2016
Àwọn àṣàyàn
OṢù Ẹ̀bibi 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kárún Ọdún 2016

Àwọn àṣàyàn

Njẹ́ láé kí a le máa yan èyítí ó tọ́ tí ó le jù, dípò àṣìṣe tí ó rọrùn jù.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, kí ntó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi bí ìṣe lóní, mo máa fẹ́ràn láti kéde àwọn tẹ́mpìlì mẹ́rin titun èyí tí, nínú àwọn oṣù àti àwọn ọdún tí ó nbọ̀, a ó kọ́ wọn ní àwọn ibi wọ̀nyí: Quito, Ecuador; Harare, Zimbabwe; Belém, Brazil; àti tẹ́mpìlì kejì ní Lima, Peru.

Nígbàtí mo di ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ní 1963, àwọn tẹ́mpìlì méjìlá ni ó nṣiṣẹ́ ní gbogbo Ìjọ. Pẹ̀lú ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì ti Ìlú Nlá Provo Center ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́hìn, àwọn tẹ́mpìlì ogóje ó lé mẹ́wàá ni ó nṣiṣẹ́ káàkiri àgbáyé. Ìmoore wa ha ṣe pọ̀ tó fún àwọn ìbùkún tí a ngbà ní àwọn ilé mímọ́ wọ̀nyí.

Nísisìnyí, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo fẹ́ fi ìmòore mi hàn fún ànfàní láti pín àwọn èrò díẹ̀ pẹ̀lú yín ní àárọ̀ yí.

Mo ti nronú láìpẹ́ nípa àwọn àṣàyàn. Ó ti di sísọ pé ilẹ̀kùn ìwé ìtàn ńyí lórí àwọn igun kékèèké àti pé bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbé ayé àwọn ènìyàn. Àwọn Àṣàyàn tí à nṣe npinnu àyànmọ́ ìpín wa.

Nígbàtí a kúrò ní ayé ẹ̀mí tí a wọ ayé ikú, a mú ẹ̀bùn agbára láti yàn wá pẹ̀lú wa. Òpin ìje wa ni láti gba ògo sẹ̀lẹ́stíà, àti pé àwọn àṣàyàn tí à nṣe yíò pinnu, ní apákan nlá, bóyá a ó tàbí a kò ní dé òpin ìje wa.

Púpọ̀ jù lára yín mọ nípa Alice nínú ìwé ìtàn onítumọ̀ ti Lewis Carrol àwọn Ìdáwọ́lé ti Alice ní Ilẹ̀ ìyanu Ẹ ó rántí pé ó wá sí ìkóríta kan pẹ̀lú àwọn ipa ọ̀nà méjì níwájú rẹ̀, ìkọ̀ọ̀kan ní nínà síwájú ṣùgbọ́n ní ọ̀nà tí ó kọjú sí òdìkejì. Bí ó ṣe ngbèrò ọ̀nà èyí tí òun yíò yípadà sí, ológbò Chesshire pè é níjà, ẹnití Alice bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ipa èwo ni kí èmí ó tẹ̀lé?”

Ológbò náà dáhùn, “Èyíinì dá lórí ibi tí o fẹ́ lọ. Bí o kò bá mọ ibi tí o fẹ́ lọ, kò jẹ́ nkankan ipá ọ̀nà yówù kí o gbà.”1

Yàtọ̀ sí Alice, a mọ̀ ibi tí a fẹ́ lọ, ó sì jẹ́ nkan ipa ọ̀nà èyí tí a bá lọ, nítorí ipá ọ̀nà tí a bá tẹ̀lé ní ayé yí ndarí sí ibùdó wa ní ayé tí nbọ̀.

Njẹ́ kí a lè yàn láti kọ́ ìgbàgbọ́ nlá àti alágbára kan sí inú ara wa èyí tí yíò jẹ́ ààbò wa tí ó dára jùlọ ní ìdojúkọ àwọn ète ti ọ̀tá—ìgbàgbọ́ tòótọ́, irú ìgbàgbọ́ èyí tí yíò mú wa dúró tí yíò ṣe àtìlẹhìn fún ìfẹ́ inú wa láti yan èyí tí ó tọ́. Láìsí irú ìgbàgbọ́ náà, a kò lọ sí ibì kankan. Pẹ̀lú rẹ̀, a lè ṣe àṣeparí àwọn òpin ìje wa.

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí a máa yàn pẹ̀lú ọgbọ́n, àwọn ìgbà míran wà nígbàtí a ó ṣe àwọn àṣàyàn òmùgọ̀. Ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà, tí Olùgbàlà wa pèsè, njẹ́ kí a ṣe àtúnṣe àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀nà wa, kí a lè padà sí ipá ọ̀nà èyí tí yíó darí wa sí sẹ̀lẹ́stíà ológo tí à nwá.

Njẹ́ kí a le mú ìgboyà wa dúró láti dojúkọ ìfohùnṣọ̀kan. Njẹ́ láé kí a le máa yan èyítí ó tọ́ tí ó le jù, dípò àṣìṣe tí ó rọrùn jù.

Bí a ṣe ngbèrò àwọn ìpinnu tí à nṣe ní ìgbé ayé wa lójojúmọ́—bóyá láti ṣe yíyàn èyí tàbí yíyàn tọ̀hún—bí a bá yan Krístì, yío jẹ́ pé a ti ṣe yíyàn tí ó pé.

Kí èyí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àdúrà àtọkànwá àti ìrẹ̀lẹ̀ mi ní orúkọ Jésù Krístì, Olúwa àti Olùgbàlà wa, àmín.

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Tí a yọ kúrò nínú Lewis Carroll, àwọn Ìdáwọ́lé ti Alice ní Ilẹ̀ ìyanu (1898), 89.