2014
Sin Olúwa pẹ̀lú Ìfẹ́
Oṣù Kejì Ọdún 2013


Ọ̀rọ̀ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kejì Ọdún 2014

Sin Olúwa pẹ̀lú Ìfẹ́

Àwòrán
Ààrẹ Thomas S. Monson

Olúwa Jésù Krístì ti kọ́ pé, “Ẹnikẹ́ni tí yíò bá gba ẹ̀mí rẹ̀ là yíò sọọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí yíò bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yíò sì gbàá là.” (Luke 9:24).

“Mo gbàgbọ́,” ni Ààrẹ Thomas S. Monson sọ, “Olùgbàlà ńsọ fún wa pé láì jẹ́ pé a sọ ara wa nù nínú iṣẹ́ ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn, èrò díẹ̀ ni ó wà fún ẹ̀mí ti ara wa. Àwọn tí ó gbé fún ara wọn nìkan nígbẹ̀hìn kákò sókè, àti pé ní àpẹrẹ wọ́n sọ ẹ̀mí ara wọn nù, nígbàtí àwọn tó sọ ara wọn nù nínú iṣẹ́ ìsìn ńdàgbà tí wọ́n sì ńgbèrú si— àti pé ní ìyọrísí wọ́n gba ẹ̀mí wọn là.”1

Nínú àwọn ìyọkúrò látinú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Ààrẹ Monson, ó rán àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn léti pé àwọn ni olùgbọ̀wọ́ ti Olúwa àti pé àwọn ìbùkún ti ayérayé ńdúró de àwọn wọnnì tó sin àwọn ẹlòmíràn lódodo.

Iṣẹ́ Ìsìn nínú Tẹmpìlì

“Iṣẹ́ ìsìn ńlá ni a fúnni nígbàtí a bá ṣe àwọn ìlànà dípò ẹlòmíràn tó ti kú. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbà a kìí mọ àwọn wọnnì fún ẹni tí a ṣiṣẹ́ náà fún. A kò retí ọpẹ́ kankan, tàbí kí a ní ìdánilójú pé wọn yíò gba eyíinì tí a fún wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, à ńsìn, àti pé ní ọ̀nà náà à ńdé ibi èyí tí ó ńwá nípa àìní ìgbìyànjú míràn rárá: Níti ẹ̀kọ́ à ńdi àwọn Olùgbàlà lórí òkè Síónì. Gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ṣe fi ẹ̀mí Rẹ̀ sílẹ̀ bí ìrúbọ kan dípò ẹlòmíràn fún wa, bẹ́ẹ̀ni àwa, ní àwọn ìdiwọ̀n kékèké, ńṣe bákannáà nígbàtí à ńṣe iṣẹ́ ìdúrófún ní tẹ́mpìlì fún àwọn wọnnì tí kò ní ọ̀nà rírìn síwájú kankan láì jẹ́ pé wọ́n bá ṣe ohunkan fún wọn nípa àwa wọnnì níbí lórí ilẹ̀.”2

Olùgbọ̀wọ́ Ti Olúwa Ni a jẹ́

“Ẹ̀yin arákùnrin mi àti ẹ̀yin arábìnrin, àwọn tí ó nílò ìfojúsí wa ni ó yí wa ká, ìgbàniníyànjú wa, àtìlẹ́hìn wa, ìtùnú wa, inúrere wa, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ojúlùmọ̀, tàbí àwọn àlejò. Olùgbọ̀wọ́ ti Olúwa ni a jẹ́ níbí lórí ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú àṣẹ láti sìn àti láti gbé àwọn ọmọ Rẹ̀ sókè. Ó nígbẹ́kẹ̀lé lórí ìkọ̀ọ̀kan lára wa. …

Iṣẹ́ ìsìn náà èyítí a ti pe gbogbo wa sí ni iṣẹ́ ìsìn ti Olúwa Jésù Krístì.3

Sísìn nínú òjijì ti Olùgbàlà

“Nínú ayé tuntun, àjíìnde Olùgbàlà ti kéde, ‘Ẹ̀yin mọ àwọn ohun tí ẹ̀yin ní láti ṣe nínú Ìjọ mi; nítorí àwọn ohun èyí tí ẹ̀yin tí rí tí èmi ṣe, òun ní kí ẹ̀yin ó ṣe pẹ̀lú; nítorí ohun tí ẹ̀yin tí rí tí èmi ṣe òun pàápàá ní kí ẹ̀yin ó ṣe’ [3 Nephi 27:21].

“À ńbùkún àwọn ẹlòmíràn bí a ṣe ńsìn nínú òjìji ti Jésù ti Názárẹ́tì … ẹni tí ó ńkiri ṣe oore’ [Acts 10:38]. Ọlọ́run bùkún wa láti rí ayọ̀ ní sísin Bàbá wa ní ọ̀run bí a ṣe ńsin àwọn ọmọ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”4

A nílò láti Sìn

“A nílò láti gba ìfúnni láyè kan láti sìn. Fún àwọn ọmọ ìjọ tí ó ti yọ̀ kúrò ní aápọn tàbí tí ó dáwọ́ dúró àti pé tí ó dúrósí àìfarasìn, a lè fi tàdúràtàdúrà ṣe àwàrí fún àwọn ọ̀nà láti dé ọ̀dọ̀ wọn. Bíbèèrè pé kí wọ́n sìn ní àwọn agbára díẹ̀ lè jẹ́ ìṣínilórí gan an tí wọ́n nílò láti padà sí aápọn kíkún. Ṣùgbọ́n àwọn olórí tí ó lè ṣèrànwọ́ ní ìkàsí yí máa ńfìgbàmíràn lọ́ra láti ṣe bẹ́ẹ̀. A nílò láti ní ìfaradà nínú ọkàn wa pé ènìyàn lè yípadà. Wọ́n lè gbé àwọn ìwà burúkú wọn ti sẹ́hìn. Wọ́n lè ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ìwà ìrékọjá wọn. Wọ́n lè nífaradà yíyẹ fún oyè àlùfáà. Àti pé wọ́n lè fi taratara sin Olúwa.”5

Njẹ́ À Nṣe Gbogbo Ohun tó yẹ káṣe?

“Ayé wà nílò ìrànlọ́wọ́ ti wa. Njẹ́ À Nṣe Gbogbo Ohun tó yẹ káṣe? Njẹ́ a rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti Ààrẹ John Taylor: ‘Tí a kò bá ṣe ìgbéga àwọn ìpè wa, Ọlọ́run yíò mú wa dáhùn fún àwọn wọ̀nnì tí àwa ìbá ti gbàlà, kání a ṣe ojúṣe wa”? Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Olùdarí Àgbà ti Ìjọ: John Taylor Àwọn ẹsẹ̀ wà láti múdúró, àwọn ọwọ́ láti dìmú, àwọn iyè inú láti gbàníyànjú, àwọn ọkàn láti ní ìmísí, àwọn ẹ̀mí láti gbàlà. Àwọn ìbùkún ti ayérayé ńdúró dè ọ́ Tìrẹ ni ànfàní náà láti máṣe jẹ́ àwọn olùwòran ṣùgbọ́n àwọn olùṣe lórí ìtàgé ti iṣẹ́ ìsìn.”6

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. “Kíni Mo Ti Ṣe Fún Ẹ̀nìkan Lóní?” Liahona, Nov. 2009, 85

  2. Títí Tí A Ó Fi Pàdé Lẹ́ẹ̀kan Si,” Liahona, May 2009, 113–14

  3. “Kíni Mo Ti Ṣe Fún Ẹ̀nìkan Lóní?” 86, 87.

  4. “Ìpè Ti Olùgbàlà Láti Sìn,” Liahona, Aug. 2012, 5.

  5. “Rí Àwọn Míràn bí Wọ́n Ṣe Lè Dà,” Liahona, Nov. 2012, 68.

  6. “Nínífẹ́ àti Yíyẹ Láti Sìn,” Liahona, May 2012, 69.

  7. Kíkọ́, Kò sí Ìpè Tó Tóbi Jù: Orísun Ìtọ́sọ́nà kan Fún Kíkọ́ Ìhìnrere (1999), 12

Ìdánilẹ́kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Yìí

“Tí o bá ní ìfẹ́ bíi Krístì, ìwọ yíò ti múràsílẹ̀ dáadáa láti kọ́ ìhìnrere. Ìwọ yíò ní ìmísí láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ láti mọ Olùgbàlà àti láti tẹ̀lé E.7 Gbèrò gbígbàdúrà fún pípọ̀si ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ fún àwọn tí ò ńbẹ̀wò. Bí o ṣe ńgbèrú si ní ìfẹ́ bíi Krístì fún wọn, ìwọ yíò lè sìn dáadáa si ní àwọn ọ̀nà tó nítumọ̀ sí Olúwa àti sí àwọn tí ò ńkọ́ bákannáà.