2017
A Dúpẹ Lọwọ Rẹ, Áà Ọlọrun, fún Wòlíì kan
September 2017


Ọ̀dọ̀

A Dúpẹ Lọwọ Rẹ, Áà Ọlọrun, fún Wòlíì kan

Báwo ni wòlíì wa, Ààrẹ Thomas S. Monson, ṣe ti fún ọ lókun? Kíni ìwọ yíó rántí jùlọ nípa rẹ̀? Gbèrò kíkọ nípa Ààrẹ Monson àti ìgbé ayé rẹ̀ sínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ—púpọ̀ bí ó ṣe ṣe àpèjúwe nínú ọ̀rọ̀ yí nípa ipa wòlíì kọ̀ọ̀kan tí ó rántí.

Bákannáà ẹ lè fẹ́ láti yan àyọsọ ààyò kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ẹ sì kọọ́ sí ibi tí ẹ ó ti rí i leralera, bíi orí ìlà ilé ìwé tàbí àkọsílẹ̀ nínú yàrá yín. Àní ẹ tún lè ṣe àwòrán àyọsọ jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ fóònù yín! Gbogbo ìgbà tí ẹ bá rí àyọsọ náà, ẹ lè ronú lórí pàtàkì wòlíì alààyè kí ẹ sì rantí pé òun wà níhĩn láti fẹ́ràn àti láti tọ́ wa sọ́nà lónìí