2016
Ẹbí Jẹ́ Yíyàn Láti Ọwọ́ Ọlọ́run
OṢù Ọ̀wàrà 2016


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kẹ́wá Ọdún 2016.

Ẹbí Jẹ Yíyàn Láti Ọwọ Ọlọrun

Ẹfitàdúrà-tàdúràkaohunèlòyìíkíẹsìlépalatimọohuntíẹóṣeàbápín Báwo ni níní óye Ẹbí Náà: Ìkéde kan sí gbogbo ayé yíò fi mú kí ìgbàgbọ yín nínú Ọlọ́run pọ̀ si kí ẹ sì bùkún àwọn wọnnì tí ẹ nṣe ìtọjú lórí wọn nípa ìbẹniwò kikọni? Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìrànlọwọ

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ [orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀], Ẹbí Jẹ́ ti Ọlọ́run, … a ránwa létí ẹ̀kọ́ àìléérí, ni Carole M. Stephens, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbòò sọ. A kò kọ́ pé ẹbí jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan ṣùgbọ́n bakannáà pé ìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ apákan ti ẹbí Ọlọ́run. …

“…Ètò ti Bàbá fún àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ ètò ìfẹ́ kan. Ó jẹ́ ètò láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀—Ẹbí Rẹ—ṣọkan pẹ̀lú Rẹ̀.”1

Alàgbà L. Tom Perry (1922–2015) ti Iyejú àwọn Àpóstélì Mẹ́jìlá sọ pé: Bákanńaà a gbàgbọ́ pé àwọn ẹbí ìsẹ̀dálẹ̀ tí ó lágbára kìí ṣe kókó ẹ̀ka ti àwùjọ tí ó dúró déédé, ètò ọrọ̀ ajé tí ó dúró déédé, àti àṣà tí ó níye lórí tí ó dúró déédé nìkan—ṣùgbọ́n pé bákannáà wọ́n jẹ́ kókó ẹ̀ka ti ayérayé àti ti ìjọba àti àkóso ti Ọlọ́run.

“A gbàgbọ́ pé ètò ẹsẹẹsẹ àti àkóso ti ọ̀run yíò dá lórí àwọn ẹbí àti àwọn ẹbí tó pẹ̀ka jìnà.”2

Olukúlùkù, bí ó ti wù kí ọrọ ìgbeyàwó wọn rí tàbí iye ọmọ wọn,le jẹ olùgbèjà ètò Olúwa tí a ṣe àpèjúwe rẹ nínú ìkéde ẹbí, ni Bonnie L. Oscarson sọ, Ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin Gbogbogbòò. Bí ó bá jẹ ètò ti Olúwa, ó nílati jẹ ètò tiwa bákannáà3

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ

Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 2:1–3; 132:19

Ẹ̀kọ́ ti Ẹbí

Arábìnrin Julie B. Beck, Ààrẹ Gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tẹ́lẹ̀rí, kọ́ni pé ìmọ̀ Ọlọ́run nípa ẹbí gbé lé orí Ìṣẹ̀dá, Ìṣubú náà, àti Ètùtù ti Jésù Krístì:

“Ìṣẹ̀dá ti ilẹ̀ ayé pèsè ibi kan níbití àwọn ẹbí lè gbé. Ọlọ́run dá ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n jẹ́ àwọn ìlájì méjì pàtàkì ti ẹbí. O jẹ́ apákan ètò ti Bàbá Ọ̀run pé kí a so Adámù àti Éfà pọ̀ kí wọ́n ó sì di ẹbí ayérayé kan.

“… Ìṣubú Náà mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti ní àwọn ọmọkùrin àti àwọn ọmọbìnrin.

“Ètùtù ti [Krístì] fi àyè gba ẹbí láti jẹ́ síso papọ̀ fún ayérayé. O fi àyè gba àwọn ẹbí láti ní ìdàgbàsókè ayérayé àti jíjẹ́ pípé. Ètò ìdùnnú náà, tí à npè ní ètò ìgbàlà bákanńaà, ni ètò kan tí a dá fún àwọn ẹbí. …

“… Eyí ni ẹ̀kọ́ ti Krístì … Láìsí ẹbí, kò sí ètò kankan; ko sí ìdí kankan fún ìgbé ayé ikú.”4

Àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Carole M. Stephens, “Ẹbí Jẹ ti Ọlọrun” Amọ̀nà Oṣù Karun 2015, 11, 13.

  2. L. Tom Perry,” Kínìdí Ìgbeyàwó àti Ọ̀ràn Ẹbí—Níbi gbogbo ní àgbáyé,” Amọ̀nà Oṣù Karun 2015, 41.

  3. Bonnie L. Oscarson, Olùdá ààbò bo ti Ìkéde Ẹbí, Amọ̀nà, Oṣù Karun 2015, 15.

  4. Julie B. Beck, “Kíkọ́ni ní Ẹkọ́ ti Ẹbí,” Amọ̀nà Oṣù Kẹ́ta. 2011, 32, 34.

Gbèrò Èyí

Kíni ìdí ti ẹbí fi jẹ́ ẹ̀ka tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ní ìgbà yìí àti ní ayérayé?