2014
Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Àpẹrẹ
Oṣù Kínní Ọdún 2014


Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kìnní 2014

Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Àpẹrẹ

Ẹ fi tàdúrà tàdúrà ṣe àṣàrò iṣẹ́ yìí kí ẹ sì wá lati mọ̀ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbé ayé ati iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Olùgbàlà ti ṣe àlékún ìgbàgbọ́ yin nínú Rẹ̀ ati bùkún awọn tí ẹ̀yin ń bójútó nípasẹ̀ ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org

Bí ó ṣe ń yéwa pé Jésù Krístì jẹ́ àpẹrẹ fún wa nínú ohun gbogbo, a lè ṣe àlékún ìfẹ́ wa lati tẹ̀lé E. Awọn ìwé mímọ́ kún fún ìgbaniníyànjú fún wa lati tẹ̀lé awọn ipa ẹsẹ̀ ti Krístì. Sí awọn ará Nífáì, Krístì sọ, “Nítorípé awọn iṣẹ́ tí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe, òun ni kí ẹ̀yin ó máa ṣe pẹ̀lú” (3 Nífáì 27:21). Sí Thomas, Jésù sọ, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ mi” (Jòhánù 14:6).

Lónìí awọn olùdarí wa ń rán wa létí lati gbé Olùgbàlà wa kalẹ̀ bíi àpẹrẹ wa. Linda K. Burton, ààrẹ gbogbogbòò ti Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́, sọ, “Nigbati olukúlùkù wa bá ní ẹ̀kọ́ nipa Ètùtù náà ní kíkọ jinlẹ̀ nínú awọn ọkàn wa, nigbanáà ni a ó bẹ̀rẹ̀ síi dàbí irú awọn ènìyàn ti Olúwa fẹ́ kí á jẹ́.”1

Ààrẹ Thomas S. Monson sọ, “Oluwa ati Olùgbàla wa, Jésù Krístì, ni Àpẹrẹ ati okun wa.”2

Ẹ jẹkí a pinnu lati súnmọ́ Jésù Krístì, lati gbọ́ràn sí awọn òfin Rẹ̀, ati lati sa ipa wa láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run.

Láti Àwọn ìwé Mímọ́

2 Nífáì 31:16; Álmà 17:11; 3 Nífáì 27:27; Mórónì 7:48

Láti inu Ìtàn Wa

“Ó ṣe àmì ipa ọ̀nà ó sì ṣãjú ní ọ̀na náà,” Eliza R. Snow kọ, olùdarí gbogbogbòò kejì ti Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́, nipa iṣẹ́ ìránṣẹ ti Jésù Krístì nínú ara.3 Ó bomirin olukúlùkù — ní ẹni kọ̀ọ̀kan. Ó kọni pé a nílati fi awọn àádọ́rùn ati mẹ́sàn sílẹ̀ lati gba ẹyọ kan ti ó sáko là (rí Lúkù 15:3–7). Ó wòsàn Ó sì kọ́ awọn olukúlùkù ní ẹ̀kọ́, àní ní fífi ààyè sílẹ̀ fún ẹni kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ èrò ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ ènìyàn (rí 3 Nífáì 11:13–15; 17:25).

Nipa awọn obìnrin Mímọ́ ti Ọjọ́ Ìkẹhìn, Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf, Olùdámọ̀ràn Kejì Nínú Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, sọ: “Ẹ̀yin arábìnrin tí ó kún fún ìyanu ńṣe iṣẹ́ ìsìn àánú sí awọn ẹlòmíràn fún awọn èrèdí tí ó kọjá ìfẹ́ fún ànfãaní ti ara ẹni. Nínú èyí ẹ ńṣe bíi Olùgbàlà. … Awọn ìrònú Rẹ̀ nígbà gbogbo mã nyí sí lati ràn awọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.”4

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Linda K. Burton, “Njẹ́ a kọ Ìgbàgbọ́ nínú Ètùtù ti Jésù Krístì sí inú Àwọn Ọkàn Wa?” Ensign or Liahona, Nov. 2012, 114.

  2. Thomas S. Monson, “Pípàdé Awọn Ìpèníjà Ìgbé Ayé,” Ensign, Nov. 1993, 71.

  3. “Ọgbọ́n ati Ìfẹ́ náà ti Tóbi Tó,” Hymns, no. 195.

  4. Dieter F. Uchtdorf, “Ìdùnnú, Ogún Yín,” Ensign or Liahona, Nov. 2008, 120.