2014
Iṣẹ́ Ìsìn àti ayé àìnípẹ̀kun
Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2014


Ọ̀rọ̀ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kẹ́ta Ọdún 2014

Iṣẹ́ Ìsìn àti ayé àìnípekun

Àwòrán
Ààrẹ Henry B. Eyring

Olùgbàlà jẹ́ àpẹrẹ wa fún iṣẹ́ ìsìn àìmọtaraẹni nìkan. Ayé pípé Rẹ̀ ti jẹ́ ìyàsímímọ́ sí sísin Bàbá Ọ̀run àti gbogbo àwọn ọmọ ti Bàbá Rẹ̀. Ètò ìdàpọ̀ ti Bàbá àti Ọmọkùnrin náà ni láti fún gbogbo wa ní ẹ̀bùn ti àìkú àti ìbùkún ti ayé àìnìpẹ̀kun (rí Moses 1:39).

Láti yẹ fún ayérayé, a gbọ́dọ̀ di yíyípadà nínú ètùtù ti Krístì — di àtúnbí àti ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ọmọ kékeré lábẹ́ ọjọ́ orí ọdún mẹ́jọ, bákannáà, wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ àti pé wọ́n ní ìràpadà nínú Ètùtù (rí Mosiah 3:16, 21; Moroni 8:10–12).

Fún gbogbo wa tí ó ti dé ọjọ́ orí dídáhùn fún, ètò ìyanu kan wà tí ó fàyè gbà wá láti ní ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti láti múrasílẹ̀ fún ayé àìnípẹ̀kun. Mímúrasílẹ̀ náà ńbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrìbọmi nípasẹ̀ àṣẹ oyè àlùfáà àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbànáà a gbọ́dọ̀ máa rántí Olùgbàlà nígbàgbogbo àti pé kí a pa àwọn òfin tí Ó ti fún wa mọ́.

Ọba Bẹ́njámínì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ìwé Mọ́mọ́nì ti ayọ̀ tó ńwà látinú ìmọ̀lára ìdáríjì kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nípa Ètùtù ti Jésù Krístì. Nígbànáà ó kọ́ wọn pé láti mú ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn dúró, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn láti sin ara wọn àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ láti bá ìlò ara àti ẹ̀mí àwọn tí ó yí wọn ká mu. (rí Mosiah 4:11–16).

Ó kọ́ bákannáà, “Àti pé kíyèsíi, mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún yín pé kí ẹ̀yin lè kọ́ ọgbọ́n; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ wípé bí ẹ̀yin bá wà nínú iṣẹ́ ìsìn arákùnrin yín, inú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin ṣáà wà”(Mosiah 2:17).

Jésù ńkiri ní kíkọ́ ìhìnrere Rẹ̀ àti ṣíṣe rere (rí Acts 10:38). Ó mú aláìsàn lára dá Ó jí òkú dìde. Pẹ̀lú agbára Rẹ̀ Ó bọ́ ẹgbẹgbẹ̀rún nígbàtí ebi ńpa wọ́n àti pé láìsí oúnjẹ (rí Matthew 14:14–21; John 6:2–13). Lẹ́hìn Àjíìnde Rẹ̀, Ó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn Àpọ́stélì Rẹ̀ ní oúnjẹ bí wọ́n ṣe wá sí èbúté ní etí òkun ti Gálílì (rí John 21:12–13). Ní àwọn Amẹ́ríkà, Ó mú aláìsàn lára dá, Ó sì bùkún àwọn ọmọdé ní ìkọ̀ọ̀kan. (rí 3 Nephi 17:7–9, 21).

Jákọ́bù àpọ́stélì kọ́ wa bí ìfẹ́ láti sin àwọn ẹlòmíran ṣe ńjáde látinú ìmoore wa fún ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa:

Ṣùgbọ́n ẹnití ó bá ńwo inú òfin pípé, òfin òmìnira nì, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò jẹ́ olùgbọ́ tó ńgbàgbé, bíkòṣe olùṣe iṣẹ́, olúwarẹ̀ yíò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

Ìsìn mímọ́ àti àìléérí níwájú Ọlọ́run àti Bàbá ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìníbaba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara wọn mọ́ láìlábàwọ́n kúrò ní ayé”.

Ọ̀kan lára àwọn ìdánilójú pé ò ńní ìyàsímímọ́ ni àlékún ìfẹ́ kan láti sin àwọn ẹlòmíràn fún Olùgbàlà. Kíkọ́ni Ilé àti Abẹniwò Kíkọ́ni ńdi ohun ayọ̀ si àti dídínkù ti iṣẹ́. Òó rí ara rẹ ní íyọ̀ọ̀dà léraléra si ní ilé ìwé ibì kan tàbí ṣíṣèrànlọ́wọ́ ìtọ́jú fún aláìní ní agbègbè rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé o lè ní owó kékeré láti fún àwọn wọnnì tí kò ní púpọ̀, ìwọ rò pé kí o ní púpọ̀ síi kí o lè fún wọn ní púpọ̀ síi (rí Mosiah 4:24). O rí ara rẹ nítara láti sin àwọn ọmọ rẹ àti láti fi hàn wọ́n bí wọ́n ó ṣe sin àwọn ẹlòmíràn.

Bí ìwà ẹ̀dá rẹ ṣe ńyípadà, ìwọ yíò ní ìmọ̀lára ìfẹ́ láti fúnni ní iṣẹ́ ìsìn tó tóbi jùlọ láìsí ìkàsí. Mo mọ àwọn ọmọ ẹ̀hìn Olùgbàlà tí ó ti fi àwọn ẹ̀bùn ńlá ti owó àti iṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú ìpinnu kan pé kò sí ẹnìkan ṣùgbọ́n Ọlọ́run àti àwọn ọmọ wọn ni yíò mọ̀ nípa rẹ̀. Ọlọ́run ti ka iṣẹ́ ìsìn wọn sí nípa bíbùkún wọn ní ayé yí, àti pé Òun yíò bùkún wọn ní ayé àìnípẹ̀kun tó ńbọ̀ (rí Matthew 6:1–4; 3 Nephi 13:1–4).

Bí ìwọ ti ṣe ńpa òfin mọ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn (rí Matthew 22:39), ìwọ ti ní ìmọ̀lára ti ìyípadà kan ní mímọ̀lára ti ìgbéraga rẹ. Olùgbàlà bá àwọn Àpọ́stélì Rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ní asọ̀ nípa ẹnití yíò jẹ́ títóbi jùlọ̀ láárín wọn. Ó sọ:

Kí a má sì ṣe pè yín ní olùkọ́ni, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, àní Krístì.

“Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, Òun ni yíò jẹ́ ìrànṣẹ́ yín.” (Matthew 23:10–11).

Olùgbàlà náà ti kọ́ wa bí a ṣe lè kọ́ láti sin àwọn ẹlòmíràn. Ó sìn ní pípé, a sì gbọ́dọ̀ kọ́ láti sìn bí Ó ṣe kọ́—ẹsẹ lórí ẹsẹ (rí D&C 93:12–13). Nínú iṣẹ́ ìsìn tí a fúnni, a lè dàbíi Tirẹ̀ síi. A ó gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo agbára ti ọkàn wa láti fẹ́ àwọn ọ̀tá wa bí Ó ṣe nífẹ́ wọn (rí Matthew 5:43–44; Moroni 7:48). Nígbànáà, nígbẹ̀hìn, a lè di bíbámu fún ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Rẹ̀ àti Bàbá wa Ọ̀run.

Mo ṣèlérí pé a lè wá láti sin ní pípé si bí a ṣe ńtẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ ti Olùgbàlà àti àpẹrẹ.

Ìdánilẹ́kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Yìí

Alàgbà M. Russell Ballard ti Àpapọ̀ Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ti gbà wá níyànjú láti gbàdúrà fún ààyè láti sìn: “Nínú àdúrà rẹ ní ọjọ́ tuntun kọ̀ọ̀kan, bèèrè lọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run láti tọ́ọ sọ́nà láti ní ìkàsí ààyè kan láti sin ìkan lára àwọn ojúlówó ọmọ Rẹ̀. Nígbànáà lọ káàkiri ọjọ́ náà … wíwò fún ẹnìkan láti rànlọ́wọ́” (“Fi Taratara gbà síṣẹ́,” Ensign or Liahona, Nov. 2012, 31). Gbèrò pípe àwọn wọnnì tí ò ńkọ́ láti gbé ètò gbígbàdúrà kalẹ̀ láràárọ̀ fún àwọn àyè láti sìn àti pé nígbànáà láti ṣàwárí wọn káàkiri ọjọ́ náà.