2017
Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì
May 2017


Ọ̀rọÌbẹniwò Kíkọni Oṣù Kárún Ọdún 2017

Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì

Àwòrán
Ààrẹ Thomas S. Monson

Mo rọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa láti fitàdúràtàdúrà ṣe àṣàrò àti pé ki a jíròrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ojoojúmọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo kíi yín pẹ̀lú ìyárí bí a ṣe pàdé lẹ́ẹ̀kansi ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Ṣíwájú kí ntó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi bí ìṣe ní òní, Èmi fẹ́ láti polongo àwọn tẹ́mpìlì marun titun èyí tí a ó kọ́ ní àwọn ibí wọ̀nyí: Brazil; Manila tó tóbi jìlọ, agbègbè Philippines; Nairobi, Kenya; Pocatello, Idaho, USA; àti Saratoga Springs, Utah, USA.

Ní àárọ̀ yí mo nsọ̀rọ̀ nípa agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ìlò líle tí a ní gẹ̀gẹ́bí ọmọ Ìjọ yí láti ṣe àṣàrò, jíròrò, àti láti lo ìkẹ́ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínu ayé wa. Pàtàkì níní ẹ̀rí tó dúró ṣinṣin àti èyí tó dájú nípa Ìwé Mọ́mọ́ni ni à kò lè sọ̀ jù.

À ngbé ní ìgbà ewu nlá àti ìwà ìkà. Kíni ohun tí yíò dá ààbò bò wá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ibi tó kárí ayé ní òní? Mo tẹnumọ pé ẹ̀rí tó ní okun nípa Olùgbàlà wa, Jésù Krísti, àti ìhìnrere Rẹ̀ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mu wa kọjá síbi ààbò. Tí ẹ kò bá nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójojúmọ́, jọ̀wọ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá nkàá tàdúràtàdúrà àti pẹ̀lú ìfẹ́ òdodo láti mọ òtítọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi òtítọ́ rẹ̀ hàn yín. Tí ó bá jẹ́ òótọ́—àti pé mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́ẹ̀rí pé ìgbànáà ni—Joseph Smith jẹ́ wòlíì tí ó rí Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Nítorí Iwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ni Ìjọ Olúwa ní órí ilẹ̀ ayé, àti pé oyè-àlùfáà mímọ́ ti Ọlọ́run ni a ti múpadàbọ̀sípò fún èrè àti ìbùkún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Tí ẹ kò bá ní ẹ̀rí tó dúró ṣinṣin nípa awọn wọ̀nyí, ẹ ṣe èyí tó tọ́ láti gbà á. Ó ṣe pàtàkì fún yín láti ní ẹ̀rí ti ara yín ní àwọn ìgbà ìṣòrò wọ̀nyí, nítorí ẹ̀rí àwọn ẹlòmíràn ko lè gbée yìn dúró pẹ́. Bákannáà, nígbà tí ẹ bá ti gbàá, ẹ nílò láti tọ́jú ẹ̀rí yín dáadáa ní ààyè nípa ìgbọ́nran lemọ́lemọ́ sí àwọn òfin Ọlọ́run àti nípa àdúrà ojojúmọ́ àti àṣàrò ìwé mímọ́.

Ẹ̀yìn ẹlẹgbẹ́ẹ̀ mi ọ̀wọ́n nínú iṣẹ́ Olúwa, mo rọ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa láti fi tàdúràtàdúrà ṣe àṣàrò kí a sì jíròrò lórí Ìwé ti Mọ́mọ́nì lojojúmọ́. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, a ó wà ní ipò láti gbọ́ ohùn Ẹ̀mí, láti tàpá sí àdánwò, láti borí iyèméjì àti ẹ̀rù, àti láti gba ìrànlọ́wọ́ ọ̀run ní ilé ayé wa. Ni mo jẹ́ẹ̀rí pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní orúkọ̀ Jésù Krístì, Àmín.