A kò tíì dárúkọ ìwé ìtàn ẹbí pàápàá, àwọn ìpàgọ́ awọn ọ̀dọ́, àwọn ibi ìsìn, ṣíṣe àṣàrò nínú ìwé mímọ́, ìdánilẹ́kọ́ fun àwọn olórí, àwọn ìdárayá fun awọn ọ̀dọ́, ibi ìkọ́ni àárọ̀ kùtùkùtù, títọ́jú àwọn ilé Ìjọ, àti pé bákannáà òfin ìlera ti Olúwa wà, ãwẹ̀ oṣoṣù láti ran awọn aláìní lọ́wọ́, àti ìdámẹ́ẹ̀wá.

Ọkùnrin náà sọ pé, “Báyìí ọkàn mi dàrú. Kíni ìdí tí ẹnikẹ́ni yíò fi fẹ́ dárapọ̀ mọ́ irú ìjọ náà?”

Tọkọtayà náà rẹ́rín wọ́n sì sọ pé, “A lérò pé o kò ní bèèrè láéláé.”

Kíni Ìdí tí Ẹnikẹ́ni yíò fi Darapọ̀ mọ́ Irú Ìjọ náà?

Ní ìgbà kan nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọ kákiri àgbáyé ńní ìrírí díndínkù pàtàkì nínú iye, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kéré ní fífiwé pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn—ó jẹ́ ìkan lára àwọn ìjọ tí ó ńdàgbà sókè jù ní àgbáyé. Ní oṣù kẹ́sán ọdún 2013 ìjọ náà ní ju ọmọ ìjọ mílíọ̀nù mẹ́ẹ́dógún kákiri àgbáyé.

Àwọn ìdí púpọ̀ ní o wà fún èyí, ṣùgbọ́n njẹ́ kí ńfún yín ní díẹ̀?

Ìjọ ti Olùgbàlà

Àkọ́kọ́, Ìjọ yí wá sí ìmúpadàsípò ní ọjọ́ wa nípasẹ̀ Jésù Krístì Fúnrarẹ̀. Níbí yĩ ìwọ yíò rí àṣẹ náà láti ṣiṣẹ́ ní orúkọ Rẹ̀—láti ṣè ìrìbọmi fún ìdáríjì ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀, láti fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ fúnni, àti láti fi èdidì di ní ayé àti ní ọ̀run.1

Àwọn wọnnì tí wọn bá darapọ̀ mọ́ Ìjọ yí fẹ́ràn Olùgbàlà Jésù Krístì wọ́n sì ńfẹ́ láti tẹ̀lé E. Wọ́n ńyọ̀ nínú ìmọ̀ pé Ọlọ́run tún ńbá irú ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Nígbàtí wọ́n bá gba àwọn ìlànà oyè àlùfáà mímọ́, tí wọ́n sì dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n lè ní ìmọ̀lára agbára Rẹ̀ nínú ayé wọn.2 Nígbà tí wọ́n bá wọ inú tẹ́mpìlì mímọ́, wọ́n ń ní òye pé wọ́n wà níwájú Rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ka àwọn ìwé mímọ́3 tí wọ́n sì ńgbé ìgbé ayé ẹ̀kọ́ kíkọ́ni ti àwọn wòlíì Rẹ̀, wọ́n ńdàgbà súnmọ́ Olùgbàlà tí wọ́n nífẹ́ sí gidi.

Ìgbàgbọ́ tí ó ní Ãpọn

Ìdí míràn ní nítorí pé Ìjọ ńpèsè àwọn ànfãní fún ṣíṣe rere.

Gbígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ní àyẹ́sí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ńfẹ́ láti ṣe púpọ̀ ju fífi etí sí àwọn ìwàásù tí ó ní ìmísí tàbí àlá nípa ibùgbé wọn lókè.4 Wọ́n fẹ́ láti fi ìgbàgbọ́ wọn sí ìṣe. Wọ́n fẹ́ láti ká apá aṣọ wọn sókè kí wọ́n sì di gbígbàsí iṣẹ́ nínú ètò ńlá yí

Àti pé èyínì ni ohun ti ó ńṣẹlẹ̀ nígbàtí wọ́n bá darapọ̀ pẹ̀lú wa wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ànfãní láti yí àwọn ẹ̀bùn ọ̀run wọn padà, àánú, àti àsìkò sínú àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí a kò ní àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti ìbílẹ̀ kan tí à ńsan owó fún ní ìjọ wa kákiri àgbáyé, àwọn ọmọ ìjọ ńṣiṣẹ́ ti ìránṣẹ́ ìhìnrere fúnrara wọn. Wọ́n ńgba ìpè nípa ìmísí. Ìgbà míràn á ńyọ̀ọ̀da ara wa; nígbàmíràn à jẹ́ “yíyọ̀ọ̀da fún.” A kò rí àwọn iṣẹ́ yíyànfúnni bí àjàgà ṣùgbọ́n bí àwọn ànfãní láti mú àwọn májẹ̀mú wa tí a fi tayọ̀tayọ̀ dá ṣẹ lati sin Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

Àwọn Ìbùkún tí ó ní Ìṣúra

Ìdí kẹ́ta tí awọn ènìyàn ṣe ńdarapọ̀ mọ́ Ìjọ ni nítorípé rírìn ní ọ̀nà ti ọmọ ẹ̀hìn ńdarí sí àwọn ìbùkún oníyebíye.

A rí ìrìbọmi bí àmì ìbẹ̀rẹ̀ ní ìrìn àjo wa bĩ ọmọlẹ́hìn. Ìrìn ojojúmọ́ wa pẹ̀lú Jésù Krístì ńdarí sí àláfíà àti èrò ní ayé yí àti ayọ̀ ìjinlẹ̀ pẹlú ìgbàlà àìnípẹ̀kun ní ayé tí ńbọ̀

Àwọn wọnnì tí wọn tẹ̀lé ọ̀nà yí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfàsẹ́hìn, àwọn ìbànújẹ́, àti àwọn àbámọ̀ ti ayé.

Òtòṣì ní ẹ̀mí àti olóótọ́ ọkàn ńrí awọn ìṣura ńlá ti ìmọ̀ ní ibíyĩ.

Àwọn wọnnì tí wọ́n ńjìyà tàbí ní ìkẹdùn ńrí ìwòsàn níbíyĩ.

Àwọn tí wọn ní àjàgà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ńrí ìdáríjì, ìdásílẹ̀, àti ìsinmi.

Sí Àwọn Tí Wọn Kúrò

Wíwá òtítọ́ kiri ti darí ìlọ́po mílíọ́nù awọn ènìyàn sí Ìjọ Jésù Krísti ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan wà tí wọ́n kúrò ní Ìjọ tí wọ́n ti fẹ́ràn nígbà kan rí.

Ẹnìkan lè bèèrè, “Bí ìhìnrere bá jẹ́ ìyanu, kíni ìdí tí ẹnìkẹ́ni yíò kúrò?”

Nígbà míràn a lè rò pé bóyá nítorípé a ti ṣẹ̀ wọ́n tàbí wọn ya ọ̀lẹ tàbí ẹlẹ́ṣẹ̀. Nítòótọ́, kìí ṣe ohun tí ó rọrùn. Lótítọ́, kò sí ìdí kan pàtó tí ó jẹ mọ́ onírurú àwọn ipò.

Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ wa ọ̀wọ́n ńtiraka fún ọ̀pọ̀ ọdún pẹ̀lú ìbèèrè náà bóyá wọ́n yíò pín ara wọn níyà kúrò ní Ìjọ.

Ní Ìjọ yí tí ó ńfì ọlá fún ṣíṣe ojú ara ẹni gidigidi, tí a múpadàsípò nípasẹ ọmọdékùnrin tí ó bèèrè àwọn ìbèèrè tí ó sì wá ìdáhùn, a bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó ńfi ìnú mímọ́ wá òtítọ́ kiri. O lè ba ọkàn wa jẹ́ nígbàtí ìrìn àjò wọ́n bá ńgbé nwọn kúrò ní Ìjọ tí a fẹ́ràn àti òtítọ́ tí a ti rí, ṣùgbọ́n a fi ọlá fún ẹ̀tọ́ wọn láti jọ́sìn fún Ọlọ́run Olódùmarè ní ìbámu pẹlú ẹ̀rí ọkàn ara wọn, gẹ́gẹ́bí awa náà ṣe gba ànfàní náà mọ́ra fúnra wa.5

Àwọn Ibèèrè Àìdáhùn

Àwọn kan ńtiraka pẹ̀lú àwọn àìdáhùn ìbèèrè nípa àwọn ohun tí a ti ṣe tàbí sọ ní àtẹ̀hìnwá. A jẹ́wọ́ ní gbangba pé lati bíi igba ọdún ninu ìtàn Ìjọ ní àpapọ̀ pẹ̀lú àìsí ìdádúró àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtọ̀runwá ti wọ́n ní ìmísí ati àyẹ́sí, àwọn ohun kan wà tí a ti sọ àti tí a ti ṣe tí ó le fa kí awọn ènìyàn ní ìbéèrè.

Ní ìgbà míràn àwọn ìbèèrè ńwá nítorí a kò ní gbogbo ìwífúnni àti pé a kàn nílò láti ní sùúrù díẹ̀ si. Nígbàtí a bá mọ gbogbo òtítọ́ nígbẹ̀hìn, àwọn ohun tí kò mú ọgbọ́n wá lójú wa tẹ́lẹ̀ yíò wá yanjú sí ìtẹ́lọ́rùn wa.

Nígbà míràn ìyàtọ̀ ńwà nínú èrò inú nipa ohun tí “awọn òtítọ́” túmọ̀ sí dájúdájú. Ìbèèrè kan tí ó ńdá iyèméjì sínú àwọn kan lè kọ́lé ìgbàgbọ́ sínú àwọn míràn, lẹ́hìn ìwáàdí fínnífínní.

Àwọn Àṣìṣe ti Àìpé Ènìyàn

Àti pé, kí a sọ òtítọ́ ní pípé, àwọn ìgbà kan ti wà nígbàtí àwọn ọmọ ìjọ tàbí olórí nínú Ìjọ ti ṣe àwọn àṣìṣe. Àwọn nkankan le ti wà tí wọ́n ti sọ tàbí ṣe tí kò wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àsà wa, àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tàbí ẹ̀kọ́.

Mo ṣebí Ìjọ yíò di pípé bí àwọn tí ó ńdarí rẹ̀ bá jẹ́ ènìyàn pípé nìkan. Ọlọ́run jẹ́ pípé, àti pé ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jẹ́ àìlábàwọ́n. Ṣùgbọ́n Òun ńṣiṣẹ́ nípasẹ̀ wa —àwa ọmọ Rẹ̀ aláìpé, — àti pé aláìpé ènìyàn ńṣe àwọn àṣìṣe.

Ní ojú ewé àkọlé Ìwé ti Mọ́rmọ́nì a kà pé, “Àti pé nísisìnyí, tí àwọn àṣìṣe bá wà, àṣìṣe ti àwọn ènìyàn ni, nítorínáà, máṣe dá àwọn ohun ti Ọlọ́run lẹ́bi, kí ẹ lè wà láìléérí ní ìtẹ́ ìdájọ́ ti Krístì.”6

Báyìí ni ó ṣe ti rí ní gbogbo ìgbà àti pé yíò rí bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ pípé nígbàtí Krístì fúnra Rẹ̀ yíò jọba níti ara lórí ayé.

Ó jẹ́ ohun búburú pé àwọn kan ti ṣubú nítorí àwọn àṣìṣe tí ó ṣẹlẹ̀ lati ọwọ́ àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n bí èyí tilẹ̀ rí bẹ̃, òtítọ́ àìnípẹ̀kun ti ìmúpadàsípò ìhìnrere tí a rí ní Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn kò bàjẹ́, dínkù, tàbí parun.

Gẹ́gẹ́bí Àpọ́stélì ti Olúwa Jésù Krístì kan àti bí ẹnìkan tí ó ti kọ́kọ́ rí àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ti Ìjọ yí, mo fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìjẹ́rí pé kò sí ìpinnu pàtàkì tí ó nĩṣe pẹlú Ìjọ yí tàbí àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ tí a ṣe láé láì fi ìtara ṣe àwárí ìmísí, ìtọ́sọ́nà, àti ìfaramọ́ ti Bàbá wa Ayérayé. Èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì. Ọlọ́run kò ní gba Ìjọ Rẹ̀ lãyè láti yà kúrò ní ipá ọ̀nà ìpín rẹ̀ tàbí kùnà láti mú àyànmọ́ àtọ̀runwá rẹ̀ ṣẹ.

Àyè wà Fún Ọ.

Sí àwọn wọ̀nnì tí wọ́n ti pín ara wọn níyà kúrò ní Ìjọ, mo sọ pé, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ibì kan ṣì wà síbẹ̀síbẹ̀ fún ọ níbí.

Wa kí o sì fi àwọn ẹ̀bùn abínibí, àwọn ìrànwọ́, àti àwọn okun rẹ kún tiwa. Gbogbo wa yíò dára sĩ ní àyọrísí rẹ̀.

Àwọn kan lè bèèrè, “Ṣùgbọ́n báwo ní ti àwọn ìyèméjì mi?”

Ó jẹ́ àdánidá láti ní àwọn ìbèèrè— èso ti ìwádí òtítọ́ ti máa ńfi ìgbà míràn jáde síta kí ó sì dàgbà di bĩ igi ńlá ti òye kan. Àwọn ọmọ ìjọ díẹ̀ wà tí wọ́n kò tĩ fi ìgbà kan tàbí òmíràn ja ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìbèèrè tí ó gba agbára tàbí jẹ́ ẹlẹgẹ́. Ọ̀kan nínú àwọn èrò ti Ìjọ ni láti kẹ́ àti láti tọ́ èso ti ìgbàgbọ́ pàápàá nígbà púpọ̀ ní ilẹ̀ yanrìn ti iyèméjì àti àìnídánilójú Ìgbàgbọ́ jẹ́ láti ní ìrètí fún àwọn ohun tí a kò rí ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ òtítọ́.7

Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n—ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n—jọ̀wọ́, kọ́kọ́ ṣe iyèméjì awọn iyèméjì rẹ kí o tó ṣe iyèméjì ìgbàgbọ́ rẹ.8 A kò gbọdọ̀ gba iyèméjì láàyè láti fi wá sí ìhámọ́ àti láti fi wá pamọ́ kúrò ní ìfẹ́ ti ọ̀run, àláfíà, àti àwọn ẹ̀bùn tí ó ńwá nípa ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì.

Àwọn míràn lè sọ pé, “Èmi kò wà ní ìbámu pẹ̀lú yín nínú Ìjọ.

Tí ó bá lè rí inú ọkàn wa, bóyá ìwọ yíò ri pé o wà ní ìbámu dáradára jù bí ó ti rò lọ. O lè yà ọ́ lẹ́nu láti rĩ pé a ní àwọn ìpòngbẹ àti ìgbìyànjú àti ìrètí tí ó fi ara pẹ́ tìrẹ. Àyíká yín tàbí bí a ṣe tọ́ọ yín dàgbà lè dàbí ẹnipé ó yàtọ̀ sí ohun tí ẹ le rí nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà ìkẹhìn, ṣùgbọ́n èyĩnì lè jẹ́ ìbùkún kan. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, a nílò àwọn àra ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn àmútọ̀runwá yín àti àwọn ìwòye yín. Yíyàtọ̀ ti àwọn olukúlùkù ati awọn ọ̀wọ́ ènìyàn kákiri gbogbo àgbáyé jẹ́ agbára kan ti ìjọ yí.

Àwọn míràn lè sọ pé, “èmi kò rò pé mo lè gbé ìgbé ayé òsùnwọ̀n yín .

Gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìdí sĩ láti wá! Ìjọ náà jẹ́ piperò lati tọ́jú aláìpé, onítiraka, àti aláárẹ̀. Ó kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn láti pa àwọn òfin mọ́, pàápàá tí wọn kò bá tíì mọ̀ wọ̀n tán dáadáa síbẹ̀síbẹ̀.

Àwọn kan lè sọ pé, “mo mọ ọmọ ìjọ yín kan tó jẹ́ alábòsí. Èmi kò lè darapọ̀ mọ́ ìjọ kankan láéláé tí ó ní ẹnìkan bíi tirẹ̀ ní ọmọ ìjọ .

Tí o bá túmọ̀ alábòsí bí ẹnìkan tí ó kùnà láti gbé ìgbé ayé pípé sí ohun tí óun lọkùnrin tàbí lobìnrin gbàgbọ́, nígbànáà gbogbo wa la jẹ́ alábòsí. Kòsí ìkankan lára wa tí ó dàbí Krísti bí a ṣe mọ̀ pé ó yẹ kí á jẹ́. Ṣùgbọ́n a ńfi ìtara nífẹ́ láti borí àwọn ẹ̀bi wa àti ìdarísí láti dá ẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lú ọkàn wa àti iyè inú à ńpòngbẹ láti di dídárasĩ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ètùtù ti Jésù Krístì.

Bí àwọn wọ̀nyí bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ, nígbànáà láìka àwọn ipò rẹ sí, ìtàn ara rẹ, tàbí agbára ti ẹ̀rí rẹ, àyè wà fún ọ nínú Ìjọ yí. Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa!

Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa!

Pẹ̀lú àwọn àìpé ènìyàn tiwa, mo ní ìdánilójú pé ìwọ yíò rí láárín àwọn ọmọ ìjọ yí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkàn tí ó dára jù tí ayé yí ní lati fúnni Ìjọ Jésù Krístì dàbí ẹnipé ó ńṣe ìfàmọ́ra ònínú rere àti olùtọ́jú, olóótọ́ àti aláápọn.

Bí o bá ńretí láti rí ènìyàn pípé níbí, ìwọ yíò ní ìjákulẹ̀. Ṣùgbọ́n tí o bá ńwá ẹ̀kọ́ àìlábàwọ́n ti Krístì, ọ̀rọ̀ ti Ọlọ́run èyí tí ó ńwo ọgbẹ́ ọkàn sàn”9 àti agbára ìyàsímímọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, nígbà náà níhín ni ìwọ yíò rí wọn. Ní àsìkò yí ti ìgbàgbọ́ ńdínkù —ní àsìkò yí tí ọ̀pọ̀ ńní ìmọ̀lára jíjìnà kúrò ní gbígbàmọ́ra ti ọ̀run—níbíyĩ ìwọ ó rí awọn ènìyàn tí ó ń pòngbẹ láti mọ̀ àti láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wọn nípa sísin Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn, bíi tirẹ. Wá, darapọ̀ pẹ̀lú wa!

Ṣé Ẹ̀yin Yíò Lọ Bákannáà

A ránmi létí ìgbà kan ní ìgbé ayé Olùgbàlà nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ pa Á tì.10 Jésù bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ méjìlá:

Ṣé ẹyin yíò lọ bákannáà?

“Nígbànáà Símónì Pétérù dã lóhùn pé, Olúwa, ọ̀dọ̀ tani kí àwa lọ? ìwọ ní ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé.”11

Àwọn ìgbà míràn wà nígbàtí a níláti dáhùn ìbèèrè kannáà. Njẹ́ a ó lọ bákannáà? Tàbí àwa, bíi Pétérù, yíó di àwọn ọ̀rọ̀ ti ìyè ayérayé mú gidigidi?

Bí o bá ńwá òtítọ́, ìtumọ̀, àti ọ̀nà kan láti yí ìgbàgbọ́ padà sí ìṣe; bí o bá ńwá ibìkan láti jẹ́ àjùmọ̀ kẹ́gbẹ́: Wá, darapọ̀ pẹ̀lú wa!

Bí o bá ti fi ìgbàgbọ́ tí o ti fi ìgbàkan gba mọ́ra sílẹ̀: Padà wá lẹ́ẹ̀kansi. Darapọ̀ pẹ̀lú wa!

Bí o bá ńgbìdánwò láti jọ̀wọ́ ara rẹ sílẹ̀:. Dúró síbẹ̀ díẹ̀ si. Àyè wà fún ọ níbí.

Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó gbọ́ tàbí ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Wa, darapọ̀ pẹ̀lú wa. Wá gbọ́ ìpè ti Krístì onírẹ̀lẹ̀. Gbé àgbélèbú rẹ kí o sì tẹ̀lé E.12

Wá, darapọ̀ pẹ̀lú wá! Nítorí níbí iwọ ó rí ohun tí ó níyelorí ju iye owó lọ.

Mo jẹ́rí pé níbí ẹ ó rí àwọn ọ̀rọ̀ ti ìyè ayérayé, ìlérí ti ìbùkún ìràpadà, àti ọ̀nà tí ó lọ sí àláfíà àti ìdùnnú.

Mo fi tọkàntọkàn gbàdúrà pé kí wíwákiri tiyín fún òtítọ́ lè tẹ̀ àmì sí orí ọkàn yín ti ìfẹ́ láti wá kí ẹ sì dara pọ̀ pẹ̀lú wa. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín