2017
Ojúkojú
January 2017


Àwọn Ọmọdé

Ojúkojú

Ààrẹ Uchtdorf sọ pé ìhìnrere dàbí ṣíṣe àfọjúsùn A nílò láti fi ọkàn sí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Àwọn òfin tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Tí a bá dojúkọ àwọn ohun méjì wọ̀nyí, a lè ta ojukoju nígbà gbogbo!

Ya àfọjúsùn nlá kan lórí ẹ̀là ìwé. Jẹ́ kí òbí kan ka ìtòlẹ́sẹ̃sẹ tí ó tẹ̀le fún ọ. Tí ọ̀kan lórí àwọn ìtòlẹ́sẹ̃sẹ náà bá jẹ́ ohun kan tí yíò ràn wá lọ́wọ́ làti fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn, nígbànáà kọ tàbí yàá sí àárín àfọjúsùn náà.

Pín àwọn ìṣeré rẹ

Jí kándì

Lọ sí ilé ìjọsìn

Pe ẹnìkan ní orúkọ tí kò dára

Gba àdúrà rẹ

Fun ẹnìkan ní ìgbámọ́ra

Jà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábínrin rẹ