2013
Njẹ́ Mo Le Pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì?
December 2013


Ọ̀dọ́

Njẹ́ Mo Le Pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì?

Olùkọ̀wé náà ń gbé ni Washington, USA.

Ní ọdún àkọ́kọ́ mi ní ilé ìwé gíga, olùkọ́ sẹ́mínírì mi pe kíláàsì mi lati fi awọn Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún awọn ọ̀rẹ́ ti wọn kìí ṣe ọmọ ìjọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mã ń tijú púpọ̀, síbẹ̀ mo tẹ́wọ́gba ìpè nã.

Ó gbà mi ní awọn ọjọ́ díẹ̀ lati le ṣe ìgboyà, ṣugbọ́n ní ìkẹhìn mo fun ọ̀rẹ́ mi Britny ní ìwé nã ní àsìkò ounjẹ ọ̀sán mo sì jẹ́ ẹ̀rí ní ṣókí. Britny dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún ìwé nã.

Ní ìparí ọdún ní ilé ìwé nã, Britny kó kúrò, ṣugbọ́n a máa ń kàn sí ara wa, Ó sọ fun mi nipa ilé ìwé rẹ̀ tuntun ati bí ó ṣe fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ, ṣugbọn kò sọ̀rọ̀ nipa ohun ti ẹ̀mí pẹ̀lú mi rí.

Eléyìí yípadà kí n tó lọ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, Mo gba iṣẹ́ rírán kan lati ọdọ̀ Britny tí ó sọ pé oun ní ìròhìn títóbi kan fun mi: ó ti ńlọ ṣe ìrìbọmí, ó sì fẹ́ lati dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún jíjẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati fífi àpẹrẹ rere lélẹ̀.

Ọlọ́run mú onítìjú ọmọdékùnrin ẹni ọdún mẹ̃dogun kan tí kò ní ìrírí iṣẹ́ ìrànṣẹ́ rárá ó sì darí rẹ̀ lati pín ìhìnrere pẹ̀lú ẹnikan tí Ó mọ̀ pé yío tẹ́wọ́ gbà á. Mo mọ̀ pé nípa fífi etí sílẹ̀ sí Ẹ̀mí nã, gbogbo wa lè ṣe àwárí awọn èniyàn ní àyíká wa tí wọ́n ń dúró lati mọ̀ nipa ìhìnrere tí a mú padà bọ̀ sípò nã. Mo mọ̀ pé bí a bá ṣe ìrànwọ́ lati mú àní ẹnìkan wá sí ọ̀dọ̀ Oluwa, “bawo ni ayọ̀ [wa] yío ṣe tóbi tó pẹ̀lú ọkùnrin [tabi obìnrin] nã ní ìjọba ti Baba [wa]!” (D&C 18:15).