2016
Ìrètí ti Ìfẹ́ Ẹbí Ayérayé
OṢù Ògún 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kẹ́jọ Ọdún 2016

Ìrètí ti Ìfẹ́ Ẹbí Ayérayé

Nínú gbogbo ẹ̀bùn tí olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run ti pèsè fún àwọn ọmọ Rẹ̀, èyí tí ó tóbi jùlọ ni ìyè ayérayé (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 14:7). Ẹ̀bùn náà ni láti gbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ títí láé nínú àwọn ẹbí. Nínú àwọn ìjọba ti Ọlọ́run tó ga jùlọ nìkan, sẹ̀lẹ́stíà náà, ni ìgbé ayé ìsopọ̀ ìfẹ́ ẹbí yíò ti máa tẹ̀síwájú.

Gbogbo wa ní ìrètí fún ayọ̀ ti gbígbé nínú àwọn ẹbí olùfẹ́ni. Fún díẹ̀ lára wa, o jẹ́ ìmọ̀lára tí a kò tíì ní ìrírí rẹ̀—ìmọ̀lára kan tí a mọ̀ pé ó ṣeéṣe ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ tí a kò tíì dámọ̀. A lè ti ríi nínú ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn. Fún àwọn míràn lára wa, ìfẹ́ ẹbí ti dàbíi dídánilójú àti iyebíye síi nígbàti ikú bá yà wá kúrò lọ́dọ̀ ọmọ kan, ìyá kan, bàbá kan, arákùnrin kan, arábìnrin kan, tàbí olùfẹ́ni àti àyànfẹ́ obí àgbà kan.

Gbogbo wa ti ní ìmọ̀lára ìrètí pé ní ọjọ́ kan a tún lè ní ìmọ̀lára lẹ́ẹ̀kansii ti fífẹ́ràn àtọkànwá ti ọmọlẹ́bí náà tí a nífẹ̀ẹ́ gidi gan tí a sì ntara nísisìnyí láti gbà mọ́ra lẹ́ẹ̀kansíi.

Olùfẹ́ni Bàbá wa Ọ̀run mọ ọkàn wa. Èrò Rẹ̀ ni láti fún wa ní ìdùnnú (wo 2 Nífáì 2:25). Àti pé nítorínáà Ó fún wa ní ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ kí ayọ̀ ìsopọ̀ ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú títí láé ṣeéṣe. Nítorí Olùgbàlà já ìdè ikú, a ó jí dìde. Nítorí Ó ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a lè, nípa ìgbàgbọ́ wa àti ironúpìwàdà, di yíyẹ ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, níbi tí a ti di àwọn ẹbí papọ̀ nínú ìfẹ́ títí láé.

Olùgbàlà rán Wòlíì Èlíjàh sí Joseph Smith láti mú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà padàbọ̀sípò. (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110). Pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̃nnì ni agbára èdidì wá, ní fífi ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ó ga jùlọ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀—ìyè ayérayé nínú àwọn ẹbí tí a dì papọ̀ títí láé.

Ó jẹ́ ìfúnni kan tí olúkúlùkù ọmọ Ọlọ́run tí ó wá sínú ayé lè ní ẹ̀tọ́ sí. Ìdá kan nínú mẹ́ta lára àwọn ọmọ Ẹ̀mí Rẹ̀ kọ ìfúnni Rẹ̀ sílẹ̀ ní ayé ẹ̀mí. Nítorí àìní ìgbàgbọ́ tó àti ìṣọ̀tẹ̀ ìta gbangba, wọ́n yàn láti máṣe mọ titi láé nípa ayọ̀ ẹ̀bùn Baba Ọ̀run ti àwọn ẹbí ayérayé.

Fún àwọn wọnnì lára wa tí wọ́n ti yege ìdánwò pàtàkì nínú ayé ẹ̀mí ṣaájú ara ikú tí wọ́n sì yege láti gba ẹ̀bùn ti ara ikú, àṣàyàn nlá ti ìyè ayérayé náà ṣì jẹ́ tiwa láti ṣe. Bí a bá di alábùkún fún láti rí ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò náà, a lè yàn láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tí yíó mú wa yege fún ìyè ayérayé. Bí a ṣe nífaradà nínú ìṣòtítọ́ náà, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi ẹ̀sẹ̀ ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa múlẹ̀ pé a wà ní ipá ọ̀nà sí ìyè ayérayé, láti gbé nínú àwọn ẹbí títí láé ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.

Fún àwọn díẹ̀, ayọ̀ ayérayé náà lè dàbíi ìrètí tí ónṣàárẹ̀ tàbí tí ó tilẹ̀ nkú lọ. Àwọn òbí, àwọn ọmọ, àwọn arákùnrin, àti arábìnrin lè ti ṣe àwọn àṣàyàn tí ó dàbíi pé ó mú wọn kùnà kúrò nínú ìyè ayérayé. Àní ẹ lè wòye bóyá- a ti múu yín yege síbẹ̀ nípasẹ̀ Ètùtù ti Jésù Krístì.

Wòlíì Ọlọ́run kan ti fìgbàkàn fún mi ní ìmọ̀ràn tí ó fún mi ní àláfíà. Mo ní ìdàmú pé àwọn àṣàyàn àwọn ẹlòmíràn lè má jẹ́ kò ṣeéṣe fún ẹbí wa láti wà papọ̀ títí láé. Ó sọ pé, “Ẹ̀ ndàmú nípa wàhálà tí kò tọ́. Ẹ ṣáà gbé ní yíyẹ fún ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, àti pé àwọn ètò ẹbí yíò níyanu jù bí ẹ ṣe lérò lọ”.

Sí gbogbo àwọn wọnnì tí ìrírí araẹni wọn tàbí tí ìgbeyàwó wọn àti ọmọ—tàbí àìsí nínú èyí náà—gbé òjìji àìnípá lé orí ìrètí wọn, mo fún wọn ní ẹ̀rí mi pé: Bàbá Ọ̀run mọ̀ Ó sì fẹ́ràn yín gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀. Nígbàti ẹ wà pẹ̀lú Rẹ̀ àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ṣíwájú ayé yí, Wọ́n fi ìrètí ìyè ayérayé tí ẹ ní sínú ọkàn yín. Pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ agbára Ètùtù ti Jésù Krístì àti pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ lè ní ìmọ̀lára nísisìnyí àti pé ẹ ó ní ìmọ̀lára ní ayé tó nbọ̀ ti ìfẹ́ ẹbí tí Bàbá yín àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ fẹ́ fún un yín lọ́pọ̀lọpọ̀ lati gbà.

Mo jẹ́rí pé bí e ṣe ngbé ìgbé ayé yíyẹ fún ìjọba sẹ̀lẹ́stìà, ìlérí ti wòlíì pé “àwọn ètò ẹbí yíò níyanu ju bí ẹ ṣe lèrò lọ” yíò jẹ́ tiyín.

Ìkọ́ni látinú Ọrọ Yì

Gbèrò bíbẹ̀rẹ̀ nípa sísọ fún àwọn wọnnì tí ẹ̀ nkọ́ nípa àsìkò kan nígbàtí ẹ ti fì ìmoore hàn fún ìrètí àwọn ẹbí ayérayé. Pè wọ́n láti jíròrò lórí àwọn àsìkò nígbàtí wọ́n ti ní ìmọ̀lára ìmòòre fún àwọn ẹbí ayérayé. Bèèrè lọ́wọ́ wọn tí wọ́n bá fẹ́ran láti ṣe àbápín. Nígbànáà ẹ lè pè wọ́n láti ronú nípa àwọn ọ̀nà láti ṣe àtúnṣe àti láti gbé ní yíyẹ síi fún ìjọba sẹ̀lẹ́stíà kí ìlérí ti wòlíì nípa “àwọn ètò ẹbí … níyanu ju bí ẹ ṣe lèrò lọ” lè jẹ́ ti wọn.