2017
Èrè Níní Ìfaradà Dáradára
July 2017


Ọ̀rọ̀Àjọ ÁÁRE KÍNNÍ, OṢÙ Kéje Ọdún 2017

Èrè Níní Ìfarada Dáradára

Ní ìgbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, mo sìn nínú ìjọ gẹ́gẹ́bí olùdámọ̀ràn sí ọlọ̀gbọ́n ààrẹ ẹ̀kùn kan. Ó ngbìyànjú lemọ́lemọ́ láti kọ́ mi. Mo rántí ìmọ́ràn tí ó fún mi nígbàkan: “Nígbàtí o bá pàdé ẹnìkan, ṣe wọ́n bí ẹnipé wọ́n wà nínú wàhálà líle, àti pé ìwọ ó wà ní ìbámu kọjá ìlàjì àkokò.” Nígbànáà mo rò pé ó jẹ́ oníyèméjì . Nísisìnyí, ju àádọ́ta ọdún lọ lẹ́hìn náà, mo lè rí bí ó ti ní òye ayé àti ìgbé ayé dáradára sí.

Gbogbo wa lá ní àdánwò láti dojúkọ—ní àwọn ìgbà mĩràn, àwọn àdánwò tó le gidi. A mọ̀ pé Olúwa nfi àyè gbà wá láti la àwọn àdánwò kọjá ní èrò fún wa láti di dídára àti pípéye kí a lè wà pẹ̀lú Rẹ̀ títí láé.

Olúwa kọ́ Wòlíì Joseph Smith ní ẹ̀wọ̀n Liberty pé èrè fún fífarada àdánwò rẹ̀ dáradára yíò ràn án lọ́wọ́ láti yege fún ìyè ayérayé:

“Ọmọ mi, àláfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀;

“Àti pé nígbànáà, tí o bá fi ara dàá dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga sókè; ìwọ yíò borí gbogbo ọ̀tá rẹ” (D&C 121:7–8).

Nítorínáà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ní ó nṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé wa tí ó le dàbí ẹnipé ó le láti faradà dáradára. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹbí kan bí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ohun ọ̀gbìn nígbàtí kò sí òjò r. Ó lè yà wọ́n lẹ́nu pé, “Báwo ni a ó ṣe dúro pẹ́ tó?” Ó lè rí bẹ́ẹ̀ sí ọ̀dọ́ kan tí ó ni ìdojúkọ pẹ̀lú títako àgbàrá ìdọ̀tí àti àdánwò tí ó ndìde. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ sí ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ntiraka láti gba ẹ̀kọ́ tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó nílò fún iṣẹ́ láti ṣe àtìlẹ́hìn fún ìyàwó àti ẹbí. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ sí ẹnìkan tí kò lè rí iṣẹ́ tàbí tí ó sọ iṣẹ́ nù lẹ́hìn iṣẹ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọlọ́rọ̀ ajé ṣe ntilẹ̀kùn ilé iṣẹ́ wọn. Ó lè rí bẹ́ẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìdojúkọ pẹ̀lú ìyọnu àìlera àti okun ti àgọ́ ara, èyí tí ó lè wá ní kùtùkùtù tàbí ní ọjọ́ alẹ́ fún wọn tàbí fún àwọn wọ̃nnì tí wọ́n fẹ́ràn.

Ṣugbọ́n olùfẹ́ni Ọlọ́run kan kò gbé irú ìdánwò bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ níwájú wa láti kàn rí bí a ṣe lè farada ìṣòro ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ láti rí bí a ṣe lè faradà wọ́n dáradára kí a sì di títúnṣe.

Àjọ Ààrẹ Ìkínní kọ́ Alàgbà Parley P. Pratt (1807–57) nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pèé bí ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá pé: “A ti kà ọ́ yẹ nínú iṣẹ́ tí ó nfẹ́ gbogbo ifojúsun rẹ́; … di ohun ìdọ̀tí ti a túnṣe. … O gbọ́dọ̀ farada làálàá púpọ̀, iṣẹ́ púpọ̀, àti ọ́pọ̀ àìní láti di títúnṣe ní pípé. … Bàbá rẹ̀ Ọ̀run nfẹ́ bẹ́ẹ̀; pápá Rẹ̀ ni; iṣẹ́ Rẹ̀ ni; Òun yíò sì … mú ọ́ tújúká … yíò sì gbé ó sókè.”1

Nínú ìwé Hébérù, Páùlù sọ̀rọ̀ nípa èso níní ìfaradà dáradára: “Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísisìnyí, bíkòṣe ìbànújẹ́: ṣùgbọ́n níkẹhìn a so èso àláfíà ti òdodo fún àwọn tí a ti tọ́ nípa rẹ̀” (Hebrews 12:11).

Àwọn àdánwò wa àti àwọn ìṣòrò wa yíò fún wa ní ànfààní láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti dàgbà, àní wọ́n sì lè yí ìwà àdánidá wa gan an padà. Tí a bá lè yípadà sí Olùgbàlà nínú àṣejù wa, ẹ̀mí wa lè di títúnṣe bí a ṣe nní ìfaradà.

Nítorínáà, ohun àkọ́kọ́ láti rántí ni láti gbàdúrà nígbàgbogbo (wo D&C 10:5; Alma 34:19–29).

Ohun ìkejì ni láti làkàkà léraléra láti pa àwọn òfin mọ́—èyíkéyìí àtakò , àdánwò, tàbí ìrùkèrúdò ní àyíká wa (wo Mosiah 4:30).

Ohun ìkẹ́ta tó ṣe kókó láti ṣe ni láti sin Olúwa (wo D&C 4:2; 20:31).

Nínú iṣẹ́ ìsìn ti Olùkọ́ni, a ti mọ̀ọ́ a sì ti ní ifẹ́ Rẹ̀. Tí a bá ní ìforítì nínú àdúrà àti iṣẹ́ ìsìn òdodo, a ó bẹ̀rẹ̀síí dá ọwọ́ Olùgbàlà àti agbára Ẹmí Mímọ́ mọ̀ nínú ayé wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa ti fi ìgbà díẹ̀ ṣe irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ tí a sì ti ní ìmọ̀lára ojúgbà náà. Tí o bá rònú sẹ́hìn sí ìgbà náà, ìwọ yíò rántí pé àwọn ìyípadà ti wà nínú rẹ. Àdánwò láti ṣe ibi dàbí ẹnipé ó dínkù. Ìfẹ́ láti ṣe rere pọ̀ si. Àwọn wọ̃nnì tí wọ́n mọ̀ ọ́ dáradára tí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀ lè ti sọ pé: “O ti di onínúrere àti onísùúrù síi. Ìwọ kò dà bíi ẹnìkan náà mọ́.”

Ìwọ kìí ṣe ẹnìkan náà. O ti di yíyípadà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì nítorí ìwọ gbékẹ̀lé E ní ìgbà àdánwò rẹ.

Mo ṣe ìlérí fún ọ pé Olúwa yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú àwọn àdánwò rẹ̀ tí o bá wá A tí o sì sìn Ín àti pé ẹ̀mí rẹ̀ yíò di títúnṣe nínú ètò náà. Mo pè ọ́ níjà láti gbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ sínú Rẹ̀ nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀

Mo mọ̀ pé Ọlọ́run Bàbá wà láàyè àti pé Ó ngbọ́ Ó sì ndáhùn sí gbogbo àdúrà wa. Mo mọ̀ pé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, sàn ẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa àti pé Ó nfẹ́ kí a wá sí ọ̀dọ́ Rẹ. Mo mọ̀ pé Bàbá àti Ọmọ nbojútó wa wọ́n sì ti múra ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti ní ìfaradà dáradára àti láti wá síle lẹ́ẹ̀kansi.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Ìtàn araẹni ti Parley P. Pratt, ed. Parley P. Pratt Jr. (1979), 120.