2016
Àwọn Ọmọbìrin ti Bàbá Wa Ayérayé
OṢù Ìgbé 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, oṣù Kẹ́rin ọdún 2016

Àwọn Ọmọbìrin ti Bàbá Wa Ayérayé

Fitàdúràtàdúràkaohunèlòyĩkíosìwákirilatimọohuntiõṣeàbápínrẹ Báwo ni níní óye “Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo Ayé yíò ṣe mú kí ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ tó àti láti bùkún àwọn wọnnì tí ọ nṣe ìṣọ́ lé lórí nípa ìbẹniwò kíkọ́ni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Àwòrán
Èdidì Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́

Ìgbàgbọ́, Ẹbí, Ìrànlọ́wọ́

Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ wa pé “a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run” (Acts 17:29). Ọlọ́run tọ́ka sí Emma Smith, ìyàwó Wòlíì Joseph Smith, bíi ọmọbìnrin mi (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:1). Ìkéde ẹbí náà kọ́ wá pé ẹnìkọ̀ọ̀kàn wa jẹ́ olùfẹ́ ẹ̀mí kan … ọmọbìnrin ti àwọn òbí ọ̀run.”1

“Ní ijọba [ṣíwájú ayé ikú] a kọ́ nípa ìdánimọ̀ ayérayé wa bíi obínrin,” ni Carole M. Stephens sọ, olùdámọ̀ràn kínní nínú àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ gbogbogbòò.

“Ìrìnàjò ara ikú wa sí orí ilẹ̀ ayé kò yí àwọn òtítọ́ wọnnì padà.”2

“Bàbá yín ní Ọ̀run mọ orúkọ yín Ó sì mọ̀ ipò yín,” ni Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. “Ó ngbọ́ àdúrà yín. Ó mọ àwọn ìrètí àti àlá yín, pẹ̀lú àwọn ẹ̀rù yín àti àwọn ìdènà.”3

“Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ti àti pé a nílò wa nínú ẹbí Ọlọ́run,” ni Arábìnrin Stephens sọ. “Gbogbo àwọn Ẹbí ti ayé ni wọ́n yàtọ̀ síra. Ati pè nígbàtí a bá ṣe gbogbo bí a tí lè ṣe tó láti ṣe ìdásílẹ̀ àwọn ẹbí tí ó bá àṣà mu gidi, jíjẹ́ ọmọlẹ́bí nínú ẹbí ti Ọlọ́run kò dá lé órí irú ipò kankan—ipò lọ́kọláya, ipò ṣíṣe òbí, ipò ìṣúna owó, ipò ìbákẹ́gbẹ́, tàbí àní irú ipòkípò tí a lè gbé sí ìròhìn ìbákẹ́gbẹ́4

ÀfikúnÀwọnÌwéMímọ

Jeremiah 1:5; Romans 8:16; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:23-24

LátiinúÌwéÌtànWa

Nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa Ìran Àkọ́kọ́,5 Wòlíì Joseph Smith fi ẹsẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ múlẹ̀—nínú rẹ̀ ni pé Baba wa Ọ̀run mọ orúkọ wa.

Ọ̀dọ́ Joseph tiraka lati mọ ìjọ ti yío darapọ̀ mọ́ ó sì rí ìtọ́ni ninu Jákọ́bù 1:5. Jósẹ́fù pinnu pé òun ó bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.

Ní òwúrọ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan ní 1820, ó lọ sí inú oko igi lati gbàdúrà ṣùgbọ́n lójúẹsẹ̀ awọn agbára òkùnkùn kan dìí mú. Nípa èyí ó kọ pé:

“Ní àsìkò ẹ̀rù nlá yí gan an, mo rí òpó ìmọ́lẹ̀ kan ní ọ̀gangan òkè orí mi, tí ó ju dídán ìtànṣán oòrùn lọ, èyí tí ó nsọ̀ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi bà lé mi lórí.

“Kò pẹ́ tí ó farahàn ni mo rí ìgbàlà ara mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tà èyí tí ó dì mi mú ní ìgbèkùn. Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ náà sinmi lé mi lórí mo rí àwọn Ẹni Nlá méjì, àwọn ẹnití ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn ju gbogbo àpèjúwe, wọ́n ndúró ní òkè orí mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kàn lára wọn sọ̀rọ̀ sí mi, ó pè mí ní orúkọ ó sì sọ pé, ní nínawọ́ sí ẹnìkejì—Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. GbọỌ! (Joseph Smith—History 1:16–17).

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ẹbí Náà Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé, Liahona, Nov. 2010, 129.

  2. Carole M. Stephens, Ẹbí Jẹ́ ti Ọlọ́run, Liahona, May 2015, 11.

  3. Ìkéde kan sí Gbogbo Ayé, Liahona, Nov. 2005, 28.

  4. Carole M. Stephens, Ẹbí Jẹ́ ti Ọlọ́run, Liahona, May 2015, 11.

  5. Wo Àwọn Àkọlé Ìhìnrere, “Àkọsílẹ̀ Ìran Àkọ́kọ́,” topics.lds.org.

GbèròÈyí

Báwo ni mímọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọbìnrin ti Ọlọ́run ṣe nní ipá lórí ìpinnu yín?