2016
Bàbá wa, Olùtọ́nisọ́nà wa
OṢù Òkúdu 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹfà ọdún 2016

Bàbá Wa, Olùtọ̀nisọ́nà Wa

Njẹ́ ẹ ti ṣí àpótí kan ti ó ní àwọn ẹ̀yà rí, tí ẹ fa ìwé àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ́ni nípa àtòpọ̀ wọn jade, tí ẹ sì ròó pé, Èyí kó mú ọgbọ́n kankan wá rárá?

Ní àwọn ìgbà míràn, pẹ̀lú pé àwọn èrò inú àti ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni wa dára jùlọ, à nfa ẹ̀yà kan jade a sì nbèèrè pé, Kíni èyíinì wà fún? tàbí Báwo ni èyíinì ṣe bámu?

Ìjákulẹ̀ wa npọ̀ síi bí a ṣe nwo àpótí náà tí a sì nṣe àkíyèsí ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ kan tí ó sọ pé, Ó nílò Àtòpọ̀—ẹni ọdún mẹ́jọ sókè. Nítorí síbẹ̀ a kò tíì ní amọ̀nà kan, èyí kò mú ìgbẹ́kẹ̀lé wa gbèrú síi tàbí ìgbéra ẹni níyì wa.

Ní àwọn ìgbà míràn a nní irú ìrírí kan náà pẹ̀lú ìhìnrere. Bí a ṣe nwo àwọn apákan rẹ̀, a lè ha orí wa kí a sì ro ohun tí apákan náà wà fún. Tàbí bí a ṣe nṣe àyẹ̀wò apákan mìíràn, ó le yé wa, àní lẹ́hìn títiraka pẹ̀lú agbára láti ní òye ní kíkún, pé a kò lè fi òye gbé ìdí rẹ̀ tí apákan náà fi jẹ́ fi wà nínú rẹ̀.

Bàbá Wa Ọ̀run Ni Olùtọ́nisọ́nà Wa

Ní rere, Bàbá wa Ọ̀run ti fún wa ní ìyanu àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ́ni kan fún síṣe ètò ìgbé ayé wa àti ní ṣíṣe àkópọ̀ àwọn ibi tí a dára sí jùlọ. Àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ́ni wọ̃nnì nṣiṣẹ́ láìka ọjọ́ orí tàbí ipò wa sí. Ó ti fún wa ní ìhìnrere àti Ìjọ ti Jésù Krístì. Ó ti fún wa ní ètò ìràpadà, ètò ìgbàlà, àní ètò ìdùnnú. Kò tíì fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àìsí ìdánilójú tàbí àwọn ìpèníjà ti ayé, ní sísọ pé, níhín ni ẹ lọ. Orí rere. Fi òye gbé e.

Tí a bá lè ní sùúrù nìkan kí a sì wòó pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ àti inú mímọ́, a ó ríi pé Ọlọ́run tí fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò láti ní òye dáradára síi nípa kíkún àwọn ọ̀rọ̀ ìkọni Rẹ̀ fún ìdùnnú wa nínú ayé:

  • Ó ti fún wa ní ẹ̀bùn àìníye ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó ní agbára láti jẹ́ olùtọ́ ti ara ẹni, ti ọ̀run bí a ṣe nṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ngbìyànjú láti mú àwọn èrò àti ìṣe wa sí ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

  • Ó ti fún wa ní gbogbo ààyè sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn àdúrà ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀bẹ̀ ti ọkàn òtítọ́.

  • Ó ti fún wa ní àwọn àpọ́stélì àti wòlíì òde-òní, àwọn ẹni tí ó nfi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn ní ọjọ́ wa tí wọ́n sì ní àṣẹ láti sopọ̀ tàbí fi èdìdi dì lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run.

  • Ó ti mú Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò—títò lẹ́sẹẹsẹ ti àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n nṣiṣẹ́ papọ̀ láti ran ara wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe nṣiṣẹ́ fún ìgbàlà wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù, gbígbọ̀n rìrì, àti ayọ̀ àìláfiwé.1

  • Ó ti fún wa ní àwọn ìwé mímọ́—Ọ̀rọ̀ kíkọ́ Rẹ̀ sí wa.

  • Ó ti fúnni ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbà–lódé láti ràn wá lọ́wọ́ nínú ìrìn wa ti ọmọlẹ́hìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò ìyanu wọ̀nyí ni a lè rí ní LDS.org.

Kíni ìdí tí Bàbá wa Ọ̀run ṣe fún wa ní ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Ó nífẹ́ wa. Àti pé nítorí, bí Ó ṣe sọ nípa ti Ara Rẹ̀, Èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.2

Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Bàbá Ọ̀run jẹ́ Ọlọ́run wa, àti pé Ọlọ́run jẹ́ olùtọ́nisọ́nà kan sí wa.

Bàbá wa ní Ọ̀run mọ àìní àwọn ọmọ Rẹ̀ dáradára ju ẹnikẹ́ni lọ. Ó jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ àti ògo láti ràn wá lọ́wọ́ ní ìyanà kọ̀ọ̀kan, ní fífún wa ní àwọn ohun èlò yíyanilẹ́nu ti ara àti ẹ̀mí láti ràn wá lọ́wọ́ ní ipà ọ̀nà wa láti padà sí ọ́dọ̀ Rẹ̀.

Gbogbo Bàbá Jẹ́ Olùtọ́nisọ́nà

Ní àwọn apákan ní àgbáyé, a nbu ọlá fún àwọn bàbá láti ọwọ́ àwọn ẹbí àti ẹgbẹ́ nínu Oṣù Kẹfa. Ó máa ndára nígbà gbogbo láti fi ọlá àti ìtẹríba fún àwọn òbí wa. Àwọn Bàbá a maa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun dáradára fún àwọn ẹbí wọn, wọ́n sì máa nní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìhùwàsí tí ó ṣeé mú yangàn. Méjì nínú àwọn ojúṣe tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí àwọn bàbá ní nínú ayé àwọn ọmọ wọn ni ti jíjẹ́ àpẹrẹ rere àti olùtọ́nisọ́nà. Àwọn Bàbá nṣe ju sísọ fún àwọn ọmọ wọn ohun tí ó tọ́ tàbí tí kò tọ́; wọ́n nṣe púpọ̀ ju jíju ìwé kíkà lù wọn kí wọ́n sì lérò pé wọ́n yíò fi òye gbé ìgbé ayé fúnra wọn.

Àwọn bàbá ntọ́ àwọn ọmọ wọn iyebíye sọ́nà, wọ́n sì nfi ọ̀nà tí a fi ngbé ìgbé ayé òtítọ́ hàn nípa àpẹrẹ rere wọn. Àwọn bàbá kìí fi àwọn ọmọ wọn nìkan sílẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n máa ńyára sí ìtìlẹhìn wọn, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti dìde lórí ẹsẹ̀ wọn nígbàkugbà tí wọ́n bá ṣubú. Àti nígbà míràn tí ó bá jẹ́ àbá ọgbọ́n, àwọn bàbá nfi ààyè gba àwọn ọmọ wọn láti tiraka, ní mímọ̀ pé èyí lè jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jùlọ fún wọn láti kọ́ ẹ̀kọ́.

Gbogbo Wa Jẹ́ Olùtọ́nisọ́nà

Nígbàtí àwọn bàbá ti ayé nṣe èyí fún àwọn ọmọ ti ara wọn, ẹ̀mí ìtọ́nisọ́nà jẹ́ ohun kan tí a nílò láti fi jì fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, láìka ọjọ́ orí, ibùgbé, tàbí ipò sí. Ẹ ránti pé, àwọn ọmọ Ọlọ́run jẹ́i àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa; gbogbo wa jẹ́ ẹbí ayérayé kannáà.

Nínú òye yí, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ olùtọ́nisọ́nà—kí á ní ìtara láti nawọ́ jáde kí a sì ran ara wa lọ́wọ́ láti di bí a ṣe lè dára tó jùlọ. Nítorí a jẹ́ ìran ti Ọlọ́run, a ní agbára láti dàbíi Rẹ̀. Níní ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ọmọnìkẹjì wa, pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, àti títẹ̀lé àpẹrẹ ti Krístì jẹ́ ipá ọ̀nà tààrà, tóóró, àti ti ayọ̀ padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ọ̀run.

Bí Ọlọ́run gbogbo àgbáyé bá nṣè ìtọ́jú nípa wa púpọ̀ bẹ́ẹ̀ tí Òun fi jẹ́ olùtọ́nisọ́nà sí wa, bóyá àwa náà lè nawọ́ jade sí àwọn ọmọnìkejì wa, láìka àwọ̀, ẹ̀yà, ipò ẹgbẹ́ àti ọ̀rọ̀ ajé, èdè, tàbí ẹ̀sìn wọn sí. Ẹ jẹ́ kí a di olùtọ́nisọ́nà tí ó ní ìmísí kí a sì bùkùn ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn—kìí ṣe àwọn ọmọ tiwa nìkan ṣùgbọ́n bákannáà gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run káàkiri àgbáyé.

Ẹkọ láti inú Ọrọ Yí

Ẹ lè fẹ́ bẹ̀rẹ̀ nípa bíbèèrè lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí ẹ̀ nkọ́ láti ronú nípa àkokò kan tí Bàbá Ọ̀run ti tọ́ wọn sọ́nà. Nígbànáà ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ wọn láti ronú nípa àwọn ìbáramu láàrin àsìkò náà àti àsìkò kan nígbàtí wọ́n ní ìmọ̀lára ìtọ́nisọ́nà láti ọwọ́ Bàbá wọn ti ayé. Ẹ sọ fún wọ́n láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbáramu nípa bí a ṣe tọ́ wọ́n sọ́nà. Ẹ lè pè wọ́n níjà láti gbìyànjú láti fi ara wé ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ nínú akitiyan láti jẹ́ àpẹrẹ dídára síi fún àwọn ẹlómíràn.