2017
Dída Ọmọlẹ́hìn tòótọ́
October 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kẹ́wá 2017

Dída Ọmọlẹ́hìn tòótọ́

Ní gbogbo ìpàdé oúnjẹ́ Olúwa, a ní ànfàní láti ṣe ìlérí fún Bàbá Ọ̀run pé a ó máa rántí Olùgbàlà nígbàgbogbo àti pé a ó máa pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ kí Ẹ̀mí Rẹ̀ lè wà pẹ̀lú wa (wo Moroni 4:3; 5:2; D&C 20:77, 79). Rírántí Rẹ̀ nígbàgbogbo yíò wá sọ́dọ̀ wá wọ́ọ́rọ́ bí a ṣe ngbé orúkọ Rẹ̀ lé orí wa. À nṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀nà púpọ̀ ṣùgbọ́n pàtàkì nígbàtí a bá sìn àwọn ẹlòmíràn ní orúkọ Rẹ̀, ka àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ Rẹ̀, tí a sì gbàdúrà láti mọ ohun tí Òun yíò fẹ́ kí a ṣe.

Ó ṣẹlẹ̀ sí mi nígbàtí mo ṣe ìrìbọmi fún ọ̀dọ́mọkùnrin kan. Mo mọ̀ pé mo ti gba ìpè láti ọwọ́ àwọn ìranṣẹ́ Olùgbàlà tí a ti yàn gẹ́gẹ́bí ìránṣẹ́ ìhìnrere kan láti kọ́ni ní ìhìnrere Rẹ̀ àti láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀ àti nípa Ìjọ òtítọ́ Rẹ̀. Ẹnìkejì ìránṣẹ́ ìhìnrere mi àti èmi ti ṣe ìlérí fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà pé yíò gba ìwẹ̀nùmọ́ nípa agbára ètùtù Jésù Krístì bí ó bá ti ronúpìwàdà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà tí ó sì ṣe ìrìbọmi láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí ó ní àṣẹ.

Bí mo ṣe gbé ọ̀dọ́mọkùnrin ná jáde láti inú omi ti ibi ìrìbọmi, ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí mi létí, “Mo ti mọ́, Mo ti mọ́.” Ní àkokò náà, mo rántí ìrìbọmi Olùgbàlà láti ọwọ́ Jòhánnù nínú Odò Jórdánì. Àní jùlọ, mo rántí pé mò nṣe iṣẹ́ ìgbanilà ti Olùgbàlà tí ó jììnde tí ó sì wà láàyè—ní ìfojúsí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́bi Jòhánnù ti jẹ́.

Fún èmi àti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, rírántí Olùgbàlà lè ju gbígbé ara lé ìrántí ìmọ̀ àti àwọn ìrírí wa pẹ̀lú Rẹ̀ lọ. A le ṣe àwọn àṣàyàn ojoojúmọ́ tí yíò fà wá súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ní ìsisìnyí.

Àṣàyàn tí ó rọrùn jùlọ lè jẹ́ láti ka àwọn ìwé mímọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè jèrè àwọn ìmọ̀lára sísún mọ́ Ọ. Fún èmi, sísún mọ́ni nwá nígbàkugba tí mo bá kà nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì. Ní àwọn ìṣẹ́jú àkọ́kọ́ tí mo ka nínú àwọn orí 2Nífáì, mo gbọ́ ohun Nífàì àti Léhì nínú mi tí wọ́n nṣe àpèjúwe Olùgbàlà bíì ípé wọ́n mọ̀ọ́ taratara. Ìmọ̀lára ìsùnmọ́ni kan nwá.

Fún ẹ̀yin, àwọn ibi míràn nínú ìwé mímọ́ ní pàtàkì lè fà yín sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ibikíbi àti ìgbàkugbà tí ẹ bá ka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ọkàn tòótọ́ láti rántí Olùgbàlà, ẹ̀yin yíò pọ̀ si nínú ìfẹ́ yín láti gbé orúkọ Rẹ̀ lé orí ara yín nínú ìgbé ayé yin ojoojúmọ́.

Ìfẹ́ náà yíò yí ọ̀nà tí ẹ fi nsìn nínú Ìjọ Olúwa padà. Ẹ̀yin yíò gbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ àní ní ṣíṣe gbígbéga ohun tí ó fi ara hàn síi yín bíi ìpè kékeré. Ìrànlọ́wọ́ tí ẹ ó bèèrè fún ni agbára láti gbàgbé ara yín kí ẹ sì kọ ojú sí ohun tí Olùgbàlà nfẹ́ fún àwọn wọnnì tí a pè yín láti sìn.

Mo ti ní ìmọ̀lára ọwọ́ Rẹ̀ àti sísúnmọ́ni Rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn mi pẹ̀lú àwọn ọmọ wa nígbàtí mo gbàdúrà láti mọ̀ bí èmi ó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àláfíà tí ìhìnrere nìkan nmú wá. Ní irú àwọn àkokò náà, èmi kò ṣe àníyàn nípa rírí ara mi bí òbí aláṣeyege, ṣùgbọ́n mo nṣe àníyàn tí ó jìnlẹ̀ nípa àṣeyege àti wíwà ní àláfíà ti àwọn ọmọ mi.

Ìfẹ́ láti fún àwọn wọnnì tí à nsìn ní ohun tí Olùgbàlà yíò fún wọn ndarí lọ sí àdúrà tí ó jẹ́ bíbẹ̀bẹ̀ sí Bàbá Ọ̀run, nítòótọ́ ní orúkọ Jésù Krístì. Nígbàtí a bá gbàdúrà ní ọ̀nà náà—ní orúkọ Olùgbàlà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀—Bàbá máa ndáhùn. Ó nran Ẹ̀mí Mímọ́ láti ṣe atọ́nà, tù wá nínú, àti lati gbà wá níyànjú. Nítorí Ẹ̀mí máa njẹ́ ẹ̀rí Olùgbàlà nígbà gbogbo (wo 3 Nífáì11:32, 36; 28:11; Étérì 12:41), agbárà wa làti ni ìfẹ̀ Oláwa pẹ̀lu gbogbo ọkan wa,inú, àtni agbára npọ́ si lwo (see Márkù 12:30; Lúkù 10:27; D&C 59:5).

Àwọn ìbùkún rírántí lójoojúmọ́ àti ìsisìnyí yíò wá díẹ̀díẹ̀ àti jẹ́jẹ́ bí a ṣe nsìn Ín, tí a nṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Rẹ̀, tí a sì ngbàdúrà nínú ìgbàgbọ́ ní orúkọ Rẹ̀. Àti pe rírántí yìí yíò tún wa ṣe láti di ọmọlhìn Olúwa Jésù Krístì ní tòótọ́ nínú ìjọba Rẹ̀ lórí ilẹ̀ aye—àti pé lẹ́hìn náà pẹ̀lú Bàbá Rẹ̀ nínú ayé ológo tí ó nbọ̀.